الدروس المهمة لعامة الأمة (يوربا)

  • earth Language
    (يوربا)
  • earth Author:
    الشيخ عبد العزيز بن باز
PHPWord

 

 

 

الدُّرُوسُ المُهِمَّةُ لِعَامَّةِ الأُمَّةِ

 

 

Awọn ẹkọ ti o pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi)

 

 

لِسَمَاحَةِ الشَّيْخِ العَلَّامَةِ

عَبْدِ العَزِيزِ بْنِ عَبْدِ اللهِ بْنِ بَازٍ

رَحِمَهُ اللهُ

 

Ti alufaa àgbà Shaikh Ọlọpọlọpọ mimọ kọ

Abdul Azeez ọmọ Abdullah ọmọ Bāz

Kí Ọlọhun ba wa kẹ ẹ

 


بِسْمِ اللهِ الرَّحمَنِ الرَّحِيمِ

Awọn ẹkọ ti o pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi)

Ni orukọ Ọlọhun Ọba Ajọke aye Ọba Aṣakẹ ọrun

Ọrọ iṣiwaju lat'ọdọ Onkọwe

Gbogbo ẹyin ti Ọlọhun ni, Ọba gbogbo agbaye, igbẹyin daadaa n bẹ fun awọn olupaya Ọlọhun, ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ ki o maa bà ẹru Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ Anọbi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ.

Lẹyìn igba na:

Eleyii ni awọn ọrọ ṣoki nipa alaye apakan awọn nkan ti o jẹ dandan ni ki gbogbo eeyan o mọ ọn nipa ẹsin Isilaamu, mo sọ ọ ni: Ad durūsul muhimmah li ‘āmatil 'ummah (Awọn ẹkọ ti o ṣe pataki fun gbogbo ali'ummah ( ìjọ musulumi ) ).

Ati pe mo wa n bẹ Ọlọhun ki o fi i ṣe awọn musulumi ni anfaani, ki O si tẹwọ gba a ni ọwọ mi, Oun ni Ọba Ọlọrẹ Alapọnle.

Abdul Azeez ọmọ Abdullah ọmọ Bāz lo kọ Awọn ẹkọ ti o ṣe pataki fun gbogbo ali'ummah (apapọ ìjọ musulumi)1

Ẹkọ alakọkọ: Sūratul Fātiah ati awọn sūrah kukuku (Èyí tí kò gùn)

Sūratul Fātiah ati eleyi ti o ba rọrun ninu awọn sūrah kukuku, lati Sūratu Zalzalah titi de Sūratun Nās, niti pipe sini lẹnu, ati ṣiṣe àtúnṣe kika, ati ṣiṣe ni hiha, ati ṣiṣe alaye awọn nkan ti jẹ dandan láti gbọye.

Ẹkọ ẹlẹẹkeji: Awọn origun ẹṣin Isilaamu

Ṣiṣe alaye awọn origun Isilaamu mararun-un, ati pe akọkọ ati eyiti o tobi julọ ninu rẹ ni: Ijẹrisi pe dajudaju ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, (Ọlọhun) ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni pẹlu alaye awọn itumọ rẹ, ati alaye awọn majẹmu laa ilaaha illa Allāhu, ati pe itumọ rẹ ni: (laa ilaaha) o n ni àtakò sí gbogbo nkan ti wọn n sin yatọ si Allāhu, (illa Allāhu) o n ṣe afirinlẹ ijọsin fun Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si si orogun fun Un. Ẹẹ wa ri awọn majẹmu laa ilaaha illa Allāhu ( pé kòsí nkán tí o yẹ kí a máa fí ìjọsìn fún ayaafi Ọlọhun ) oun ni: Imọ eleyii ti yóò takò aimọkan, ati amọdaju eleyii ti o tako iyemeji, ati ise mimọ fún Ọlọhun eleyii ti o tako imu orogun mọ Ọlọhun, ati ododo eleyii ti o tako irọ, ati ifẹ eleyii ti o tako ikorira, ati ijupa-jusẹ silẹ eleyii ti o tako igbejusilẹ, ati itẹwọgba eleyii ti o tako idapada, ati ṣiṣe aigbagbọ pẹlu nkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Allāhu (Ọlọhun). Ati pe wọn ti ko o jọ sinu ile orin meji ti n bọ yii:

Imọ ati amọdaju ati imọkanga ati ododo rẹ pẹlu ifẹ ati ijupa-jusẹ silẹ ati itẹwọgba a . Wọn wa ṣẹ alekun ẹkẹẹjọ rẹ ti se isè ainiigbagbọ rẹ sí gbogbo nkan ti wọn ba ti n jọsin fun yatọ si Allāhu. ( Ọlọhun)

Pẹlu ṣiṣe alaye ijẹrisi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun nii se, nkan ti o sì da lẹjọ ni pé: Gbigba a ni ododo nibi ọrọ tí o ba muwa, ati titẹle e nibi aṣẹ ti o ba pa, ati jijina si nkan ti o ba kọ fún wa, ati pe a o gbọdọ jọsin fun Ọlọhun ayaafi pẹlu nkan ti Ọlọhun - ti o tóbi ti O gbọn-un-gbọn - ati ojiṣẹ Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ba ṣe lofin nínú ẹṣin. Lẹyin naa ni yio ṣe alaye fun akẹkọ awọn origun Isilaamu mararun-un yoku, oun ni: Irun, ati zakah, ati awẹ Ramadan, ati lilọ ile Ọlọhun fún abeewọ fun ẹni ti o ba ni agbara lati lọ.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta ni: Awọn origun igbagbọ.

mẹfa ni wọn: awọn naa ni ki o gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, ati awọn malaaikah Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati pe ki o ni igbagbọ si kadara;( eto Ọlọhun àti alaa silẹ Rẹ) eleyi ti o daa nibẹ ati eleyi ti kò dara, ki o ni igbagbọ wipe lati ọdọ Ọlọhun Allah ni o ti wa.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin: Awọn ipin taoheed (imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo) ati awọn ipin shirk (imu orogun mọ Ọlọhun).

Alaye awọn ipin taoheed (imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo), mẹta ni i: Taoheed rubūbiyyah [imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo nibi ijẹ

Olúwa fún gbogbo nkan], ati taoheed ulūhiyyah [Imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo nibi ilẹtọ si ijọsin Rẹ], ati taoheed al-asmā'i wa sifāti [imu Ọlọhun lọkan nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ].

Oun ti wọn npe ni Taoheedur- Rubuubiyyah ni: ini igbagbọ wipe Ọlọhun Ọba Allah ti O mọ kanga ni Oluda gbogbo nkan ati Oluṣe bi o ṣe wu U nibi gbogbo nkan ti ko si orogun fun Un nípa ṣíṣe bẹ.

Oun ti wọn npe ni "Taoheedul-Uluuhiyah" ni: ini igbagbọ pe Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti o yẹ kí a maa jọsin fun lododo ti Ko si ni orogun nibẹ, oun naa si tun ni itumọ gbolohun "LAA ILAAHA ILLA LAAH" ti itumọ rẹ jẹ: "ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun Ọba Allah. Gbogbo awọn ijọsin, bẹrẹ lati ori irun ati aawẹ ati awọn nkan ti o yatọ si i, dandan ni ki a ni imọkanga ọkan pẹlu Ọlọhun nikan ṣoṣo nibi gbogbo rẹ, kosi lẹtọ ki a dari nkankan nínú rẹ sí ọdọ nkan miran yatọ si Allah (Ọlọhun).

Oun ti wọn gba lero pẹlu " TAOHEEDUL-AS'MAAHI WAS-SIFAAT" naa ni ini igbagbọ sí gbogbo nkan ti o wa lati inu Alukurani Alapọnle tabi ọrọ Anabi ti o ni alaafia ninu awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ati iṣe ifirinlẹ rẹ fun Ọlọhun Ọba Allah nikan ṣoṣo ni ọna ti o ba Ọlọhun mu, lai ṣe iyi itumọ rẹ pada, ati aima maa dagunla rẹ ati laini maa fi we nkankan ati laini maa fi jọ nkankan ni itẹle ọrọ Ọlọhun ti O ga julọ ti o sọ pe :

﴿قُلۡ هُوَ ٱللَّهُ أَحَدٌ1 ٱللَّهُ ٱلصَّمَدُ2 لَمۡ يَلِدۡ وَلَمۡ يُولَدۡ 3 وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ كُفُوًا أَحَدُۢ4﴾

(Sọ pé: "Òun ni Allāhu, (Ọlọhun) Ọ̀kan ṣoṣo.(1)

Allāhu (Ọlọhun) ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn) (2)

Kò bímọ. Ẹnikan kò sì bí I (3)

Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́) [Suuratul Ikhlaas: 1-4] Ati ọrọ Ọlọhun Ọba ti O ga julọ ti O si gbọn-n-gbọn ti O sọ pe:

﴿...لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ﴾

( Kò sí kiní kan tí ó dà bí Rẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Olùríran) [Surah Ash-Shūrā: 11], Ati pe awọn kan ninu awọn onimimọ ṣe e ni ipin meji, wọ́n ti ini igbagbọ ninu Ọlọhun nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ bọ inú ini igbagbọ ninu Ọlọhun nibi ijẹ Oluwa Rẹ, kò sì sí ijiyan nibi iyẹn; nitori pe nǹkan ti wọn gba lero fi oju han nibi pinpin mejeeji.

Awọn ipin ẹbọ mẹta ni: Ẹbọ nla, ati ẹbọ kekere, ati ẹbọ ti o pamọ.

Ẹbọ nla: yoo sọ bibajẹ iṣẹ rẹ ati ṣiṣe gbere ninu ina di dandan fun ẹni ti o ba ku le e lori, gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pe:

﴿...وَلَوۡ أَشۡرَكُواْ لَحَبِطَ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ﴾

(Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ rere ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́) (Suratul An'aam: 88), Ọlọhun Ọba - ti mimọ n bẹ fun Un - tun sọ pe:

﴿مَا كَانَ لِلۡمُشۡرِكِينَ أَن يَعۡمُرُواْ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ شَٰهِدِينَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِم بِٱلۡكُفۡرِۚ أُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ وَفِي ٱلنَّارِ هُمۡ خَٰلِدُونَ17﴾

(Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn oluṣẹbọ láti ṣe àmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná) [Surah At-Tawbah: 17], Atipe ẹniti o ba ku lori rẹ, wọn ò ni ṣe aforijin fun un, bakannaa ni wọ́n ó ṣe alujanna (ile Idẹra) leewọ fun un, gẹgẹbi Ọlọhun - ti O gbọngbọn - ṣe sọ pe:

﴿إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُ...﴾

(Dájúdájú Ọlọhun kò níí foríjin ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí I, Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́) [suratu Nisaa: 48], Ọlọhun - mimọ ni fun Un - tun sọ pe:

﴿...إِنَّهُۥ مَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ حَرَّمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ ٱلۡجَنَّةَ وَمَأۡوَىٰهُ ٱلنَّارُۖ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ﴾

Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí. (Surah Al-Maa'ida: 72).

Ninu awọn oriṣiriṣi rẹ ni: kikepe awọn oku fún ìrànlọ́wọ́, ati awọn oriṣa, ati wiwa iranlọwọ pẹlu wọn, ati ṣíṣe ileri fun wọn, ati didunbu (pipa nkán) fun wọn, ati nnkan ti o jọ ìyẹn.

Ṣugbọn ẹbọ kekere ni tiẹ: oun ni eyikeyi nkan ti pipe e ni ẹbọ ba rinlẹ pẹlu ẹri ninu tira Ọlọhun tabi lati inu sunnah Anabi ṣugbọn ti kii ṣe iran kan ninu ẹbọ nla; Apẹrẹ rẹ ni ṣiṣe karimi nibi awọn iṣẹ kan, mimaa fi nkan miran to yatọ si Ọlọhun bura, ati gbolohun: 'ti kii ba ṣe ọla fifẹ Ọlọhun ati lagbaja ni', ati nkan to jọ bẹẹ; Eleyii ri bẹẹ nitori ọrọ Anọbi - ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati igẹ Rẹ fun un- to sọ pe:

«أَخْوَفُ مَا أَخَافُ عَلَيْكُمْ الشِّرْكَ الَأصْغَرَ» فَسُئِلَ عَنْهُ، فَقَالَ: «الرِّيَاءُ».

"Ohun ti mo nbẹru ju fun yin ni: ẹbọ kekerẹ, wọn wa bi i lee re nipa rẹ, o wa sọ pe: iṣe karimi "2 Imam Ahmad lo gba a wa, ati Tọbarọọniy, ati Baihaqiy, lati ọdọ Mahmud ọmọ Lubaed Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i- pẹlu ẹgbawa (iṣe afiti) ti o daa, Tobarọọniy naa tún gba a wa pẹlu awọn ẹgbawa ti wọn daa, lati ọdọ Mahmud ọmọ Labeed, lati ọdọ Raafi' ọmọ Khadeej, lati ọdọ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

ati ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

«مَنْ حَلَفَ بِشَيْءٍ دُونَ اللَّهِ فَقَدْ أَشْرَكَ».

«Ẹnikẹni ti o ba bura pẹlu nnkan kan ti o yatọ si Ọlọhun dajudaju onitọhun ti ṣe ẹbọ»3 Imam Ahmad lo gba a wa pẹlu iṣe afiti ti o ni alaafia, lati ọdọ Umar ọmọ Khotob- ki Ọlọhun yọnu si i- Abu Daud lo gba a wa, ati Tirimidhiy pẹlu ẹgbawa ti o ni alaafia, ninu hadiisi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o sọ pe:

«مَنْ حَلَفَ بِغَيْرِ اللَّهِ فَقَدْ كَفَرَ أَوْ أَشْرَكَ».

"Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣe ẹbọ."4 ati ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -

«لَا تَقُولُوا: مَا شَاءَ اللَّهُ وَشَاءَ فُلانٌ، وَلَكِنْ قُولُوا: مَا شَاءَ اللَّهُ ثُمَّ شَاءَ فُلانٌ».

"Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ"5 Abu Daud ni o mu u jade pẹlu ẹgbawa ti o ni alaafia, lati ọdọ Hudhaifa ọmọ Al-Yaman- ki Ọlọhun yọnu si i-

Ati pe iru eleyii ò lee muni kuro ninu ẹsin, kò sì lee muni ṣe gbere ninu ina, amọ ó maa ni àtakò si pipe imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo ti o jẹ dandan.

Oríṣi ẹlẹẹkẹta ni: ṣíṣe ẹbọ tí ó pa mọ́, ẹri tí ó wa fún eleyi ni ọrọ Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba a:

«أَلَا أُخْبِرُكُمْ بِمَا هُوَ أَخْوَفُ عَلَيْكُمْ عِنْدِي مِنَ المَسِيحِ الدَّجَّالِ؟» قَالُوا: بَلَى يَا رَسُولَ اللَّهِ، قَالَ: «الشِّرْكُ الخَفِيُّ، يَقُومُ الرَّجُلُ فَيُصَلِّي فَيُزَيِّنُ صَلَاتَهُ لِمَا يَرَى مِنْ نَظَرِ الرَّجُلِ إِلَيْهِ».

"Ẹ jẹ ki n fun yin niro nkan ti n pami laya ju lori yin ju Al’masihi dajjaali lọ ( arákùnrin obi? Wọn fun un lesi wipe: bẹẹ ni irẹ ojisẹ Ọlọhun (fun wa ni'ro rẹ), o sọ wipe nkan naa ni imorogun m'Ọlọhun eyi ti o pamọ, oun naa ni bii ki eniyan kan duro lati kirun bẹẹ ni yoo si bẹrẹ sini maa ṣe irun rẹ ni ọṣọ latari pe o rii pe ẹnikan nwo òun."6 Imaamu Ahmad lọ gba a wa ninu musnad rẹ (tira rẹ), lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-khudriy – ki Ọlọhun yọnu si i.

O si tun tọ ki a pin ẹbọ (imu orogun mọ Ọlọhun) si oríṣi meji pere:

ẹbọ nla ati ẹbọ kekere, ẹẹ wa ri ẹbọ ti o pamọ, dajudaju oun ni o ko mejeeji sinu; aa maa waye ninu ẹbọ nla gẹgẹ bii ẹbọ awọn munaafiki; nitori pe awọn wọnyi nfi adisọkan wọn ti ko dáa pamọ, wọn si nfi Isilaamu han ni ti karini ati ibẹru ẹmi ará wọn.

yoo maa waye bakannaa ninu ẹbọ kekere, gẹgẹ bíi sise karimi, gẹgẹ bi o ṣe wa ninu hadīth Mahmūd ọmọ Labiid Al-anṣāriy ti o ṣaaju, ati hadīth Abu Sa‘eed eleyii ti a ti darukọ. Ọlọhun ni Olufini ṣe kongẹ.

Ẹkọ ẹlẹẹkarun-un: iṣe Daadaa

Origun daadaa, oun ni: Ki ọ maá jọsin fún Ọlọhun bi igbati o n ri I, ti oo ba tí ẹ ri I, dajudaju Oun n ri ọ.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹfa: Awọn majẹmu irun.

Mẹsan ni i:

Isilaamu, ( ijẹ musulumi) ati laakaye , ati ṣiṣe ìdá nkan mọn (gbigbọn), ati gbigbe ẹgbin kuro lara, ati mimu idọti kuro lara, ati bibo ihoho ara, ati wiwọle asiko, ati didajukọ qiblah (ibu dájú kọ kirun), ati aniyan.

Ẹkọ ẹlẹẹkeje: Awọn origun irun

Mẹrinla ni i:

Diduro kirun ni'wọn igba ti a ba lagbara lati ṣe bẹẹ, ṣiṣe kabara (Allahu akbar , igbe Ọlọhun tó bí ) eyi ti a fi nbẹrẹ irun l náà, kika suratul Faatiat, titẹriba, diduro tọ lẹyin titẹriba, fifori kanlẹ pẹlu lilo orike ara meje kan, gbigbori soke lẹyin iforikanlẹ, jijoko laarin iforikanlẹ mejeeji, fifarabalẹ nibi ṣiṣe gbogbo awọn iṣẹ ori irun, tito awọn origun naa le ara wọn, kika gbolohun ijẹri (attahiyyat) to kẹyin, jijoko ka a, ṣiṣe asalatu fun Anọbi - ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati igẹ Rẹ fun un - ati sisalamọ mejeeji.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹjọ: Awọn ọranyan irun.

Mẹjọ ni i:

Gbogbo kabara ( igbe titobi fún Ọlọhun) yatọsi kabara ( gbigbe títóbi fún Olohun ) ti ibẹrẹ irun, ati gbolohun: Sami‘aLlāhu liman hamidaHu (Ọlọhun gbọ ohun ẹni tí nyin) fun Imaamu ati ẹni ti n da irun ki, ati gbolohun: Rọbbabaa wa laKal hamdu ( Olúwa wa iwọ nikan ni ọpẹ to sí) fun gbogbo wọn, ati gbolohun: Subhāna Robbiyal ‘Adhiim (mimọ ni fún Olúwa mi tí o tobi) nibi itẹkọkọ, ati gbolohun: Subhāna Robbiyal A‘lā ( mimọ fún rẹ Olúwa mi tí o ga julọ ) nibi iforikanlẹ, ati gbolohun: Robbi igfir li (Olúwa mi ṣe aforijin fún mí ) laarin iforikanlẹ mejeeji, ati ataayah (gbólóhùn ijeri) alakọkọ, ati ijokoo rẹ.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹsan: Alaye ataayah

( gbólóhùn ijẹri).

Oun naa ni ki o sọ pe:

(Attahiyyātu liLlāh, waṣ ṣolawaatu, wat tọyyibāt, as salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmotuLloohi wabarakātuHu, as salaamu alayna wa alaa ‘ibaadiLlāhis ṣoolihiina, ash’hadu allā ilaaha illa Allāhu, wa ash’hadu anna Muhammadan abduHu wa rọsūluHu (Gbogbo kìkì àti ikẹ àti dáadáa tí Ọlọhun nii se, àlàáfíà Ọlọhun kí ọ máa bá irẹ Anọbi ati ikẹ àti òòrè a jẹ njẹ tan Rẹ , àlàáfíà Ọlọhun kí ọ máa bá àwa náà kí o si máa bá awọn ẹrú Ọlohun tí wan jẹ ẹnii re, mọ jẹri pé kò sí nkan kan tí o yẹ láti máa jọsin fún àyàfi Ọlọhun nìkan, mọsi jẹri pé Anọbi Muhammad ẹrú ati òjíṣẹ Rẹ ni).

Lẹyin naa yoo ṣe asalatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – yoo si tun tọrọ ibukun fun un, yoo wa sọ pe: (Allāhummo ṣolli ala Muhammadin, wa ala āli Muhammadin, kamā ṣollayTa alaa Ibrāhīm wa alaa āli Ibrāhīm, innaKa Hamiidun Majiid, wa baarik alaa Muhammadin, wa alaa āli Muhammadin, kamā baarakTa alaa Ibrāhīm, wa alaa āli Ibrāhīm, innaKa Hamiidun Majiid). Ìtumọ rẹ nipe: Ọlọhun ba wa se ikẹ fún Anọbi Muhammad àti fún awọn ara ile anọbi Muhammad, gẹgẹ bí O ti se ikẹ fún Anọbi Ibrahim àti awọn ará ilé anọbi Ibrahim dájúdájú Irẹ Ọlọhun ni Ọba tí wọn dupẹ fún tí wọn sí ngbe tóbi. Bawa se Ìbùkún fún anọbi Muhammed àti fún awọn ara ile anọbi Muhammed gẹgẹ bí o ti se ibunkun fún anọbi Ibrahim àti awọn ará ilé anọbi Ibrahim dájúdájú Irẹ Ọlọhun ni Ọba tí a nyin tí a si ngbé tóbi).

Lẹyin naa ni yio wa iṣọra pẹlu Ọlọhun nibi atayah igbẹyin kuro nibi iya Jahannama (ina) ati iya saare, ati nibi fitina ( wahala ) iye ati iku, ati nibi fitina masiihu dajjal, lẹyin naa ni yio ṣẹsa ninu adua eyiti o ba wu u, agaga julọ eyiti wọn gba wa ninu iyẹn, ati pe ninu rẹ ni:

(Allāhummo a‘inni ala dhikriKa wa shukriKa wa husni ‘ibādatiKa, Allāhummo inni zọlamtu nafsi zulman kathiira, wa laa yagfiru dhunūba illaa Anta, fagfir li magrifọtan min ‘indiKa, warhamni innaKa Antal Gafūrur Raheem). Ìtumọ rẹ: ( Mọ pe irẹ Ọlọhun má ṣáà rán mi lọwọ lórí ìrántí rẹ àti lórí didaa ìjọsìn fún Ọ, mo pe irẹ Ọlọhun dájú dájú emi ti se abosi tí o pọ fún ra mi kò si sí ẹnikan tí o le se aforijin fún mi ayaafi iwọ nìkan ṣoṣo, se aforijin fún mi láti ọdọ araarẹ wa, kí o si se ikẹ mi dájú dájú iwọ ni Alaforiji ati Onikẹ).

Ṣugbọn nibi ataayah alakọkọ, yio dide lẹyin gbólóhùn ijẹrisi mejeeji lọ sibi rakah kẹta nibi irun Zuhri, Asri, Magrib ati Ishai, ati pe tí o bá ṣe àsàlátù fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - ìyẹn lo dara ju; nitori apapọ awọn Hadiisi to waye lori rẹ, lẹyin naa ni yio dide lọ sibi rakah kẹta.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹwa: Awọn sunnah irun

Ninu wọn ni:

1- Ṣiṣi irun

2- Fifi ọwọ ọtun lori osi tí méjèjì yóò sí wa lori igbaaya nibi idide, ṣíwájú titẹ kọkọrọ ati lẹyin rẹ.

3- Gbigbe ọwọ mejeeji ni ẹni ti yoo di àwọn ọmọnika papọ ti yoo na taara si deedee ejika mejeeji tabi eti mejeeji nibi kikabara (gbígbé titobi fún Ọlọhun) akọkọ, ati nibi titẹkọkọrọ, ati didide kuro nibẹ, ati nibi didide kuro nibi ataaya àkọ́kọ́ si bi rakah ẹlẹẹkẹta.

4- Ṣiṣe afọmọ ti titẹkọkọrọ ati ti iforikanlẹ le jù ẹyọkan lọ.

5- Nnkan ti o lekun lori gbolohun: (Robanna wa lakal hamdu) : (Olúwa wa Irẹ ni ọpẹ tọ sí) lẹyin didide kuro ni titẹkọkọrọ, ati nnkan ti o lekun lori ẹyọkan nibi adura titọrọ aforiji laaarin iforikanlẹ mejeeji.

6- Fifi ori si ọgangan ẹyin nibi titẹkọkọrọ.

7- Gbigbe apa mejeeji jinna si ẹgbẹ mejeeji, ati ikun si itan mejeeji, ati gbígbé itan mejeeji jina sí ojugun méjèjì nibi iforikanlẹ.

8- Gbigbe apa mejeeji kúrò lórí ilẹ nibi iforikanlẹ.

9- Jijokoo olukirun lori ẹsẹ rẹ osi ni nnkan ti a tẹ silẹ, ati gbigbe ọtun soke nibi ataaya ( gboloun ijẹri ) àkọ́kọ́ ati laaarin iforikanlẹ mejeeji.

10- At-Tawarruk nibi ataaya Igbẹyin nibi irun olopo mẹrin ati irun olopo mẹta, itumọ At-Tawarruk ni: jijoko lórí alafo ẹsẹ pẹlu kí awẹ ìdí máa kan ilẹ ati fifi ẹsẹ rẹ osi sábẹ́ ọtun ati gbigbe ọtun soke.

11- Itọka pẹlu ọmọnika ilabẹ ti ọwọ ọtun nibi ataaya ( gbólóhùn ijẹri) àkọ́kọ́ ati ikeji lati igba tí o ba ti jokoo titi di ipari ataaya( gbólóhùn ijẹri) ati gbigban ika naa nigbati o ba nṣe adura.

12- Ṣiṣe asalatu ati titọrọ alubarika ( ìbùkún ) fun Muhammad, ati awọn ara ile Muhammad, ati fun Ibrahim, ati awọn ara ile Ibrahim nibi ataaya àkọ́kọ́.

13- Adura ṣiṣe nibi ataaya ( gbólóhùn ijẹri ) Igbẹyin.

14- Igbe ohun soke pẹlu kika Qur'an nibi irun alufajari (Aarọ) ati irun Jimọh, ati irun yidi mejeeji, ati irun ibeere fun ojo, ati nibi rakah mejeeji akọkọ nibi irun Magrib ( Irun aṣálẹ ) ati Ishai ( Irùn akisun) .

15- Ṣiṣe ohun jẹẹjẹ pẹlu kika Qur'an nibi Irun Zuhr ( ọsan ) ati Asr (irọlẹ) ati nibi rakah kẹta irun Magrib (irun aṣálẹ) ati rakah mejeeji igbẹyin irun Ishai (Irun Akisun)

16- Kika nnkan ti o lekun lori Fatiha ninu Kuraani, pẹlu iwoye si nnkan ti o ṣẹku ninu nnkan ti o wa ninu awọn sunnah nibi irun yatọ si awọn nnkan ti a darukọ yii, ninu wọn ni: Nnkan ti o lekun lori ọrọ olukirun pe: Olúwa wa iwọ nikan ni ọpẹ tọ sí (Robanna wa lakal hamdu), Lẹyin gbigbe ori kuro ni bi titẹkọkọrọ Imam, ati ero ẹyin rẹ, ati oludarunki, dajudaju sunnah ni eyi. ninu wọn bakanna ni: Gbigbe ọwọ mejeeji lori orunkun mejeeji ni ẹni ti yoo ya awọn ọmọnika nibi titẹkọkọrọ.

Ẹ̀kọ́ ẹlẹẹkọkanla: Awọn nnkan tin nba irún jẹ

Mẹjọ ni wọn:

1- Ọ̀rọ̀ ti a mọ̀ọ́mọ̀ sọ pẹlu iranti ati mimọ pé o le ba irun jẹ, ṣugbọn ẹni ti o gbagbe ati alaimọkan, irun rẹ ko bajẹ pẹlu iṣẹlẹ bẹẹ.

2- Ẹrin rírín lórí irun.

3- Jijẹ nkan

4- Mímu nkan

5- Ki ihoho ṣi silẹ

6- Yiyẹ kuro tí o pọ nibi ọgan-angan Qibla ( ibudajukọ kirun)

7- Ere ti o pọ, ti o tẹlera wọn lori irun.

8- Bibajẹ imọra (Aluwala).

Ẹkọ ẹlẹẹkejila: Awọn majẹmu aluwala

Mẹwaa ni wọn:

Isilaamu, ati laakaye, ati ida ìyàtọ̀ mọ (gbigbọn), ati aniyan, ati igbe idajọ rẹ lori ipilẹ pẹlu pe ki o ma daniyan jija rẹ titi imọra rẹ fi maa pe, ati dida nnkan ti o le sọ aluwala di dandan, ati imọra pẹlu omi tabi imọra pẹlu okuta ṣíwájú rẹ, ati ijẹ mimọ omi rẹ ati nini ẹtọ rẹ, ati mimu nnkan ti o le kọdi rẹ lati ma de ara kuro, ati wíwọlé asiko irun ni ti iwọ ẹni ti ipo ẹgbin rẹ jẹ nnkan ti o wa pẹlu rẹ.

 

Ẹkọ ẹlẹẹkẹtala: Awọn ọran-anyan aluwala

Mẹfa ni wọ́n:

Fifi omi wẹ oju, ninu rẹ ni fifi omi yọ ẹnu wa ati fifi i fin imu lapapọ, ati fifọ ọwọ mejeeji de igunpa mejeeji, ati fifi omi pa gbogbo ori, ninu omi naa la o ti pa eti mejeeji, ati fifọ ẹsẹ mejeeji de kokosẹ, ati tito o tẹle ara wọn, ati yiyara se wọn. Wọn fẹ pipaara fifọ oju, ati ọwọ mejeeji, ati ẹsẹ mejeeji ni ẹẹmẹta, bayii naa ni fifi omi yọ ẹnu, ati fifi i fin imu, eleyi ti o jẹ ọranyan ninu iyẹn ni ẹẹkan ṣoṣo, ṣugbọn pipa ori, wọn ò fẹ pipaara rẹ gẹgẹ bi awọn hadiithi ti o ni alaafia ṣe tọka si.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrinla: Awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ

Mẹfa ni wọn jẹ

Nkan ti n jade lati iho ara mejeeji, ati nkan to njade ti ko daa ti o si jẹ nkan ẹgbin lati ara, ati yiyẹ laakaye pẹlu sisun abi awọn nkan ti o yatọ si i, ati fifi ọwọ kan oju abẹ ni oju ara ni o jẹ ni abi lati ibi idi lai si gaga Kankan, bakannaa jijẹ ẹran rakunmi ati kikoomọ kuro ninu ẹsin Isilaamu, ki Ọlọhun sọ wa ati awọn musulumi kuro nibi iru nkan bẹẹ.

Itaniji ti o ṣe pataki: ṣugbọn o, wiwẹ fun oku, eleyi ti o ni alaafia julọ naa ni wipe ko ba aluwala jẹ, oun ni eleyi ti awọn onimimọ sọ julọ lọrọ; nitori pe ko si ẹri kankan pato ti o ntọka le e lori, ṣugbọn ti ọwọ ẹni ti o nwẹ oku ba kan oju ara oku laisi gaga kankan ti o kọdi dide ibẹ, aluwala ti di dandan fún un.

Eleyi ti o wa jẹ dandan le e lori naa ni pe ki o ma fi ọwọ kan oju ara oku ayafi ni abẹ gaga, bakannaa ni gbigba obinrin mu kii ba aluwala jẹ ni sanpọnna, ibaa jẹ pe nitori adun ni o abi laisi igbadun nibẹ ni eleyi ti o fi nlalaafia julọ ninu ọrọ awọn onimimọ lopin igba ti nkankan o ba ti jade loju ara rẹ; nitori Anabi Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- gbe ẹnu ko awọn apakan ninu awọn iyawo rẹ lẹnu ti o si kirun lai tun aluwala reb ṣe.

Ṣugbọn ọrọ Ọlọhun Ọba ti O sọ nibi ayah mejeeji ninu suratu-Nisah ati Suratul-Maa'idah pe:

﴿...أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ...﴾

tàbí ẹ súnmọ́ wan obinrin  [An-Nisā'i: 43] [Al-Māidah: 6] nkan ti wọn gbalero pẹlu rẹ ni: Ibalopọ, ni eyiti o fi n ni alaafia julọ ninu ọrọ meji ti o wa lọdọ awọn olumọ, oun naa si ni ọrọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, ati apapọ awọn kan ninu awọn aṣáájú (saabe) ati awọn ti wọn wa lẹyin wọn. Ọlọhun ni Ọba Olufiniṣekongẹ.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹdogun: Ṣiṣe ọṣọ pẹlu awọn iwa ti wọn ṣe lofin fun gbogbo musulumi.

Ninu rẹ ni: Ododo, ati ifọkantan, ati ikora ẹni ni ijanu, ati itiju, ati akin, ati ọrẹ, ati ipe adehun, ati mimọ kanga kuro nibi gbogbo nkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, ati ṣiṣe daadaa si alamuleti (alabagbe), ati ṣiṣe iranlọwọ fun awọn ti wọn ni bukaata si i bi agbara ba ṣe mọ, ati nkan ti o yatọ si iyẹn ninu awọn iwa eleyi ti tira Ọlọhun ati sunnah anabi n tọka si jijẹ oun tí wọ́n se ní ìlànà ẹṣin.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin-din-logun: Lilo awọn ẹkọ Isilaamu.

Ninu rẹ ni: Salamọ (kiki awọn ènìyàn), ati itujuka, ati jijẹ un pẹlu ọwọ ọtun ati mimu pẹlu rẹ, ati didarukọ Ọlọhun ni ibẹrẹ, ati idupẹ fun Ọlọhun ni ipari, ati idupẹ fun Ọlọhun lẹyin sisin, ati kiki ẹni ti o sin ti o ba dupẹ fun Ọlọhun, ati ṣiṣe abẹwo alaarẹ, ati titẹle òkú lati kirun si i lara ati lati sin in, ati awọn ẹkọ shariah nibi wiwọ masalasi, tabi ile, ati jijade kuro ni ààyè mejeeji, ati nibi irin-ajo, ati pẹlu obi mejeeji, ati awọn alasunmọ ati alabagbe, ati awọn agbalagba ati ọmọde, ati ikini fun t'ọmọ tuntun, ati ikini fun igbeyawo, ati ibanikẹdun nibi ajalu, ati nkan ti o yatọ si iyẹn ninu awọn ẹkọ Isilaamu nibi wiwọ ati bibọ aṣọ ati bàtà.

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta-din-logun: Isọni lara kuro nibi mimu orogun mọ Ọlọhun ati awọn oríṣiriṣi ẹṣẹ.

Ninu rẹ ni: Awọn nkan meje ti maa n pa'ni run, oun ni: Imu orogun mọ Ọlọhun, ati idan, ati pipa ẹmi eleyi ti Ọlọhun ṣe ni eewọ ayaafi pẹlu ẹtọ, ati jijẹ owo ele, ati jijẹ dukia ọmọ orukan, ati yiyi ẹyin pada ni oju ogun, ati piparọ agbere mo awọn obinrin ti wọn kó ara wọn ni ijanu ti ko si si sina lori ọkan wọn ti wọn si tun jẹ olugbagbọ ododo.

ninu rẹ tun ni: Iyapa obi mejeeji, ati jija okun ẹbí, ati ijẹri eke, ati ibura irọ, ati ifi'arani alamuleti, ati ṣiṣe abosi awọn eeyan nibi awọn ẹjẹ, ati awọn dukia, ati awọn ọmọluabi, ati mimu nkan ti maa n muni hunrira (pani bí ọtí), ati fifi qimār (tẹtẹ) ṣere - oun naa ni: tẹtẹ tita -, ati ọrọ ẹyin, ati ofofo, ati nkan ti o yatọ si iyẹn ninu nkan ti Ọlọhun - ti O tóbi ti O gbọn-un-gbọn - kọ̀ kuro nibẹ, tabi ojiṣẹ Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -.

Ẹkọ ẹlẹẹkeji-din-logun: Ipalẹmọ oku ati kiki irun si i lara ati si sin in.

Eleyii ni alaye ìyẹn:

Ni akọkọ: Wọn ṣe lofin ninu ìlànà ẹṣin láti nu ẹniti npọkaka iku ní gbolohun “Laa ilaaha illal’loohu” ; latari ọrọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti o sọ pe:

«لَقِّنُوا مَوْتَاكُمْ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ».

"Ẹ maa nu awọn oku yin ni gbolohun Laa ilaaha illal’LLAHU"7 Muslim lo gba a wa ninu sohiihu (tira) rẹ, Ati pe nkan ti wọn gbà lero pẹlu awọn tí wọn ti ku ninu hadīth yii ni: Awọn ti wọn pọkaka iku lọwọ , awọn naa ni awọn ti awọn ami iku ti han loju wọn.

Ẹlẹẹkeji: Ti o ba tí hàn dájú pé o tiku , wọn o fi ọwọ wọ oju rẹ mejeeji walẹ, wọn o si di agbọn rẹ pọ mọ ẹnu rẹ, nitori pe o wa ninu Sunnah.

Ẹlẹẹkẹta: Wiwẹ oku musulumi jẹ dandan ayaafi ti o ba jẹ ẹni ti o ku si oju ogun, dajudaju a o nii wẹ ẹ, a o si nii kirun si i lara, a maa sin in pẹlu aṣọ rẹ; toripe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ko wẹ awọn ti wọn ku si oju ogun Uhud, ko si kirun si wọn lara.

Òhun ni kí wọn o bo ihoho rẹ, lẹyin naa wọn yóò gbe e soke diẹ, ti wọn o si fi ọwọ fun ikun rẹ pẹlu pẹlẹpẹlẹ, lẹyin naa ni ẹni ti o fẹ wẹ yóò so egige aṣọ kan mọ ọwọ rẹ tabi nkan ti o jọ ọ (gẹgẹ bí ibọwọ) lati fi ṣe imọra fun un, lẹyin naa ni yio ṣe aluwala irun fun un, lẹyin naa ni yio wẹ ori rẹ ati irungbọn rẹ pẹlu omi ati sidir tabi nnkan ti o ba jọ ọ, lẹyin naa ni yio wẹ ẹgbẹ ọtun rẹ, lẹyin naa ẹgbẹ osi rẹ, lẹyin naa yio wẹ ẹ bẹẹ ni eekeji ati ẹẹkẹta, ti yio maa mu ọwọ rẹ kọja lori ikun rẹ ni gbogbo igba, ti nkankan ba si jade yio fọ ọ, ti yio si di aaye naa (aaye ti ẹgbin ti n jade) pẹlu owu tabi nkan ti o jọ ọ, ti ko ba wa dùro yio lo amọ gbigbona tabi awọn nkan iṣegun igbalode lati fi di i; gẹgẹ bii pilasita tabi nkan ti o jọ ọ.

Yóò tun aluwala rẹ ṣe, ti ko ba mọ ni ẹẹmẹta yóò ṣe alekun rẹ titi di ẹẹmarun-un, tabi ẹẹmeje, lẹyin naa yóò nu u lara pẹlu aṣọ, ti yoo fi lọfinda si awọn ibi ti ẹgbin ba parapọ si (abiya), ati awọn aaye iforikanle rẹ, ti o ba si jẹ pe o fi lọfinda si gbogbo ara rẹ ìyẹn naa daa, wọ́n maa ko awọn aṣọ oku naa jọ pẹlu turari, ti irun imu rẹ tabi awọn èékánná rẹ ba gun wọ́n maa mu kuro nibẹ, ti wọ́n ba si fi iyẹn silẹ ko si ẹṣẹ nibẹ, wọn ko nii tu irun rẹ silẹ, wọn ko nii fa irun abẹ ikun rẹ, wọn ko nii dabẹ fun un; nitori aisi ẹri lori iyẹn, wọ́n maa ko irun obinrin jọ si kiko mẹta, ti wọn yoo da silẹ ni apa ẹyin rẹ.

Ikarun-: Fífún oku ní aṣọ

Eyi ti o daa julọ ni ki wọn fún ọkùnrin ni aṣọ mẹta funfun ti ko si ẹwu tabi lawani nibẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọn gbe wọ ọ ni ti gbigbe wọ, ti wọn ba fun oku ni aṣọ ti nṣe ẹwu ati iro ati ibora ko si laifi nibẹ.

Ati pe obinrin wọn maa da aṣọ bo o ninu aṣọ márùn-ún: Awọ soke aṣọ, ati aṣọ ti o maa bo o lati ori de ilẹ̀, ati iro ati ìbora meji. Wọn maa da aṣọ bo ọmọde lọ́kùnrin ninu aṣọ kan ṣoṣo si aṣọ mẹta, wọn si maa da aṣọ bo ọmọde lobinrin ninu ẹwu ati ibora meji.

Nnkan ti o jẹ dandan ti gbogbo oku lẹtọ si ni aṣọ kan ṣoṣo ti yóò bo gbogbo ara oku, ṣùgbọ́n ti oku naa ba jẹ ẹni ti o ti gbe harami wọ, wọn maa wẹ ẹ pẹlu omi ati ewe sidiru, wọn si maa da aṣọ bo o pẹlu iro rẹ ati ibora rẹ tabi pẹlu eyi ti o yàtọ̀ si i, wọn ko si nii bo ori rẹ tabi oju rẹ, wọn ko si nii fin lọfinda si i; nitori pe wọn maa gbe e dide ni ọjọ igbende ni ẹni ti o n ṣe Labaika ni, gẹgẹ bi o ṣe ni alaafia ninu Hadith lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a -, ti ẹni ti o gbe harami ba jẹ obinrin wọn yóò da aṣọ bo o gẹgẹ bi ẹni ti o yatọ si i, ṣugbọn wọn ko nii fin lọfinda si ara rẹ, wọn ko si nii bo oju rẹ pẹlu iboju, tabi ọwọ rẹ mejeeji pẹlu ibowọ meji, ṣùgbọ́n wọn maa bo oju rẹ ati ọwọ rẹ mejeeji pẹlu aṣọ oku ti wọn fi bo o, gẹgẹ bi alaye dida aṣọ bo obìnrin ṣe ti ṣíwájú.

Ẹlẹẹkẹfa: Ẹni ti o lẹ́tọ̀ọ́ julọ ninu awọn eniyan si wiwẹ oku ati kiki irun si i lara ati sisin in

ẹniti o sọ asọọlẹ rẹ fun, lẹyinna ni baba, lẹyinna ni baba-baba, lẹyinna ni alasunmọ ati alasunmọ ninu awọn ti maa njẹ asẹkubọ awọn ologun ti a ti pebubu ni ibamu si ti ọkunrin.

Ẹniti o lẹtọ si wiwẹ obinrin: ni moẹniti o sọ asọtẹlẹ rẹ fun, lẹyin naa ni iya, lẹyin naa ni iya-iya, lẹyin naa ni alasunmọ ati alasunmọ ninu awọn obinrin, ọkọ ati iyawo naa si le wẹ arawọn; toripe As’siddiq – ki Ọlọhun yọnu si i – iyawo rẹ lo wẹ ẹ, atipe dajudaju Aliyy – ki Ọlọhun yọnu si i – lo wẹ iyawo rẹ Faatimah – ki Ọlọhun yọnu si i.

Ẹlẹẹkeje: Alaye ikirun si oku lara:

Yio ṣe Alloohu Akbar ni ẹẹmẹrin, ohun ti yio ka lẹyin alakọkọ ni: Faatiah, ti o ba si ka Suurah kúkúrú pẹlu rẹ tabi Aayah kan tabi Aayah meji o daa, latari hadiith ti o fi ẹsẹ rinlẹ ti o wa lori ẹ lati ọdọ ọmọ Abbaas – ki Ọlọhun yọni si awọn mejeeji, lẹyinna yio ṣe Alloohu Akbar ẹlẹẹkeji, yio wa ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – gẹgẹbi asalaatu ibi ataaya, lẹyinna ni yio ṣe Alloohu Akbar ẹlẹẹkẹta, yio wa sọ pe: Ọlọhun dakun se aforijin fún aláayè wa àti òkú nínú wa, àti ẹni t'owa nibi ati ẹni tí kòsí nibi àti ọmọ kékeré wa àti agbalagba wa, àti Ọkùnrin wa àti Obìnrin nínú wa, Ọlọhun o dakun ẹni tí ọ ba sẹku saye nínú wa jẹ kí ọ máa sẹku lórí Islam, ẹni tí o ba gba èmí rẹ nínú wa dakun gba èmí rẹ lórí ìgbàgbọ, Ọlọhun ba wa forijin òkú yii kí o si bá wa kẹ ẹ, ba wa ṣe amojukuro fún un, ba wa fún ní ilera, ba wa ṣe apọnle aaye isọkalẹ sí rẹ, ba wa gbàá láàyè nínú saare rẹ, ba wa wẹ ẹ pẹlu omi àti omi tútú àti yìnyín, ba wa fọ mọn nibi aṣiṣe rẹ gẹgẹ bí wọn ṣe má nfọ aṣọ funfun mọ níbi idọti, ba wa fi ilẹ to dáa ju ilẹ rẹ lọ parọ fun, àti ara ile to daaju ara ile rẹ lọ parọ fun, ba wa fi sí alujanah ( Ọgbà idẹra), kí o si bá wa sọ níbi iya saare àti níbi iya ina, ba wa gbàá laaye nínú saare rẹ, kí ò sì ba wa tan imọlẹ sí, Ọlọhun má ṣe laada àti ẹsan ikirun leewọ fún wa, bẹẹni má se jẹ kí a sọnu lẹyin iku rẹ.

(Allaahumm-aghfir li ḥayyinaa wa mayyitinaa, wa shaahidinaa wa ghaa’ibinaa, wa sagheerinaa wa kabeerinaa, wa dhakarinaa wa unthaanaa, Allaahumma man ahyaytahu minnaa fa-ahyihi ‛alaal-islaam, wa man tawaffaytahu minnaa fa tawaffahu ‛alaal-’eemaan, Allaahumma igfir lahu war hamhu wa 'aafihi wa'fu anhu wa akrim nuzulahu, wa wassi' mudkholahu wag silhu bil maahi wath-thalji wal barad, wa naqqihi minal khotooya kamaa yunnaqqa thaobul abyadu minad danas, wa abdilhu daaron khoiron min daarihi, wa ahlan khoiron min ahlihi, wa adkhilhul jannata, wa a'idh-hu min 'azabil qobri wa' azabin naar wafsah lahu fi qobrihi wa nawwir lahu fiihi, Allaahumma laa tahrimnaa ajrahu, wa laa tudillanaa ba‛dah), Lẹyinna yio ṣe Alloohu Akbar ẹlẹẹkẹrin, ( Ọlọhun lotobi jùlọ) yio wa salamọ ni ẹẹkan si apa ọtun rẹ .

Wọn ṣe ni nnkan ti a fẹ lati gbe ọwọ mejeeji soke pẹlu gbogbo takbīrah kọọkan, ti oku naa ba jẹ obinrin, a o sọ pe: Ọlọhun ṣe aforijin fún (Allaahumma-igfir laha...) titi de ipari, ti awọn oku naa ba jẹ meji, a o sọ pe: Ọlọhun ṣe aforijin fún awan méjèjì (Allaahumma-igfir lahumaa...) titi de ipari, ati pẹlu ọpọ ti awọn oku naa ba pọ ju iyẹn lọ, a o sọ pe: Ọlọhun ṣe aforijin fún wàn (Allaahumma-igfir lahum...) titi de ipari, amọ ti o ba jẹ ọmọde ti o ṣiwaju, a o sọ dipo adua aforijin fun un pe: Ọlọhun ṣe e ni oun adele ba àti òun iti sí waju fún awọn òbí rẹ méjèjì, àti ẹni tí wọn yóò gba isipẹ rẹ, Ọlọhun fi ṣe sababi titẹṣuwọn iṣẹ awọn méjèjì, kí O sì fi ṣe sababi gbigbé ẹsan awọn méjèjì tobi, ba wa daa papọ mọn awọn asíwájú tí wọn jẹ ẹni rere ninu awọn mumini, ba wa jẹ kí o wa ni abẹ itọju àti amojuto Ibrahim - kí a lalafia àti ikẹ Ọlọhun máa ba -, ba wa sọ pẹlu aanu àti ikẹ rẹ níbi ìyá ina jahim

(Allaahumma-j'alhu furtan wa dhukhran li waalidaihi, wa shafii'an mujaaban, Allāhumma thaqqil bihi mawaaziinahumaa, wa-a'zim bihi ujuurohumaa, wa alhikhu bi soolihi salafil mu'mineen, waj-alhu fi kafaalati Ibrahim 'alayhis solaatu was salaam, wa qihi bi rahmatika 'azaabal jahiim).

Sunnah ( ìlànà anọbi ) ni ki imam o duro ṣíwájú ni ọgangan ori ọkùnrin, ati aarin obinrin, ki ọkùnrin wa ninu awọn ti o maa tẹle imam ti awọn ti wọn fẹ kirun si oku lara ba kojọpọ, ki obinrin si wa ninu awọn ti o maa tẹle Qibla (ibudajukọ), ti awọn ọmọde ba wa laaarin wọn, ọmọdékùnrin máa ṣíwájú obinrin, lẹyin naa obinrin, lẹyin naa ọmọdébìnrin, ti ori ọmọdékùnrin maa wa ni agbegbe ori ọkùnrin, ati aarin obinrin maa wa ni agbegbe ori ọkùnrin, bakannaa ni ọmọdébìnrin, ori rẹ maa wa ni agbegbe ori obinrin, aarin rẹ maa wa ni agbegbe ori okunrin, gbogbo awọn olukirun pata maa wa lẹyin imam, afi ti ẹnikan ko ba ri aaye lẹyin imam yoo duro ni ẹgbẹ ọtun rẹ.

Ẹlẹẹkẹjọ: Alaye sinsin oku

Eyi ti a ṣe ni ofin ni gbigbẹ saare ki o jin titi de aarin ọkùnrin, ati pe ki o jẹ lahdi (ki wọn gbẹ ihò síi lẹgbẹ) lati agbegbe ìdojúkọ Qibla, ki wọn si gbe oku sinu lahdi lori ẹgbẹ rẹ ọtun, ki wọn si tu koko aṣọ tí wan fí di oku, ki wọn má fa a ja, bi ko ṣe pe ki wọn fi i silẹ, ki wọn má ṣi oju rẹ kalẹ yala oku jẹ ọkunrin ni tabi obinrin, lẹyin naa ki wọn da erupẹ amọ̀ le e lori, ki o di amọ titi o fi maa rinlẹ ki o le ṣọ ọ nibi yepẹ, ti amọ ko ba rọrun ki o jẹ eyi ti o yàtọ̀ si gẹgẹbi awọn ọpọn, tabi awọn okuta, tabi awọn pako ti yoo sọ ọ nibi yepẹ, lẹ́yìn naa ni wọn maa rọ iyepẹ le e lori, wọn ṣe e ni nnkan ti a fẹ ki a maa sọ nibi iyẹn ni pe: (Bismillah, wa 'alaa millati Rọsuulillaahi), ìtumọ rẹ nipe: Pẹlu orúkọ Ọlọhun àti lórí ìlànà òjíṣẹ Ọlọhun) wọn maa gbe saare soke ni odiwọn nnkan ti a le fi ọwọ wọn, ki wọn si gbe awọn okuta wẹ́wẹ́ le e lori ti o ba rọrun bẹ , ki wọn si wọn omi le e lori.

Wọn wa ṣe e lofin fun awọn ti wọn ba tẹle oku ki wọn o duro nibi saare lẹniti yio maa tọrọ adua fun oku nitori pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹniti o ṣe pe ti o ba ti pari eto sinsin oku tan, yio wa duro sibi saare naa, yio wa sọ pe:

«اسْتَغْفِرُوا لِأَخِيكُمْ، وَاسْأَلُوا لَهُ التَّثْبِيتَ، فَإِنَّهُ الْآنَ يُسْأَلُ».

"Ẹ maa tọrọ aforijin fun ọmọ iya yin ninu ẹsin, ki ẹ si maa beere fun itọ ahọn sọna si oju ọna, (ìdúró ṣinṣin) nitori pe ni isinsinyi, wọn ti nbi i leere awọn ibeere"8.

Ẹlẹẹkẹsan-an: Wọn ṣe e ni ofin fun ẹni ti ko ba kirun si i lara lati ki i si lara lẹyin ti wọn ba sin in tan;

Nitori pe Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - ṣe bẹẹ, lori pe ki eleyiun waye laaarin oṣu kan tabi ki o kere si i, ṣugbọn ti asiko náà ba ti ju bẹẹ lọ, wọn kò ṣe ikirun si saare lara lofin; nitori pe wọn ko gba ìru rẹ wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - pe o kirun si saare lara lẹyin oṣu kan ti wọn ti sin oku.

Ẹlẹẹkẹwaa: Ko lẹ́tọ̀ọ́ fun awọn ara ile oku lati se oúnjẹ fun awọn eniyan; nitori ọrọ Jareer ọmọ Abdullah Al-Bajaliy sahaabe ti o pataki- ki Ọlọhun yọnu si i-

«كُنَّا نَعُدُّ الِاجْتِمَاعَ إِلَى أَهْلِ الْمَيِّتِ وَصَنْعَةَ الطَّعَامِ بَعْدَ الدَّفْنِ مِنَ النِّيَاحَة».

"A maa n ka kikojọpọ si ọdọ ara ile oku ati didana ounjẹ lẹyin igba ti eto sinsin oku ti pari, a maa n ka a si ibarajẹ àti isun ẹkùn lórí òkú "9 Imam Ahmad lo gba a wa pẹlu ẹgbawa ti o daa,

Ṣùgbọ́n sise oúnjẹ fun wọn, tabi fun awọn alejo wọn ko si laifi nibẹ, wọn ṣe e lofin fun awọn alasunmọ rẹ ati awọn aládugbò rẹ lati se oúnjẹ fun wọn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà ti iro iku Ja'far ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- ni ilu Shaam de waa ba a, o pàṣẹ fun àwọn ara ile rẹ lati ṣe oúnjẹ fun awọn ara-ile Ja'far, o sọ pe:

«إِنَّهُ أَتَاهُمْ مَا يَشْغَلُهُمْ».

"Dajudaju ohun ti yoo ko airoju ba wọn ti wa de ba wọn"10.

Ko si ẹṣẹ fun awọn arale oku ki wọn o pe awọn alamuleti wọn tabi awọn ti o yatọ si wọn lati wa jẹ ninu ounjẹ ti wọn fi tọrẹ fun wọn, ati pe ìyẹn o si ni asiko kan pato nibamu si nkan ti a mọ ninu ofin ẹsin.

Ẹlẹẹkọkanla: Ko lẹtọ fun obinrin ki o ṣe opo( ifarada ìbànújẹ ) fun oku kankan tayọ ọjọ mẹta ayaafi fun ọkọ rẹ.

Dajudaju o jẹ dandan fun un ( obìnrin) ki o ṣe opo fun un fun oṣu mẹrin ati ọjọ mẹwa, ayaafi ti o ba jẹ oloyun, ti tiẹ si di igbati o ba bímọ; latari ririnlẹ sunnah ti o ni alaafia lati ọdọ anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pẹlu ìyẹn.

Ṣugbọn ọkunrin ko lẹtọ fun ki o ṣe igbele fun ìbànújẹ ẹnikẹni ninu awọn alasunmọ tabi ẹni ti o yatọ si wọn.

Ẹlẹẹkejila: Wọn ṣe e lofin fun awọn ọkunrin láti ṣe abẹwo saare laarin asiko kan si omiran lati ṣe adura fun wọn ati lati tọrọ ikẹ fun wọn ati lati le ranti iku ati nkan ti o wa lẹyin rẹ.

nitori ọrọ Anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe:

«زُورُوا الْقُبُورَ، فَإِنَّهَا تُذَكِّرُكُمُ الْآخِرَةَ».

«Ẹ maa ṣe abẹwo saare, toripe dajudaju yio maa ran yin leti ọjọ ikẹhin»11 " Muslim lo gbe e jade ninu sohiihu rẹ. "

ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o maa n kọ awọn saabe rẹ nigbati wọn ba bẹ saare wo pe ki wọn maa sọ pe:

«السَّلَامُ عَلَيْكُمْ أَهْلَ الدِّيَارِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُسْلِمِينَ، وَإِنَّا إِنْ شَاءَ اللَّهُ بِكُمْ لَاحِقُونَ، نَسْأَلُ اللَّهَ لَنَا وَلَكُمُ الْعَافِيَةَ، يَرْحَمُ اللَّهُ الْمُتَقَدِّمِينَ مِنَّا وَالْمُسْتَأْخِرِينَ».

"As salaamu alaykum ahlad- diyaar minal mu'miniina wal muslimiin, wa innaa insha Allahu bikum laahiquun, nas'alu llaha lanaa wa lakumu al aafiyah, yar'hamu llahul mutaqọdimiina minnaa wal mutahakhiriina" itumọ rẹ ni pe: Alaafia Ọlọhun ki o maa ba yin ẹyin ara itẹ ninu ẹyin olugbagbọ ododo ati musulumi, ati pe awa naa nbọ wa dára pọ mọn yin pẹlu ogo Ọlọhun, awa tọrọ alaafia lati ọdọ Ọlọhun fun yin ati fun awa naa, ki Ọlọhun o kẹ awọn ti wọn siwaju ku ati awọn ti o kẹyin ku ninu wa12.

Ṣugbọn awọn obinrin bíbẹ saare wo ko si fun wọn; toripe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sẹbi le awọn olùṣe abẹwo saare lóbìnrin, ati pe wọn n paya fitina ati aito suuru nibi ṣiṣe abẹwo wọn, bẹẹ gẹlẹ ni pe ko lẹtọ fun wọn titẹle oku lọ si itẹ; toripe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ fun wọn kuro nibi iyẹn. Ṣugbọn kikirun si oku lara ni mọsalasi, abi ni gbangba ita ikirun, eleyi jẹ ohun ti wọn ṣe lofin fun awọn ọkunrin ati awọn obinrin lapapọ.

Eleyii ni opin nkan tí o rọrun láti ko jọ. Ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ ki o maa ba Anabi wa Muhammad, ati awọn arale rẹ ati awọn saabe (ọmọ lẹyìn rẹ) rẹ.

 

 

***

Index

 

Ni orukọ Ọlọhun Ọba Ajọke aye Ọba Aṣakẹ ọrun 2

Ọrọ iṣiwaju lat'ọdọ Onkọwe 2

Ẹkọ alakọkọ: Sūratul Fātiah ati awọn sūrah kukuku (Èyí tí kò gùn) 3

Ẹkọ ẹlẹẹkeji: Awọn origun ẹṣin Isilaamu 3

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta ni: Awọn origun igbagbọ. 4

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin: Awọn ipin taoheed (imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo) ati awọn ipin shirk (imu orogun mọ Ọlọhun). 4

Ẹkọ ẹlẹẹkarun-un: iṣe Daadaa 10

Ẹkọ ẹlẹẹkẹfa: Awọn majẹmu irun. 10

Ẹkọ ẹlẹẹkeje: Awọn origun irun 11

Ẹkọ ẹlẹẹkẹjọ: Awọn ọranyan irun. 11

Ẹkọ ẹlẹẹkẹsan: Alaye ataayah 12

( gbólóhùn ijẹri). 12

Ẹkọ ẹlẹẹkẹwa: Awọn sunnah irun 14

Ẹ̀kọ́ ẹlẹẹkọkanla: Awọn nnkan tin nba irún jẹ 16

Ẹkọ ẹlẹẹkejila: Awọn majẹmu aluwala 16

Ẹkọ ẹlẹẹkẹtala: Awọn ọran-anyan aluwala 17

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrinla: Awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ 17

Ẹkọ ẹlẹẹkẹdogun: Ṣiṣe ọṣọ pẹlu awọn iwa ti wọn ṣe lofin fun gbogbo musulumi. 18

Ẹkọ ẹlẹẹkẹrin-din-logun: Lilo awọn ẹkọ Isilaamu. 19

Ẹkọ ẹlẹẹkẹta-din-logun: Isọni lara kuro nibi mimu orogun mọ Ọlọhun ati awọn oríṣiriṣi ẹṣẹ. 19

Ẹkọ ẹlẹẹkeji-din-logun: Ipalẹmọ oku ati kiki irun si i lara ati si sin in. 20

 

 

***

 


Imām Ahmad lo gbe e jade (5/428), ati At-Tọbarọọniy ninu Al-Kabīr (4/338), ati Bayhaqiy ninu Ash-Shu‘ab (14/355), o sọ ninu Majma‘ Az-Zawā’id (1/121) pé: Ahmad lo gbe e jade, àwọn arọ́wọ́ rẹ̀ sì ni àwọn arọ́wọ́ As-Sọhīh.

Imam Ahmad ni o gbe e jade (1/47).

Abu Daa'ud ni o gbe e jade (3251), ati Tirmidhi (1535).

Abu Dawood ni o gbe e jade (4980), ati Ahmad (5/ 384).

Ibnu Mājah ni o gbe e jáde (4204), ati Imām Ahmad (3/30).

Muslim ni o gbe e jade, (916-917).

Abu Daa'ud ni o gbe e jade, pẹlu ounka (3221), ati Haakim (3/ 399).

Ibnu Mājah ni o gbe e jade (1612), ati Imam Ahmad (2/204).

Muslim Al-janāiz (976), An-nasāi Al-janāiz (2034), Abu Dāud Al-janāiz (3234), Ibnu Maajah Maa jā'a fi Al-janāiz (1569), Ahmad (2/441).

Ibnu Mājah ni o gbe e jáde, (1569), Albaaniy sọ pé ó ní àlàáfíà.

Muslim ni o gbe e jade (975).

Apapọ awan ìdáhùn sí ibere ọrọ ẹṣin àti awàn orísirísi ọrọ apilekọ (3/ 288- 298).