ثَلَاثَةُ الأُصُولِ وَأَدِلَّتُهَا
Awọn ipilẹ mẹta ati awọn ẹri rẹ
لِلشَّيْخِ
مُحَمَّدٍ التَّمِيمِي رَحِمَهُ اللهُ
Sheikh Muhammad At-Tamimi - kí Ọlọhun ba wa kẹ ẹ - ni o kọ
بِسْمِ اللهِ الرَّحمَنِ الرَّحِيمِ
Awọn ipilẹ mẹta ati awọn ẹri rẹ
Ni orukọ Ọlọhun Ọba Ajọke aye Aṣakẹ ọrun
Mọ̀ - kí Ọlọhun kẹ́ ọ - pé ó ṣe dandan fún wa láti kọ́ àwọn ọrọ àgbéyẹ̀wò mẹrin kan:
Akọkọ ni : Imọ, oun ni mimọ Ọlọhun, ati mimọ Anabi Rẹ, ati mimọ ẹsin Islām pẹlu awọn ẹri.
Ẹlẹẹkeji ni : Ṣiṣe àmúlò rẹ.
Ikẹta ni : Pipepe si bẹ.
Ẹlẹẹkẹrin ni : Ṣiṣe suuru lori ṣuta tí o wa níbẹ .
“Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-: “Pẹlu orúkọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ ayé Aṣakẹ ọrùn”
﴿وَٱلۡعَصۡرِ1 إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَفِي خُسۡرٍ2 إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡحَقِّ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ3﴾
(Allāhu fi àkókò ìrọ̀lẹ́ ayé búra.
Dájúdájú ènìyàn wà nínú òfò.
Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo láààrin ara wọn, tí wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ sùúrù láààrin ara wọn).
[Suuratul-Asr: 1-3].
Imaamu Shaafi'hi - ki Ọlọhun ti ọla Rẹ ga kẹ ẹ - sọ pe: "Ti Ọlọhun ko ba sọ ẹri kankan kalẹ fun awọn ẹda Rẹ ayafi suurah yii, iba to wọn."
Atipe Bukhaariy – ki Ọlọhun ti O ga kẹ ẹ – sọ pe: ""Orí ọ̀rọ̀: Ìmọ̀ ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ; ati pe ẹri rẹ ni ọrọ Rẹ -ti ọla Rẹ ga- pe: (Nitori naa, mọ pe dajudaju ko si ọlọhun tòótọ́ láti jọsin fún ayaafi Ọlọhun Allahu, ki o si tọrọ aforijin fun ẹṣẹ rẹ...) [Muhammad: 9], "Ó bẹrẹ pẹlu ìmọ̀" ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ.""
Lọ Mọ - ki Ọlọhun kẹ ọ -: pe dajudaju o jẹ dandan fun gbogbo Musulumi ọkunrin ati Musulumi obinrin, kikọ awọn akori ọrọ mẹta yii, ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu wọn:
Akọkọ ni pe : dájúdájú Ọlọhun da wa, O si pèsè ijẹ-imu fun wa, ko si fi wa silẹ lasan; kàkà bẹ́ẹ̀, O ran Ojiṣẹ kan si wa, ẹni tí ó bá tẹle e; yóò wọ Alujanna, ẹni tí ó bá si yapa rẹ; yóò wọ iná.
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿إِنَّآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡكُمۡ رَسُولٗا شَٰهِدًا عَلَيۡكُمۡ كَمَآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ رَسُولٗا15 فَعَصَىٰ فِرۡعَوۡنُ ٱلرَّسُولَ فَأَخَذۡنَٰهُ أَخۡذٗا وَبِيلٗا16﴾
(Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon. *
Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle).
[Al-Muzzammil: Ayah 15-16].
Èkejì ni pé : dajudaju Ọlọhun kò yọnu kí a fi ẹnikẹni ṣe orogún papọ mọn Ọlọhun níbi ìjọsìn fún Un, ki baa jẹ iransẹ tí o sunmọ Ọlọhun tàbí anọbi tí wọ́n ran niṣẹ; ẹ̀rí rẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tó sọ pé:
﴿وَأَنَّ ٱلۡمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدۡعُواْ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدٗا18﴾
(Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu).
[Sūrah Al-Jinni: āyah 18].
Ìkẹta ni pe : ẹni ti o ba tẹle Ojiṣẹ ti o si ṣe Ọlọhun ni Ọkan soso ; ko tọ fun un ki o rọ̀ mọ́ tabi ki o ba ẹni ti o tako Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ṣe papọ, koda ki o jẹ ibatan ti o sunmọ julọ.
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿لَا تَجِدُ قَوۡمٗا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ يُوَآدُّونَ مَنۡ حَآدَّ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَوۡ كَانُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ أَوۡ أَبۡنَآءَهُمۡ أَوۡ إِخۡوَٰنَهُمۡ أَوۡ عَشِيرَتَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَأَيَّدَهُم بِرُوحٖ مِّنۡهُۖ وَيُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ أُوْلَٰٓئِكَ حِزۡبُ ٱللَّهِۚ أَلَآ إِنَّ حِزۡبَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ22﴾
(Ọ kó ò níí rí ìjọ kan tó ni igbàgbọ́ sí Ọlọhun Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì fi ẹ̀rí òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè).
[Suratul Mujaadalah :22].
Mọ̀ - ki Allahu ṣe itọsọna rẹ si ibi itẹle asẹ Rẹ - pe: Dajudaju Al-Haneefiyyah - tii se ìlànà Anabi Ibrahim - ni pe ki o jọsin fun Allahu ni Oun nikan ṣoṣo ni ṣiṣe afọmọ ẹsin fun Un, ati pe iyẹn ni Allahu pa ni aṣẹ fun gbogbo eniyan, ti O si ṣẹda wọn nitori rẹ; gẹgẹ bi Allahu ti ọla Rẹ ga se sọ pe:
﴿وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ56﴾
( Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi). [Suuratudh Dhāriyāt: 56], Àti pé ìtumọ̀ "jọ́sìn fún Mi" ni: kí wọ́n ṣe Mi ní Ọ̀kan ṣoṣo.
Ati pe eyi ti o tobi julọ ninu nnkan ti Ọlọhun pa laṣẹ pẹlu rẹ ni: Ṣiṣe Ọlọhun lọ́kan, oun ni: imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin.
Ati pe eyi ti o tobi julọ ninu ohun ti O kọ̀ ni: Ẹbọ, oun ni: pipe ẹni ti o yatọ si I pẹlu Rẹ.
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗا...﴾
( Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan pẹlu Rẹ ni bí ìjọsìn Fún ). [An-Nisaa: 36].
Tí wan bá sọ fún ọ pé: Kí ni awọn ipilẹ mẹta tí nini imọ nipa rẹ jẹ dandan fún ènìyàn?
Sọ pé: Ki ẹrusin mọ Oluwa rẹ, ati ẹsin rẹ, ati Anabi rẹ Muhammad- ki ikẹ ati Ọla Ọlọhun maa ba a.
[Ipilẹ Alakọkọ]
"Ti wan ba sọ fun ọ pe: Ta ni Olúwa rẹ?"
Sọ pé: Allāhu ni Olúwa mi, Ẹni tí Ó tọ́ mi, tí Ó sì tọ́ gbogbo ẹ̀dá pẹ̀lú àwọn ìdẹ̀ra Rẹ̀. Òun sì ni Ẹni tí mo ń jọ́sìn fún, kò sí ẹni tí mo ń jọ́sìn fún kankan àfi Òun; ẹ̀rí rẹ̀ sì ni ọrọ Ọlọhun Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga ti O sọ pé:
﴿ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ2﴾
(Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá). [Sūratul Fātiha: 2]. Àti pé gbogbo ohun tí ó yàtọ̀ sí Allāhu, ẹ̀dá ni, èmi sì jẹ́ ọ̀kan nínú awan ẹ̀dá náà.
Nitori naa, ti wọn ba sọ fun ọ pe: "Ki ni o fi mọ Olúwa rẹ?"
Sọ pé: Pẹ̀lú àwọn àmì Rẹ̀ àti àwọn ẹ̀dá Rẹ̀.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá.
Àti pé nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ ni: àwọn sánmọ̀ méje àti àwọn nkán tí ń bẹ nínú wọn, àti àwọn ilẹ̀ méje àti àwọn nkan tí ń bẹ nínú wọn, àti n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin méjèèjì.
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلَّيۡلُ وَٱلنَّهَارُ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُۚ لَا تَسۡجُدُواْ لِلشَّمۡسِ وَلَا لِلۡقَمَرِ وَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ ٱلَّذِي خَلَقَهُنَّ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ37﴾
(Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ kò gbọ́dọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni tó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo). [Sūratu Fussilat: 37].
Ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُغۡشِي ٱلَّيۡلَ ٱلنَّهَارَ يَطۡلُبُهُۥ حَثِيثٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ وَٱلنُّجُومَ مُسَخَّرَٰتِۭ بِأَمۡرِهِۦٓۗ أَلَا لَهُ ٱلۡخَلۡقُ وَٱلۡأَمۡرُۗ تَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ54﴾
(Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá). [Ṣūratul A‘rōf: 54].
Oluwa, Oun ni Ẹni ti a n jọsin fun; Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ21 ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ فِرَٰشٗا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءٗ وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجَ بِهِۦ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ رِزۡقٗا لَّكُمۡۖ فَلَا تَجۡعَلُواْ لِلَّهِ أَندَادٗا وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ22﴾
(Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó dá ẹ̀yin àti àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè máa bẹ̀rù Allāhu (kí ẹ sì lè ṣọ́ra fún ìyà Iná ) 21.
(Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí), Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ (fún yín), Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́). [Suratul Baqarat: 21-22].
Ibnu Katheer -ki Ọlọhun ti ọla Rẹ ga kẹ ẹ- sọ pe: Aṣẹda awọn nkan wọnyi, Oun ni Ẹni ti O lẹtọọ si ijọsin.
Ati awọn iran ijọsin ti Ọlọhun palaṣẹ: - Gẹgẹ bii: Islam ( ijẹ Musulumi) , ati Igbagbọ , ati Ihsan ( ise daada ) ; ati pe ninu rẹ ni: adua ( ijirẹbẹ ) , ati ibẹru, ati irankan, ati gbigbẹkẹle, ati iṣeoju kòkòrò, ati ìpayà, ati irẹrasilẹ, ati iwarìrì, ati idari sí ọdọ Ọlọhun, ati iwa iranlọwọ, ati iwa iṣora, ati iwa ìgbàlà, ati didu ẹran tàbí nkán ọsin, ati ileri, ati eyi ti o yatọ si i ninu awọn iran ijọsin ti Ọlọhun pa ni aṣẹ - gbogbo rẹ wa fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga; ati pe ẹri rẹ ni: ọrọ Rẹ ti ọla Rẹ ga:
﴿وَأَنَّ ٱلۡمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدۡعُواْ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدٗا18﴾
(Dájúdájú àwọn mọ́sálásí àti ààyè iforikọnlẹ ti Allāhu nii ṣe . Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu). [Sūrah Al-Jinni: āyah 18].
Nitori naa, ẹnikẹni tí ó bá ṣe kankan ninu rẹ fún nǹkan tí ó yàtọ̀ sí Ọlọhun; onitọhun jẹ́ ooṣẹbọ, kèfèrí; ati pe ẹri ni ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَمَن يَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ لَا بُرۡهَٰنَ لَهُۥ بِهِۦ فَإِنَّمَا حِسَابُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ117﴾
(Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò sí ẹ̀rí fún lórí rẹ Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè).
[Al-Mu'minuun: 117].
Atipe ọ wa ninu hadith pé :
"الدُّعَاءُ مُخُّ العِبَادَةِ".
“Adua ni koko ( ọpọlọ fún ) ìjọsìn.”
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدۡعُونِيٓ أَسۡتَجِبۡ لَكُمۡۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِي سَيَدۡخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ60﴾
(Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ). [Gaafir: 60].
Ẹri fún ìbẹ̀rù ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...فَلَا تَخَافُوهُمۡ وَخَافُونِ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ﴾
(ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo). [Āli ‘Imrān: 175].
Ẹri ti ọ wá fún ireti ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...فَمَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلۡيَعۡمَلۡ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَلَا يُشۡرِكۡ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدَۢا﴾
( ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀ (kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ sí Olúwa rẹ̀).
[Al-Kahf: 110].
Ẹri gbigbarale Ọlọhun ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga:
﴿...وَعَلَى ٱللَّهِ فَتَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ﴾
(Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo). [Al-Maahidah: 23], ati ọrọ rẹ ti o sọ pe:
﴿...وَمَن يَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِ فَهُوَ حَسۡبُهُ...﴾
(Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Óun náà yóò máa tó o). [At-Tolāq: 3].
Atipe ẹri ireti, ipaaya, ati irẹlẹ ọkan ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...إِنَّهُمۡ كَانُواْ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِ وَيَدۡعُونَنَا رَغَبٗا وَرَهَبٗاۖ وَكَانُواْ لَنَا خَٰشِعِينَ﴾
(Wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrẹlẹ okọn àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa). [Suuratul Anbiyaah: 90].
Ẹri ti o wa fún ìbẹ̀rù ni: Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga julọ-:
﴿...فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِ...﴾
(ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi) [Al'Maa'idah 3].
Ẹri ìdarí sí Ọdọ Ọlọhun ni: Ọ̀rọ̀ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَأَنِيبُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَأَسۡلِمُواْ لَهُ...﴾
(Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un...) [Az-Zumar: 54].
Atipe ẹri wiwa iranlọwọ ni: Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga julọ -:
﴿إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ5﴾
(Ìwọ nìkan ṣoṣo ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá ìrànlọ́wọ́ sí) . [Al-Faatiha: 5],
Atipe o wa ninu hadith pe :
"إِذَا اسْتَعَنْتَ فَاسْتَعِنْ بِاللَّهِ".
"Ti ọ ba fẹ wa iranlọwọ, Ọlọhun ni ki o wa iranlọwọ Rẹ."
Ẹri wiwa isadi ni; Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga julọ-:
﴿قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلۡفَلَقِ1﴾
(Sọ pé: “Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù).
[Al-Falaq:1], ati
﴿قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ1﴾
(Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn).
"[An-Nās:1]."
Ẹri titọrọ ìgbàlà tàbí akoyọ ninu ewu ni: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga julọ-:
﴿إِذۡ تَسۡتَغِيثُونَ رَبَّكُمۡ فَٱسۡتَجَابَ لَكُمۡ...﴾
(Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn..). [Surah Al-Anfâl: 9].
Ẹri pipa ẹran tàbí didu nkan ọsin ni: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿قُلۡ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحۡيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ162 لَا شَرِيكَ لَهُ...﴾
(Sọ pé: “Dájúdájú ìrun mi, ẹran (pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá).
Kò sí akẹgbẹ́ fún Un... [Al-An’am: 162-163],
Ọ wa Ninu Sunnah:
"لَعَنَ اللَّهُ مَنْ ذَبَحَ لِغَيْرِ اللَّهِ".
"Ọlọhun ń ṣẹbi le ẹni tó bá du nkan fún ohun tó yàtọ̀ si Ọlọhun".
Ẹri Ìlérí ni: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga julọ-:
﴿يُوفُونَ بِٱلنَّذۡرِ وَيَخَافُونَ يَوۡمٗا كَانَ شَرُّهُۥ مُسۡتَطِيرٗا7﴾
(Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an). [Al-Insaan:7].
[Ipilẹ keji]
Mimọ ẹsin Isilaamu pẹlu awọn ẹri, oun ni: Jijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun pẹlu gbigba A lọkan ṣoṣo, ati gbigba fun Un pẹlu itẹle aṣẹ Rẹ̀, ati ibọpa-bọsẹ kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹlẹbọ.
O si ni ipò tabi ipele mẹta : Isilaamu, ati Igbagbọ, ati Ṣíṣe dáadáa.
Àti pé ipele kọ̀ọ̀kan ni ó ní àwọn orígun.
Marun ni àwọn origun Islaam jẹ́ : ìjẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọsìn ododo tọ́ sí àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Muhammad òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, àti gbígbé irun dúró, àti yíyọ Zakah, àti gbígba ààwẹ̀ Ramadān, àti ṣíṣe Hajj (lilọ sí) Ilé Ọlọ́run ile ọwọ.
Ẹri ijẹri ni; Ọ̀rọ̀ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَأُوْلُواْ ٱلۡعِلۡمِ قَآئِمَۢا بِٱلۡقِسۡطِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ18﴾
(Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n).
[Aal Im’raan: 18].
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé: Ko si ẹni ti a le maa jọ́sìn fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayaafi Allāhu.
"“Lā ilāha” ti o n ṣe ikọsilẹ fún gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun."
"Illā Allāhu" ti o ń fi ẹsẹ ìjọ́sìn múlẹ̀ fún Ọlọ́hun ní Oun nìkan.
Ko ni orogun nibi ijọsin Rẹ, gẹgẹ bi o ti jẹ pe ko ni igbakeji nibi ọlá Rẹ.
Ati pe alaye rẹ eyi ti o nṣe afihan rẹ ni: Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦٓ إِنَّنِي بَرَآءٞ مِّمَّا تَعۡبُدُونَ26 إِلَّا ٱلَّذِي فَطَرَنِي..﴾
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi). [Surah Az-Zukhruf: 26-27] ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿قُلۡ يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ تَعَالَوۡاْ إِلَىٰ كَلِمَةٖ سَوَآءِۭ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمۡ أَلَّا نَعۡبُدَ إِلَّا ٱللَّهَ وَلَا نُشۡرِكَ بِهِۦ شَيۡـٔٗا وَلَا يَتَّخِذَ بَعۡضُنَا بَعۡضًا أَرۡبَابٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِۚ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقُولُواْ ٱشۡهَدُواْ بِأَنَّا مُسۡلِمُونَ64﴾
(Sọ pé: “Ẹ̀yin tí wan ti fún ni tira ṣiwaju, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan tó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa). [Aal Im’raan: 64].
Ati ẹrí ti ọ wá fún pe Muhammad òjíṣẹ Ọlọhun ni; ni ọrọ Rẹ ti O ga:
﴿لَقَدۡ جَآءَكُمۡ رَسُولٞ مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ عَزِيزٌ عَلَيۡهِ مَا عَنِتُّمۡ حَرِيصٌ عَلَيۡكُم بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ رَءُوفٞ رَّحِيمٞ128﴾
( Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó wàhálà ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore) fún yín; aláàánú àti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo). [Sūratut Taobah: 128].
Ati pe itumọ jijẹrii pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni: òun ni Titẹle e nibi nkan ti o ba pa laṣẹ, ati gbigba a ni ododo nibi iro ti o ba muwa, ati jijina si nkan ti o ba kọ funni kuro nibẹ ti o si tun leni jina si, ati pe a ko gbọdọ jọsin fun Ọlọhun ayaafi pẹlu nkan ti o ba ṣe lofin.
Ẹri irun, ati Zakaah, ati itumọ nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo ni: ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga - to sọ pe:
﴿وَمَآ أُمِرُوٓاْ إِلَّا لِيَعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلۡقَيِّمَةِ5﴾
(Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀).
[Al-Bayyinah:5].
Ẹri aawẹ ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ183﴾
(Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ ní ọ̀ran-anyàn fún yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu))
[Al-Baqara 183].
Ẹri hajj ni: Ọ̀rọ̀ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...وَلِلَّهِ عَلَى ٱلنَّاسِ حِجُّ ٱلۡبَيۡتِ مَنِ ٱسۡتَطَاعَ إِلَيۡهِ سَبِيلٗاۚ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ﴾
(Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé Rẹ ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá) [Aal Im’raan: 97].
«Ipele keji: Igbagbọ; oun si ni: ẹka aadọrin ati diẹ, eyi to ga julọ nibẹ ni gbólóhùn: Laa ilaaha illallohu, ati eyi to kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro ni oju-ọna, ati pe itiju jẹ ẹka kan ninu igbagbọ»
Awọn origun rẹ mẹfa ni: ki o gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, ati awọn malaaikah Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati kadara; ( eto Ọlọhun lórí gbogbo nkan tí o da ) èyí ti o daa nibẹ ati èyí ti o buru.
Atipe ẹri lori awọn origun mẹfẹẹfa yii ni Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿لَّيۡسَ ٱلۡبِرَّ أَن تُوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ قِبَلَ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ وَٱلۡكِتَٰبِ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ...﴾
(Kì í ṣe ohun rere ni pé, kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni tó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ojiṣẹ Ọlọhun).
[Suuratul Baqara: 177].
Ẹri Kadara ni; Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga julọ:
﴿إِنَّا كُلَّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَٰهُ بِقَدَرٖ49﴾
(Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá (agbe kalẹ eto). [Suratul Qomar: 49].
Ipele kẹta: Iṣe Daadaa -origun kan ni-, oun ni ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba ri I, dajudaju Oun n ri ẹ.
Ẹri ni Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّٱلَّذِينَ هُم مُّحۡسِنُونَ128﴾
(Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn tó ń ṣe rere). [An-Nahl: 128].
ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ217 ٱلَّذِي يَرَىٰكَ حِينَ تَقُومُ218 وَتَقَلُّبَكَ فِي ٱلسَّٰجِدِينَ219﴾
(Kí o sì gbáralé Alágbára ( Oba pàtàkì ) , Àṣàkẹ́-ọ̀run);*
( Ẹni tó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)*
( àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀). [As-Shuaraa' 217-219].
ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿وَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٖ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٖ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِ...﴾
( Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é...)
[Yunus: 61] Aayah.
Ẹri lati inu Sunnah ni: Hadisi Jibril ti o gbajumọ, lati ọdọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
"بَيْنَمَا نَحْنُ عِنْدَ رَسُولِ اللَّهِ ﷺ ذَاتَ يَوْمٍ، إِذْ طَلَعَ عَلَيْنَا رَجُلٌ، شَدِيدُ بَيَاضِ الثِّيَابِ، شَدِيدُ سَوَادِ الشَّعَرِ، لَا يُرَى عَلَيْهِ أَثَرُ السَّفَرِ، وَلَا يَعْرِفُهُ مِنَّا أَحَدٌ، حَتَّى جَلَسَ إِلَى النَّبِيِّ ﷺ فَأَسْنَدَ رُكْبَتَيْهِ إِلَى رُكْبَتَيْهِ، وَوَضَعَ كَفَّيْهِ عَلَى فَخِذَيْهِ، وَقَالَ: يَا مُحَمَّدُ !
«Laarin igba ti a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ọjọ kan, ni arakunrin kan ba yọ si wa lo jiji, aṣọ rẹ si funfun gbòò, irun ori rẹ si dudu kirikiri, ko si àpẹẹrẹ irin-ajo kankan lara rẹ, ẹnikankan o si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jokoo si ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o wa fi orunkun rẹ mejeeji ti orunkun rẹ mejeeji, o si gbe ọwọ rẹ mejeeji le ori itan rẹ mejeeji, o wa sọ pe: Irẹ Muhammad!»
أَخْبِرْنِي عَنِ الإِسْلَامِ؟
Fun mi niro nipa Islam?
فَقَالَ رَسُولُ اللَّهِ ﷺ: الإِسْلَامُ: أَنْ تَشْهَدَ أَلَّا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ، وَتُقِيمَ الصَّلَاةَ، وَتُؤْتِيَ الزَّكَاةَ، وَتَصُومَ رَمَضَانَ، وَتَحُجَّ البَيْتَ إِنِ اسْتَطَعْتَ إِلَيْهِ سَبِيلًا، قَالَ: صَدَقْتَ - فَعَجِبْنَا لَهُ، يَسْأَلُهُ وَيُصَدِّقُهُ –.
Ojiṣẹ Ọlọ́run (kí ikẹ ati ọla Rẹ máa bá a) sì sọ pé: Islaam ni kí o jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọsìn ododo tọ́ sí àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Muhammad òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, kí o máa gbé irun dúró, kí o máa yọ Zakah, kí o máa gba ààwẹ̀ Ramadān, kí o sì ṣe abẹwo pẹlu ṣiṣe Hajj sí Ilé Ọlọ́run tí o bá ní agbára láti dé ibẹ̀, ó sọ pé: O sọ òótọ́ - ọ sì yà wá lẹnu fún un pé , ó ń bi í léèrè, ó sì ń jẹ́rìí sí i pé ó sọ òótọ́ -.
قَالَ: فَأَخْبِرْنِي عَنِ الْإِيمَانِ؟
O sọ pe: Fun mi ni iro nipa igbagbọ?
قَالَ: أَنْ تُؤْمِنَ بِاللَّهِ، وَمَلَائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ، وَرُسُلِهِ، وَاليَوْمِ الْآخِرِ، وَتُؤْمِنَ بِالقَدَرِ خَيْرِهِ وَشَرِّهِ، قَالَ: صَدَقْتَ.
O sọ pe: Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o ni igbagbọ ninu kadara eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru, o sọ pe: O sọ ootọ.
قَالَ: فَأَخْبِرْنِي عَنِ الْإِحْسَانِ؟
O sọ pé: Sọ fún mi nípa dáadáa?
قَالَ: أَنْ تَعْبُدَ اللَّهَ كَأَنَّكَ تَرَاهُ، فَإِنْ لَمْ تَكُنْ تَرَاهُ فَإِنَّهُ يَرَاكَ.
O ni: Ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba tilẹ ri I, dajudaju Oun n ri ẹ.
قَالَ: فَأَخْبِرْنِي عَنِ السَّاعَةِ؟
Ó sọ pé: Sọ fún mi nípa Àkókò náà?
قَالَ: مَا المَسْؤُولُ عَنْهَا بِأَعْلَمَ مِنَ السَّائِلِ.
O sọ pé: Ẹni tí wọ́n bi ni ibeere nipa rẹ kò ni imọ ju ẹni tí ó n beere lọ.
قَالَ: فَأَخْبِرْنِي عَنْ أَمَارَاتِهَا؟
O sọ pe: Sọ fun mi nipa awọn ami rẹ?
قَالَ: أَنْ تَلِدَ الأَمَةُ رَبَّتَهَا، وَأَنْ تَرَى الحُفَاةَ العُرَاةَ العَالَةَ رِعَاءَ الشَّاءِ، يَتَطَاوَلُونَ فِي البُنْيَانِ.
Ó sọ pé: "Kí ẹrúbìnrin bí ọ̀gá rẹ̀, àti kí o rí àwọn aláìní bàtà, aláìláṣọ, aláìní, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ( alaai wọ bàtà ), tí wọ́n ń bá ara wọ́n díje nínú kíkọ́ ilé gíga."
قَالَ: ثُمَّ انْطَلَقَ فَلَبِثْتُ مَلِيًّا، ثُمَّ قَالَ لِي: يَا عُمَرُ! أَتَدْرِي مَنِ السَّائِلُ؟ قُلْتُ: اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: فَإِنَّهُ جِبْرِيلُ، أَتَاكُمْ يُعَلِّمُكُمْ دِينَكُمْ".
O sọ pe: Lẹ́yìn naa o pẹyin da, mo wa wa nibẹ fun ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà ni o wa sọ fún mi pe: Irẹ Umar! Ǹjẹ́ o mọ onibeere naa? Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: Dajudaju Jibril ni, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin.
[Ipilẹ kẹta]
Mímọ Anabi yin Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a -, oun ni Muhammad ọmọ Abdullah ọmọ Abdul Muttalib ọmọ Hāshim, ti Hāshim wa lati idile Quraysh, ti Quraysh wa lati iran larubawa, ti larubawa si jẹ arọmọdọmọ Ismā‘īl ọmọ Ibrāhīm ààyò Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla ti o lọla julọ maa ba oun ati Anabi wa -.
Ọmọ ọdún mẹtalelọgọta ni o jẹ - o lo ogójì ọdún ṣíwájú ki o to di ojiṣẹ, o si lo ọdún mẹtalelogun ni ijẹ anọbi ati ojiṣẹ.
A sọ ọ́ di Ànnábì pẹ̀lú igba ọrọ b'Iqra'', a sì rán an ní Òjíṣẹ́ pẹ̀lú igba ọrọ 'al-Muddaththir', ìlú rẹ̀ sì ni Makkah.
Ọlọhun gbe e dide pẹlu ikilọ kuro nibi ẹbọ, ati pipepe lọ sibi mimọ Ọlọhun lọkan ṣoṣo ; ẹri si ni ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti O sọ pe:
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُدَّثِّرُ1 قُمۡ فَأَنذِرۡ2 وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ3 وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ4 وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ5 وَلَا تَمۡنُن تَسۡتَكۡثِرُ6 وَلِرَبِّكَ فَٱصۡبِرۡ7﴾
( Ìwọ olùdaṣọbora.
Dìde kí o ṣè ikìlọ̀.
Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
kí ọ yaa jìnnà sí ẹbọ , fi óòsa ṣíṣe silẹ
Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún). [Al-Muddathir: 1-7]
Itumọ̀ ọrọ Ọlọhun pe :
﴿قُمۡ فَأَنذِرۡ﴾
( Dìde kí o ṣè ikìlọ̀). Ó ń kìlọ̀ kúrò níbi mimu orogun pẹlu Ọlọhun Ọba, ó sì ń pèpé lọ sí ibi mímọ Ọlọhun ní Ọkan ṣoṣo.
﴿وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ﴾
( Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún).
O túmọ̀ si pe: Gbé E tobi pẹlu mimọ Ọlọhun ni ọkan.
﴿وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ﴾
(Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́).
Ìyẹn ni pe: Fọ awọn iṣẹ rẹ mọ kuro nibi ẹbọ sise.
﴿وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ﴾
(Òrìṣà ni kí o jìnnà sí).
Òrìṣà: Àwọn ère. Ati jíjìnnà sí i: gbigbe e ju silẹ, ati
Ibọpa bọsẹ kuro ninu rẹ ati lọdọ awọn eniyan rẹ.
O lo ọdun mẹ́wàá lori eyi ti o n pepe si imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo, lẹyin ọdun mẹ́wàá naa; ni wọn gbe e goke lọ si sanma, ti wọn si ṣe awọn irun marun-un ni ọran-anyan le e lori, o si ki irun ni Mẹka fun ọdun mẹta, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ ki o ṣe hijira lọ sí ìlú Madina.
Hijira ni : kikuro ni ilu ẹbọ lọ sí ilu Islam.
Ati pe Hijira jẹ ọranyan lori ijọ yii lati kuro ni ilu ẹbọ lọ sí ilu Islam, ó sì máa wà títí tí Asiko igbẹhin aye yóò fi wáyé
Ẹri ni Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡ قَالُواْ فِيمَ كُنتُمۡۖ قَالُواْ كُنَّا مُسۡتَضۡعَفِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ قَالُوٓاْ أَلَمۡ تَكُنۡ أَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٗ فَتُهَاجِرُواْ فِيهَاۚ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرًا97 إِلَّا ٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ حِيلَةٗ وَلَا يَهۡتَدُونَ سَبِيلٗا98﴾
(Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fún yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.
Àyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀). [An-Nisā': 97-98].
ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ أَرۡضِي وَٰسِعَةٞ فَإِيَّٰيَ فَٱعۡبُدُونِ56﴾
( Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò, ọ sí fe Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún). [Suratul Ankabut: 56].
Al-Bagọwiy (Ki Ọlọhun ba wa kẹ ẹ) sọ pe: Ìdí ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí: Nípa àwọn mùsùlùmí t’ó wà ní Makkah tí wọn kò ṣe hijrah ( wan ko fi ìlú sílẹ̀ nítorí Ọlọhun) , Allāhu pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ ìgbàgbọ́ òdodo.
Ẹri lori síse Hijrah ninu Sunnah ni ọ̀rọ̀ anọbi ki ikẹ Ọlọhun àti Ọlá Rẹ máa ba:
"لَا تَنْقَطِعُ الهِجْرَةُ حَتَّى تَنْقَطِعَ التَّوْبَةُ، وَلَا تَنْقَطِعُ التَّوْبَةُ حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ مِنْ مَغْرِبِهَا".
"Hijirah ko ni dawọ duro titi ironupiwada o fi dawọ duro, ati pe ironupiwada ko ni dawọ duro titi oorun o fi yọ lati ibuwọ rẹ."
Nigbati o wa fidi mulẹ ni Mẹdina; ni wọn pa a l'aṣẹ awọn ofin yoku ninu Isilaamu - bii: Saka, ati aawẹ, ati Hajj, ati pipe irun, ati jihaadi ( ìjagun sì ojú ona Ọlọhun ) , ati pipaṣẹ iṣẹ rere ati kikọ iṣẹ ibi - o lo ọdun mẹwa lori eleyii.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ku ti ẹsin rẹ si ṣẹku, eyi si ni ẹsin rẹ, ko si oore kankan ayaafi ki o jẹ pe ọ ti tọ ijọ rẹ sọna si i, ko si aburu kankan ayaafi ki o jẹ pe ọ ti kilọ fun wọn kuro nibé.
Àti pé oore èyí tí ó ṣe itọna rẹ sí ni: imú Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo, àti gbogbo ohun tí Ọlọhun nífẹẹ sí tí Ó sì yọnú sí.
Ati pe aburu ti o ṣe ìkìlọ̀ fún un kúrò níbẹ̀ ni: Ẹbọ, ati gbogbo ohun ti Ọlọhun kórìíra ( kò ní ifẹ sí ) tí O sì kọ̀ ọ́.
Ọlọhun rán an si gbogbo awọn eniyan patapata, O si ṣe igbọran si i ni dandan lori gbogbo awọn eeyan ati alijannu - alijannu ati eeyan -; ẹri si ni ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- wipe:
﴿قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡ جَمِيعًا...﴾
( Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá...( Lapapọ)).
[ Suratul A'raf: 158].
Ati pe Ọlọhun ti pe ẹsin pẹlu rẹ; Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga jù lọ :
﴿...ٱلۡيَوۡمَ أَكۡمَلۡتُ لَكُمۡ دِينَكُمۡ وَأَتۡمَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ نِعۡمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ ٱلۡإِسۡلَٰمَ دِينٗاۚ...﴾
(Lónìí ni Mo parí ẹ̀sìn yín fún yín. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fún yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fún yín). [Al'Maa'idah 3].
Atipe ẹri lori iku rẹ ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿إِنَّكَ مَيِّتٞ وَإِنَّهُم مَّيِّتُونَ30 ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عِندَ رَبِّكُمۡ تَخۡتَصِمُونَ31﴾
(Dájúdájú ìwọ máa ( yóò ) kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú).
(Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ igbende dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín., )
[Az-Zumar: 30-31].
Àti pé nígbà tí àwọn ènìyàn bá ti kú, wọn yóò gbé wọn dìde; ẹ̀rí rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga ti Ó sọ pé:
﴿مِنۡهَا خَلَقۡنَٰكُمۡ وَفِيهَا نُعِيدُكُمۡ وَمِنۡهَا نُخۡرِجُكُمۡ تَارَةً أُخۡرَىٰ55﴾
( Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn). [Too'haa: 55] ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿وَٱللَّهُ أَنۢبَتَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ نَبَاتٗا17 ثُمَّ يُعِيدُكُمۡ فِيهَا وَيُخۡرِجُكُمۡ إِخۡرَاجٗا18﴾
( Allāhu ( Ọlọhun) mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀ ni wíwú jáde ).
( Lẹ́yìn náà, yóò da yín padà sínú rẹ̀. yóò sì tún mu yín jáde tààrà). [Nuuh:17-18].
Lẹ́yìn igbedide, a óò ṣe ìṣirò fún wọn, a ó sì san wọ́n ní ẹsan iṣẹ́ wọn; ẹ̀rí rẹ̀ ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿...لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى﴾
( ..nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere). [Surah An-Najm: 31].
Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ìgbedide nírọ́, ó ti ṣe àìgbàgbọ́; ẹri ni ọrọ Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga ti o sọ pe:
﴿زَعَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن لَّن يُبۡعَثُواْۚ قُلۡ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتُبۡعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلۡتُمۡۚ وَذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ7﴾
(Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fún yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu lati ṣe ).
[At-Tagoobun: 7].
Ọlọhun si ran gbogbo àwọn Ojiṣẹ pátá ni oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀; ẹri si ni ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe:
﴿رُّسُلٗا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةُۢ بَعۡدَ ٱلرُّسُلِۚ...﴾
(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí)wan ti ran àwọn Òjíṣẹ́...) [Suuratun Nisai: 165].
Akọkọ wọn ni anọbi Nuh- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-.
Ati pe igbẹyin wọn ni Anọbi Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, oun si ni igbẹyin awọn Anọbi, ko si anabi kankan lẹyin rẹ mọ; ẹri si ni ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga to sọ pe:
﴿مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ...﴾
((Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì...) Suratul Ahzab: 40
Ẹri lori pe akọkọ wọn ni anọbi Nuh ni: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga ti ọ sọ pe -:
﴿إِنَّآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ كَمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ نُوحٖ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعۡدِهِ...﴾
( Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀...) [Suratul Nisai: 163].
« Ati pe ìjọ kọ̀ọ̀kan ni Ọlọhun gbé Òjíṣẹ́ dìde sí - láti ọ̀dọ̀ Nuh títí dé ọ̀dọ̀ Muhammad - tí ó ń pa wọ́n l'áṣẹ ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, tí ó sì ń kọ̀ wọ́n kúrò níbi ijọsin fun awọn òrìṣà; ẹ̀rí náà sì ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (tí O ga) pé:
﴿وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَ...﴾
(Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà...). [Suratul Nahl: 36].
Ati pe Ọlọhun ṣe ni dandan lori gbogbo awọn ẹrú: ṣiṣe aigbagbọ si Tágúùtì ( Gbogbo nkan ti wan jọsin fún yatọ si Ọlọhun Allah ) , ati nini igbagbọ ninu Ọlọhun.
Ibnu-l-Qayyim - ki Ọlọhun ti ọla Rẹ ga kẹ ẹ - sọ pe: "Ìtumọ Tọọguut ni Ohun ti ẹru ba fi rekọja ala rẹ - nínú ẹni ti a n jọsin fun, tàbí ẹni ti a n tẹle, tàbí ẹni ti a n gbọ tirẹ."
Atipe awọn òun tí wan nmu ni ọlọhun pọ, awọn olori wọn si jẹ marun-un: Ibilisi - ki ibi dandan Allāhu maa ba a, ati ẹni ti wọn jọsin fun ti o si yọnu si i, ati ẹni ti o pe awọn eniyan si ijosin fun ara rẹ, ati ẹni ti o sọ pe oun mọ nkan kan ninu imọ ikọkọ, ati ẹni ti o ṣe idajọ pẹlu nkan ti o yatọ si eyi ti Ọlọhun sọkalẹ.
Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿لَآ إِكۡرَاهَ فِي ٱلدِّينِۖ قَد تَّبَيَّنَ ٱلرُّشۡدُ مِنَ ٱلۡغَيِّۚ فَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلطَّٰغُوتِ وَيُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱسۡتَمۡسَكَ بِٱلۡعُرۡوَةِ ٱلۡوُثۡقَىٰ لَا ٱنفِصَامَ لَهَاۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ256﴾
( Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀). [Al-Baqorah: 256], Èyí sì ni itumọ “Lā ilāha illā Allāhu”, ( pé kò sí ẹniyan kankan ti ọ yẹ ki a fi ìjọsìn fún ayaafi Ọlọhun ) ati ninu Hadiisi:
"رَأْسُ الأَمْرِ: الإِسْلَامُ، وَعَمُودُهُ: الصَّلَاةُ، وَذِرْوَةُ سَنَامِهِ: الجِهَادُ فِي سَبِيلِ اللَّهِ".
"Olórí gbogbo nǹkan ni: Islam, àti òpó rẹ̀ ni: Irun kiki, àti òpin gíga rẹ̀ ni: iṣẹ́ ìgbìyànjú sí ojú ọ̀nà Ọlọ́hun."
Ọlọhun lo nimọ julọ.
***
Atọka awọn nkan to nbẹ ninu tira
Awọn ipilẹ mẹta ati awọn ẹri rẹ 2
[Ipilẹ Alakọkọ] 5
[Ipilẹ keji] 11
[Ipilẹ kẹta] 19
***
yo36v2.0 - 26/09/2026