نُبذَةٌ فِي العَقِيدَةِ الإِسْلَامِيَّة (شَرْحُ أُصُولِ الإِيمَانِ)
Ọrọ ṣoki nipa adisọkan ti Isilaamu
بِقَلَم فَضِيلَة الشَّيخ العَلَّامَة
مُحَمَّدِ بْنِ صَالِحٍ العُثَيمِين
غَفَرَ اللَّهُ لَهُ وَلِوَالِدَيْهِ وَلِلْمُسْلِمِين
Lati ọwọ Ọlọla julọ Sheikh ọlọpọlọpọ mimọ
Muhammad ọmọ Solih Al-Uthaymīn
Ki Ọlọhun fi ori jin in ati awọn obi rẹ mejeeji ati gbogbo Musulumi
بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ
Ọrọ ṣoki nipa adisọkan ti Isilaamu
Pẹ̀lú orúkọ Ọlọhun, Ajọke-aye Aṣakẹ-ọrun
Ọrọ iṣaaju
Dajudaju gbogbo ọpẹ n bẹ fun Ọlọhun, a n dupẹ fun Un, a n wa iranlọwọ lọ si ọdọ Rẹ, a n wa aforijin Rẹ, a n ronú piwada lọ si ọdọ Rẹ, A n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn aburu awọn ẹmi wa, ati kuro nibi awọn aburu iṣẹ wa, Ẹni ti Ọlọhun ba fi mọna ko si ẹni ti o le ṣi i lọna, ẹni ti O ba sọ nu ko si afinimọna fun un, Mo n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si afi Allohu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, Mo n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni Ojiṣẹ Rẹ ni, ki Ọlọhun kẹ ẹ ati awọn ara ile rẹ, ati awọn sọhaba rẹ, ati ẹni ti o ba tẹle wọn pẹlu daadaa, ki O si ṣe ọlà fun un.
Lẹyin naa: Dajudaju (Imọ imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo nibi ìjọsìn) ni eyi ti o ni ọla julọ ninu awọn imọ, ati eyi ti o gbọnngbọn julọ ninu awọn ni ti iyi, ti o si jẹ dandan julọ lati wa; nitori pe dajudaju oun ni imọ nipa Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn iwọ̀ Rẹ lori awọn ẹru Rẹ, ati nitori pe oun ni kọkọrọ oju-ọna lọ si ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati ipilẹ awọn ofin Rẹ
Nitori eyi: Awọn Ojiṣẹ fi ẹnu kò lori ipepe lọ si ọdọ Rẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِيٓ إِلَيۡهِ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدُونِ25﴾
{A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi}.
[Surah Al-Anbiyâ’: 25]
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- jẹrii fun ara Rẹ pẹlu ijẹ ọkan ṣoṣo, ti awọn mọlaika Rẹ naa jẹrii fun Un pẹlu rẹ, ati awọn onimimọ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَأُوْلُواْ ٱلۡعِلۡمِ قَآئِمَۢا بِٱلۡقِسۡطِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 18﴾
{Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n}. [Surah Âl-`Imrân: 18]
Nigba ti ọrọ imu Ọlọhun lọkan ti ri bayii, o jẹ dandan lori gbogbo Musulumi kọọkan lati ko akolekan pẹlu rẹ ni ti kikọ, ati ni ti kikọ ẹlomiran, ati ni ti ironu si, ati ni ti adisọkan; lati le mọ ẹsin rẹ lori ipilẹ ti o ni alaafia, ati ifayabalẹ ati gbígbà fún pátápátá; titi yio fi ṣe oriire pẹlu awọn eso rẹ, ati awọn abajade rẹ
Ọlọhun ni olufini ṣe kongẹ
Olukọwe
Ẹsin Isilaamu
Ẹsin Isilaamu: Oun ni ẹsin ti Ọlọhun gbe Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dide pẹlu rẹ ti O si pari awọn ẹsin pẹlu rẹ, ti O pé e fun awọn ẹru Rẹ, O si ṣe aṣepe idẹra le wọn lori pẹlu rẹ ti O yọnu si i ni ẹsin fun wọn, ti ko si nii gba ẹsin ti o yatọ si i lọwọ ẹni kankan, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا 40﴾
{(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan}.
[Surah Al-Ahzâb: 40]
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...ٱلۡيَوۡمَ أَكۡمَلۡتُ لَكُمۡ دِينَكُمۡ وَأَتۡمَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ نِعۡمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ ٱلۡإِسۡلَٰمَ دِينٗا...﴾
{…Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fun yín…}. [Surah Al-Mâ'idah: 3]
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿إِنَّ ٱلدِّينَ عِندَ ٱللَّهِ ٱلۡإِسۡلَٰمُ...﴾
{Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām…}.
[Surah Âl-`Imrân: 19]
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَمَن يَبۡتَغِ غَيۡرَ ٱلۡإِسۡلَٰمِ دِينٗا فَلَن يُقۡبَلَ مِنۡهُ وَهُوَ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 85﴾
{Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò}. [Surah Âl-`Imrân: 85]
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ṣe ni dandan lori gbogbo awọn eniyan lati jọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu rẹ, O sọ ni ẹni ti O ba Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọrọ pe:
﴿قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡ جَمِيعًا ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِ ٱلنَّبِيِّ ٱلۡأُمِّيِّ ٱلَّذِي يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَكَلِمَٰتِهِۦ وَٱتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ 158﴾
{Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni t’Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà}.
[Surah Al-A`râf: 158]
O wa ninu Sohiihu Muslim: Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju o sọ pe:
«وَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَا يَسْمَعُ بِي أَحَدٌ مِنْ هَذِهِ الْأُمَّةِ يَهُودِيٌّ وَلَا نَصْرَانِيٌّ، ثُمَّ يَمُوتُ وَلَمْ يُؤْمِنْ بِالَّذِي أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَّا كَانَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ».
“Mo fi ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ nípa mi ninu ijọ yii, Júù lo jẹ ni tabi Kristẹni, lẹyin naa ni o wa ku, ti ko si gbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ki o wa ninu awọn ero ina”.
Nini igbagbọ pẹlu rẹ: Gbigba nnkan ti o wa pẹlu rẹ ni ododo pẹlu gbigba a wọle ati itẹriba, ko nii jẹ gbigba lododo nikan, fun idi eyi ni Abu Tolib ko fi jẹ onigbagbọ nínú Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu gbigba nnkan ti o wa pẹlu rẹ ni ododo, ati ijẹrii rẹ pe dajudaju o wa ninu eyi ti o daa julọ ninu awọn ẹsin
Ẹsin Isilaamu: O ko gbogbo anfaani ti awọn ẹsin iṣaaju ko sínú si inú, ti o si yatọ si wọn pẹlu pe o daa fun gbogbo igba ati aaye ati ìjọ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ti O n ba Ojiṣẹ Rẹ sọrọ pe:
﴿وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمُهَيۡمِنًا عَلَيۡهِ...﴾
{A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀…}.
[Surah Al-Mâ’idah: 48]
Itumọ didaa rẹ fun gbogbo asiko ati aaye ati ìjọ ni: Dajudaju gbigba a mu ko tako awọn anfaani ìjọ ni eyikeyi asiko tabi aaye, bi ko ṣe pe oun ni didaa rẹ, itumọ ìyẹn ko kii ṣe pe o tẹriba fun gbogbo asiko ati aaye ati ìjọ, gẹgẹ bi apakan ninu awọn eniyan ṣe fẹ ẹ bẹẹ
Ẹsin Isilaamu: Oun ni ẹsin ododo ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi ọwọ́ sọ̀yà fun ẹni ti o ba dirọ mọ ọn bi o ṣe yẹ lati ran an ṣe, yio si maa fi borí ẹni ti o yatọ si i, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿هُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلۡهُدَىٰ وَدِينِ ٱلۡحَقِّ لِيُظۡهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُشۡرِكُونَ 9﴾
{(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀}.
[Surah As-Saff: 9]
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَيَسۡتَخۡلِفَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ كَمَا ٱسۡتَخۡلَفَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَلَيُمَكِّنَنَّ لَهُمۡ دِينَهُمُ ٱلَّذِي ٱرۡتَضَىٰ لَهُمۡ وَلَيُبَدِّلَنَّهُم مِّنۢ بَعۡدِ خَوۡفِهِمۡ أَمۡنٗاۚ يَعۡبُدُونَنِي لَا يُشۡرِكُونَ بِي شَيۡـٔٗاۚ وَمَن كَفَرَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 55﴾
{Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe àrólé. Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́}. [Surah An-Nûr: 55]
Ẹsin Isilaamu: Adisọkan ni, ati ofin, o pe nibi adisọkan rẹ, ati awọn ofin rẹ:
1- O n pàṣẹ pẹlu imu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni ọkan ṣoṣo nibi ijọsin ati pe o n kọ kuro nibi ẹbọ
2- O n paṣẹ pẹlu ododo sisọ, o si n kọ kuro nibi irọ pipa
3- O n paṣẹ pẹlu ṣíṣe deedee o si n kọ kuro nibi ojoro, deedee ni ṣíṣe dọgba laarin nnkan ti o jẹ nǹkan kan naa, ati ṣíṣe iyatọ laarin nnkan ti wọn yatọ si ara wọn, deedee ko kii ṣe ṣíṣe dọgba ti a kàn tú sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, bi awọn kan ṣe maa n pe e nigba ti wọn ba n sọ pe: Ẹsin Isilaamu jẹ ẹsin ọgbọọgba, o maa wa tu u silẹ bẹ́ẹ̀, dajudaju ọgbọọgba laaarin awọn nnkan ti wọn yatọ si ara wọn jẹ àbòsí kan ti Isilaamu ko le mu wa, ti ko si le yin ẹni ti o ba ṣe e
4- O n pàṣẹ pẹlu jijẹ olufọkantan, o si n kọ kuro nibi jijanba
5- O n paṣẹ pẹlu imu adehun ṣẹ, o si n kọ kuro nibi jijanba àdéhùn
6- O n paṣẹ pẹlu ṣíṣe dáadáa si awọn obi mejeeji, o si n kọ kuro nibi ṣiṣẹ wọn
7- O n pàṣẹ pẹlu dida ẹbi pọ, awọn naa ni awọn mọlẹbi, o si n kọ kuro nibi gige okun ẹbi.
8- O n pàṣẹ pẹlu ṣíṣe daadaa si awọn ara adugbo, o si n kọ kuro nibi ṣíṣe aburu si wọn
Ni àkótán: Dajudaju (Isilaamu) n pàṣẹ pẹlu gbogbo iwa ọlọla, o si n kọ kuro nibi iwa iyẹpẹrẹ. O n pàṣẹ pẹlu gbogbo iwa rere, o si n kọ kuro nibi gbogbo iwa aburu
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَٱلۡإِحۡسَٰنِ وَإِيتَآيِٕ ذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَيَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِ وَٱلۡبَغۡيِۚ يَعِظُكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 90﴾
{Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí}. [Surah An-Nahl: 90]
Awọn origun Isilaamu
Awọn origun Isilaamu: Awọn ipilẹ rẹ ti o duro le lori, wọn jẹ marun-un:
مَذْكُورَةٌ فِيمَا رَوَاهُ ابْنُ عُمَرَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا، عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، أَنَّهُ قَالَ: «بُنِيَ الْإِسْلَامُ عَلَى خَمْسٍ: عَلَى أَنْ يُوَحَّدَ اللَّهُ -وَفِي رِوَايَةٍ: عَلَى خَمْسٍ-: شَهَادَةِ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، وَإِقَامِ الصَّلَاةِ، وَإِيتَاءِ الزَّكَاةِ، وَصِيَامِ رَمَضَانَ، وَالْحَجِّ». فَقَالَ رَجُلٌ: الْحَجُّ، وَصِيَامُ رَمَضَانَ؟ قَالَ: «لَا، صِيَامُ رَمَضَانَ، وَالْحَجُّ». هَكَذَا سَمِعْتُهُ مِنْ رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ.
Wọ́n darukọ wọn ninu nnkan ti Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si i- gba wa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju o sọ pe: “Wọn mọ Isilaamu pa lori nnkan marun-un kan: Lori pe ki wọn mu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo nibi ìjọsìn- ninu ẹgbawa kan “lórí nnkan marun-un kan”-: Jijẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn ododo tọ si afi Allohu, dajudaju Anabi Muhammad jẹ ẹru Rẹ ati Ojiṣẹ Rẹ, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigba awẹ Ramadan, ati lílọ si ile Oluwa”, arakunrin kan sọ pe: Lilọ si ile Olúwa, ati gbigba awẹ Ramadan? o sọ pe: “Rárá, gbigba awẹ Ramadan, ati lílọ si ile Oluwa”, báyìí ni mo ṣe gbọ ọ lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
1- Ṣugbọn jíjẹ́rìí pe ko si ẹni ti ìjọsìn ododo tọ si afi Allohu, dajudaju Anabi Muhammad jẹ ẹru Rẹ ati Ojiṣẹ Rẹ ni: Adisọkan ti o rinlẹ ti a n fi ahọn sọ ọ pẹlu ijẹrii yii, gẹgẹ bii pe o n wò ó pẹ̀lú bi o ṣe fi rinlẹ yii, bi ko ṣe pe wọn ṣe ijẹrii yii ni origun ẹyọkan pẹlu pé awọn ti a fi n jẹrii ju ẹyọkan lọ
Ninu ki o ṣe pe: Nitori pe Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni tí n jẹ iṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, nítorí naa ijẹrii fun Un pẹlu ijẹ ẹru ati ijẹ ojiṣẹ wa ninu aṣepe ijẹrii pe ko si ẹni ti ti ìjọsìn ododo tọ si afi Allohu
Tabi ki o ṣe pe: Nitori pe ijẹrii mejeeji naa ni ipilẹ nini alaafia awọn iṣẹ ati itẹwọgba wọn; nigba ti o ṣe pe ko si ini alaafia fun iṣẹ kan tabi itẹwọgba kan, afi pẹlu imọkanga fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati itẹle fun Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Ati pe pẹlu nini imọkanga fun Ọlọhun, jíjẹ́rìí pe: Ko si ẹni ti ìjọsìn ododo tọ si afi Allohu maa wa si imuṣẹ, ati pe pẹlu itẹle Ojiṣẹ Rẹ, jíjẹ́rìí pe: Anabi Muhammad jẹ ẹru Rẹ ati Ojiṣẹ Rẹ naa maa wa si ìmúṣẹ.
Ninu awọn eso ti wọn n bẹ fun ijẹrii ti o tobi yii ni: Titu ọkan silẹ ati ẹ̀mí kuro nínú ijẹ ẹru fun awọn ẹda, ati titẹle awọn ti wọn yatọ si awọn Ojiṣẹ
2- Sugbọn gbigbe irun duro: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu ṣíṣe e lori ojupanna ìdúróṣinṣin ati aṣepe ni awọn asiko rẹ, ati awọn ọna ti a n gba ṣe e.
Ninu awọn eso ti wọn n bẹ fun un: Ìṣípayá igba-aya, ati itutu oju, ati kikọ kuro nibi iwa ibajẹ ati ohun burúkú
Ṣùgbọ́n yíyọ saka: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu nina odiwọn ti o jẹ dandan ninu awọn dukia ti wọn lẹ́tọ̀ọ́ si yíyọ saka ninu wọn
Ninu awọn eso ti n bẹ fun un ni: Fifọ ẹmi mọ kúrò nínú iwa yẹpẹrẹ (Ahun) ati gbigbọ bukaata Isilaamu ati awọn Mùsùlùmí
Ṣùgbọ́n gbigba awẹ Ramadan: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu kiko ẹnu ro kuro nibi awọn nnkan ti n ba aawẹ jẹ ni ọsan Ramadan
Ninu awọn eso ti n bẹ fun un ni: Rire ẹ̀mí lori gbigbe àwọn nnkan ti a nífẹ̀ẹ́ si ju silẹ; lati wa iyọnu Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-
Ṣùgbọ́n lílọ si ile Oluwa: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu gbigbero ile ọwọ; lati ṣe awọn iṣẹ hajj
Ninu awọn eso ti n bẹ fun un ni: Rire ẹ̀mí lori nina igbiyanju ti dukia ati ti ara síbi itẹle Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; fun idi yii ni lílọ si ile Oluwa ṣe jẹ igbiyanju si oju ọna Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ati pe awọn eso ti a darukọ yii fun awọn ipilẹ yii ati awọn ti a ko darukọ wọn maa ṣe ìjọ naa ni ìjọ ti Isilaamu ti o mọ, ti o maa jọsin fun Ọlọhun ni ẹsin ododo, ti yoo si máa lò pẹlu ẹ̀dá pẹ̀lú deedee ati ododo Nitori pe nnkan ti o yatọ si i ninu awọn ofin Isilaamu n daa pẹlu dídára awọn ipilẹ yìí, ti awọn iṣesi ìjọ naa n daa pẹlu dídára alamọri ẹsin wọn, ti dídára awọn iṣesi wọn o maa bọ fun wọn pẹlu odiwọn nnkan ti o ba bọ fun wọn ninu dídára awọn alamọri ẹsin wọn
Ẹni ti o ba fẹ ṣe àwárí ìyẹn, ki o lọ ka ọrọ Ọba- ti ọla Rẹ ga-:
﴿وَلَوۡ أَنَّ أَهۡلَ ٱلۡقُرَىٰٓ ءَامَنُواْ وَٱتَّقَوۡاْ لَفَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَرَكَٰتٖ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِن كَذَّبُواْ فَأَخَذۡنَٰهُم بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 96 أَفَأَمِنَ أَهۡلُ ٱلۡقُرَىٰٓ أَن يَأۡتِيَهُم بَأۡسُنَا بَيَٰتٗا وَهُمۡ نَآئِمُونَ 97 أَوَأَمِنَ أَهۡلُ ٱلۡقُرَىٰٓ أَن يَأۡتِيَهُم بَأۡسُنَا ضُحٗى وَهُمۡ يَلۡعَبُونَ 98 أَفَأَمِنُواْ مَكۡرَ ٱللَّهِۚ فَلَا يَأۡمَنُ مَكۡرَ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 99﴾
{Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ará ìlú náà gbàgbọ́ lódodo ni, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), A ìbá ṣínà àwọn ìbùkún fún wọn láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n pe òdodo nírọ́. Nígbà náà, A mú wọn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní alẹ́ ni, nígbà tí wọ́n bá ń sùn lọ́wọ́?Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní ìyálẹ̀ta ni, nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré lọ́wọ́?Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu ni? Kò mà sí ẹni t’ó máa fàyà balẹ̀ sí ète Allahu àfi ìjọ olófo}. [Surah Al-A`râf: 96-99]
Ki o lọ wo itan àwọn ti wọn ṣaaju; dajudaju itan jẹ ariwoye fun awọn ọlọpọlọpọ, ati imọ amọdaju fun ẹni ti gaga o ba ti di ọkàn rẹ, Ọlọhun ni a n wa oore lọ si ọdọ Rẹ
Àwọn ipilẹ adisọkan ti Isilaamu
Ẹsin Isilaamu:- Gẹgẹ bi a ṣe ṣe alaye ṣiwaju- adisọkan ati ofin ni, a ti tọka si nnkankan ninu awọn ofin rẹ, a darukọ awọn origun rẹ ti a ka si ipilẹ fun awọn ofin rẹ
Ṣùgbọ́n adisọkan ti Isilaamu, awọn ipilẹ rẹ ni: Nini igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn mọlaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati kadara: Eyi ti o daa nibẹ, ati eyi ti o buru nibẹ
Tira Ọlọhun ti tọka si awọn ipilẹ yii, ati Sunnah Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Ninu iwe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni O n sọ pe:
﴿لَّيۡسَ ٱلۡبِرَّ أَن تُوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ قِبَلَ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ وَٱلۡكِتَٰبِ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ...﴾
{Kì í ṣe ohun rere ni kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni t’ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì…}. [Surah Al-Baqarah: 177] O n sọ nipa kadara pe:
﴿إِنَّا كُلَّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَٰهُ بِقَدَرٖ 49 وَمَآ أَمۡرُنَآ إِلَّا وَٰحِدَةٞ كَلَمۡحِۭ بِٱلۡبَصَرِ 50﴾
{Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá*Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú}. [Surah Al-Qamar:49-50]
Ninu Sunnah Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ ni ẹni ti o n da Jibril lohun nigba ti o bi i nipa igbagbọ pe:
«الْإِيمَانُ: أَنْ تُؤْمِنَ بِاللَّهِ، وَمَلَائِكَتِهِ، وَكُتُبِهِ، وَرُسُلِهِ، وَالْيَوْمِ الْآخِرِ، وَتُؤْمِنَ بِالْقَدَرِ: خَيْرِهِ وَشَرِّهِ ».
Igbagbọ ni: Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn mọlaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o ni igbagbọ ninu kadara: èyí ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru”
Nini igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ṣugbọn nini igbagbọ ninu Ọlọhun ko awọn alamọri mẹrin kan sinu:
Alamọri akọkọ: Nini igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-:
O ti tọka si bibẹ Rẹ- ti ọla Rẹ ga-: Adamọ, ati laakaye, ati sharia, ati imọlara
1- Ṣugbọn itọka adamọ lori bibẹ Rẹ- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-: Dajudaju gbogbo nnkan ti a da, wọn da wọn lori igbagbọ nínú Aṣẹ̀dá rẹ lai ṣẹ̀ṣẹ̀ maa ronú tẹ́lẹ̀, tabi kọ ẹ̀kọ́ kankan, ko si nii yẹ kuro nibi nnkan ti adamọ yìí n beere fun afi ẹni ti nnkan ti o le yi i ba ṣẹlẹ si ọkan rẹ;
«مَا مِنْ مَوْلُودٍ إِلَّا يُولَدُ عَلَى الْفِطْرَةِ، فَأَبَوَاهُ يُهَوِّدَانِهِ أَوْ يُنَصِّرَانِهِ أَوْ يُمَجِّسَانِهِ».
Fun ọrọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe: “Ko si ninu ẹni ti a bi kan afi ki wọn bi i lori adamọ, awọn obi rẹ mejeeji ni yio sọ ọ di Júù , tabi Kristẹni tabi Abọná”
2- Ṣugbọn itọka laakaye lori bibẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni pe awọn ẹda yii: Eyi ti wọn da ṣáájú rẹ ni ati èyí ti wọn da lẹyin rẹ ni, ko si ibuyẹ ti ko fi nii si Aṣẹ̀dá fun un ti O mu u bẹ; nigba ti o ṣe pe ko rọrun lati mu ara rẹ bẹ, ko si rọrun ki wọn maa bẹ pẹ̀lú èèsì
Ko rọrun ki wọn mu ara wọn bẹ fun ara wọn; nitori pe nnkan ko le ṣẹda ara rẹ; nitori pe ko sii ṣiwaju bibẹ rẹ, bawo ni yio ṣe jẹ aṣẹda?!
Ko si rọrun ki wọn maa bẹ pẹ̀lú èèsì; nitori pe gbogbo nnkan ti o ba n bẹ, dandan ni ki o ni ẹni ti o maa mu u bẹ. Torí pé bibẹ wọn lórí ètò ti o rẹwa yii, ati ìbámu ti o so pọ yii, ati asopọ ti o yi yii, láàrin àwọn okùnfà ati awọn nǹkan ti n fà á, ati laarin awọn nnkan ti n bẹ si ara wọn, eyi maa kọ̀ pátápátá ki bibẹ wọn o ṣèèṣì; torí pé nǹkan ti n ṣèèṣì bẹ, ko wulẹ̀ si lórí ètò ni ipilẹ bibẹ rẹ, bawo wa ni o ṣe maa ni ètò nígbà tí o wa n bẹ lọ ati igba ti o n dàgbà sókè si?
Ti ko ba rọrun ki awọn ẹda maa mu ara wọn bẹ fun ara wọn, ti wọn ko si maa bẹ ní ti ṣèèṣì; o di dandan ki wọn ni ẹni tí o maa mu wọn maa bẹ, Oun naa ni Allahu Oluwa awọn ẹda
Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti darukọ ẹri ti laakaye yii ati awijare ti ko si iyèméjì nibẹ ninu Surah At-Tur; níbi ti O ti sọ pe:
﴿أَمۡ خُلِقُواْ مِنۡ غَيۡرِ شَيۡءٍ أَمۡ هُمُ ٱلۡخَٰلِقُونَ 35﴾
{Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?} [Surah At-Tûr: 35]" O n tumọ si pe: Dajudaju wọn ko ṣẹda wọn láìsí Aṣẹda, wọn ko si ṣẹda ara wọn; o wa di dandan pe ki Aṣẹda wọn jẹ Allahu- ibukun ni fun Un ti ọla Rẹ ga- Fun idi eyi, nigba ti Jubayr ọmọ Mut’him- ki Ọlọhun yọnu si i- gbọ lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n ka Surah At-Tur, ni o wa de ibi àwọn aaya yii:
﴿أَمۡ خُلِقُواْ مِنۡ غَيۡرِ شَيۡءٍ أَمۡ هُمُ ٱلۡخَٰلِقُونَ 35 أَمۡ خَلَقُواْ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۚ بَل لَّا يُوقِنُونَ 36 أَمۡ عِندَهُمۡ خَزَآئِنُ رَبِّكَ أَمۡ هُمُ ٱلۡمُصَۜيۡطِرُونَ 37﴾
{Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?*Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni*Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn àpótí ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?}. [Surah At-Tûr: 35-37]
Nigba naa Jubayr jẹ oluṣẹbọ, o sọ pe: “Ọkan mi fẹẹ le fo, ìyẹn ni akọkọ igba ti igbagbọ maa wọ inu ọkan mi”.
Ki a mu apejuwe wa ti yio ṣe àlàyé ìyẹn: Ti ẹni kan ba ba ẹ sọrọ nipa ààfin kan ti o ga, ti awọn ọgba rọkirika rẹ, ti awọn akeremọdo n san ni abẹ rẹ, ti o kun fun awọn ìtẹ́ àti ibùsùn, ti wọn ṣe ọṣọ síbẹ̀ pẹlu awọn orisirisi ọṣọ ninu awọn nnkan ti o gbe e ro ati nnkan ti o mu u pe Ti wa sọ fun ẹ pe: Dajudaju ààfin yii ati nnkan ti o wa nibẹ ninu pipe ni o mu ara rẹ maa bẹ, tabi o kan ṣèèṣì maa bẹ bayii naa ni láìsí ẹni ti o n mu u maa bẹ, waa tete tako ìyẹn ti waa si pe e ni irọ, ti waa ka ọrọ rẹ si ọrọ agọ̀. Njẹ o lẹtọọ lẹyin ìyẹn ki aye ti o gbooro yii: pẹlu ilẹ rẹ, ati sánmà rẹ, ati awọn òpópónà róbótó rẹ, ati awọn iṣesi rẹ, ati eto rẹ ti o rẹwa ti o bùáyà, ki o jẹ pe oun ni o mu ara rẹ maa bẹ, tabi o n bẹ ní ti ṣèèṣì láìsí ẹni tí ó mu u maa bẹ?!
3-Ṣùgbọ́n itọka ti sharia si bibẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-ni: Nitori pe dajudaju awọn iwe ti sánmà patapata n sọrọ nípa iyẹn, ati pe nnkan ti o wa pẹlu rẹ ninu awọn idajọ ti o n ṣe deedee ti o kun fun awọn anfaani ẹda jẹ ẹri lori pe dajudaju o wa lati ọdọ Oluwa Ọba Ọjọgbọn Onimimọ julọ nípa awọn anfaani ẹda Rẹ Ati nnkan ti o wa pẹlu rẹ ninu awọn iroyin ti aye ti nnkan ti o n ṣẹlẹ jẹrii sí ododo rẹ, ìyẹn jẹ ẹri lori pe dajudaju o wa lati ọdọ Oluwa Ọba ti O ni ikapa lori mimu nnkan ti o sọrọ nipa rẹ bẹ
4- Ṣugbọn ẹri ìmọ̀lára lori bibẹ Ọlọhun; o jẹ lati abala meji:
Ọkan ninu mejeeji: Dajudaju awa n gbọ a si n ri ninu idahun awọn olupepe, ati gbigba awọn ti ara n ni là, nnkan ti o n tọka si bibẹ Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- ni itọka ti ko ni iyèméjì, Ọlọhun- mimọ ni fun Un- sọ pe:
﴿وَنُوحًا إِذۡ نَادَىٰ مِن قَبۡلُ فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ...﴾
{(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú (yín). A sì dá a lóhùn…}. [Surah Al-Anbiyâ’: 76] Ọba ti ọla Rẹ ga tun sọ pe:
﴿إِذۡ تَسۡتَغِيثُونَ رَبَّكُمۡ فَٱسۡتَجَابَ لَكُمۡ...﴾
{(Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn…}. [Surah Al-Anfâl: 9]
O wa ninu Sohiihu Bukhari lati ọdọ Anas ọmọ Malik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju larubawa oko kan wọlé ni ọjọ jimọh- ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si n ṣe khutuba lọ́wọ́- o sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dukia parun, ẹbi si n pa awọn ara ile, ba wa ke pe Ọlọhun; o gbe ọwọ rẹ mejeeji soke, o si pe E, ni ẹsujo ba rú sókè gẹgẹ bi awọn oke, ko i tii sọ̀kalẹ̀ lori minbari rẹ titi ti mo fi ri ojo ti o n san wálẹ̀ lati irun agbọn rẹ
Ni jimọh keji, larubawa oko naa dìde, tabi ẹni ti o yatọ si i, o sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ile ti wo, dukia ti tẹri, pe Ọlọhun fun wa; o ba gbe ọwọ rẹ mejeeji si oke, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Allahumo awaalainaa wa laa alainaa”, ko tọka si àgbègbè kan afi ki o la
Idahun awọn olupepe o yẹ ko gbo ni alamọri kan ti a n ri titi di asiko wa yii fun ẹni ti o ba sá di Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni ododo, ti o si mu awọn majẹmu gbigba adua wa
Oju keji: Dajudaju awọn ami awọn Anabi ti a n pe ni iṣẹ iyanu ti awọn eniyan n ri wọn, tabi gbọ nípa wọn, jẹ ẹri ti ko ni iyèméjì lori bibẹ ẹni ti O ran wọn ni iṣẹ, Oun ni Allahu- ti ọla Rẹ ga-; nitori pe dajudaju wọn jẹ alamọri ti wọn tayọ ikapa ẹda, ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- n mu wọn waye; lati le fi kun awọn Ojiṣẹ Rẹ lọwọ, ati lati ran wọn ṣe
Apẹrẹ ìyẹn ni: Ami Anabi Musa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- nigba ti Ọlọhun pa a láṣẹ lati fi ọ̀pá rẹ lu odo, ti o si pinya si oju mejila ti o gbẹ, ti omi wa laaarin wọn gẹgẹ bii awọn oke, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿فَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنِ ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡبَحۡرَۖ فَٱنفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرۡقٖ كَٱلطَّوۡدِ ٱلۡعَظِيمِ 63﴾
{A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá}.
[Surah Ash-Shu`arâ’: 63]
Apejuwe keji: Ami Anabi Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- nigba ti o sọ òkú di alaaye, ti o mu wọn jade lati inu saare wọn pẹlu iyọnda Ọlọhun, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa rẹ pe:
﴿...وَأُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ...﴾
{…mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu…}. [Surah Âl-`Imrân: 49] O sọ pe:
﴿...وَإِذۡ تُخۡرِجُ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِي...﴾
{…(Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi…}.
[Surah Al-Mâ'idah: 110]
Apejuwe kẹta: Fun Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti awọn Quraishi bere ami kan lọwọ rẹ, o ba tọka si òṣùpá, o ba pin si meji, awọn eniyan si ri i, nipa ìyẹn ni ọrọ Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- pe:
﴿ٱقۡتَرَبَتِ ٱلسَّاعَةُ وَٱنشَقَّ ٱلۡقَمَرُ 1 وَإِن يَرَوۡاْ ءَايَةٗ يُعۡرِضُواْ وَيَقُولُواْ سِحۡرٞ مُّسۡتَمِرّٞ2﴾
{Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì)*Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: "Idán kan (t’ó lágbára) t’ó máa lọ ni}.
[Surah Al-Qamar: 1:2]
Àwọn ami ti a n ni ìmọ̀lára wọn yii, ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- n mu wọn waye; lati le fi kun awọn Ojiṣẹ Rẹ lọwọ, ati lati ran wọn ṣe, wọ́n n tọka si bibẹ Rẹ- Ọba ti O ga- ni itọka ti ko ni iyèméjì.
Alamọri kejì ninu nnkan ti nini igbagbọ ninu Ọlọhun ko sinu: Nini igbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun nikan ṣoṣo ni Oluwa ti ko si orogun fun Un tabi oluranlọwọ
Oluwa: Ẹni ti dida n bẹ fun Un, ati ikapa, ati àṣẹ, ko si Aṣẹ̀dá kankan afi Allahu, ko si Olukapa kankan afi Oun, ko si aṣẹ fun ẹni kankan afi fun Un, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿...أَلَا لَهُ ٱلۡخَلۡقُ وَٱلۡأَمۡرُ...﴾
{…Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ…} [Surah Al-A`râf: 54] O sọ pe:
﴿...ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۚ وَٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ مَا يَمۡلِكُونَ مِن قِطۡمِيرٍ﴾
{…(Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù}. [Surah Fâtir: 13]
A ko mọ ẹni kankan ninu ẹda ti wọn tako ijẹ Olúwa Ọlọhun- mimọ ni fun Un-, afi ko jẹ alágídí ti ko ni adisọkan nnkan ti o n sọ, gẹgẹ bi o ṣe ṣẹlẹ lati ọwọ Fir'aun, nigba ti o sọ fun ìjọ rẹ pe: {Ó sì wí pé:
﴿فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ 24﴾
{Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ}. [Surah An-Nâzi`ât: 24], o sọ pe:
{Fir‘aon wí pé:
﴿...يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ مَا عَلِمۡتُ لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرِي...﴾
{…Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi!...}. [Surah Al-Qasas:38].
ṣugbọn ko ni ìyẹn ni adisọkan. Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَجَحَدُواْ بِهَا وَٱسۡتَيۡقَنَتۡهَآ أَنفُسُهُمۡ ظُلۡمٗا وَعُلُوّٗا...﴾
{Wọ́n takò ó pẹ̀lú àbòsí àti ìgbéraga, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú péòdodo ni} [Surah An-Naml: 14] Anabi Musa sọ fun Fir'aun níbi nnkan ti Ọlọhun gba ẹnu rẹ sọ pe:
﴿...لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَآ أَنزَلَ هَٰٓؤُلَآءِ إِلَّا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ بَصَآئِرَ وَإِنِّي لَأَظُنُّكَ يَٰفِرۡعَوۡنُ مَثۡبُورٗا﴾
{(Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) àmì t’ó yanjú. Dájúdájú èmi náà lérò péẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon}. [Surah Al-Isrâ’: 102] Fun idi eyi àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ìjẹ Olúwa Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- rinlẹ, pẹlu ida nnkan papọ pẹlu Rẹ nibi ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿قُل لِّمَنِ ٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهَآ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 84 سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ85 قُلۡ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلسَّبۡعِ وَرَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ 86 سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ 87 قُلۡ مَنۢ بِيَدِهِۦمَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيۡهِ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 88 سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ فَأَنَّىٰ تُسۡحَرُونَ 89﴾
{Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?*Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?*Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?*Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?*Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?” Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?*Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?} [Surah Al-Mu’minûn: 84-89]
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ 9﴾
{Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ẹni t’ó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀}. [Surah Az-Zukhruf: 9]
Ọba- ti mimọ n bẹ fun Un- sọ pe:
﴿وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 87﴾
{Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?}
[Surah Az-Zukhruf: 87]
Àṣẹ Ọlọhun- mimọ ni fun Un- ko àṣẹ ti ayé ati ti ofin sinu, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pe Oun ni Oludari aye Oludajọ nibẹ pẹlu nnkan ti O ba fẹ, nibamu si nnkan ti ọgbọn Rẹ ba beere fun, Oun naa ni Oludajọ nibẹ pẹlu ofin awọn ijọsin, ati awọn idajọ ibaṣepọ, nibamu si nnkan ti ọgbọn Rẹ ba beere fun. Ẹni ti o ba ni aṣofin kan pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ijọsin tabi oludajọ kan nibi ibaṣepọ; dajudaju o ti ṣe ẹbọ pọ mọ Ọn, ko si mu igbagbọ ṣẹ
Alamọri kẹta ninu nnkan ti nini igbagbọ ninu Ọlọhun ko sinu: Nini igbagbọ pẹlu ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si, o n túmọ̀ si pe: Dájúdájú Oun nikan ṣoṣo ni Ọlọhun ododo ti ko si orogun fun Un, (Al-Ilaahu) n túmọ̀ si: (Al-Mahluuh), o n túmọ̀ si: (Ẹni ti a n jọsin fun) ni ti ifẹ ati igbetobi
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ 163﴾
{Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run}.
[Surah Al-Baqarah: 163]
﴿شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَأُوْلُواْ ٱلۡعِلۡمِ قَآئِمَۢا بِٱلۡقِسۡطِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 18﴾
{Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n}. [Surah Âl-`Imrân: 18] Gbogbo ẹni ti o ba mu Ọlọhun kan pẹlu Allahu, ti o n jọsin fun un yatọ si I; nini igbagbọ ninu ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si rẹ ti bajẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ 62﴾
{Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi}. [Surah Al-Hajj: 62] Sisọ wọn ni orúkọ ọlọhun ko fun wọn ni ẹtọ ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa (Al-laata ati Al-'uzza ati manaata) pe:
﴿إِنۡ هِيَ إِلَّآ أَسۡمَآءٞ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍ...﴾
{(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀…}. [Surah An-Najm: 23]
O sọ nipa Anabi Hud- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pe dajudaju o sọ fun ìjọ rẹ pe:
﴿...أَتُجَٰدِلُونَنِي فِيٓ أَسۡمَآءٖ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّا نَزَّلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٖ...﴾
{…Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un?}" {Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un?...}
[Surah Al-A`râf: 71]
O sọ nipa Anabi Yusuf- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pe dajudaju o sọ fun awọn akẹgbẹ inu ẹ̀wọ̀n méjèèjì pe:
﴿يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ ءَأَرۡبَابٞ مُّتَفَرِّقُونَ خَيۡرٌ أَمِ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ 39 مَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ أَسۡمَآءٗ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍ...﴾
{Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ l’ó lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?*Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un…}.
[Surah Yûsuf: 39-40]
Fun idi eyi ni awọn Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn- fi maa n sọ fun awọn ijọ wọn pe:
﴿...ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُ...﴾
{…ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀…}. [Surah Al-A`râf: 59]" Ṣùgbọ́n awọn ọ̀ṣẹbọ kọ ìyẹn, wọn si mu ẹni ti o yatọ si Ọlọhun ni òrìṣà, ti wọn n jọsin fun wọn pẹlu Ọlọhun- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga- ti wọn si n wa àrànṣe pẹlu wọn, ti wọn si n wa iranlọwọ wọn
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ba nini ti awọn ọ̀ṣẹbọ ni awọn òrìṣà yii jẹ́ pẹlu awijare ti laakaye méjì:
Akọkọ: Dajudaju ko si nnkankan ninu awọn nnkan ẹsa ini ẹtọ si ijọsin ododo lara awọn òrìṣà ti wọn mu yii, nnkan ti wọn da ni wọn ti wọn ko lee da ẹda, ti wọn ko lee wa anfaani fun awọn olùjọsìn fún wọn, ti ko lee mu inira kuro fun wọn, ti wọn ko lee fun wọn ni iṣẹmi tabi iku, ti won ko lee kapa nnkankan ninu awọn sanmọ, ti wọn ko si lee kópa nibẹ
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗ لَّا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ وَلَا يَمۡلِكُونَ لِأَنفُسِهِمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا وَلَا يَمۡلِكُونَ مَوۡتٗا وَلَا حَيَوٰةٗ وَلَا نُشُورٗا 3﴾
{(Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Wọn kò sì lè dá kiní kan. A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde}.
[Surah Al-Furqân: 3]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿قُلِ ٱدۡعُواْ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا لَهُمۡ فِيهِمَا مِن شِرۡكٖ وَمَا لَهُۥ مِنۡهُم مِّن ظَهِيرٖ 22 وَلَا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ عِندَهُۥٓ إِلَّا لِمَنۡ أَذِنَ لَهُۥ...﴾
{Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ olúwa) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn*Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé:
{Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi}. [Surah Saba’: 22:23]
وقال تعالى: ﴿أَيُشۡرِكُونَ مَا لَا يَخۡلُقُ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ 191 وَلَا يَسۡتَطِيعُونَ لَهُمۡ نَصۡرٗا وَلَآ أَنفُسَهُمۡ يَنصُرُونَ 192﴾
{Ọba ti ọla Rẹ ga: {Ṣé wọn yóò sọ n̄ǹkan tí kò lè dá n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ Rẹ̀, A sì ṣẹ̀dá wọn ni?*Àwọn òrìṣà kò lè ṣe àrànṣe kan fún àwọn abọ̀rìṣà. Àti pé àwọn òrìṣà gan-an kò lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n}.
[Surah Al-A`râf: 191-192]
Ti eyi ba jẹ iṣesi awọn òrìṣà yẹn, dajudaju mimu wọn ni ọlọhun jẹ iwa omugọ julọ ninu iwa omugọ, ati iwa ibajẹ julọ ninu ibajẹ
Ikeji: Dajudaju awọn ọ̀ṣẹbọ yii fi rinlẹ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Oun nikan ṣoṣo ni Oluwa Aṣẹ̀dá ti akoso gbogbo nnkan wa lọwọ Rẹ, Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀, eleyii n ṣe ni dandan lati mu U ni ọkan ṣoṣo pẹlu títọ si ijọsin, gẹgẹ bi wọn ṣe mu U ni ọkan ṣoṣo pẹlu ijẹ Oluwa,
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ21 ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ فِرَٰشٗا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءٗ وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجَ بِهِۦ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ رِزۡقٗا لَّكُمۡۖ فَلَا تَجۡعَلُواْ لِلَّهِ أَندَادٗا وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 22﴾
{Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná)*(Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́)}.
[Surah Al-Baqarah: 21:22]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé:
﴿وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 87﴾
{Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?} [Surah Az-Zukhruf: 87]
"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé:
﴿قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ أَمَّن يَمۡلِكُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَمَن يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَمَن يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۚ فَسَيَقُولُونَ ٱللَّهُۚ فَقُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ 31 فَذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمُ ٱلۡحَقُّۖ فَمَاذَا بَعۡدَ ٱلۡحَقِّ إِلَّا ٱلضَّلَٰلُۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ32﴾
{Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?*Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?} [Surah Yûnus: 31:32]
Alamọri kẹrin ninu nnkan ti nini igbagbọ ninu Ọlọhun ko sinu ni: Nini igbagbọ pẹlu awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ:
O n túmọ̀ si: Fifi nnkan ti Ọlọhun fi rinlẹ fun ara Rẹ rinlẹ ninu iwe Rẹ, tabi sunnah Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn orukọ ati awọn iroyin, lori ojupanna ti o yẹ Ẹ́ láìsí ayipada tabi sisọ pe ko ri bẹẹ tabi sisọ bi o ṣe ri tabi isafiwe, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَلِلَّهِ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ فَٱدۡعُوهُ بِهَاۖ وَذَرُواْ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ أَسۡمَٰٓئِهِۦۚ سَيُجۡزَوۡنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 180﴾
{Ti Allāhu ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn t’ó ń yẹ̀ kúrò níbi àwọn orúkọ Rẹ̀ tì. A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́}.
[Surah Al-A`râf: 180]
﴿...وَلَهُ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ﴾
{Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n}.
[Surah Ar-Rûm: 27]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿...لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ﴾
{…Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran}. [Surah Ash-Shûrâ: 11]
Dajudaju awọn ijọ meji ti sọnu latara alamọri yii:
Akọkọ ninu wọn: (Awọn ti wọn sọ pe ko ri bẹẹ) awọn ti wọn tako awọn orukọ ati awọn iroyin, tabi apakan ninu wọn, ti wọn n lero pe dajudaju fifi wọn rinlẹ fun Ọlọhun maa ṣe àfijọ ni dandan, o n tumọ si: Ṣíṣe àfijọ Ọlọhun-ti ọla Rẹ ga- pẹlu ẹda Rẹ, eleyii jẹ irori ibajẹ; fun awọn ojupanna kan, ninu wọn:
Akọkọ: Dajudaju o maa sọ awọn nnkan kan ti ko dára di dandan; gẹgẹ bii títako-ara-ẹni níbi ọrọ Ọlọhun- mimọ ni fun Un-, ìyẹn ni pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi awọn orukọ ati awọn iroyin rinlẹ fun ara Rẹ, O si kọ ki nnkan kan da bii Rẹ, Ti fifi wọn rinlẹ ba maa ṣe ṣíṣe afijọ ni dandan ni; a jẹ pe títako-ara-ẹni naa maa di dandan nibi ọrọ Ọlọhun, ati ki apakan rẹ maa pe apakan ni irọ
Ikeji: Dajudaju ko jẹ dandan ki nnkan meji papọ níbi orúkọ kan tabi iroyin kan pe ki mejeeji jẹ nnkan kan naa, ìwọ naa maa ri pe èèyàn meji le papọ nibi pe ọkọọkan wọn jẹ ọmọniyan ti o n gbọ, ti o n ri, ti o n sọrọ Ko waa ni jẹ dandan latara iyẹn ki mejeeji jẹ nnkan kan naa nibi awọn itumọ ijẹ ọmọniyan, ati gbigbọ, ati riri, ati ọrọ sisọ
Waa ri pe awọn ẹranko ni ọwọ́ ati ẹsẹ ati oju, ko si nii jẹ dandan nibi ipapọ wọn yii ki awọn ọwọ wọn, ati awọn ẹsẹ wọn, ati awọn oju wọn jẹ nnkan kan naa
Ti iyatọ ba han laaarin awọn ẹda nibi nnkan ti wọn ti papọ ninu awọn orukọ tabi awọn iroyin; a jẹ wipe iyatọ laaarin Aṣẹ̀dá ati ẹda maa yatọ julọ o si maa tobi julọ
Awọn ijọ keji: (Awọn asafiwe) àwọn ti wọn fi awọn orukọ ati awọn iroyin rinlẹ pẹlu isafiwe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu ẹda Rẹ, awọn ti wọn lero pe dajudaju eyi ni nnkan ti itumọ awọn ọrọ Ọlọhun n tọka si; nitori pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- n ba awọn ẹru sọrọ pẹlu nnkan ti wọn gbọye, èrò yii jẹ ibajẹ; fun awọn ojupọnna kan, ninu wọn:
Akọkọ: Dajudaju isafiwe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu ẹda Rẹ jẹ alamọri kan ti laakaye ati ofin tako, ti ko rọrun ki nnkan ti awọn ọrọ Ọlọhun ati Sunnah n tọka si jẹ ọ̀rọ̀ ibajẹ.
Ikeji: Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ba awọn ẹru sọrọ pẹlu nnkan ti wọn gbọye ti a ba n sọ nipa ipilẹ itumọ, ṣugbọn nipa pàápàá itumọ naa, Ọlọhun nikan ni O ni imọ nipa rẹ nipa nǹkan ti o nii ṣe pẹ̀lú pàápàá Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Ti Ọlọhun ba fi rinlẹ fun ara Rẹ pe dajudaju oun ni Olugbọ; dajudaju gbigbọ jẹ nnkan ti a mọ nipasẹ ipilẹ itumọ (dídá àwọn ohun mọ) ṣugbọn paapaa ìyẹn nibamu si gbigbọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ohun ti a ko mọ ni; nitori pe paapaa gbigbọ jẹ nnkan ti o yatọ nibi awọn ẹda; ti o ba ri bẹẹ, iyatọ nibẹ laaarin Aṣẹ̀dá ati ẹda jẹ nnkan ti o hàn julọ ti o si tobi julọ
Ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ba sọ nipa ara Rẹ pe dajudaju Oun gunwa lori aga ọla Rẹ; dajudaju igunwa, ti a ba n sọ nípa ipilẹ itumọ jẹ nnkan ti a mọ, ṣugbọn paapaa igunwa ti O wa lori rẹ jẹ nnkan ti a ko mọ nibamu si igunwa Ọlọhun lori aga ọla Rẹ; nitori pe dajudaju paapaa igunwa jẹ nnkan ti o yatọ láàárín àwọn ẹda Igunwa lori aga kan ti o wa ni oju kan ko da bii igunwa lori gàárì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ olorikunkun, ti o ba yatọ lọdọ ẹda; ki o yatọ láàrin Aṣẹ̀dá ati ẹda maa jẹ nnkan ti o hàn julọ ti o si tobi julọ.
Ati pe nini igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori nnkan ti a royin yio maa so eso fun olugbagbọ ni awọn eso ti wọn tobi, ninu wọn:
Akọkọ: Mimu nini igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣẹ, ni ọna ti agbiyele kan ko nii so pọ mọ ẹni ti o yatọ si I, tabi ipaya kan, ti wọn ko si nii jọsin fun ẹni ti o yatọ si I
Ikeji: Pipe nini ifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati gbigbe E tobi ni ibamu si awọn orukọ Rẹ ti wọn dáa julọ ati awọn iroyin Rẹ ti wọn ga julọ.
Ikẹta: Mimu awọn ijọsin Rẹ ṣẹ pẹlu ṣíṣe nnkan ti O pàṣẹ rẹ, ati jijina si nnkan ti O kọ kuro nibẹ
Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika
Awọn mọlaika: Agbaye kọ̀kọ̀ kan ni wọn, ti a da wọn, ti wọn n jọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, wọn ko si ni ìròyìn kankan ninu ijẹ Olúwa ati ini ẹtọ si ijọsin ni ododo, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- da wọn lati ara imọlẹ, ti O fun wọn ni itẹle ti o pe fun àṣẹ Rẹ, ati agbara lori mimu u ṣẹ. Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...وَمَنۡ عِندَهُۥ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَلَا يَسۡتَحۡسِرُونَ 19 يُسَبِّحُونَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ لَا يَفۡتُرُونَ 20﴾
{…TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Àti pé wọ́n kò kọ́lẹ*Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; kò sì rẹ̀ wọ́n}. [Surah Al-Anbiyâ’: 19-20]
Wọn jẹ onka ti o pọ, ko si ẹni ti o mọ iye wọn afi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, o fi ẹsẹ rinlẹ ninu Sohiihu mejeeji ninu hadisi Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- ninu itan gigun sánmà lọ pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọn gbe BAYTUL MAH’MUUR dide fun un ni sanmọ, ti awọn mọlaika ẹgbẹ̀rún ni ọna àádọ́rin n kirun nibẹ ni ojoojumọ, ti wọn ba jade wọn ko nii pada síbẹ̀, opin igba ti wọn maa wọ ibẹ naa nìyẹn.
Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika ko awọn alamọri mẹrin sinu:
Akọkọ: Nini igbagbọ ninu bibẹ wọn
Ikeji: Nini igbagbọ ninu ẹni ti a mọ orúkọ rẹ ninu wọn pẹlu orúkọ rẹ (gẹgẹ bii Jibril), ṣùgbọ́n awọn ti a ko mọ orúkọ wọn a maa ni igbagbọ ninu wọn lapapọ
Ikẹta: Nini igbagbọ ninu nnkan ti a mọ ninu awọn iroyin wọn, gẹgẹ bii iroyin (Jibril), Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun wa ni iro pe dajudaju oun ri i lori iroyin rẹ ti wọn da a le lori, ati pe iyẹ ọgọ́rùn-ún mẹfa ni o n bẹ fun un ti o bo oju sanmọ
Mọlaika le yi pada pẹlu àṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- si àwòrán ọkùnrin,
كَمَا حَصَلَ لِجِبْرِيلَ حِينَ أَرْسَلَهُ اللَّهُ تَعَالَى إِلَى مَرْيَمَ، فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرًا سَوِيًّا، وَحِينَ جَاءَ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَهُوَ جَالِسٌ فِي أَصْحَابِهِ، جَاءَهُ بِصِفَةِ رَجُلٍ شَدِيدِ بَيَاضِ الثِّيَابِ، شَدِيدِ سَوَادِ الشَّعْرِ، لَا يُرَى عَلَيْهِ أَثَرُ السَّفَرِ، وَلَا يَعْرِفُهُ أَحَدٌ مِنْ أَصْحَابِهِ، فَجَلَسَ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَأَسْنَدَ رُكْبَتَيْهِ إِلَى رُكْبَتَيْهِ، وَوَضَعَ كَفَّيْهِ عَلَى فَخِذَيْهِ، وَسَأَلَ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَنِ الْإِسْلَامِ، وَالْإِيمَانِ، وَالْإِحْسَانِ، وَالسَّاعَةِ، وَأَمَارَاتِهَا؛ فَأَجَابَهُ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَانْطَلَقَ، ثُمَّ قَالَ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: هَذَا جِبْرِيلُ؛ أَتَاكُمْ يُعَلِّمُكُمْ دِينَكُمْ.
Gẹgẹ bi o ṣe ṣẹlẹ si (Jibril) nigba ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ran an si Maryam, o sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé. Ati igba ti o lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti o jókòó laaarin awọn sohaba rẹ, o wa ba a pẹlu iroyin arakunrin kan ti aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ dudu gan, wọn ko ri apẹrẹ irin ajo lara rẹ, ti ẹni kan kan ninu awọn sohaba rẹ ko si mọ ọn, o jokoo si ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o fi orunkun rẹ mejeeji ti orunkun rẹ mejeeji, o gbe àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ mejeeji le itan rẹ mejeeji, o bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa Isilaamu, ati igbagbọ, ati daadaa, ati ọjọ igbedide, ati awọn ami rẹ; Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun, o si yi ẹsẹ pada, lẹyin naa ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Eleyii ni Jibril; o wa ba yin lati wa kọ yin ni ẹsin yin”
Gẹgẹ bẹẹ ni awọn mọlaika ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ran si Anabi Ibrahim, ati Lut, wọn wa lori aworan awọn ọkunrin
Ikẹrin ninu nnkan ti nini igbagbọ ninu awọn mọlaika ko sinu: Nini igbagbọ pẹlu nnkan ti a mọ ninu awọn wọn ti wọn mu oju to pẹlu àṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; gẹgẹ bii ṣíṣe afọmọ fun Un, ati jijọsin fun Un ni alẹ ati ọsan laisi ikosusu tabi olẹ
Ati pe awọn kan ninu wọn le ni iṣẹ́ kan pato.
Gẹgẹ bii: Jubril alamojuto iṣẹ imisi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Ọlọhun maa n ran an pẹlu rẹ si awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ
Gẹgẹ bii: Mikhail: Alamojuto òjò ati irugbin
Gẹgẹ bii: Israfil: Alamojuto fifọn fèrè oníwo nigba ti ọjọ igbedide ẹ̀dá bá tó.
Gẹgẹ bii: Malakul maot: Alamojuto gbigba awọn ẹ̀mí nigba iku
Gẹgẹ bii: Maalik: Alamojuto ina, oun ni ẹ̀ṣọ́-Iná
Gẹgẹ bii: Awọn mọlaika alamojuto awọn ọmọ ninu awọn apo ibi, ti ọmọniyan ba ti pe oṣu mẹrin ninu ikun iya rẹ, Ọlọhun a gbe mọlaika kan dìde si i ti yoo pa a láṣẹ pẹlu kikọ arisiki rẹ, ati igba rẹ, ati iṣẹ rẹ, ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire
Gẹgẹ bii: Awọn mọlaika alamojuto ṣiṣọ awọn iṣẹ ọmọ Anabi Adam ati kikọ wọn kalẹ, mọlaika meji ni n bẹ fun gbogbo ọmọniyan, ọkan ninu wọn n bẹ ni ẹgbẹ ọtun ti ikeji n bẹ ni ẹgbẹ osi
Gẹgẹ bii: Awọn mọlaika alamojuto bibeere lọwọ oku ti wọn ba gbe e si inu saare rẹ; awọn mọlaika meji kan o waa ba a ti wọn yoo ma bi i nipa Oluwa rẹ, ati ẹsin ati Anabi rẹ
Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika yio maa so awọn eso kan ti o tobi, ninu wọn:
Ikeji: Didu ọpẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori akolekan Rẹ pẹlu ọmọ Anabi Adam; nigba ti o ṣe pe o n bẹ ninu gbogbo awọn mọlaika yii ẹni ti o n mójú tó ṣiṣọ wọn, ati kikọ awọn iṣẹ wọn, ati eyi ti o yatọ si ìyẹn ninu awọn anfaani wọn
Ikẹta: Nini ifẹ awọn mọlaika lori nnkan ti wọn ṣe ninu ijọsin Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ati pe awọn ijọ kan ninu awọn ti wọn yẹ gẹrẹ tako ijẹ abara awọn mọlaika, wọn sọ pe: Dajudaju wọn jẹ agbara daadaa ti wọn pamọ si ara awọn ẹda ni wọn, eleyii jẹ pipe iwe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni irọ, ati Sunnah Ojiṣẹ Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ifẹnuko awọn Musulumi
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَ...﴾
{Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin…}. [Surah Fâtir: 1]
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin}[Surah Fâtir: 1]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ يَتَوَفَّى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَضۡرِبُونَ وُجُوهَهُمۡ وَأَدۡبَٰرَهُم...﴾
{Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí I nígbà tí àwọn mọlāika bá ń gba ẹ̀mí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ni, tí wọ́n ń lu ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn…}. [Surah Al-Anfâl: 50]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿...وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّٰلِمُونَ فِي غَمَرَٰتِ ٱلۡمَوۡتِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَاسِطُوٓاْ أَيۡدِيهِمۡ أَخۡرِجُوٓاْ أَنفُسَكُمُۖ...﴾
{…Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí I nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé)}. [Surah Al-An`âm: 93]
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: ﴿...حَتَّىٰٓ إِذَا فُزِّعَ عَن قُلُوبِهِمۡ قَالُواْ مَاذَا قَالَ رَبُّكُمۡۖ قَالُواْ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ﴾
{…Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi}. [Surah Saba’: 23]
O sọ nipa awọn ara alujanna pe:
﴿...وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَدۡخُلُونَ عَلَيۡهِم مِّن كُلِّ بَابٖ 23 سَلَٰمٌ عَلَيۡكُم بِمَا صَبَرۡتُمۡۚ فَنِعۡمَ عُقۡبَى ٱلدَّارِ 24﴾
{…Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan*(Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fun yín nítorí ìfaradà yín.” Àtubọ̀tán Ilé náà sì dára}.
[Surah Ar-Ra`d: 23-24]
Ati pe o wa ninu sọhiihu Bukhari lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: “Ti Ọlọhun ba nifẹẹ ẹrú, O maa pe Jibril pe: Dajudaju Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ lagbaja, ki ìwọ naa yaa nífẹ̀ẹ́ rẹ, Jubril yoo si nífẹ̀ẹ́ rẹ, Jibril yoo si pe awọn ara inu sanmọ pe: Dajudaju Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ lagbaja, ki ẹyin naa yaa nífẹ̀ẹ́ rẹ, awọn ara sanmọ yoo si maa nífẹ̀ẹ́ rẹ, lẹyin naa yoo waa di ẹni itẹwọgba lórí ilẹ̀”.
Nibẹ bákan náà lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
«إِذَا كَانَ يَوْمُ الْجُمُعَةِ كَانَ عَلَى كُلِّ بَابٍ مِنْ أَبْوَابِ الْمَسْجِدِ الْمَلَائِكَةُ يَكْتُبُونَ الْأَوَّلَ فَالْأَوَّلَ، فَإِذَا جَلَسَ الْإِمَامُ طَوَوْا الصُّحُفَ وَجَاءُوا يَسْتَمِعُونَ الذِّكْرَ».
Ti o ba di ọjọ jimọh, àwọn mọlaika maa wa ni gbogbo ẹnu ọ̀nà mọsalasi, wọn yoo maa kọ orúkọ àwọn èèyàn bi wọ́n ba ṣe de sí, ti imaamu ba ti wa jokoo, wọn yoo pa awọn iwe naa de, wọn si maa tẹti si iranti”.
Àwọn aaya ati hadiisi wọnyi n la ọrọ mọ́lẹ̀ pe abara ni àwọn mọlaika, wọn kii ṣe agbára aifojuri, gẹgẹ bi àwọn ti wọn yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ ṣe sọ, nnkan ti awọn aaya ati hadiisi yii n tọ́ka si naa ni àwọn Musulumi fi ẹnu ko le lori. "
Nini igbagbọ pẹlu awọn tira
Al-Kutub: Jẹ nnkan ọpọ fun (Kitab) itumọ rẹ ni (nnkan ti a kọ)
Nnkan ti a gba lero pẹlu rẹ nibi ni: Àwọn iwe ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọkalẹ fun awọn Ojiṣẹ Rẹ ni ti ikẹ fun ẹda, ati imọna fun wọn; ki wọn le ti atara wọn de ibi oriire wọn ni aye ati ọrun
Nini igbagbọ ninu awọn iwe ko awọn alamọri mẹrin kan sinu:
Akọkọ: Nini igbagbọ pe dajudaju sisọ wọn kalẹ wa lati ọdọ Ọlọhun lododo
Ìkejì: Nini igbagbọ ninu nnkan ti a mọ orúkọ rẹ ninu wọn pẹlu orúkọ rẹ: Gẹgẹ bii Kuraani ti a sọkalẹ fun Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati Taoreeta ti a sọkalẹ fun Anabi Musa- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Ati Injil ti a sọkalẹ fun Anabi Isa- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Ati Sabura ti a fun Anabi Daud- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣugbọn eyi ti a ko mọ orúkọ rẹ, a maa ni igbagbọ ninu rẹ lapapọ
Ikẹta: Gbigba nnkan ti o ni alaafia ninu awọn iro, gẹgẹ bii awọn iro Kuraani, ati awọn iro nnkan ti wọn ko jirọ tabi yi pada ninu awọn iwe ìṣáájú
Ikẹrin: Ṣíṣe iṣẹ pẹlu awọn idajọ eyi ti wọn kò parẹ ninu wọn, ati yiyọnu ati gbigba fun un, boya a gbọ ọgbọn rẹ ye ni tabi a ko gbọ ọ ye, ati gbogbo awọn iwe iṣaaju ti wọn ti parẹ pẹlu Kuraani ti o tobi
﴿وَأَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمُهَيۡمِنًا عَلَيۡهِۖ...﴾
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀…}. [Surah Al-Mâ'idah: 48] túmọ̀ si (O n dajọ le lori)
Lori eyi: Ṣíṣe iṣẹ pẹlu eyikeyi idajọ ninu awọn idajọ awọn iwe ìṣáájú ko lẹ́tọ̀ọ́ afi nnkan ti o ni alaafia ninu wọn ti Kuraani fi rinlẹ
Nini igbagbọ ninu awọn tira maa so awọn eso ti o tobi, ninu wọn ni:
Akọkọ: Nini imọ nipa akolekan Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu ẹru Rẹ; nigba ti O sọ iwe kọọkan kalẹ fun gbogbo ijọ kọọkan ti O n fi wọn mọna pẹlu rẹ
Ikeji: Nini imọ nipa ọgbọn Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- níbi awọn ofin Rẹ, nigba ti O ṣe ni ofin fun gbogbo ijọ kọọkan nnkan ti o maa ba awọn iṣesi wọn mu
﴿...لِكُلّٖ جَعَلۡنَا مِنكُمۡ شِرۡعَةٗ وَمِنۡهَاجٗا...﴾
Gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe: {…Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún…}.
[Surah Al-Mâ'idah: 48]
Ikẹta: Idupẹ idẹra Ọlọhun níbi ìyẹn
Nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ
Ar-Rusul: Nnkan ọpọ fun (Rosuul), o n túmọ̀ si: (Ẹni ti a ran niṣẹ), o n túmọ̀ si ẹni ti a gbe dide lati jẹ iṣẹ kan.
Nnkan ti a gba lero pẹlu rẹ nibi ni: Ẹni ti a fi imisi ránṣẹ́ si ninu ẹda pẹlu ofin ti wọn si pa a láṣẹ lati jẹ iṣẹ naa.
Akọkọ awọn Ojiṣẹ ni Nuh- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ti igbẹyin wọn jẹ Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
﴿إِنَّآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ كَمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ نُوحٖ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعۡدِهِ...﴾
{Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀…}. [Surah An-Nisâ': 163]
O wa ninu sohiihu Bukhari lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- nipa hadisi iṣipẹ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
«ذُكِرَ أَنَّ النَّاسَ يَأْتُونَ إِلَى آدَمَ؛ لِيَشْفَعَ لَهُمْ، فَيَعْتَذِرُ إِلَيْهِمْ وَيَقُولُ: ائْتُوا نُوحًا أَوَّلَ رَسُولٍ بَعَثَهُ اللَّهُ» وذكر تمام الحديث.
O sọ pe awọn eniyan yoo wa ba Adam lati ṣipẹ fun wọn, yoo wa awijare fun wọn, yoo wa sọ pe: Ẹ lọ ba Nuh akọkọ Ojiṣẹ ti Ọlọhun gbe dide”, o wa sọ hadisi naa délẹ̀.
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- :
﴿مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ...﴾
{(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì…}. [Surah Al-Ahzâb: 40]
﴿وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَ...﴾
{Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà…}. [Surah An-Nahl: 36]
﴿...وَإِن مِّنۡ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٞ﴾
{…Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn}. [Surah Fâtir: 24]
﴿إِنَّآ أَنزَلۡنَا ٱلتَّوۡرَىٰةَ فِيهَا هُدٗى وَنُورٞۚ يَحۡكُمُ بِهَا ٱلنَّبِيُّونَ ٱلَّذِينَ أَسۡلَمُواْ لِلَّذِينَ هَادُواْ...﴾
{Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Dájúdájú Àwa sọ Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn t’ó di yẹhudi…}.
[Surah Al-Mâ’idah: 44]
Àwọn Ojiṣẹ jẹ ẹda ti a da wọn, ti nnkankan ninu awọn ìròyìn ìjẹ Oluwa ati ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si ko si fun wọn, Ọlọhun-ti ọla Rẹ ga- sọ nipa Anabi Muhammad pe oun ni asiwaju awọn Ojiṣẹ, ati ẹni ti o tobi julọ ni iyi lọdọ Ọlọhun:
﴿قُل لَّآ أَمۡلِكُ لِنَفۡسِي نَفۡعٗا وَلَا ضَرًّا إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ وَلَوۡ كُنتُ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ لَٱسۡتَكۡثَرۡتُ مِنَ ٱلۡخَيۡرِ وَمَا مَسَّنِيَ ٱلسُّوٓءُۚ إِنۡ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ وَبَشِيرٞ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 188﴾
{Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo}. [Surah Al-A`râf: 188]
﴿قُلۡ إِنِّي لَآ أَمۡلِكُ لَكُمۡ ضَرّٗا وَلَا رَشَدٗا 21 قُلۡ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ ٱللَّهِ أَحَدٞ وَلَنۡ أَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلۡتَحَدًا 22﴾
{Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Sọ pé: “Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fun yín* Sọ pé: “Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan t’ó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀}. [Surah Al-Jinn: 21-22]
Àwọn ìròyìn ẹ̀dá maa n ṣẹlẹ si wọn, bii aisan, ati iku, ati ini bukaata si oúnjẹ, ati nǹkan mimu, ati eyi ti o yatọ si yẹn, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi iroyin rẹ fun Oluwa rẹ- ti ọla Rẹ ga- pe:
﴿وَٱلَّذِي هُوَ يُطۡعِمُنِي وَيَسۡقِينِ 79 وَإِذَا مَرِضۡتُ فَهُوَ يَشۡفِينِ 80 وَٱلَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحۡيِينِ 81﴾
{Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu;*Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;*Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè}.
[Surah Ash-Shu`arâ’: 79-81]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Dajudaju emi jẹ ẹda gẹgẹ bii yin, mo n gbagbe bi ẹ ṣe n gbagbe, ti n ba ti gbagbe ẹ ran mi leti”.
Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ṣe iroyin wọn pẹlu ijẹ ẹru nibi eyi ti o ga julọ ninu ipo wọn, nibi ti O ti n royin wọn;
﴿...إِنَّهُۥ كَانَ عَبۡدٗا شَكُورٗا﴾
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa Nuh- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: {…Dájúdájú (Nūh) jẹ́ ẹrúsìn, olùdúpẹ́}. [Surah Al-Isrâ’: 3]
﴿تَبَارَكَ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡفُرۡقَانَ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦ لِيَكُونَ لِلۡعَٰلَمِينَ نَذِيرًا 1﴾
O sọ nipa Anabi Muhammad pe: {Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá}. [Surah Al-Furqân: 1]
﴿وَٱذۡكُرۡ عِبَٰدَنَآ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ أُوْلِي ٱلۡأَيۡدِي وَٱلۡأَبۡصَٰرِ 45 إِنَّآ أَخۡلَصۡنَٰهُم بِخَالِصَةٖ ذِكۡرَى ٱلدَّارِ 46 وَإِنَّهُمۡ عِندَنَا لَمِنَ ٱلۡمُصۡطَفَيۡنَ ٱلۡأَخۡيَارِ 47﴾
O sọ nipa Ibrahim, ati Ishaq, ati Ya'kub,- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn- pe: {Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára, olùríran (nípa ẹ̀sìn)* Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan; ìrántí Ilé Ìkẹ́yìn.* Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa}.
[Surah Sâd: 45-47]
﴿إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 59﴾
O sọ nipa Isa ọmọ Maryam pe: {Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl}. [Surah Az-Zukhruf: 59]
Nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ ko awọn alamọri mẹrin kan sinu:
Akọkọ: Nini igbagbọ pe dajudaju riran wọn ni iṣẹ jẹ ododo lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si riran ọkan ninu wọn ni iṣẹ ti ṣe aigbagbọ si gbogbo wọn Gẹgẹ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pe:
﴿كَذَّبَتۡ قَوۡمُ نُوحٍ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 105﴾
{Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní opurọ}.
[Surah Ash-Shu`arâ’: 105].
Ọlọhun ṣe wọn ni ẹni ti o pe gbogbo àwọn Ojiṣẹ ni irọ, pẹ̀lú wipe ko si Ojiṣẹ kankan yatọ si i nígbà ti wọn pe e ni opurọ. Lori eyi, awọn Kristẹni ti wọn pe Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni opurọ ti wọn ko tẹle e; wọn ti pe Al-Maseeh ọmọ Maryam ni opurọ, wọn ko si tẹle oun naa, pàápàá julọ o tun ti fun wọn ni iro idunnu nipa Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ko si itumọ fun ifun wọn ni iro idunnu pẹlu rẹ afi pe dajudaju Ojiṣẹ lo jẹ fun wọn ti Ọlọhun o yọ wọn kuro ninu anu pẹlu rẹ, ti yoo fi wọn mọ oju-ọna taara
Ikeji: Nini igbagbọ pẹlu ẹni ti a mọ orúkọ rẹ ninu wọn pẹlu orúkọ rẹ gẹgẹ bii: Muhammad, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa, ati Nuh,- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn- Awọn marun-un yii ni awọn onipinnu ninu awọn Ojiṣẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- dárúkọ wọn ni aaye meji ninu Kuraani nibi ọrọ Rẹ pe:
﴿وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِيثَٰقَهُمۡ وَمِنكَ وَمِن نُّوحٖ وَإِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۖ وَأَخَذۡنَا مِنۡهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا 7﴾
{(Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn t’ó nípọn}. [Surah Al-Ahzâb: 7]
﴿شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ 13﴾
Ati ọrọ Rẹ: {(Allāhu) ṣe ní òfin fun yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà)}. [Surah Ash-Shûrâ: 13]
Ṣùgbọ́n ẹni ti a ko mọ orúkọ rẹ ninu wọn; a maa ni igbagbọ ninu rẹ lapapọ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ...﴾
{Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A ò sì sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn}.
[Surah Ghâfir: 78]
Ikẹta: Gbigba nnkan ti o ni alaafia nipa awọn iroyin wọn gbọ lododo
Ikẹrin: Ṣíṣe amulo ofin ẹni ti wọn ran si wa ninu wọn, oun naa ni opin wọn Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti a ran an si gbogbo eniyan, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤۡمِنُونَ حَتَّىٰ يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيۡنَهُمۡ ثُمَّ لَا يَجِدُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَرَجٗا مِّمَّا قَضَيۡتَ وَيُسَلِّمُواْ تَسۡلِيمٗا 65﴾
{Rárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá}. [Surah An-Nisâ': 65]
Awọn eso ti o tobi ni o n bẹ fun nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ, ninu wọn:
Akọkọ: Nini imọ nipa ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati iko akolekan Rẹ pẹlu awọn ẹru Rẹ, nigba ti O ran awọn Ojiṣẹ si wọn ki wọn le fi wọn mọna lọ sí oju ọna Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ki wọn si ṣàlàyé fun wọn bi wọn yóò ṣe maa jọsin fun Ọlọhun; nitori pe laakaye ti ẹda nikan o le da ìyẹn mọ
Ikeji: Idupẹ fun Ọba- ti ọla Rẹ ga- lori idẹra ti o tobi julọ yii
Ikẹta: Nini ifẹ awọn Ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn- ati gbigbe wọn tobi, ati yiyin wọn pẹlu nnkan ti o yẹ wọn; nitori pe awọn ni Ojiṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti wọn si mójú tó ijọsin Rẹ, ati mimu iranṣẹ Rẹ de ogongo, ati ṣíṣe isiti fun awọn ẹru Rẹ
Dajudaju awọn alagidi ti tako awọn Ojiṣẹ wọn ti wọn lero pe awọn Ojiṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- wọn ko nii jẹ ẹda! Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti sọ ero yii, O si ba a jẹ pẹlu ọ̀rọ̀ Rẹ- mimọ ni fun Un- pe:
﴿وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَبَعَثَ ٱللَّهُ بَشَرٗا رَّسُولٗا94 قُل لَّوۡ كَانَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَلَٰٓئِكَةٞ يَمۡشُونَ مُطۡمَئِنِّينَ لَنَزَّلۡنَا عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَلَكٗا رَّسُولٗا 95﴾
{Kò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni? *Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́}.
[Surah Al-Isrâ’: 94-95]
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ba ero yii jẹ pe dajudaju o jẹ dandan ki Ojiṣẹ jẹ ẹda, nitori pe A ran an si awọn ara ilẹ ti wọn jẹ ẹda, ti awọn ara ilẹ̀ ba jẹ mọlaika ni, Ọlọhun ko ba sọkalẹ fun wọn lati inu sanmọ mọlaika kan lati jẹ Ojiṣẹ, ki o le da bii wọn Gẹgẹ bayii ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe gba ẹnu awọn ti wọn pe awọn Ojiṣẹ ni opurọ sọ̀rọ̀ pe wọn sọ pe:
﴿...إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا تُرِيدُونَ أَن تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا فَأۡتُونَا بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ 10 قَالَتۡ لَهُمۡ رُسُلُهُمۡ إِن نَّحۡنُ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَمُنُّ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ وَمَا كَانَ لَنَآ أَن نَّأۡتِيَكُم بِسُلۡطَٰنٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِ...﴾
{Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan tayọ abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé*Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu}. [Surah Ibrâhîm: 10-11]
Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin
Ọjọ ikẹyin: Ọjọ igbedide ti wọn maa gbe ọmọniyan dide nibẹ fun iṣiro ati ẹsan
Wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe ko si ọjọ miiran lẹyin rẹ, nigba ti awọn ara alujanna yoo maa ṣe gbere ninu awọn ibugbe wọn ti awọn ara ina naa yoo maa ṣe gbere ninu awọn ibugbe wọn
Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin ko awọn alamọri mẹta kan sinu:
Akọkọ: Nini igbagbọ ninu igbedide: Oun ni sisọ awọn òkú di alaaye nígbà tí wọ́n ba fọn fèrè ẹlẹẹkeji; ti awọn eniyan maa dide fun Oluwa gbogbo ẹda láìwọ bata, ni ìhòòhò, ni ẹni tí wọn kò dá abẹ́ fún, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...كَمَا بَدَأۡنَآ أَوَّلَ خَلۡقٖ نُّعِيدُهُۥۚ وَعۡدًا عَلَيۡنَآۚ إِنَّا كُنَّا فَٰعِلِينَ﴾
{…Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀}. [Surah Al-Anbiyâ’: 104]
Igbedide: Ododo kan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ni, ti tira Ọlọhun, ati Sunnah Anabi, ati ipanupọ awọn Musulumi si n tọka si.
﴿ثُمَّ إِنَّكُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ لَمَيِّتُونَ 15 ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تُبۡعَثُونَ 16﴾
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yó sì di òkú*Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde Wọ́n máa gbe yín dìde}.
[Surah Al-Mu’minûn: 15-16]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
«يُحْشَرُ النَّاسُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ حُفَاةً عُرَاةً غُرْلًا».
“Wọn maa ko awọn eniyan jọ ni ọjọ igbedide ni ẹni ti ko nii wọ bata, ni arin-hoho, ni ẹni tí wọn ko da abẹ fun”. Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa
Awọn Musulumi fi ẹnu ko lori fifi ẹsẹ rinlẹ rẹ, oun naa ni o ba ọgbọ́n mu; torí pé ohun ti o ba ọgbọ́n mu ni ki Ọlọhun jẹ ki awọn ẹda yii ni ibusẹrisi, ti yoo san wọn ni ẹsan nibẹ lori nnkan ti O ṣe ni ofin fun wọn níbi nnkan ti O gbe awọn Ojiṣẹ Rẹ dide pẹlu rẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿أَفَحَسِبۡتُمۡ أَنَّمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ عَبَثٗا وَأَنَّكُمۡ إِلَيۡنَا لَا تُرۡجَعُونَ 115﴾
{Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?} [Surah Al-Mu’minûn: 115] O sọ fun Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe:
﴿إِنَّ ٱلَّذِي فَرَضَ عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لَرَآدُّكَ إِلَىٰ مَعَادٖ...﴾
{Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ, Ó sì máa dá ọ padà sí èbúté kan…}.
[Surah Al-Qasas: 85]
Ikeji: Nini igbagbọ ninu iṣiro-iṣẹ ati ẹsan: Wọn maa ṣe iṣiro fun ẹda lori iṣẹ rẹ, wọn yoo si san an ni ẹsan lori rẹ, ti tira Ọlọhun, ati Sunnah Anabi, ati ìfẹnukò awọn Musulumi si tọka si i.
﴿إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ 25 ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم 26﴾
{Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà*Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn}. [Surah Al-Ghâshiyah: 25-26]
﴿مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ عَشۡرُ أَمۡثَالِهَاۖ وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَا وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 160﴾
{Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú iṣẹ́ dáadáa wá, (ẹ̀san) mẹ́wàá irú rẹ̀ l’ó máa wà fún un. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wa, A ò níí san án ní ẹ̀san àyàfi irú rẹ̀. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn}. [Surah Al-An`âm: 160]
﴿وَنَضَعُ ٱلۡمَوَٰزِينَ ٱلۡقِسۡطَ لِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَلَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡـٔٗاۖ وَإِن كَانَ مِثۡقَالَ حَبَّةٖ مِّنۡ خَرۡدَلٍ أَتَيۡنَا بِهَاۗ وَكَفَىٰ بِنَا حَٰسِبِينَ 47﴾
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò}.
[Surah Al-Anbiyâ’: 47]
Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a ati awọn ara ile rẹ- sọ pe:
«إِنَّ اللَّهَ يُدْنِي الْمُؤْمِنَ، فَيَضَعُ عَلَيْهِ كَنَفَهُ - أَيْ سَتْرَهُ - وَيَسْتُرُهُ: فَيَقُولُ: أَتَعْرِفُ ذَنْبَ كَذَا؟ أَتَعْرِفُ ذَنْبَ كَذَا؟ فَيَقُولُ: نَعَمْ أَيْ رَبِّ، حَتَّى إِذَا قَرَّرَهُ بِذُنُوبِهِ، وَرَأَى فِي نَفْسِهِ أَنَّهُ هَلَكَ قَالَ: سَتَرْتُهَا عَلَيْكَ فِي الدُّنْيَا وَأَنَا أَغْفِرُهَا لَكَ الْيَوْمَ، فَيُعْطَى كِتَابَ حَسَنَاتِهِ، وَأَمَّا الْكُفَّارُ وَالْمُنَافِقُونَ فَيُنَادَى بِهِمْ عَلَى رُؤُوسِ الْخَلَائِقِ: هَؤُلَاءِ الَّذِينَ كَذَبُوا عَلَى رَبِّهِمْ، أَلَا لَعْنَةُ اللَّهِ عَلَى الظَّالِمِينَ».
“Dajudaju Ọlọhun yoo sún olugbagbọ mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀, yóò sì da gaga Rẹ bò ó, Yoo si sọ pe: Njẹ o mọ ẹṣẹ bayii? Njẹ o mọ ẹṣẹ báyìí? Yoo sọ pe: Bẹẹni Ìrẹ Olúwa mi, titi di igba ti yoo fi mu u jẹwọ awọn ẹṣẹ rẹ, yoo wa ri ara rẹ pe dajudaju oun ti parun, Ọlọhun maa wa sọ pé: Mo bo ẹ lasiri rẹ ni aye, Emi yoo si fi ori rẹ jìn ẹ lonii, wọn maa wa fun un ni iwe awọn daadaa rẹ, ṣugbọn awọn alaigbagbọ ati awọn munaafiki, wọn yoo pe wọn síta lójú awọn ẹda pé: Awọn yii ni awọn ti wọn pa irọ́ mọ Oluwa wọn, gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí” Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa
O ni alaafia lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-:
«أَنَّ مَنْ هَمَّ بِحَسَنَةٍ فَعَمِلَهَا؛ كَتَبَهَا اللَّهُ عِنْدَهُ عَشْرَ حَسَنَاتٍ إِلَى سَبْعِ مِئَةِ ضِعْفٍ إِلَى أَضْعَافٍ كَثِيرَةٍ، وَأَنَّ مَنْ هَمَّ بِسَيِّئَةٍ فَعَمِلَهَا؛ كَتَبَهَا اللَّهُ سَيِّئَةً وَاحِدَةً».
“Dajudaju ẹni ti o ba gbero daadaa kan ti o si ṣe e, Ọlọhun yoo kọ ọ sọ́dọ̀ Rẹ ni daadaa mẹwaa titi de adipele ọgọ́rùn-ún meje titi de awọn adipele ti o pọ, ti o ba gbero aburu ti o si ṣe e Ọlọhun yoo kọ ọ pe aburu kan ni”
Awọn Musulumi fi ẹnu ko lori ifi ẹsẹ rinlẹ ìṣirò-iṣẹ́ ati ẹsan lori awọn iṣẹ, oun si ni nnkan ti o ba ọgbọ́n mu; nitori pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ awọn tira kalẹ, O si ran awọn Ojiṣẹ, O si ṣe ni dandan le àwọn ẹru lori lati gba nnkan ti wọn mu wa, ati ṣíṣe amulo nnkan ti lílo rẹ jẹ dandan ninu rẹ, O si ṣe gbigbe ogun ti awọn alatako fun un ni dandan, O si ṣe ita ẹjẹ wọn silẹ ni ẹtọ, ati awọn àrọ́mọdọ́mọ wọn, ati awọn iyawo wọn, ati awọn dukia wọn. Ti ko ba si iṣiro-iṣẹ ni tabi ẹsan, eleyii ko ba wa ninu ere ti Oluwa Ọjọgbọn mọ kuro nibẹ, dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti tọka si ìyẹn pẹlu ọ̀rọ̀ Rẹ pe:
﴿فَلَنَسۡـَٔلَنَّ ٱلَّذِينَ أُرۡسِلَ إِلَيۡهِمۡ وَلَنَسۡـَٔلَنَّ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 6 فَلَنَقُصَّنَّ عَلَيۡهِم بِعِلۡمٖۖ وَمَا كُنَّا غَآئِبِينَ 7﴾
{Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́)*Dájúdájú A óò ròyìn (iṣẹ́ ọwọ́ wọn) fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀. Àwa kò ṣàì wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀)}.
[Surah Al-A`râf:6-7]
Ikẹta: Nini igbagbọ ninu alujanna ati ina ati pe dajudaju awọn ni ibudesi gbere fun ẹda
Alujanna ni ọgba idẹra ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pese rẹ fun awọn olugbagbọ awọn olubẹru Ọlọhun, awọn ti wọn ni igbagbọ pẹlu nnkan ti Ọlọhun ṣe ni dandan le wọn lori lati gba a gbọ, ti wọn tẹle Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ, ti wọn ṣe afọmọ fun Ọlọhun, ti wọn tẹle Ojiṣẹ Rẹ, awọn oríṣiríṣi idẹra ni n bẹ nibẹ
«مَا لَا عَيْنٌ رَأَتْ، وَلَا أُذُنٌ سَمِعَتْ، وَلَا خَطَرَ عَلَى قَلْبِ بَشَرٍ».
“Ti oju ko ri ri, ti eti ko gbọ ri, ti ko si ṣe wuyẹ lori ọkan ẹda”. Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمۡ خَيۡرُ ٱلۡبَرِيَّةِ 7 جَزَآؤُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ رَّضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ رَبَّهُۥ 8﴾
{Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t’ó dára jùl*Ẹ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀}.
[Surah Al-Bayyinah: 7:8]
﴿فَلَا تَعۡلَمُ نَفۡسٞ مَّآ أُخۡفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعۡيُنٖ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 17﴾
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe: {Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere)}.
[Surah As-Sajdah: 17]
Ṣùgbọ́n ina: Oun ni ilé iya ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pa lese silẹ fun awọn alaigbagbọ awọn alabosi, awọn ti wọn ṣe aigbagbọ si I ti wọn yapa awọn Ojiṣẹ Rẹ, awọn oríṣiríṣi iya ni n bẹ nibẹ ti ko leè ṣe wuyẹ lori ẹmi
﴿...وَٱتَّقُواْ ٱلنَّارَ ٱلَّتِيٓ أُعِدَّتۡ لِلۡكَٰفِرِينَ﴾
{Kí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí Wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́}. [Surah Âl-`Imrân: 131]
Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَقُلِ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَن شَآءَ فَلۡيُؤۡمِن وَمَن شَآءَ فَلۡيَكۡفُرۡۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمۡ سُرَادِقُهَاۚ وَإِن يَسۡتَغِيثُواْ يُغَاثُواْ بِمَآءٖ كَٱلۡمُهۡلِ يَشۡوِي ٱلۡوُجُوهَۚ بِئۡسَ ٱلشَّرَابُ وَسَآءَتۡ مُرۡتَفَقًا 29﴾
{Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan t’ó dà bí òjé idẹ gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ó burú ní mímu. Ó sì burú ní ibùkójọ}. [Surah Al-Kahf: 29]
﴿إِنَّ ٱللَّهَ لَعَنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمۡ سَعِيرًا 64 خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ لَّا يَجِدُونَ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا 65 يَوۡمَ تُقَلَّبُ وُجُوهُهُمۡ فِي ٱلنَّارِ يَقُولُونَ يَٰلَيۡتَنَآ أَطَعۡنَا ٱللَّهَ وَأَطَعۡنَا ٱلرَّسُولَا۠66﴾
{Dájúdájú Allāhu ṣẹ́bi le àwọn aláìgbàgbọ́. Ó sì pèsè Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n*Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé; wọn kò níí rí olùṣọ́ tàbí alárànṣe kan*Ní ọjọ́ tí A óò yí ojú wọn padà nínú Iná, wọn yó sì wí pé: “Yéè! Àwa ìbá tẹ̀lé ti Allāhu, àwa ìbá sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́}. [Surah Al-Ahzâb: 64-66]
Awọn eso ti o tobi ni o n bẹ fun nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin, ninu wọn ni:
Akọkọ: Iṣe ojúkòkòrò itẹle ti Ọlọhun; ni ìrètí ẹsan ọjọ yẹn
Ikeji: Ibẹru lati dá ẹṣẹ, ati ki èèyàn ma yọ́nú si i ni ti ipaya iya ọjọ yẹn
Ikẹta: Titu ẹ̀mí olugbagbọ kuro nibi nnkan ti o ba bọ fun un ninu aye pẹlu nnkan ti o n wa ninu idẹra ọrun ati ẹsan rẹ
Àwọn alaigbagbọ tako igbedide lẹyin iku; ti wọn lero pe dajudaju ìyẹn o rọrun
Èrò yii jẹ ibajẹ, sharia náà si tọka si ibajẹ rẹ, ati imọlara ati laakaye
Ṣùgbọ́n ti sharia, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿زَعَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن لَّن يُبۡعَثُواْۚ قُلۡ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتُبۡعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلۡتُمۡۚ وَذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 7﴾
{Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ kọ́, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fun yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu} [Surah At-Taghâbun: 7] Gbogbo awọn iwe sanmọ fi ẹnu ko le e lori
Ṣugbọn ti ìmọ̀lára: Ọlọhun ti mu awọn ẹru Rẹ ri sísọ oku di alaaye ni aye yii, apejuwe marun-un n bẹ ninu Surah Al-Baqarah lori ìyẹn, awọn ni:
Apejuwe akọkọ: Ijọ Anabi Musa nigba ti wọn sọ fun un pe:
﴿...لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ ...﴾
{ò níí gbà ọ́ gbọ́ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkorojú} [Surah Al-Baqarah: 55] Nibi iyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n ba awọn ọmọ Ísírẹ́lì sọrọ pe:
﴿وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡكُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ 55 ثُمَّ بَعَثۡنَٰكُم مِّنۢ بَعۡدِ مَوۡتِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 56﴾
{(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: Mūsā, a ò níí gbà ọ́ gbọ́ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkorojú Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀*Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu)}
[Surah Al-Baqarah: 56]
Apejuwe keji: Nibi itan ẹni ti wọn pa ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ifanfa lórí ẹ, ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- wa pa wọn laṣẹ lati pa màálù kan ki wọn fi apakan ninu rẹ lu u; lati fun wọn ni iro nipa ẹni ti o pa a, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿وَإِذۡ قَتَلۡتُمۡ نَفۡسٗا فَٱدَّٰرَٰءۡتُمۡ فِيهَاۖ وَٱللَّهُ مُخۡرِجٞ مَّا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ 72 فَقُلۡنَا ٱضۡرِبُوهُ بِبَعۡضِهَاۚ كَذَٰلِكَ يُحۡيِ ٱللَّهُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 73﴾
{(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́*Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè}.
[Surah Al-Baqarah: 73]
Apejuwe kẹta: Nibi itan awọn ijọ ti wọn jade lati inu awọn ile wọn ti wọn sa fun iku lẹgbẹẹgbẹrun; Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pa wọn, lẹyin naa O sọ wọn di alaaye, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ خَرَجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَهُمۡ أُلُوفٌ حَذَرَ ٱلۡمَوۡتِ فَقَالَ لَهُمُ ٱللَّهُ مُوتُواْ ثُمَّ أَحۡيَٰهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ243﴾
{Ṣé o ò rí àwọn t’ó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un)}.
[Surah Al-Baqarah: 243]
Apejuwe kẹrin: Nibi itan ẹni ti o kọjá ni abúlé kan ti o ti ku, o wa gba pe ko rọrùn ki Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ọ di alaaye; Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- si pa a fun ọgọ́rùn-ún ọdun, lẹyin naa O sọ ọ di alaaye, nibi iyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿أَوۡ كَٱلَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرۡيَةٖ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحۡيِۦ هَٰذِهِ ٱللَّهُ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۖ فَأَمَاتَهُ ٱللَّهُ مِاْئَةَ عَامٖ ثُمَّ بَعَثَهُۥۖ قَالَ كَمۡ لَبِثۡتَۖ قَالَ لَبِثۡتُ يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۖ قَالَ بَل لَّبِثۡتَ مِاْئَةَ عَامٖ فَٱنظُرۡ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمۡ يَتَسَنَّهۡۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجۡعَلَكَ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِۖ وَٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡعِظَامِ كَيۡفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكۡسُوهَا لَحۡمٗاۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥ قَالَ أَعۡلَمُ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 259﴾
{Tàbí bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí ó ti tú tòrùlé-tòrùlé rẹ̀. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn. Sì tún wo eegun náà bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan}.
[Surah Al-Baqarah: 259]
Apejuwe karun-un: Nibi itan Anabi Ibrahim ààyò Ọlọhun, nigba ti o beere lọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati mu oun ri bi yoo ṣe sọ oku di alaaye; Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pa a láṣẹ lati dunbu mẹrin ninu awọn ẹyẹ, ki o pin wọn kelekele sórí awọn oke ti wọn wa ni ẹgbẹ rẹ, lẹyin naa o maa pe wọn; ti awọn ipin naa si maa lẹ papọ mọ ara wọn, wọn yoo si wa ba Ibrahim ni kiakia, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّ أَرِنِي كَيۡفَ تُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ قَالَ أَوَلَمۡ تُؤۡمِنۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِن لِّيَطۡمَئِنَّ قَلۡبِيۖ قَالَ فَخُذۡ أَرۡبَعَةٗ مِّنَ ٱلطَّيۡرِ فَصُرۡهُنَّ إِلَيۡكَ ثُمَّ ٱجۡعَلۡ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٖ مِّنۡهُنَّ جُزۡءٗا ثُمَّ ٱدۡعُهُنَّ يَأۡتِينَكَ سَعۡيٗاۚ وَٱعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 260﴾
{Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè." (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: "Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n}. [Surah Al-Baqarah: 260]
Awọn wọnyi ni awọn apejuwe ti imọlara ti o ṣẹlẹ, ti wọn n tọka si rí rọrùn sísọ oku di alaaye, ati pe itọka si nnkan ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe ni ami Anabi Isa ọmọ Maryam ti ṣaaju nibi sísọ oku di alaaye, ati mimu wọn jade lati inu awọn saare wọn- pẹlu iyọnda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ṣugbọn itọka laakaye: O jẹ lati ojupanna meji:
Akọkọ: Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni Aṣẹ̀dá sanmọ ati ilẹ, ati nnkan ti o wa ninu mejeeji, Oun ni O da wọn ni ibẹrẹ, Ọba Olukapa lori ibẹrẹ ẹda dida ko le kagara nibi dida a pada, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ...﴾
{Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀)}. [Surah Ar-Rûm: 27]
"Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿...كَمَا بَدَأۡنَآ أَوَّلَ خَلۡقٖ نُّعِيدُهُۥۚ وَعۡدًا عَلَيۡنَآۚ إِنَّا كُنَّا فَٰعِلِينَ﴾
{(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀}. [Surah Al-Anbiyâ’: 104] O sọ ti O n pàṣẹ lati fọ esi fun ẹni ti o tako sísọ egungun di alaaye nigba ti o ti kẹfun pe:
﴿قُلۡ يُحۡيِيهَا ٱلَّذِيٓ أَنشَأَهَآ أَوَّلَ مَرَّةٖۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلۡقٍ عَلِيمٌ 79﴾
{Sọ pé: "Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá}.
[Surah Yâ-sîn: 79]
Ikeji: Dajudaju ilẹ jẹ oku ti o gbẹ, ti ko si igi elewe nibẹ; ojo maa wa rọ le e lori; o maa wa yira padà di aláwọ̀ ewé ti o maa ṣẹ̀mí, ti gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára maa wa nibẹ, Ẹni ti O ni ikapa lori sisọ ọ di alaaye lẹyin iku rẹ, ni ikapa lori sisọ awọn oku di alaaye, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنَّكَ تَرَى ٱلۡأَرۡضَ خَٰشِعَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡۚ إِنَّ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاهَا لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 39﴾
{Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan}. [Surah Fussilat: 39]
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَنَزَّلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ مُّبَٰرَكٗا فَأَنۢبَتۡنَا بِهِۦ جَنَّٰتٖ وَحَبَّ ٱلۡحَصِيدِ 9 وَٱلنَّخۡلَ بَاسِقَٰتٖ لَّهَا طَلۡعٞ نَّضِيدٞ 10 رِّزۡقٗا لِّلۡعِبَادِۖ وَأَحۡيَيۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ ٱلۡخُرُوجُ 11﴾
{A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n máa kájẹ hù jáde"*(A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì*Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí)}. [Surah Qâf: 9-11]
O maa so pọ mọ nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin: Nini igbagbọ ninu gbogbo nnkan ti yoo ṣẹlẹ lẹyin iku gẹgẹ bii:
A) Wahala inu saare: Oun ni bibeere lọwọ oku lẹyin ti wọn ba sin in nipa Oluwa rẹ, ati ẹsin rẹ, ati Anabi rẹ; Ọlọhun si maa fi awọn olugbagbọ ododo rinlẹ pẹlu ọ̀rọ̀ ti o rinlẹ, yoo waa sọ pe: Allahu ni Oluwa mi, ẹsin mi ni Isilaamu, Anabi mi ni Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
Ọlọhun yoo wàá sọ awọn alabosi nu ti alaigbagbọ si maa sọ pe: Háà háà, mi ko mọ, ti ṣọbẹ-ṣelu tabi oniyemeji yoo sọ pe: Mi ko mọ, mo gbọ ti awọn eniyan n sọ nnkankan emi naa si sọ ọ
B) Iya inu saare ati idẹra rẹ: O maa wa fun awọn alabosi ninu awọn ṣọbẹ-ṣelu ati awọn alaigbagbọ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّٰلِمُونَ فِي غَمَرَٰتِ ٱلۡمَوۡتِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَاسِطُوٓاْ أَيۡدِيهِمۡ أَخۡرِجُوٓاْ أَنفُسَكُمُۖ ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ وَكُنتُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِهِۦ تَسۡتَكۡبِرُونَ﴾
{Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé) “Ẹ mú ẹ̀mí yín jáde wá. Lónìí ni Wọn yóò san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí ohun tí ẹ̀ máa ń sọ nípa Allāhu ní àìtọ́. Ẹ sì máa ń ṣe ìgbéraga sí àwọn āyah Rẹ̀}.
[Surah Al-An`âm: 93]
"Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nipa awọn ará ilé Fir’aon pe:
﴿ٱلنَّارُ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا غُدُوّٗا وَعَشِيّٗاۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدۡخِلُوٓاْ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ أَشَدَّ ٱلۡعَذَابِ 46﴾
{Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná t’ó le jùlọ}.
[Surah Ghâfir: 46]
O wa ninu sọhihu Muslim ninu hadisi Zaid ọmọ Thabit- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ti kii ba ṣe pe ẹ ko ni fẹ maa sin ara yin ni, mi o ba bẹ Ọlọhun ki o maa mu yin gbọ ninu iya inu saare ohun ti mo n gbọ ninu rẹ”, lẹ́yìn naa, o kọ oju rẹ siwaju o wa sọ pe: “Ẹ fi Ọlọhun wa iṣọra kuro nibi iya iná”, wọn sọ pe: A n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi iya iná, o sọ pe: “Ẹ fi Ọlọhun wa iṣọra kuro nibi iya saare”, wọ́n sọ pe: A n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi iya saare, o sọ pe: “Ẹ fi Ọlọhun wa iṣọra kuro nibi awọn wahala, eyi ti o han ati eyi ti o pamọ”, wọn sọ pe: A n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn wahala, eyi ti o han ati eyi ti o pamọ, o sọ pe: “Ẹ fi Ọlọhun wa iṣọra kuro nibi wahala Dajjal”, wọn sọ pe: A n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi wahala Dajjal.
Ṣugbọn idẹra saare: O wa fun awọn olugbagbọ ododo, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ تَتَنَزَّلُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَلَّا تَخَافُواْ وَلَا تَحۡزَنُواْ وَأَبۡشِرُواْ بِٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ 30﴾
{Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín}.
[Surah Fussilat: 30]
"Ọlọhun ti ọla Rẹ ga-sọ pe:
﴿فَلَوۡلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلۡحُلۡقُومَ 83 وَأَنتُمۡ حِينَئِذٖ تَنظُرُونَ 84 وَنَحۡنُ أَقۡرَبُ إِلَيۡهِ مِنكُمۡ وَلَٰكِن لَّا تُبۡصِرُونَ 85 فَلَوۡلَآ إِن كُنتُمۡ غَيۡرَ مَدِينِينَ 86 تَرۡجِعُونَهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ87 فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ 88 فَرَوۡحٞ وَرَيۡحَانٞ وَجَنَّتُ نَعِيمٖ 89﴾
{Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun*tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn?*Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran*Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀*kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo*Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa)*ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀)}. [Surah Al-Wâqi`ah: 83-89]
Lati ọdọ Baraah ọmọ 'Aazib- kí Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa olugbagbọ ododo ti o ba fe da awọn mọlaika mejeeji lohun ninu saare rẹ: “Olupepe kan yoo maa pe lati sanmọ pe: Òdodo ni ẹru mi sọ, ẹ tẹ ìtẹ́ fun un lati inu alujanna, ẹ wọ ọ ni aṣọ lati inu alujanna, ẹ ṣi ilẹkun kan fun un lọ sinu alujanna, o sọ pe: Ni òórùn dídùn rẹ maa wa ba a, wọn si maa gbà á láàyè ni odiwọn ibi ti irina rẹ ba dé”. Ahmad ni o gba a wa ati Abu Daud níbi hadisi kan ti o gun
Awọn èèyàn kan ti sọnu ninu awọn ti wọn ni igbunri kúrò nibi òdodo, wọn tako iya saare, ati idẹra rẹ, ti wọn lero pe dajudaju ìyẹn o rọrun fun ìyapa rẹ̀ si nnkan ti o n ṣẹlẹ, wọn sọ pe: Ti wọn ba yẹ oku wo ninu saare rẹ, wọn maa ri i gẹgẹ bi o ṣe wa, ti saare ko si ni yi pada pẹlu pe ki o fẹ síi tabi fún síi.
Ero yii jẹ ibajẹ pẹlu sharia, ati imọlara, ati laakaye:
Nipa ti sharia: Awọn ọrọ Ọlọhun ti n tọka si irinlẹ iya saare ti ṣaaju, ati idẹra rẹ
Ninu sọhihu Bukhari ninu hadisi ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade lati inu ọgbà kan ninu Madina; o ba gbọ ohun ọmọniyan meji kan ti wọn n fi iya jẹ wọn nínú saare wọn”, o wa sọ hadisi naa, o n bẹ nibẹ pe: “Dajudaju ọkan ninu wọn ko ki n bo ara rẹ nibi itọ”, ninu ẹgbawa kan: “Nibi itọ rẹ”, ati pe ikeji maa n gbe ofofo kiri, ninu ẹgbawa Muslim: “Ko ki n mọ kuro níbi itọ”.
Ṣugbọn ti imọlara: Dajudaju ẹni ti o sun maa n ri ni oju oorun rẹ pe oun wa ni aaye kan ti o fẹ̀ ti o rẹwa, ti o n gbadun nibẹ, tabi ki o wa ni aaye kan ti o fun ti ko si èèyàn kankan nibẹ, ti o maa jẹ irora nibẹ, nigba mii yoo ji latara nnkan ti o ri Sibẹsibẹ ori ibusun rẹ ni o wà ninu yara rẹ lori nnkan ti o wa lori rẹ, ati pe oorun jẹ ọmọ iya iku; nitori idi eyi, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe e ni: (Iku), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé:
﴿ٱللَّهُ يَتَوَفَّى ٱلۡأَنفُسَ حِينَ مَوۡتِهَا وَٱلَّتِي لَمۡ تَمُتۡ فِي مَنَامِهَاۖ فَيُمۡسِكُ ٱلَّتِي قَضَىٰ عَلَيۡهَا ٱلۡمَوۡتَ وَيُرۡسِلُ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّى...﴾
{Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan…}.
[Surah Az-Zumar: 42]
Nipa ti laakaye: Dajudaju ẹni ti o sun ni oju oorun rẹ maa n la àlá ododo ti o maa ba nnkan ti o n ṣẹlẹ mu, o ṣeeṣe ki o ri Anabi- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi o ṣe ri, ati pe ẹni ti o ba ri i bi o ṣe ri, dajudaju o ti ri i lododo, ti ohun ti bẹẹ, ẹni ti o sun wa ni yara rẹ lori ibusun rẹ ti o jinna si nnkan ti o ri Ti eyi ba rọrun ni awọn isẹsi aye, ṣe ko wa nii rọrun ni awọn isẹsi ọrun?!
Ṣugbọn igbarale wọn nibi nnkan ti wọn lérò pe ti wọn ba yẹ oku wò nínú saare rẹ; wọn maa ri i gẹlẹ bi o ṣe wa ni, ti saare naa ko nii fẹ̀ si ko si nii fún si; àwọn ọ̀nà kan ni a maa gba dáhùn rẹ, nínú wọn ni:
Akọkọ: Dajudaju ko lẹ́tọ̀ọ́ lati tako nnkan ti ofin wa pẹlu rẹ pẹlu iru awọn iruju burúkú yii, ti o ṣe pe ti olutako ba ronu si nnkan ti ofin wa pẹlu rẹ ni paapaa iwoyesi ko ba mọ ibajẹ awọn iruju yii, wọn ti sọ pe:
Àìmọye èèyàn ti n bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ ti o ni alaafia
Ti o si jẹ pe aleebu rẹ latara agbọye ti o saarẹ ni.
Ikeji: Dajudaju awọn iṣesi iṣẹmi lẹ́yìn ikú wa ninu awọn alamọri kọ̀kọ̀ ti a ko le ni ìmọ̀lára rẹ, ti o ba jẹ pe a le ni ìmọ̀lára rẹ ni, anfaani nini igbagbọ ninu kọ̀kọ̀ maa bọ, dajudaju awọn olugbagbọ ninu kọ̀kọ̀ maa ṣe dọgba pẹlu awọn ti wọn n tako gbigba a lododo
Ikẹta: Dajudaju iya, ati idẹra, ati gbigbaaye saare, ati fifun rẹ; oku nìkan ni o maa mọ ọn, eleyii da gẹgẹ bii ẹni ti o sun ti o wa n ri ni oju oorun rẹ pe oun wa ni aaye kan ti o fun ti ko si èèyàn kankan nibẹ, tabi aaye kan ti o fẹ̀ ti o rẹwa, ti ẹni ti o wa ni ẹgbẹ rẹ ko nii ri iyẹn tabi ki o mọ ọn lara. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gba imisi ti o si wa laaarin awọn saabe rẹ; ti yoo maa gbọ imisi naa, ti awọn saabe ko si nii gbọ ọ, o ṣeeṣe ki mọlaika kan yọ si i ni aworan ọkùnrin kan ti yoo maa ba a sọrọ ti awọn saabe ko si nii ri mọlaika naa, ti wọn ko si nii gbọ́ ọ.
Ikẹrin: Imọ ẹda ni aala pẹlu nnkan ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ba fi rọ wọn lọrun lati mọ̀, ko rọrun fun wọn lati mọ gbogbo nnkan ti o n bẹ, sanmọ jẹ meje, ati ilẹ, ati awọn ti wọn n bẹ ninu wọn, ati pe gbogbo nnkan n ṣe afọmọ pẹlu idupẹ fun Ọlọhun ni afọmọ gidi, ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa n jẹ ki ẹni ti o ba fẹ ninu ẹda Rẹ gbọ́ ọ nigba míì Ti ohun ti bẹẹ o pamọ fun wa, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿تُسَبِّحُ لَهُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ ٱلسَّبۡعُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهِنَّۚ وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا يُسَبِّحُ بِحَمۡدِهِۦ وَلَٰكِن لَّا تَفۡقَهُونَ تَسۡبِيحَهُمۡۚ...﴾
{Àwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un. Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn}. [Surah Al-Isrâ’: 44] Gẹgẹ bẹẹ ni awọn Eṣu ati alujannu naa ṣe maa n rin ni ori ilẹ ni lílọ ati bibọ, awọn alujannu ti wa ba Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wọn tẹti si kika rẹ, ti wọn dakẹ, ti wọn si ṣẹri pada si ọdọ awọn ijọ wọn ni olùkìlọ̀, sibẹsibẹ wọn pamọ fun wa, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ لَا يَفۡتِنَنَّكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ كَمَآ أَخۡرَجَ أَبَوَيۡكُم مِّنَ ٱلۡجَنَّةِ يَنزِعُ عَنۡهُمَا لِبَاسَهُمَا لِيُرِيَهُمَا سَوۡءَٰتِهِمَآۚ إِنَّهُۥ يَرَىٰكُمۡ هُوَ وَقَبِيلُهُۥ مِنۡ حَيۡثُ لَا تَرَوۡنَهُمۡۗ إِنَّا جَعَلۡنَا ٱلشَّيَٰطِينَ أَوۡلِيَآءَ لِلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ 27﴾
{Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìfòòró ba yín gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yọ àwọn òbí yín méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó gba aṣọ kúrò lára àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ìhòhò wọn hàn wọ́n. Dájúdájú ó ń ri yín; òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (ń ri yín) ní àyè tí ẹ̀yin kò ti rí wọn. Dájúdájú Àwa fi Èṣù ṣe ọ̀rẹ́ fún àwọn tí kò gbàgbọ́}. [Surah Al-A`râf: 27] Ti o ba ṣe pe ẹda ko lee mọ gbogbo nnkan ti o n bẹ, ko lẹ́tọ̀ọ́ lati tako nnkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu awọn alamọri kọ̀kọ̀, ti wọn ko si mọ ọn
Nini igbagbọ ninu kadara
Al-Qodar (Pẹlu fífún DAAL ni FAT’HA): Ipebubu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fun awọn ẹda, nibamu si imọ Rẹ ti o ti ṣaaju, ti o si ba ọgbọn Rẹ mu.
Nini igbagbọ ninu kadara ko awọn alamọri mẹrin kan sinu:
Akọkọ: Nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni imọ nipa gbogbo nnkan, ni odidi ati ifọsiwẹwẹ, ṣiwaju ati láéláé, boya o so pọ mọ awọn iṣẹ Rẹ ni, tàbí awọn iṣẹ ẹru Rẹ
Ikeji: Nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kọ ìyẹn sinu wàláà tí À ń ṣọ́, nibi awọn alamọri mejeeji yii Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّ ذَٰلِكَ فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 70﴾
{Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu}.
[Surah Al-Hajj: 70]
O wa ninu sọhiihu Muslim lati ọdọ Abdulahi ọmọ Amru ọmọ 'Aas- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ọlọhun kọ awọn kadara awọn ẹda ṣiwaju dida sanmọ ati ilẹ pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà àádọ́ta ọdun”.
Ikẹta: Nini igbagbọ pe dajudaju gbogbo awọn ẹda ko lee maa bẹ afi pẹlu ifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, boya o so pọ mọ iṣẹ Rẹ ni, tabi iṣẹ awọn ẹda, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa nnkan ti o so pọ mọ iṣẹ Rẹ pe:
﴿وَرَبُّكَ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُ وَيَخۡتَارُ...﴾
{Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà…}. [Surah Al-Qasas: 68]
﴿...وَيَفۡعَلُ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ﴾
{Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́ } [Surah Ibrâhîm: 27].
O sọ pe:
﴿هُوَ ٱلَّذِي يُصَوِّرُكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ كَيۡفَ يَشَآءُ...﴾
{Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́} [Surah Âl-`Imrân: 6]. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ nípa nǹkan ti o jẹ mọ́ ìṣe àwọn ẹ̀dá pé:
﴿...وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَسَلَّطَهُمۡ عَلَيۡكُمۡ فَلَقَٰتَلُوكُمۡ...﴾
{…Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (akin-ọkàn) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun…}.
[Surah An-Nisâ': 90]
O tun sọ pe:
﴿...وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ مَا فَعَلُوهُۖ فَذَرۡهُمۡ وَمَا يَفۡتَرُون﴾
{…Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́ (láti tọ́ wọn sọ́nà ni) wọn ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, fi wọn sílẹ̀ tòhun ti àdápa irọ́ tí wọ́n ń dá}. [Surah Al-An`âm: 112]
Ikẹrin: Nini igbagbọ pe dajudaju gbogbo nnkan ti n bẹ ni ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu awọn paapaa wọn, ati awọn iroyin wọn, ati awọn lilọ- bibọ wọn, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ 62﴾
{Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan} [Surah Az-Zumar: 62]
Ọlọhun- mimọ ni fun Un- tun sọ pe:
﴿...وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖ فَقَدَّرَهُۥ تَقۡدِيرٗا﴾
{…Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n} [Surah Al-Furqân: 2] O sọ nipa Anabi Rẹ Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o sọ fun ìjọ rẹ pe:
﴿وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ 96﴾
{Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́}
[Surah As-Sâffât: 96]
Nini igbagbọ ninu kadara- lori nnkan ti a ṣe iroyin Rẹ- ko tako ki fifẹ wa fun ẹru nibi awọn iṣẹ́ rẹ ti o jẹ ti ẹsa, ati ini ikapa le e lori; nitori pe ofin ati nnkan ti o n ṣẹlẹ n tọka si fifi ìyẹn rinlẹ fun un
Nípa ti sharia: Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ nipa fifẹ pe:
﴿...فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ مَـَٔابًا﴾
{Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà)}.
[Surah An-Naba’: 39]
O tun sọ pe:
﴿...فَأۡتُواْ حَرۡثَكُمۡ أَنَّىٰ شِئۡتُمۡ...﴾
{…Ẹ lọ s’ínú oko yín bí ẹ bá ṣe fẹ́…}
[Surah Al-Baqarah: 223]
O sọ nipa ikapa pe:
﴿فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ وَٱسۡمَعُواْ وَأَطِيعُواْ...﴾
{ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e}[Surah At-Taghâbun: 16]
O tun sọ pe:
﴿لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَعَلَيۡهَا مَا ٱكۡتَسَبَتۡ...﴾
{Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe ní’ṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú…}.
[Surah Al-Baqarah: 286]
Nípa nnkan ti o n ṣẹlẹ lododo: Dajudaju gbogbo ọmọniyan mọ pe dajudaju fifẹ ati ini ikapa n bẹ fun oun, o n ṣe iṣẹ́ pẹlu mejeeji, o n gbe iṣẹ ju silẹ pẹlu mejeeji, o n ṣe iyatọ láàrin nǹkan ti n ṣẹlẹ̀ pẹlu ero rẹ gẹgẹ bii irin, ati nnkan ti o n ṣẹlẹ láìsí ero rẹ nibẹ gẹgẹ bii gbígbọ̀n, ṣugbọn fifẹ ẹru ati ini ikapa rẹ maa n waye pẹlu fifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati ikapa Rẹ, fun ọrọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe:
﴿لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَسۡتَقِيمَ 28 وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ29﴾
{(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé*Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá}. [Surah At-Takwîr: 28] Ati pe nitori pe dajudaju aye patapata jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, nnkan kan ko le si ninu ikapa rẹ laisi imọ Rẹ ati fifẹ Rẹ nibẹ.
Nini igbagbọ ninu kadara- bi a ṣe royin rẹ- ko fun ẹru ni awijare lori nnkan ti o gbe ju silẹ ninu awọn nnkan ti wọn jẹ dandan, tabi ṣíṣe iṣẹ kan ninu awọn ẹṣẹ, lori eyi wiwa awijare pẹlu rẹ jẹ ibajẹ lati ibi awọn ojupọnna kan:
Akọkọ: ọrọ Ọba- ti ọla Rẹ ga- pe:
﴿سَيَقُولُ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَآ أَشۡرَكۡنَا وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ حَتَّىٰ ذَاقُواْ بَأۡسَنَاۗ قُلۡ هَلۡ عِندَكُم مِّنۡ عِلۡمٖ فَتُخۡرِجُوهُ لَنَآۖ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَخۡرُصُونَ 148﴾
{Àwọn t’ó ń ṣẹbọ yóò wí pé: "Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni àwa àti àwọn bàbá wa ìbá tí ṣẹbọ, àti pé àwa ìbá tí ṣe n̄ǹkan kan léèwọ̀." Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́ títí wọ́n fi tọ́ ìyà Wa wò. Sọ pé: "Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan ń bẹ ní ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ mú un jáde fún wa?" Ẹ̀yin kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Kí sì ni ẹ̀ ń sọ bí kò ṣe pé ẹ̀ ń parọ́}. [Surah Al-An`âm: 148] Ti awijare ba n bẹ fun wọn ni pẹlu kadara, Ọlọhun ko nii fi iya Rẹ jẹ wọn
Ìkejì: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe:
﴿رُّسُلٗا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةُۢ بَعۡدَ ٱلرُّسُلِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا 165﴾
{(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n}. [Surah An-Nisâ': 165] Ti kadara ba jẹ awijare fun awọn oluyapa ni, ko nii kúrò pẹ̀lú riran àwọn Ojiṣẹ; nitori pe ìyapa lẹyin riran wọn jẹ nnkan ti o waye pẹlu kadara Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ikẹta: Nnkan ti Bukhari ati Muslim gba wa- ti gbólóhùn rẹ jẹ ti Bukhari- lati ọdọ Aliy ọmọ Abu Tolib- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ko si ẹni kankan ninu yin afi ki Ọlọhun ti kọ ibujokoo rẹ ninu ina tabi ninu alujanna”, arákùnrin kan ninu ijọ ba sọ pe: Ṣe a ko nii gbe ara le e bi, irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: “Rara, ẹ maa ṣe iṣẹ́, olúkúlùkù ni a ṣe e ni irọrun fun”, lẹyin naa, o ka:
﴿فَأَمَّا مَنۡ أَعۡطَىٰ وَٱتَّقَىٰ 5﴾
{Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu)} [Surah Al-Layl: 5] Ninu ẹgbawa ti Muslim: “Olúkúlùkù ni a ṣe nǹkan ti a tori rẹ da a ni irọrun fun”. O pa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- láṣẹ pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ, O si kọ kuro nibi gbígbẹ́kẹ̀lé kadara
Ikẹrin: Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pa ẹru láṣẹ, O si kọ fun un, ko si la nnkankan bọ ọ lọrun afi nnkan ti o ni ikapa lati ṣe, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ وَٱسۡمَعُواْ وَأَطِيعُواْ...﴾
{Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e…}. [Surah At-Taghâbun: 16]
O tun sọ pe:
﴿لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَا...﴾
{Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀…} [Surah Al-Baqarah: 286] Ti ẹru ba jẹ ẹni ti a jẹ nipa lori ṣíṣe iṣẹ ni, ko ba jẹ ẹni ti a la nnkan ti ko le bọ́ ninu rẹ bọ lọrun, eleyii si jẹ ibajẹ, fun idi ìyẹn, ti ẹṣẹ ba waye lati ọwọ rẹ pẹlu aimọkan, tabi igbagbe, tabi ìjẹnípá; ko si ẹṣẹ fun un, nitori pe ẹni tí ó ni àwíjàre ni.
Ikarun-un: Dajudaju kádàrá Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- jẹ kọ̀kọ̀ kan ti o pamọ ti ẹni kankan ko mọ ọn afi lẹyin iṣẹlẹ nnkan ti a kadara, ati pe èrò ẹru fun nnkan ti o maa ṣe ti ṣaaju ṣíṣe rẹ, èrò rẹ láti ṣe e maa wa jẹ nǹkan ti a ko mọ pa lori imọ lati ọdọ rẹ nípa kádàrá Ọlọhun, nigba naa ni awijare rẹ pẹlu kadara maa kúrò, nigba ti o ṣe pe ko si awijare fun ọmọniyan nípa nnkan ti ko mọ.
Ikẹfa: Dajudaju a wa n ri ọmọniyan ti o n ṣe ojúkòkòrò nnkan ti o ba a mu ninu awọn alamọri aye rẹ; titi ti o fi le e ba, ti ko si ni yi kuro nibẹ lọ si ibi nnkan ti ko ba a mu, lẹyin naa ki o wa maa fi kádàrá ṣe awijare lori yiyi kúrò rẹ, ki ni o wa fa a ti o ba ti wa yi kúrò nibi nǹkan ti o maa ṣe e ni àǹfààní nibi ẹsin rẹ lọ sibi nǹkan ti o maa ni i lara ti o tun maa wa fi kádàrá ṣe àwíjàre? Ṣé alamọri mejeeji kii ṣe ọkan náà ni?!
Gba àpèjúwe kan ti yoo ṣàlàyé rẹ fun ẹ:
Ti oju ọna meji kan ba n bẹ niwaju ọmọniyan: Ọkan ninu mejeeji: Yoo mu u de ilu kan ti gbogbo rẹ jẹ idarudapọ: Pipa, ole, fífa ọmọlúwàbí ya, ati ipaya, ati ebi. Ikeji: Yoo mu u de ilu kan ti gbogbo rẹ jẹ eto, ati ifọkanbalẹ ti o duro déédéé, ati igbesi aye gbẹdẹmukẹ ati ibọwọ fun ẹmi ati ọmọlúwàbí ati awọn dukia, oju ọna wo ni yoo tọ?
Dajudaju yoo tọ ọna keji ti yoo mu u de ilu ti o ni eto ati ifọkanbalẹ, ko rọrun fun oni laakaye kankan rara lati tọ oju-ọna ilu idarudapọ, ati ipaya, ti yoo wa maa fi kadara ṣe awijare Ki ni ìdí tí yoo fi maa tọ oju ọna ina nibi alamọri ọjọ ikẹyin yatọ si alujanna ti yoo wa maa fi kadara ṣe awijare?
Àpèjúwe mìíràn: A maa n ri alaisan ti wọn pa laṣẹ ki o lo oògùn; yoo si mu ú, ti ẹmi rẹ ko si fẹ́ ẹ, wọn tun maa ni ki o ma jẹun ti o maa ko ìnira ba a; yoo si gbe e ju silẹ, ti ẹmi rẹ si fẹ ẹ, gbogbo ìyẹn lati wa iwosan ati ọlà, ko si rọrun ki ó má lo oògùn tabi ki o jẹ oúnjẹ ti o maa ko ìnira bá a, ki o wa maa fi kádàrá ṣe àwíjàre. Ki ni ìdí ti ọmọniyan fi n gbe nnkan ti Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ pa a láṣẹ ju silẹ tabi o n ṣe nǹkan ti Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ kọ̀, lẹ́yìn náà ki o maa wa fi kádàrá ṣe àwíjàre.
Ikeje: Ẹni ti o n fi kadara ṣe awijare lori nnkan ti o gbe ju silẹ ninu awọn nnkan ti o jẹ dandan, tabi ṣíṣe awọn ẹṣẹ rẹ, ti ẹnikan ba kọja aala le e lori pẹlu gbigba dukia rẹ, tabi fa ọgbà eewọ rẹ ya, ki o wa fi kádàrá ṣe àwíjàre, ki o wa sọ pe: Ẹ ma bu mi, ìkọjá aala mi waye pẹlu kadara Ọlọhun-, ko nii gba awijare rẹ, Bawo ni ko ṣe nii gba àwíjàre ìkọjá ààlà ẹlòmíràn le e lori pẹlu kadara, ti o maa wa fi kadara ṣe àwíjàre fun ara rẹ lori ìkọjá ààlà rẹ lori iwọ̀ Ọlọhun?!
Wọ́n maa n sọ pe alaṣẹ awọn olugbagbọ Umar ọmọ Khatob- ki Ọlọhun yọnu si i- wọn gbe ọ̀rọ̀ ole kan lọ si ọdọ rẹ ti o lẹ́tọ̀ọ́ si gige ọwọ rẹ; ni o ba pàṣẹ gige ọwọ rẹ, ni o ba sọ pe: Ṣe mi jẹ́jẹ́ irẹ alaṣẹ awọn olugbagbọ, dajudaju mo jale pẹlu kadara Ọlọhun; ni Umar ba sọ pe: Dajudaju awa náà maa ge ọwọ rẹ pẹlu kadara Ọlọhun
Awọn eso ti o pọ ni o n bẹ fun nini igbagbọ ninu kadara, ninu rẹ:
Akọkọ: Gbigbe ara le Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ṣíṣe awọn okunfa, ni ọna ti ko fi nii gbe ara le okunfa gangan fun ara rẹ; nitori pe gbogbo nnkan n bẹ pẹlu kadara Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-
Ikeji: Ki ọmọniyan ma jọ ara rẹ loju nigba ọwọ rẹ ba tẹ erongba rẹ, nitori pe dajudaju bi ọwọ rẹ ṣe tẹ ẹ jẹ idẹra kan lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu nnkan ti O kadara rẹ ninu awọn okunfa daadaa ati iyege, ati pe jijọ ara rẹ loju yoo gba a lagbe idupẹ idẹra yii
Ikẹta: Ifayabalẹ, ati isinmi ti ẹmi pẹlu nnkan ti o n ṣẹlẹ si i ninu kádàrá Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii kayasoke ti ohun ti o n fẹ́ bá bọ́ tabi ti ohun ti ko fẹ ba ṣẹlẹ; nitori pe iyẹn waye pẹlu kadara Ọlọhun ti ikapa awọn sanmọ ati ilẹ n bẹ fun Un, o maa ṣẹlẹ ti ko si ibuyẹ fun un, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مِّن قَبۡلِ أَن نَّبۡرَأَهَآۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 22 لِّكَيۡلَا تَأۡسَوۡاْ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمۡ وَلَا تَفۡرَحُواْ بِمَآ ءَاتَىٰكُمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخۡتَالٖ فَخُورٍ 23﴾
{Àdánwò kan kò níí ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ tàbí (kí ó ṣẹlẹ̀) sí ẹ̀yin àyàfi kí ó ti wà nínú Tírà ṣíwájú kí A t’ó dá ẹ̀dá. Dájúdájú ìyẹn rọ̀rùn fún Allāhu*(Ìṣẹ̀lẹ̀ ń tọ kádàrá lẹ́yìn) nítorí kí ẹ má ṣe banújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ fun yín àti nítorí kí ẹ má ṣe yọ àyọ̀jù lórí ohun tí Ó bá fun yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo onígbèéraga, onífáàrí}. [Surah Al-Hadîd: 22-23]
«عَجَبًا لِأَمْرِ الْمُؤْمِنِ إِنَّ أَمْرَهُ كُلَّهُ خَيْرٌ، وَلَيْسَ ذَاكَ لِأَحَدٍ إِلَّا لِلْمُؤْمِنِ، إِنْ أَصَابَتْهُ سَرَّاءُ شَكَرَ فَكَانَ خَيْرًا لَهُ، وَإِنْ أَصَابَتْهُ ضَرَّاءُ صَبَرَ فَكَانَ خَيْرًا لَهُ».
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Eemọ ni fun alamọri olugbagbọ ododo, dajudaju gbogbo alamọri rẹ pátá ni oore, ìyẹn ko si fun ẹni kankan afi fun olugbagbọ ododo, ti nnkan idunnu ba ṣẹlẹ si i yoo dupẹ, ìyẹn jẹ oore fun un, ti inira ba ṣẹlẹ si i yoo ṣe suuru, ìyẹn náà jẹ oore fun un”.
Dajudaju awọn ijọ meji kan ti sọnu nibi kadara:
Ọkan ninu wọn ni: Al-Jabriyyah ti wọn sọ pe: Dajudaju ẹru jẹ ẹni ti a jẹnipa lori iṣẹ rẹ, ti ko si fífẹ́ tabi ikapa fun un nibẹ
Ikeji: Al- Qodariyyah ti wọn sọ pe: Dajudaju ẹru dá duro pẹlu iṣẹ rẹ nibi fifẹ ati ikapa, ko si oripa kankan fun fifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati ikapa Rẹ
Esi ọrọ fun awọn ijọ akọkọ (Al-Jabriyyah) pẹlu sharia ati nnkan ti o n ṣẹlẹ lododo ni:
Nipa ti sharia: Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi rinlẹ fun ẹru ero ati fifẹ, O si fi iṣẹ ti si ọdọ rẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...مِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلدُّنۡيَا وَمِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَ...﴾
{…Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run…} [Surah Âl-`Imrân: 152]
O tun sọ pe:
﴿وَقُلِ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَن شَآءَ فَلۡيُؤۡمِن وَمَن شَآءَ فَلۡيَكۡفُرۡۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمۡ سُرَادِقُهَا...﴾
{Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po}. [Surah Al-Kahf: 29]
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pe:
﴿مَّنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ 46﴾
{Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn}.
[Surah Fussilat: 46]
Ṣugbọn nnkan ti o n ṣẹlẹ lododo: Dajudaju gbogbo ọmọniyan mọ iyatọ laaarin awọn iṣẹ rẹ ti ṣẹsa fun ara rẹ ti o n ṣe wọn pẹlu fifẹ rẹ: Gẹgẹ bii jijẹ, ati mimu, ati títà, ati rírà, ati laaarin nnkan ti o n ṣẹlẹ si i laisi fifẹ rẹ nibẹ: Gẹgẹ bii gbigbọn latara iba, ati iṣubu lati oke, oun ni o n ṣe nǹkan yẹn nibi akọkọ, oun ni o si ṣẹsa rẹ pẹlu erongba rẹ láìsí ijẹnipa nibẹ, ṣùgbọ́n nibi ikeji, o jẹ ẹni ti ko ṣẹsa, tabi fẹ nnkan ti o ṣẹlẹ si i
Esi ọrọ fun ìjọ keji (Al-Qodariyyah) pẹlu sharia ati laakaye:
Ni ti sharia: Dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni Aṣẹ̀dá gbogbo nnkan, ati pe gbogbo nnkan n bẹ pẹlu fifẹ Rẹ, dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ṣàlàyé ninu iwe Rẹ pe gbogbo iṣẹ awọn ẹru n ṣẹlẹ pẹlu fifẹ Rẹ, Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلَ ٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ وَلَٰكِنِ ٱخۡتَلَفُواْ فَمِنۡهُم مَّنۡ ءَامَنَ وَمِنۡهُم مَّن كَفَرَۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلُواْ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ﴾
{Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa ẹnu (si ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasara). Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́}. [Surah Al-Baqarah: 253]
Ọba ti ọla Rẹ ga tun sọ pe:
﴿وَلَوۡ شِئۡنَا لَأٓتَيۡنَا كُلَّ نَفۡسٍ هُدَىٰهَا وَلَٰكِنۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ مِنِّي لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ 13﴾
{Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ}.
[Surah As-Sajdah: 13]
Ni ti laakaye: Dajudaju gbogbo aye n jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ọmọniyan ninu aye yii naa jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ko rọrùn fun nnkan ti a ni lati ṣe bi o ṣe wu u nibi ohun ẹni ti O ni nnkan afi pẹlu iyọnda Rẹ ati fifẹ Rẹ
Awọn erongba adisọkan ti Isilaamu
Erongba ni ede: Wọn maa n lo o fun awọn itumọ kan, ninu wọn: (Erongba ti a gbe kalẹ lati ju nnkan mọ, ati gbogbo nnkan ti a ba ti gbero rẹ).
Awọn erongba adisọkan ti Isilaamu ni: Awọn erongba rẹ, ati awọn àfojúsùn abiyi rẹ, ti o maa jẹ yọ latara idirọmọ ọn, wọn pọ, oríṣiríṣi si ni wọn, nínú wọn ni:
Akọkọ: Imọ aniyan ati ijọsin kanga fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nikan ṣoṣo; nitori pe dajudaju Oun ni Aṣẹ̀dá ti ko si orogun fun Un, o si jẹ dandan ki erongba ati ijọsin jẹ tiRẹ nikan ṣoṣo
Ikeji: Titu laakaye ati irori silẹ kúrò nínú idarudapọ ti ko ni eto ti o n jẹ jade latara pipa sofo ọkan kuro nibi adisọkan yii; nitori pe ẹni ti ọkan rẹ ba pa sofo ninu rẹ, ninu ki o jẹ pe gbogbo adisọkan pátá ni ko si ninu ọkan naa, tabi ki o jẹ olùjọsìn fun ohun elo ti imọlara lásán, tabi ki o jẹ ẹni ti n yíràá ninu anu adisọkan ati ìgbàgbọ́ asan
Ikẹta: Isinmi ti ẹmi, ati ti irori, ko nii si ifoya nibi ẹmi tabi idarudapọ nibi irori; nitori pe adisọkan yii maa so olugbagbọ pọ̀ mọ́ Aṣẹ̀dá rẹ, ti yoo yọnu si I ni Oluwa, Oludari ati Adajọ Aṣofin; ọkàn rẹ yoo wa balẹ pẹ̀lú kádàrá Rẹ, inu rẹ yoo si dun si Isilaamu, ko si nii wa ijirọ fun un.
Ikẹrin: Lila erongba ati iṣẹ ninu iyẹgẹrẹ nibi ijọsin Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, tabi nibi ibaṣepọ pẹ̀lú awọn ẹda; nitori pe ninu ìpìlẹ̀ rẹ ni igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ ti o ko itẹle oju-ọna wọn ti o la nibi erongba ati iṣẹ sínú.
Ikarun-un: Ipinnu ati imu nnkan ni ọkunkundun nibi awọn alamọri, ni ọ̀nà ti o ṣe pe anfaani iṣẹ rere kan ko nii bọ afi ki o lo o; lati fi retí ẹsan, ti ko nii ri aaye ẹṣẹ afi ki o jinna si i; ni ti ipaya kuro nibi iya; nitori pe ninu ìpìlẹ̀ rẹ ni nini igbagbọ ninu igbedide, ati ẹsan lori awọn iṣẹ
Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَلِكُلّٖ دَرَجَٰتٞ مِّمَّا عَمِلُواْۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعۡمَلُونَ 132﴾
{Àwọn ipò (ìkẹ́ àti ipò ìyà) ń bẹ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ohun tí wọ́n bá ṣe níṣẹ́. Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́}.
[Surah Al-An`âm: 132]
«الْمُؤْمِنُ الْقَوِيُّ خَيْرٌ وَأَحَبُّ إِلَى اللَّهِ مِنَ الْمُؤْمِنِ الضَّعِيفِ، وَفِي كُلٍّ خَيْرٌ، احْرِصْ عَلَى مَا يَنْفَعُكَ، وَاسْتَعِنْ بِاللَّهِ، وَلَا تَعْجِزْ، وَإِنْ أَصَابَكَ شَيْءٌ فَلَا تَقُلْ: لَوْ أَنِّي فَعَلْتُ كَذَا كَانَ كَذَا وَكَذَا، وَلَكِنْ قُلْ: قَدَّرَ اللَّهُ وَمَا شَاءَ فَعَلَ؛ فَإِنَّ (لَوْ) تَفْتَحُ عَمَلَ الشَّيْطَانِ».
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ṣe wa lojukokoro lori afojusun yii nibi ọrọ rẹ pe: “Olugbagbọ alagbara daa julọ, Ọlọhun si nífẹ̀ẹ́ rẹ ju olugbagbọ ọ̀lẹ lọ, ati pe daadaa n bẹ lara olúkúlùkù, ṣe ojúkòkòrò nnkan ti yoo ṣe ẹ ni anfaani, ki o si wa iranlọwọ Ọlọhun, ma ko agara, ti nnkankan ba ṣẹlẹ si ẹ, ma ṣe sọ pe: Ti mo ba ṣe bayii ni ko ba ri bayii, ṣugbọn sọ pe: Ọlọhun kadara, nnkan ti O ba si fẹ ni yoo ṣe; nitori pe dajudaju (tí) maa n ṣi iṣẹ eṣu ni”. Muslim ni o gba a wa.
Ikẹfa: Kiko ìjọ kan ti o ni agbara jọ ti o maa na gbogbo nnkan ti o wọn ati eyi ti kò wọn sibi fifi rinlẹ ẹsin rẹ, ati ifi idi awọn òpó rẹ múlẹ̀, lai bìkítà nípa nnkan ti yoo ṣẹlẹ si i ni oju ọna ìyẹn, nibi eyi ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti n sọ pe:
﴿إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ لَمۡ يَرۡتَابُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّٰدِقُونَ 15﴾
{Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olódodo}.
[Surah Al-Hujurât: 15]
Ikeje: Dide ibi oriire aye ati ọrun pẹlu atunṣe ẹni kọọkan ati awọn ijọ, ati ki ọwọ tẹ ẹsan ati awọn oore, nibi ìyẹn ni Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ń sọ pe:
﴿مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 97﴾
{Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn}.
[Surah An-Nahl: 97]
Awọn eyi ni apakan ninu awọn erongba adisọkan ti Isilaamu, a n wa lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati mu wọn ṣẹ fun wa, ati fun gbogbo awọn Musulumi; dajudaju Oun ni Ọlọrẹ Alapọn-ọnle, gbogbo ọpẹ ki o maa bẹ fun Ọlọhun Oluwa gbogbo ẹ̀dá
Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba Anabi wa Muhammad ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ
O pari lati ọwọ ẹni ti o ṣe e
Muhammad Solih Al-Uthaymīn
***
Index
Ọrọ iṣaaju 2
Ẹsin Isilaamu 3
Awọn origun Isilaamu 9
Àwọn ipilẹ adisọkan ti Isilaamu 12
Nini igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- 14
Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika 32
Nini igbagbọ pẹlu awọn tira 38
Nini igbagbọ ninu awọn Ojiṣẹ 40
Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin 48
Nini igbagbọ ninu kadara 68
Awọn erongba adisọkan ti Isilaamu 80
***
yo71v1.0 - 07/07/2026