PHPWord

 

 

رِسَالَةٌ فِي الدِّمَاءِ الطَّبِيعِيَّةِ لِلنِّسَاءِ

 

Tira kékeré kan nipa awọn ẹjẹ adamọ fun awọn obinrin"

 

 

 

بِقَلَمِ فَضِيلَةِ الشَّيْخِ العَلَّامَةِ

مُحَمَّدِ بْنِ صَالِحٍ العُثَيْمِينِ

غَفَرَ اللَّهُ لَهُ وَلِوَالِدَيْهِ وَلِلمُسْلِمِينَ

 

Lati ọwọ Ọlọlajulọ Ash-shaykh Ọlọpọlọpọ mimọ "

Muhammad Bn Sālihu Al-U'thaimeen "

Ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un ati fun awọn obi rẹ mejeeji ati fun awọn musulumi "

 

 


بِسْمِ اللهِ الرَّحمَنِ الرَّحِيمِ

Tira kékeré kan nipa awọn ẹjẹ adamọ fun awọn obinrin"

 

Pẹlu orukọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọrun.

Gbogbo ẹyin jẹ ti Ọlọhun, a n yin In a si n wa iranlọwọ lọ si ọdọ Rẹ, a si tun n wa aforijin lọ si ọdọ Rẹ, a si n tuuba lọ si ọdọ Rẹ," A si n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn aburu ẹmi wa, ati kuro nibi awọn aburú isẹ wa." Ẹniti Ọlọhun ba ti fi mọ ọna ko si ẹniti o le si i lọna, ẹniti Ọlọhun ba si sọnu ko si ẹniti o le fi i mọna "Mo si tun n jẹrii pe ko si ọlọhun kan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun Allah nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, " "Mo si tun n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹrusin Rẹ ni Ojisẹ Rẹ si tun ni , " "Ki Ọlọhun ṣe ikẹ fun un ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ ati awọn ti wọn tẹle wọn pẹlu daada titi di ọjọ ẹsan, ki O si tun ṣe ọla fun un. "

Lẹyin naa: Dajudaju awọn ẹjẹ ti o ṣe pe o maa n da lara obìnrin ni ẹjẹ nnkan oṣu ati ẹjẹ awaada ati ẹjẹ ìbímọ, wọn wa ninu awọn alamọri ti o ṣe koko ti o ṣe pe a n bukaata si ṣiṣe alaye wọn ati mimọ awọn idajọ wọn, ati ṣiṣe iyatọ aṣiṣe kuro ninu eyi to tọ ninu awọn ọrọ awọn onimimọ nipa ẹ, " Ati pe ki igbarale nibi nkan ti wọn ni o tẹsunwọn ju tabi eyi ti wọn sọ wipe o lẹ jẹ ibamu si Iwe Ọlọhun ati ilana Ojisẹ Rẹ. "

Nitori pe dajudaju mejeeji jẹ ibuṣẹrisi ti o jẹ ìpìlẹ̀ ti o ṣe pe wọn mọ le wọn lori awọn idajọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, eyi ti o fi ni ki awọn ẹrusin Rẹ fi maa ṣe ijọsin ti O si la a bọ wọn lọrun."

Ati nitori pe o n bẹ nibi igbarale Iwe Ọlọhun ati oju ọna Ojisẹ Rẹ, ifọkanbalẹ, ati ìdùnnú, ati mimọ ẹmi, ati bibọ ara kuro nibi ojuṣe"

3-Ati nitori pe nkan ti o ba ti yatọ si mejeeji, wọn maa wa ẹri fun un ni wọn ko nii fi ṣe ẹri."

Nigba to ṣe pe ko si ẹri kankan afi ninu ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati ninu ọrọ Ojisẹ Rẹ, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ náà ni ọrọ awọn onimimọ ninu awọn saabe lori ọrọ ti o tẹsunwọn ju, pẹlu majẹmu pe ki nkan ti o tako o ma si ninu Iwe Ọlọhun ati oju ọna Ojisẹ Rẹ, " "Ki ọrọ saabe miiran si ma tako o, ti o ba ṣe pe nkan ti o tako o wa ninu Iwe Ọlọhun ati sunna Ojisẹ Rẹ, gbigba nkan ti o wa ninu Iwe Ọlọhun ati sunna Ojisẹ Rẹ mu maa jẹ dandan," Ti ọrọ saabe miiran ba si tako o, wọn yio wa èyí tí o tẹsunwọn ju laarin ọrọ mejeeji, wọn o si mu eyi ti o tẹsunwọn julọ ninu rẹ;"

﴿...فَإِن تَنَٰزَعۡتُمۡ فِي شَيۡءٖ فَرُدُّوهُ إِلَى ٱللَّهِ وَٱلرَّسُولِ إِن كُنتُمۡ تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلًا﴾

Tori ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe: {tí ẹ bá yapa ẹnu sí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀.}[An-Nisâ': 59]. "

"Eleyii ni tira kékeré kan ti o jẹ ṣoki nibi nkan ti a n bukaata si ninu alaye awọn ẹjẹ yii ati awọn idajọ wọn, ti o si ko awọn ipin ti n bọ yii sinu: "

Abala Àkọ́kọ́: Nípa itumọ nnkan oṣu ati ọgbọn ti n bẹ nibẹ. "

Abala Ẹlẹẹkeji: Nípa akoko nǹkan oṣu ati gbedeke rẹ. "

Abala Ẹlẹẹkẹta: Nípa awọn nkan pajawiri lori nǹkan oṣu. "

Ipin kẹrin: Nibi awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù.

Ipin karùn-ún: Nibi ẹjẹ awaada ati awọn idajọ rẹ.

Ipin kẹfa: Nibi ẹjẹ ibimọ ati awọn idajọ rẹ.

Ipin keje: Nibi lilo nkan ti yio kọdi riri ẹjẹ nkan oṣù tabi nkan ti yio fa a wa, ati lilo nkan ti yio kọdi oyun nini tabi nkan ti yio mu un walẹ.

Ipin àkọ́kọ́: Nibi itumọ Al-Haydu (ẹjẹ nkan oṣù) ati ọgbọn ti n bẹ nibẹ.

Al-Haydu ni ede: sisan nkan.

Ninu agbọye ofin ẹsin: Ẹjẹ kan ti maa n ṣẹlẹ si obinrin ni ibamu si adamọ laisi idi kankan ni awọn asiko kan ti a ti mọ. Oun naa ni ẹjẹ adamọ kan ti ko ni aisan ninu tabi ogbẹ tabi iwalẹ oyun tabi ibimọ. Pẹlu wipe o jẹ ẹjẹ adamọ; nitori naa o maa n yatọ ni ibamu si iṣesi obinrin ati agbegbe rẹ; fun ìdí yẹn, awọn obinrin maa n yatọ si ara wọn nibẹ ni iyatọ ti o jina si ara wọn ti o si tun fi oju han.

Ọgbọ́n ti n bẹ níbẹ̀ ni pe: Nígbà tí o jẹ wipe ọlẹ̀ (ọmọ) wa ninu ikun iya rẹ, ko rọrun ki o maa jẹ nkan ti ẹniti o wa ni ita ikun n jẹ, ko si rọrun fun ẹda ti o ba laanu rẹ julọ lati mu oúnjẹ kankan de ọdọ rẹ, nigba naa Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ṣe si ara obinrin awọn ìtújáde kan ti o jẹ ẹjẹ ti ọlẹ maa n jẹ ninu ikun iya rẹ lai bukaata si jíjẹ abi dídà, ti yio si maa de ara rẹ lati ibi idodo ni èyí tí o ṣe wipe ẹjẹ a maa ropọ mọ awọn iṣan rẹ ti yio si maa fi ṣe ounjẹ; nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá.

Eleyii ni ọgbọn ti n bẹ nibi ẹjẹ nkan oṣù yii; fun idi iyẹn, ti obinrin ba ti loyun ẹjẹ nkan oṣù rẹ maa dawọ duro, ko si nii maa ri ẹjẹ nkan oṣù mọ, ayaafi ki o ṣọwọn, bákannáà ni awọn ti n fun ọmọ lọyan, o kere ninu ẹniti maa n ri ẹjẹ nkan oṣù ninu wọn, agaga julọ ni ibẹrẹ igba ifun-ọmọ-lọyan.

Ipin keji: Nibi igba riri ẹjẹ nkan oṣù ati asiko rẹ.

Ọrọ lori ìpín yii ipele meji ni:

Ipele àkọ́kọ́: Níbi ọdun ti ẹjẹ nkan oṣù maa n wa.

Ipele ẹlẹẹkeji: Níbi asiko (igba) riri ẹjẹ nkan oṣù.

Ṣe ẹ wa ri ipele àkọ́kọ́: Ọjọ ori eleyi ti ẹjẹ nkan oṣù saaba maa wa nibẹ, oun ni laarin ọdun mejila si aadọta ọdun , ati pr o ṣeeṣe ki obinrin o ri ẹjẹ nkan oṣù ṣaaju iyẹn (ọdun mejila) tabi lẹyin rẹ (aadọrun ọdun) ni ibamu si ìṣesí rẹ ati agbegbe rẹ.

Ati pe awọn olumọ - ki Ọlọhun kẹ wọn- ti yapa pe: Ǹjẹ́ aala kan pato n bẹ fun ọjọ ori ti o rọrun ki ẹjẹ nkan oṣù maa wa nibẹ, ni èyí ti o ṣe wipe obinrin o le ri ẹjẹ nkan oṣù ṣíwájú rẹ ati lẹ́yìn rẹ, ti nkan ti o ba ri ṣaaju rẹ ati lẹyìn rẹ maa jẹ ẹjẹ burúkú?

Awọn olumọ yapa nibi iyẹn; Ad-Dārimiy sọ - lẹyin ti o sọ gbogbo iyapa ẹnu- pe: Gbogbo eléyìí lọdọ temi asisọ ni! torí pé dajudaju ibuṣẹrisi nibi gbogbo iyẹn ni bíbẹ; nitori naa eyikeyi odiwọn ti wọn ba ri ni eyikeyi ìṣesí ati ọjọ ori, dandan ni ki wọn ka a si ẹjẹ nkan oṣù. Ọlọhun ni o ni imọ julọ.

Nǹkan ti Ad-Dārimiy sọ yii ni ohun ti o bọ si oju ẹ, oun si ni ohun ti Shaykhul Islām Ibnu Taymiyah ṣẹsa; nitori naa, ìgbà tí obinrin ba ri ẹjẹ nkan oṣù, o ti di ẹniti n ṣe nkan oṣù, koda ki o mai tii to ọmọ ọdun mẹsan-an tabi ko ju aadọta ọdun lọ. Iyẹn ni nítorí pé Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ so awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù mọ riri i, Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ o si fi gbedeke ọjọ ori kan pato si i, nitori naa o jẹ dandan lati ṣẹri pada nibẹ lọ sí bíbẹ ti wọn so àwọn idajọ rẹ mọ, àti pé fifi gbedeke ọjọ ori kan pato si i bukaata si ẹri nínú Tira Ọlọhun ati Sunnah Anabi ti ko si si ẹri kankan fun iyẹn.

Àmọ́ ipele ẹlẹẹkeji ni asiko riri nkan oṣù, ìyẹn ni: Odiwọn igba rẹ.

Awọn olumọ yapa to pọ si bi ọna mẹfa tabi méje. Ibnul Mundhir - ki Ọlọhun kẹ ẹ - sọ pe: Àwọn ikọ kan sọ pe: Ko si gbedeke ọjọ kankan fun ọjọ riri nkan oṣù ti o kere ju ati eyi ti o pọ ju.

Mo sọ pe: Ọrọ yii da gẹ́gẹ́ bí ọrọ Ad-Dārimiy ti o ṣíwájú, oun naa si ni nǹkan ti Shaykhul Islām Ibnu Taymiyyah ṣẹsa, oun naa ni o si bọ si oju ẹ; torí pé tira Ọlọhun ati Sunnah Anabi pẹlu iwoye n tọka si i.

Ẹri àkọ́kọ́ ni:

﴿وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡمَحِيضِۖ قُلۡ هُوَ أَذٗى فَٱعۡتَزِلُواْ ٱلنِّسَآءَ فِي ٱلۡمَحِيضِ وَلَا تَقۡرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطۡهُرۡنَۖ...﴾

Gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe:

{Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra} [Al-Baqorah: 222]. Ọlọhun ṣe opin kikọ pe oun ni asiko mimọra, ko si se opin ni rirekọja ọjọ kan ati alẹ kan, tabi ọjọ mẹta tabi ọjọ mẹẹdogun, eyi da lori pe idi idajo ni ẹjẹ nǹkan oṣu ni ti bibẹ ati ni ti aisi, " "Nitori naa ìgbà ti wọn ba ti ri ẹjẹ nǹkan oṣu, idajọ naa ti fi ẹsẹ rinlẹ, ati pe igba ti o ba ti mọra kuro nibẹ awọn idajọ rẹ ti yẹ kuro nìyẹn."

"Ẹri ẹlẹẹkeji: "

مَا ثَبَتَ فِي صَحِيحِ مُسْلِمٍ أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ لِعَائِشَةَ وَقَدْ حَاضَتْ وَهِيَ مُحْرِمَةٌ بِالْعُمْرَةِ: «افْعَلِي مَا يَفْعَلُ الْحَاجُّ، غَيْرَ أَنْ لَا تَطُوفِي بِالْبَيْتِ حَتَّى تَطْهُرِي». قَالَتْ: فَلَمَّا كَانَ يَوْمُ النَّحْرِ طَهُرْتُ. الْحَدِيثُ.

Oun naa ni nǹkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu Sohiihu Muslim pe Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun Aa'ishah ti o si ti ṣe nǹkan oṣu ti o si jẹ ẹni tí o ti bẹrẹ isẹ Umra, pé: Ṣe nkan ti ẹni tí n ṣiṣẹ Hajj maa n ṣe yatọ si ki o rọkirika ile Oluwa titi ti waa fi mọra”, o sọ pe: Igba ti o di ọjọ iduran, mo wa mọra. Hadiisi. "

O wa ninu Sohiihu Bukhari ati Muslim pe dajudaju Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe: “Ṣe suuru, ti o ba ti wa mọra, jade lọ si aye kan ti o n jẹ Tan'iim”, Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe mimọra ni opin kikọ, ko ṣe akoko kan pato ni opin, eyi da lori pe dajudaju idajọ naa sopọ mọ ẹjẹ nǹkan oṣu ni ti bibẹ ati ni ti aisi. "

"Ẹri ẹlẹẹkẹta: Ni pe awọn ìfojúdá-nnkan yii, ati awọn alaye ni ifọsiwẹwẹ yii ti awọn alfa oni imọ agboye ẹsin sọ nípa ọrọ ẹṣin yii, ko si ninu iwe Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ko si si ninu ọrọ ojisẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu pe a n bukaata gidi gan si alaye ẹ, " Ti o ba jẹ pe o wa ninu nnkan to jẹ dandan fun awọn ẹrusin lati ni agboye ẹ ati lati ma a fi ṣe ijọsin ni, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa ṣe alaye ẹ ni alaye kan ti o maa han si gbogbo ẹni kọọkan; fun ijẹ pataki awọn idajọ ti o rọ mọ ọn bii irun ati awẹ ati fifẹ iyawo ati kikọ ara ẹni ati jijẹ ogun ati nnkan ti o yatọ si i ninu awọn idajọ, " Gẹgẹ bi Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ se ṣe alaye awọn onka awọn irun ati awọn asiko ẹ ati rukuu rẹ ati iforikanlẹ rẹ, " "Ati zakah naa: Àwọn dukia ti a fi n yọ ọ, ati iye ti o maa to ki zakah too wọ̀ ọ́, ati odiwọn rẹ, ati ibi ti a n yọ ọ si, ati awẹ naa: Gbedeke ẹ ati akoko ẹ, ati hajj ati nkan to yatọ si iyẹn," Titi ti o fi dori awọn ẹkọ jijẹ ati mimu ati sisun ati ibalopọ ati ìjókòó ati wiwọ inu ile ati jijade nibẹ, ati awọn ẹkọ bibiya bukaata, dori awọn onka imọra oni okuta, de ibi awọn nnkan to yatọ si yẹn ninu kekere awọn alamọri ati eyi to tobi nibẹ, ninu nkan ti Ọlọhun pe ẹsin pẹlu ẹ, ti O si fi pe idẹra le awọn onigbagbọ lori, "

"Gẹgẹ bi Ọba -ti ọla Rẹ ga- se sọ pe:

﴿...وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ تِبۡيَٰنٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ...

{A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan}[An-Nahl: 89]

Ọba -ti ọla Rẹ ga- tun sọ pe:

﴿...مَا كَانَ حَدِيثًا يُفْتَرَى وَلَـكِن تَصْدِيقَ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ كُلَّ شَيْءٍ...

{ (Al-Ƙur’ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan} [Yûsuf: 111]

Nigba ti a ko waa ri awọn ifojuda-nnkan ati awọn alaye ni ifọsiwẹwẹ yii ninu iwe Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- tabi ninu ọrọ ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o ti wa fi oju han pe ko si igbarale lori fun un, bi ko se pe a maa gbarale nkan ti n jẹ nǹkan oṣu ti awọn idajọ sharia sorọ mọ ọn ni ti bibẹ ati ni ti aisi, " "Ẹri yii -ohun ti mo gbà lérò ni pe: aidarukọ idajọ naa ninu iwe Ọlọhun ati ninu ọrọ ojiṣẹ jẹ ẹri kan lori aini akakun rẹ- yoo si ṣe ọ ni anfaani nibi ọrọ ẹsin yii ati eyi to yatọ si i ninu awọn ọrọ imọ; nitori pe awọn idajọ sharia o le fi ẹsẹ rinlẹ afi pẹlu ẹri kan ninu ofin ninu iwe Ọlọhun, tabi ọrọ ojisẹ Rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tabi ifi ẹnu ko awọn onimimọ taa mọ, tabi isẹ afiwọn kan to ni alaafia. " Sheikhul Islam Ibn Taimiyah sọ nibi ìlànà kan to jẹ ti ẹ pe: “Ninu ìyẹn ni orúkọ nǹkan oṣu ti Ọlọhun so awọn idajọ kan to pọ mọ ọn ninu iwe Ọlọhun ati ọrọ Anọbi, ti wọn ko si ṣe odiwọn rẹ yala eyi to kere ju ninu ẹ ni tabi eyi to pọ ju ninu ẹ, tabi ṣe odiwon mimọra laarin nǹkan oṣù meji pẹ̀lú pe o kárí ilé o kárí oko, ti gbogbo ijọ si ni bukaata si i, ati pe ede gan o ṣe iyatọ laarin odiwọn kan si odiwọn mii, ẹniti o ba wa fi odiwọn si iyẹn ti yapa iwe Ọlọhun ati sunna Anọbi”. Ọrọ rẹ ti tan. "

Ẹri ẹlẹẹkẹrin: Iwoyesi, ìyẹn ni: Ìṣe afiwọn to ni alaafia ti o kárí, iyẹn ri bẹ́ẹ̀; nitori pe dajudaju Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- fi ìdí si ẹjẹ nnkan oṣu pẹlu pe ẹgbin ni, igba ti a ba ti waa ri nnkan oṣu, ẹgbin naa ti n bẹ nìyẹn, ko si iyatọ laarin ọjọ ẹlẹẹkeji ati ọjọ àkọ́kọ́, ko si si laarin ọjọ ẹlẹẹkẹrin ati ọjọ ẹlẹẹkẹta, " Ko si si iyatọ laarin ọjọ kẹrindinlogun ati ọjọ karundinlogun, ati laarin ọjọ kejìdínlógún ati ọjọ kẹtàdínlógún," Nnkan oṣu naa ni nnkan oṣu, ẹgbin naa ni ẹgbin, idi naa si n bẹ ni ọjọ mejeeji lori odiwọn kan naa, bawo waa ni ṣiṣe iyatọ níbi idajọ laarin ọjọ mejeeji se maa waa ni alaafia pẹlu idọgba awọn mejeeji nibi idi? "Njẹ eyi o wa tako iṣe afiwọn to ni alaafia bi? Ǹjẹ́ iṣẹ afiwọn to ni alaafia kọ ni didọgba ọjọ mejeeji nibi idajọ latari idọgba awọn mejeeji nibi idi?."

Ẹri ẹlẹẹkarun-un: Ìyapa ẹnu awọn ti wọn fi ààlà si i, ati idarudapọ ẹ, dajudaju iyẹn da lori pe ko si ẹri kankan nibi ọrọ ẹsin naa ti o jẹ dandan lati ṣẹri pada si i, bi ko ṣe pe awọn idajọ ti a fi igbiyanju mọ ni ti o ṣeé ṣe ko ni àṣìṣe tabi ko tọna, ti ikan o tọ lati tẹle ju ikeji lọ, ibuṣẹrisi nigba iyapa ẹnu ni iwe Ọlọhun ati sunna Anọbi. "

Nitori naa, ti o ba ti fi oju han pe ko si ààlà fún nǹkan oṣù ti o kéré ju tabi ti o pọ ju, oun si ni o tẹsunwọn, wa lọ mọ pe gbogbo nnkan ti obinrin maa n ri ninu ẹjẹ ti adamọ ti ko ni okunfa kankan bii ọgbẹ ati nnkan ti o jọ ọ, ẹjẹ nnkan oṣu ni

lai ni odiwọn pẹlu akoko tabi ọjọ ori, ayaafi ti ko ba dá rárá, tabi ti o n da fun ìgbà díẹ̀, bii ọjọ́ kan tabi meji nínú oṣù, ẹjẹ awaada ni o maa jẹ lai ni odiwọn pẹlu akoko tabi ọjọ ori, ayaafi ti ko ba dá rárá, tabi ti o n da fun ìgbà díẹ̀, bii ọjọ́ kan tabi meji nínú oṣù, ẹjẹ awaada ni o maa jẹ. " Alaye ẹjẹ awaada ati awọn idajọ ẹ o pada maa wa -ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba fẹ-

Sheikhul Islam Ibn Taimiyah sọ pe: Ìpìlẹ̀ nibi gbogbo nnkan ti o n jade ninu apo ibi ni ki o jẹ ẹjẹ nnkan oṣu titi ti ẹri o fi wa lori pe ẹjẹ awaada ni. " O tun sọ bákannáà pe: Nǹkan ti o ba waye ninu ẹjẹ, ẹjẹ nnkan oṣu ni, ti a ko ba mọ pe ẹjẹ iṣan ni tabi ti ọgbẹ. Ọrọ rẹ parí. Ọ̀rọ̀ yii, pẹlu pe oun naa ni ọrọ to tẹsunwọn ni ibamu si ẹri, bákannáà oun naa ni o sunmọ julọ ni ti agbọye ati imọ, ti o si rọrun julọ lati mu lo ati lati fi ṣiṣe ṣe ju nkan ti awọn ti wọn fi odiwọn si darukọ lọ, àti pé nkan ti o ba ti wa ri bayẹn, oun naa ni o tọ ju lati gba a wọle pẹlu ibamu ẹ pẹlu ẹmi ẹsin Isilaamu ati ipilẹ rẹ, oun naa si ni irọrun ati idẹkun. "

Ọlọhun tí ọla Rẹ ga sọ pe:

﴿...وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖ...

“kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn”

[Hajj: 78].

«إِنَّ الدِّينَ يُسْرٌ وَلَنْ يُشَادَّ الدِّينَ أَحَدٌ إِلَّا غَلَبَهُ فَسَدِّدُوا وَقَارِبُوا وَأَبْشِرُوا».

O tun sọ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe: “Dajudaju ẹsin yii irọrun ni ẹnìkankan o wàá níí mu ẹsin yii ni líle àyàfi ki o (Ẹsin) bori rẹ, nitori naa ẹ ṣe e ni iwọntun-wọnsi, ki ẹ si sunmọ pípé, kí ẹ sì tún máa dunnu”. Bukhari ni o gba a wa.

Ati pe ninu iwa rẹ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni wipe “Dajudaju wọn o nii fún un ni ẹsa láàrin àlámọrí méjì àyàfi ki o sẹsa eyiti ọ ba rọrun ju nínú mejeeji lopin igbati kii ba tii ṣe ẹṣẹ”

Ṣiṣẹ nkan oṣù Oloyun.

Eleyi ti o pọ jù lọ ni wipe dajudaju ti obinrin ba ti ni oyún, ẹjẹ rẹ máa dúró, Imām Ahmad - ki Ọlọhun kẹ ẹ - sọ pe: “Dajudaju awọn obinrin máa n da oyun mọ pẹlu ki ẹjẹ o duro”. Nitori naa ti obinrin ba ri ẹjẹ ti o ba jẹ wipe siwaju ki o to bimo pẹlu igba diẹ ni gẹgẹbi ọjọ meji tabi ọjọ mẹta ti inira ibimọ sí wà pẹlu rẹ, ẹjẹ ibimọ ni ìyẹn”. Amọ ti o ba jẹ siwaju ibimọ pẹlu igba ti o pẹ tabi síwájú ibimọ pẹlu igba diẹ ṣugbọn kò si inira ibimọ pẹlu rẹ ìyẹn kii ṣe ẹjẹ ibimọ, ṣugbọn njẹ o le jẹ ẹjẹ nkan oṣù ti awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù o maa bẹ fún un, tabi ki o jẹ ẹjẹ idọti ti wọn o nii fun un ni àwọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù?

Ìyapa ẹnu n bẹ nibi eleyii l'ọdọ awọn olumọ, eyiti o bọ sí ojú rẹ ni wipe ẹjẹ nkan oṣù ni ti o ba wa ni ojupọna ti o ti ba sáábà nibi ẹjẹ nkan oṣù rẹ; nitoripe dajudaju ìpìlẹ̀ nibi ẹjẹ ti máa n de bá obinrin ni wipe ẹjẹ nkan oṣù ni, ti ko ba ti sí ìdí kankan ti o le kọ fún un lati ma jẹ ẹjẹ nkan oṣù, ko si ninu tira Ọlọhun ati sunnah Anabi nkan ti o kọ ṣiṣe nkan oṣù oloyun.

Ati pe eleyii ni ìròrí Maaliki ati Shāfi‘iy, ti olumọ ẹsin agba ibnu Taymiyah si ṣẹsa rẹ; o sọ ninu tira Al-Ikhtiyārāt (oju ewe 30): Al-Bayhaqiy lo gbe e wa ni ẹgbawa lati ọdọ Ahmad, ati pe o gbe e wa wipe dajudaju, o (Ahmad) ṣẹri pada si i. O ti pari.

Ati pe lori eleyii yíò máa rinlẹ fún ẹjẹ nkan oṣù oloyun nkan ti o ba rinlẹ fún ẹjẹ nkán oṣù ẹnití kii ṣe oloyun àyàfi nibi àlámọrí méjì:

Àlámọrí àkọ́kọ́: Ikọsilẹ, nitori naa o jẹ eewọ kikọ ẹnití ṣiṣe igbele ikọni silẹ ba jẹ dandan fún lásìkò ti n ri ẹjẹ nkan oṣù yatọ sí oloyun, ko jẹ eewọ fún oloyun (lásìkò ti ba n ri ẹjẹ nkan oṣù). Nitoripe ikọni silẹ lasiko ẹjẹ nkan oṣù fún ẹnití kii ṣe oloyun tako ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe:

﴿...فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ...

﴾ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe òǹkà ọjọ́ opó fún ìkọ̀sílẹ̀ wọn.﴿ [At-talāq: 1]. Amọ kikọ oloyun silẹ ni àsìkò ti n ri ẹjẹ nkan oṣù ko ta ko o; nítorí pé ẹnití o ba kọ oloyun silẹ ti kọ ọ silẹ pẹ̀lú ṣíṣe òǹkà ọjọ́ opó fún ìkọ̀sílẹ̀ rẹ, bóyá o jẹ ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù ni tabi ẹnití o wa ni imọra; torí pé odiwọn onka tiẹ pẹlu oyun ni. Fun idi yẹn kii ṣe eewọ fún un lati kọ ọ silẹ lẹyin ibalopọ yatọ sí ẹlòmíràn ti ko da bii rẹ (oloyun).

Àlámọrí ẹlẹẹkeji: Dajudaju riri ẹjẹ nkan oṣù oloyun ko le mu onka iṣe igbele (opo) ìkọ̀sílẹ̀ rẹ wá sí òpin, yatọ sí ẹjẹ nkan oṣù ẹnití o yatọ sí i (oloyun). Nitoripe dajudaju onka igbele (opo) ìkọ̀sílẹ̀ oloyun o le parí àyàfi pẹlu bibi oyun inu rẹ, bóyá o jẹ ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù ni tabi bẹẹ kọ.

Fun ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga to sọ pe:

﴿...وَأُوْلَاتُ الأَحْمَالِ أَجَلُهُنَّ أَن يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ...

{Àwọn olóyún, ìparí òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn ni pé kí wọ́n bí oyún inú wọn.} [At-talāq: 4].

Ìpín kẹta: Nípa awọn nǹkan ti maa n ṣẹlẹ̀ sí ẹjẹ nkan oṣù lójijì.

Awọn nkan ti máa n ṣẹlẹ̀ si ẹjẹ nkan oṣù ni òjijì, oríṣiríṣi ni wọn:

Ìran àkọ́kọ́: Alekun tàbí adinku, gẹ́gẹ́ bíi kí ọ jẹ wipe ìṣesí obinrin ni ọjọ mẹfa, kí ẹjẹ rẹ o wá di ọjọ méje, tabi ki ìṣesí rẹ o jẹ ọjọ méje kí o wa mọra ni ọjọ mẹfa.

Iran Kejì: Sisun siwaju ati sisun sẹyin, gẹ́gẹ́ bíi kí ẹjẹ rẹ o máa wá ní ìparí oṣù ki o wá ri ẹjẹ rẹ ni ibẹrẹ oṣù, tabi ki ẹjẹ rẹ máa wá ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù ki o wa ri i ni ipari oṣù.

Àwọn olumọ yapa nibi idajọ iran mejeeji yii, ati pe eyiti o bọ sí ojú rẹ ni wipe gbogbo igba ti o ba ti ri ẹjẹ o ti di ẹnití n ṣe nkan oṣù, ati pe igba ti o ba ti mọra kuro nibẹ, o ti wa ni ẹnití o mọ, bóyá o lekun sí ìṣesí rẹ ni tabi o dínkù, bóyá o sun si iwájú ni tabi o sun si ẹyin. Ati pe ẹri lori ìyẹn tí sáájú ni ipin ti o saaju rẹ, ni ibi ti aṣòfin ti so awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù mọ bibẹ rẹ.

Ati pe eleyii ni ìròrí ash-Shāfi‘iy, ati nǹkan ti olumọ ẹsin agba ibnu Taymiyah ṣẹsa, ti ẹnití o ni tira Al-Mugniy sí fún un ni agbara ninu rẹ (Al-Mugniy) ti o si tun ki in lẹyin o si sọ pe: Ti o ba jẹ pe wọn woye sí ìṣesí obinrin nibi ẹjẹ nkan oṣù ni ìbámu sí ojupọnna ti wọn sọ ninu irori yii ni, Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o ba ṣe àlàyé rẹ fún ìjọ rẹ, ati pe ààyè o ba ti gba a lati lọ àlàyé rẹ lára. Nigba to ṣe pe lilọ alaye lara tayọ asiko ẹ o lẹ́tọ̀ọ́, ati pe awọn iyawo rẹ ati awọn to yàtọ̀ si wọn ninu awọn obinrin ni bukaata si alaye ìyẹn ni gbogbo igba, nitori naa ko lee gbagbe alaye ẹ, " Didarukọ adamọ ati alaye rẹ ko wa lati ọdọ Rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- afi nipa ẹni tí ń ri ẹjẹ awaada nìkan.

Iran ẹlẹẹkẹta: Awọ pupa rusurusu tabi awọ kurukuru (àdàpọ̀), pẹlu pe yio maa ri ẹjẹ ti yio pupa gẹgẹ bii omi ọgbẹ tabi ki o dapọ laarin awọ pupa rusurusu ati dudu, ti eyi ba jẹ pe ni asiko ẹjẹ nnkan oṣu tabi ti o ba so pọ mọ ọn ṣíwájú mimọra, ẹjẹ nnkan oṣu ni i, a maa fi awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu rinlẹ fun un, sugbọn to ba jẹ pe ẹyin mimọra ni, ko kìí ṣe ẹjẹ nnkan oṣu; "

لِقَوْلِ أُمِّ عَطِيَّةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا: «كُنَّا لَا نَعُدُّ الصُّفْرَةَ وَالْكُدْرَةَ بَعْدَ الطُّهْرِ شَيْئًا». رَوَاهُ أَبُو دَاوُدَ بِسَنَدٍ صَحِيحٍ.

Fun ọrọ Ummu A'tiyyah -ki Ọlọhun yọnu si i-: “ A o kìí n ka awọ pupa rusurusu ati awọ kurukuru (adapọ) lẹyin mimọra si nkankan”. Abu Daud ni o gba a wa pẹlu ẹgbawa to ni alaafia, " "Bukhari naa gba a wa bakannaa laisi gbolohun rẹ: (Lẹ́yìn mimọra) nibẹ, sugbọn o mu akori wa fun un pẹlu ọrọ rẹ wipe: Abala ẹjẹ pupa rusurusu ati ẹjẹ kurukuru (adapọ) ni awọn ọjọ ti o yatọ si awọn ọjọ nnkan oṣu." O sọ ninu tira alaye rẹ to n jẹ Fathul-baari pe: “O n tọka pẹlu iyẹn lọ sibi idapọ laarin Hadiisi Aa'ishah ti o ṣaaju nibi ọrọ rẹ pe: Titi ti yoo fi ri omi funfun. " Ati laarin hadiisi Ummu Atiyyah ti a mu wa ni orí yii, iyẹn ni pe-: Hadiisi Aa'ishah- a maa gbe itumọ ẹ le ori igba ti o ba ri awọ pupa rusurusu ati awọ kurukuru (adapọ) ni awọn ọjọ ẹjẹ nnkan oṣu, sugbọn nibi eyi to yatọ si i, a maa gbe itumọ rẹ lori nnkan ti Ummu Atiyyah sọ”.. Ọrọ rẹ parí. Hadiisi Aa'ishah ti o tọka si i ni èyí tí Bukhari o so ẹgbawa rẹ papọ (o pa ẹnikan rẹ ninu awọn ti o gba hadīth naa wa) l'ẹniti o ni amọdaju pẹlu rẹ ṣíwájú orí yii, dajudaju awọn obinrin maa n fi nkan ti a n pe ni Ad-Durjah ranṣẹ si i (nkankan ni ti obinrin maa n wọ lati mọ boya nnkankan ṣẹku ninu oripa ẹjẹ nnkan oṣu) ti òwú ti pupa rusurusu wa nibẹ n bẹ nibẹ, yio waa sọ pe: “Ẹ ma se kanju titi ti ẹ maa fi ri omi funfun”. " Al-Qassotul Baydō’u jẹ omi kan to funfun ti apo ibi maa n da jade nigba ti ẹjẹ nnkan oṣu ba ti da. "

Iran ẹlẹẹkẹrin: Ṣíṣe segesege nibi ẹjẹ nnkan oṣu, l'eyiti o ṣe wipe yio ri ẹjẹ lọjọ kan, yio si ri mimọ lọjọ kan ati nnkan to jọ iyẹn, mejeeji yii ni iṣesi meji: "

Isesi àkọ́kọ́: ki eyi wa pẹlu obinrin ni gbogbo igba, eleyii ni ẹjẹ awaada, idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada yio maa fi ẹsẹ rinlẹ fun ẹniti o ba n ri i.

Isesi ẹlẹẹkeji: ko ma jẹ pe o n lọ lai dawọ dúró pẹlu obinrin, bi ko ṣe wipe yio maa de si i ni awọn asiko kan, ti asiko imọra to ni alaafia o si tun maa wa fun un. Awọn onimimọ -ki Ọlọhun kẹ wọn- ti yapa ẹnu nipa mimọ yii, ǹjẹ́ mimọra kuro nibi ẹjẹ ni tabi awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu o si maa bẹ fun un? "

Irori Shafii' nibi èyí tí o ni alaafia julọ ninu ọrọ rẹ mejeeji ni pe awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu ni yio maa bẹ fun un; nitori naa yio jẹ ẹjẹ nnkan oṣu, oun si ni Sheikhul Islam Ibn Taimiyah ati ẹniti o ni tira Al-faahiq ṣẹsa, o si tun je ìròrí Abu haneefah, " Iyẹn ri bẹẹ; nítorí pé wọn o ri omi funfun nibẹ; ati nítorí pé ti a ba ṣe e ni imọra ni, nkan ti o ṣíwájú rẹ o ba jẹ ẹjẹ nnkan oṣu, ti nkan ti o wa lẹyin rẹ naa o si tun jẹ ẹjẹ nnkan oṣu, ti ko si si ẹni ti o sọ bẹ́ẹ̀, ti ko ba ri bẹ́ẹ̀ ni, ṣíṣe onka ọjọ nnkan oṣu o ba pari pẹlu ṣiṣe nnkan oṣu fun ọjọ marun-un; " Ati nítorí pé ti wọn ba ṣe e ni imọra, wahala ati inira o ba sẹlẹ pẹlu rẹ pẹlu wiwẹ ati nkan to yatọ si i ni gbogbo ọjọ meji meji, inira si jẹ nkan ti a ko fẹ ninu sharia (ofin) yii, Ọlọhun ni gbogbo ẹyin n bẹ fun. "

Eyi to gbajugbaja ninu ìròrí awọn Anbali ni pe dajudaju ẹjẹ nnkan oṣu ni, ati pe mimọ naa imọra nibi nkan oṣù ni, ayaafi ti gbogbo ẹ lapapọ ba pọ ju ọjọ riri nnkan oṣu ti o pọju lọ; nítorí naa ẹjẹ ti o tayọ aala o maa jẹ ẹjẹ awaada. "

O sọ ninu tira Al-mugnii pe: “Eyi ti yio bọ soju rẹ ni pe dajudaju dida ẹjẹ, igba kí ìgbà ti o ba ti din si ọjọ kan, ko kii n ṣe imọra, ni ìbámu si ẹgbawa ti a gba wa nipa ẹjẹ ibimọ wipe ko nii kọbi ara si nkan ti o ba ti din si ọjọ kan, oun si ni ọrọ to ni alaafia -ti Ọlọhun ba fẹ- nítorí pé ẹjẹ máa n san nigba mii ti yoo si da nigba mii, àti pé o ń bẹ nibi ṣiṣe iwẹ ni dandan lori ẹni tí o ba mọra ni wakati kan si wakati mii, inira ti a ko fẹ́.

Fun ọrọ Ọba- ti ọla Rẹ ga- to sọ pe:

﴿...وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖ...

{kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn}

[Al-Hajj: 78] O sọ pe: Lórí eyi, dida ẹjẹ fun nkan to kere si ọjọ kan o le jẹ imọra ayaafi ki o ri nkan to maa tọka si i, gẹ́gẹ́ bíi ki dida rẹ wa ni ipari adamọ rẹ tabi ki o ri omi funfun”. Ọ̀rọ̀ rẹ pari.

Nitori naa ọrọ ẹniti o ni tira Al-mugnii yii maa jẹ ọrọ to ṣe deede laarin ọrọ mejeeji, Ọlọhun ni O ni imọ julọ nípa èyí tí ó bọ sójú ẹ.

Iran ẹlẹẹkarun-un: Gbígbẹ furufuru nibi ẹjẹ pẹlu pe ki obinrin maa ri titutu lasan, ti èyí ba wa ni asiko nnkan oṣu tabi ti o ba so pọ mọ ọn ṣíwájú imọra, eyi ni ẹjẹ nnkan oṣu, ti o ba wa jẹ pe ẹyin imọra ba ni, ko kii ṣe ẹjẹ nnkan oṣu; " Nítorí pé dajudaju opin isesi rẹ ni ki a sọ ọ pọ mọ awọ pupa rusurusu tabi awọ kurukuru (adapọ), eleyii ni idajọ rẹ. "

Orí kẹrin: Nípa awọn idajọ nnkan oṣu"

Awọn idajọ to pọ to le ni ogun lo n bẹ fun nnkan oṣu, a maa dárúkọ ninu ẹ eyi ti a ri pe a n bukaata si lọpọlọpọ ninu ìyẹn naa ni: "

Àkọ́kọ́: Irun: Irun kiki wa di eewọ fún ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù, ọranyan rẹ ati naafila rẹ, ko sì ní àlàáfíà kí o ki i, ati pe Irun o jẹ dandan fún un ayafi ti o ba bá ninu àsìkò rẹ odiwọn odidi rakah kan, nigba naa Irun jẹ dandan fún un, boya o ba a ni ibẹrẹ àsìkò ni abi ni ìparí rẹ.

Apẹrẹ ìyẹn ni ibẹrẹ àsìkò: Arábìnrin kan ti o ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ lẹyin wiwọ oòrùn pẹlu odiwọn rakah kan, nigba naa o jẹ dandan fún un ti o ba tí mọra ki o san irun Magrib; nitoripe o ti ba ninu àsìkò rẹ odiwọn rakah kan siwaju ki o to ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ.

Àpèjúwe ìyẹn ni ipari akoko: Arábìnrin kan ti o mọra kuro nibi ẹjẹ nkan oṣù rẹ siwaju yiyọ oòrùn pẹlu odiwọn rakah kan, nigba naa o jẹ dandan fún un kí o mọra láti san irun al-fajri; nitoripe o ba ninu àsìkò rẹ ipin kan ti o to fun rakah kan.

Ṣùgbọ́n ti ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù ba bá ninu àsìkò ìpín kan ti ko to fun odidi rakah kan, gẹgẹ bii kí o ri ẹjẹ nkan oṣù nibi àpèjúwe àkọ́kọ́ lẹyin wiwọ oòrùn pẹlu iṣẹju àáyá tabi ki o mọra nibi àpèjúwe ẹlẹẹkeji síwájú yiyọ oòrùn pẹlu iṣẹju aaya. Nigba naa Irun ko jẹ dandan fún un; fún ọrọ Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe:

«مَنْ أَدْرَكَ رَكْعَةً مِنَ الصَّلَاةِ فَقَدْ أَدْرَكَ الصَّلَاةَ».

“Ẹniti o ba ba rakah kan ninu Irun niti pàápàá o ti ba Irun” Bukhōriy ati Muslim lo gbé e jáde. Nitori naa dajudaju agbọye rẹ ni pe ẹnití o ba ba nkan ti o kere sí rakah kan ko le jẹ ẹnití o ba Irun.

Ti o ba ba rakah kan ninu àsìkò Irun Asri, njẹ Irun Dhuri ati Asri jẹ dandan fún un, tabi ti o ba ba rakah kan ninu àsìkò Irun Ishai igbẹyin, njẹ Irun Magrib pẹlu Ishai jẹ dandan fún un?.

Nibi eleyii ìyapa ẹnu wa laarin awọn olumọ, èyítí o bọ sí ojú rẹ ni wipe ko jẹ dandan fún un ayafi èyítí o ba àsìkò rẹ, oun náà ni Irun Asri ati Irun Ishai igbẹyin nìkan.

«مَنْ أَدْرَكَ رَكْعَةً مِنَ الْعَصْرِ قَبْلَ أَنْ تَغْرُبَ الشَّمْسُ فَقَدْ أَدْرَكَ الْعَصْرَ».

Fún ọrọ rẹ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe: “Ẹnití o ba ba rakah kan ninu Asri síwájú kí oòrùn tó wọ, o ti ba Asri” Bukhōriy àti Muslim lo gbé e jáde. Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si sọ pe: O ti bá Dhuri ati Asri. Ati pe ko dárúkọ ijẹ dandan Irun Dhuri fún un, ìpìlẹ̀ si ni bibọ ọrùn kuro nibi ọranyan, ati pe eleyii ni ìròrí Àbú Haneefah ati Maaliki, o gbe e wa láti ọdọ àwọn méjèèjì ninu tira sharhul-muhaddhab.

Ṣugbọn ṣiṣe ìrántí ati gbigbe títóbi fún Ọlọhun ati ṣiṣe afọmọ fún Ọlọhun ati fifi ẹyin fún Ọlọhun ati didarukọ Ọlọhun lori ounjẹ ati nkan ti o yatọ sí i, ati kika hadīth ati fiqhu ati ṣiṣe adua ati ṣiṣe aamiin sí i ati gbigbọ Al-Qur'āni, ikankan ninu rẹ o kii ṣe eewọ fún un.

«أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ يَتَّكِئُ فِي حِجْرِ عَائِشَةَ رَضِيَ اللهُ عَنْهَا وَهِيَ حَائِضٌ فَيَقْرَأُ الْقُرْآنَ».

O ti fìdí múlẹ̀ ninu Ṣohīhi mejeeji ati ìwé hadīth ti o yatọ sí mejeeji pe “Anọbi- kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹnití máa n rọgbọkun le itan Aaisha - ki Ọlọhun yọnu sí i - ti o si jẹ ẹnití n ṣe nkan oṣù rẹ ti yíò sì máa ka Al-Qur'āni”.

O wa ninu Ṣohīhi mejeeji bakanna pe Ummu ‘Atiyyah - kí Ọlọhun yọnu sí i - gbọ ti Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:

«يَخْرُجُ الْعَوَاتِقُ وَذَوَاتُ الْخُدُورِ وَالْحُيَّضُ -يَعْنِي: إِلَى صَلَاةِ الْعِيدَيْنِ- وَلْيَشْهَدْنَ الْخَيْرَ، وَدَعْوَةَ الْمُؤْمِنِينَ، وَيَعْتَزِلُ الْحُيَّضُ الْمُصَلَّى».

Awọn ọdọ binrin ti wọn ṣẹṣẹ bàlágà, ati awọn obìnrin ti wọn maa n wà nínú ilé lẹ́yìn gàgá, ati awọn ti n ri ẹjẹ nkan oṣù o máa jade - ìyẹn ni pé : Lati lọ kí Irun ọdún méjèèjì - ki wọn le fi oju ganni oore ati adua awọn mumini, ti awọn ti n ṣe nkan oṣù o si yẹba kúrò ni aaye ikirun.

Amọ kika Al-Qur'āni ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù fúnra rẹ, ti o ba jẹ wiwo pẹlu ojú lasan ni tabi iwoye pẹlu ọkàn laini wí i jáde pẹlu ahọ́n, ko si aburú nibi ìyẹn, gẹgẹ bii kí o gbé ìwé Al-Qur'āni tabi ọpọn kalẹ ki o waa máa wo awọn aayah ki o maa fi ọkàn rẹ ka a. Alfa An-Nawawiy sọ ninu tira sharhu al-muhaddhab pe: “o tọ laísì ìyapa kankan lórí rẹ”. Amọ ti kika rẹ bá jẹ wíwí i jáde pẹlu ahọ́n, awọn ọgọọrọ olumọ wa lórí wipe nkan ti wọn kọ ni ti ko si ni ẹtọ. Al-bukhari ati ibnu jarīr at-Tobariy ati ibnul mundhir sọ pé: o ni ẹtọ. Wọn gbà wá láti ọdọ Maaliki ati lati ọdọ ash-Shāfi‘iy ninu ọrọ atijọ, o gbà a wa lati ọdọ awọn mejeeji ninu tira Fat’hul bārii. Ati pe Al-bukhari gba a wa - ti o yọ nínú àwọn ti wọn gba ẹgbawa rẹ silẹ - lati ọdọ Ibrahim An-Nakha‘iy pe: ko si aburú nibi ki o ka aayah.

Shaykhul-Islām ibnu Taymiyah sọ ninu al- Fatāwa akojọpọ ibnu Qāsim pe: “ko sí ìlànà kankan rárá lati inu Al-Qur'āni lori kikọ ọ; torí pé gbólóhùn rẹ tó wí pé: “Ẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù ati ẹnití o ni janaba o gbọdọ ka nkankan ninu Al-Qur'āni”, hadīth ti o lẹ ni pẹlu ipanupọ awọn olumọ nipa hadīth, àti pé àwọn obìnrin jẹ ẹnití máa n rí ẹjẹ nkan oṣù ni ìgbà Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ka ni wipe kika Al-Qur'āni jẹ eewọ lórí wọn gẹ́gẹ́ bíi Irun ni, eleyii o ba wa ninu nkan ti Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o se ni àlàyé fún ìjọ rẹ ti awọn iya awọn Mu'mini a sì kọ ọ ti ìyẹn o si wa ninu nkan ti wọn yíò máa gbé kiri láàrin àwọn èèyàn. Nígbà tí ko ti si ẹni kankan ti o gba ẹgbawa lati ọdọ Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- nipa kikọ nnkan yẹn, ko ni ẹtọ ki a ṣe e ni eewọ pẹlu mimọ wipe ko kọ ọ, ati pe ti ko ba kọ ọ pẹlu pipọ riri ẹjẹ nkan oṣù nígbà ayé rẹ, o fihàn daju wipe kii ṣe eewọ.

Eyi ti o tọ lẹyin ti a ti mọ ifanfa awọn olumọ ni ki wọn sọ pé: Ohun ti o dara ju fun ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù ni kí ó má ka Al-Qur'ān ni kika jáde láti ẹnu àyàfi ti o ba bukaata sí i gẹ́gẹ́ bíi kí o jẹ olukọni ti yíò waa bukaata sí kí o maa pe e si ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ l'obinrin, tabi ni asiko ìdánwò ti akẹ́kọ̀ọ́ l'obinrin o si bukaata sí kika a fún ìdánwò tabi eyiti o jọ ìyẹn.

Ẹlẹẹkeji: Aawẹ: Aawẹ gbigba jẹ eewọ fun ẹni tí n ri ẹjẹ nkan oṣù, ọranyan rẹ ati àgbàgbọrẹ rẹ, ko sì nii ni àlàáfíà ti o ba ṣe e, ṣugbọn dandan ni fún un kí o ṣe e; latari hadiisi Aaisha ki Ọlọhun yọnu sí i.

"كَانَ يُصِيبُنَا ذَلِكَ -تَعْنِي: الْحَيْضَ- فَنُؤْمَرُ بِقَضَاءِ الصَّوْمِ وَلَا نُؤْمَرُ بِقَضَاءِ الصَّلَاةِ".

Iyẹn maa n ṣẹlẹ si wa - nkan ti o gba lero ni: nnkan oṣu- wọn maa n pa wa lasẹ pẹlu dida awẹ pada wọn o si ki n pa wa lasẹ pẹlu dida irun pada. Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. "

Ti o ba n ṣe nnkan oṣu ti o si n gba aawẹ lọwọ, aawẹ rẹ ti bajẹ, koda ki iyẹn ṣẹlẹ̀ ni o ku diẹ ki oòrùn wọ̀ pẹlu isẹju aaya, dida awẹ ọjọ yẹn pada jẹ dandan le e lori ti aawẹ yẹn ba jẹ ọranyan. "

Sugbọn ti o ba fura pe nnkan oṣu fẹ́ wa ṣíwájú wiwọ oòrùn, sugbọn ko jade ayaafi lẹyin wiwọ oòrùn, dajudaju aawẹ rẹ pe, ko si bajẹ lori ọrọ to ni alaafia; nitori pe ẹjẹ to wa ninu ikun ko ni idajọ kankan " Ati nitori pe Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti wọn bi i nipa obinrin to n ri ni oju orun rẹ nnkan ti ọkunrin maa n ri: Ǹjẹ́ iwẹ kankan jẹ dandan fun un? "

قَالَ: «نَعَمْ، إِذَا هِيَ رَأَتِ الْمَاءَ». فَعَلَّقَ الْحُكْمَ بِرُؤْيَةِ الْمَنِيِّ لَا بِانْتِقَالِهِ، فَكَذَلِكَ الْحَيْضُ لَا تَثْبُتُ أَحْكَامُهُ إِلَّا بِرُؤْيَتِهِ خَارِجًا، لَا بِانْتِقَالِهِ.

"O sọ pe: “Bẹẹni, ti o ba ri atọ”, o so idajọ naa mọ riri atọ ko kii ṣe pẹlu pe o fẹ wa, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni nnkan oṣu, awọn idajọ rẹ ko nii maa fi ẹsẹ rinlẹ afi pẹlu riri i ni nkan to jade ko kii ṣe pẹ̀lú pé o fẹ wa."

"Ti alufajari ba wa yọ ti o si jẹ ẹni tí o n se nnkan oṣu, aawẹ ọjọ yẹn o ni alaafia lati ọdọ rẹ koda ko mọra lẹyin alufajari pẹlu isẹju aaya."

" Ti o ba wa mọra ni asiko ti yiyọ alufajari ti sunmọ to wa gba aawẹ, aawẹ rẹ ni alaafia, koda ko ma ti i wẹ ayaafi lẹyin alufajari, gẹgẹ bi ẹni tí o ni janaba lara ti o ba gbero lati gba awẹ ti o si ni janaba lara ti ko si ti wẹ afi lẹyin yiyọ alufajari, dajudaju aawẹ rẹ ni alaafia; "

"كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يُصْبِحُ جُنُبًا مِنْ جِمَاعٍ غَيْرِ احْتِلَامٍ ثُمَّ يَصُومُ فِي رَمَضَانَ".

Fun hadiisi Aa'ishah -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: “Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ji ni ẹni tí o ni janaba lara latara ibanilopọ láìṣe ti àlá, lẹyin naa yio gba aawẹ ninu oṣu ramadan”. Bukhari ati Muslim ni wọ́n gba a wa. "

"Idajọ ẹlẹẹkẹta: Irọkirika ile Oluwa: Wọn ṣe irọkirika ile Oluwa ni eewọ fun un, ọranyan rẹ ati asegbọrẹ rẹ, ko si nii ni alaafia ti o ba ṣe e;"

«افْعَلِي مَا يَفْعَلُ الْحَاجُّ غَيْرَ أَلَّا تَطُوفِي بِالْبَيْتِ حَتَّى تَطْهُرِي».

Fun ọrọ ti Anọbi sọ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun Aa'ishah nigba ti o ṣe nnkan oṣu pe: “Ṣe nkan ti awọn alalaaji n ṣe yatọ si pe ko gbọdọ rọkirika ile Olúwa titi ti yoo fi wa ni mọra”.

"Sugbọn awọn iṣẹ yókù gẹgẹ bii ipọṣẹṣẹ laarin sọfa ati marwa, ati diduro si arafah, ati sisun muzdalifah mọju, ati jiju awọn okuta ati nnkan to yatọ si i ninu awọn iṣẹ hajj ati umra, ko kii ṣe eewọ fun un," Ni ibamu si eyi, ti obinrin ba wa rọkirika ile Oluwa ti o si jẹ ẹni tí o wa ni imọra, lẹyin naa ẹjẹ nnkan oṣu jade ni kete lẹyin irọkirika ile Oluwa tabi nigba ti o n ṣe ipọṣẹṣẹ lọwọ, ko si ẹṣẹ nibi iyẹn. "

"Idajọ ẹlẹẹkẹrin: Ko si irọkirika ile Oluwa ti idagbere fun un: Ti obinrin ba ti pari awọn iṣẹ hajj ati umra lẹyin naa o wa ri ẹjẹ nnkan oṣu ṣíwájú ijade lọ si ilu rẹ ti ẹjẹ nnkan oṣu naa si n da lara rẹ titi di asiko jijade rẹ, dajudaju yio jade lai nii ṣe irọkirika idagbere; " Fun hadiisi Ibn Abbas -ki Ọlọhun kẹ awọn mejeeji- o sọ pe: “Wọ́n pa awọn eeyan láṣẹ ki igbẹyin asiko wọn jẹ pẹlu irọkirika ile Oluwa, ṣùgbọ́n wọn ṣe ẹdẹ fun obinrin ti o n ṣe nnkan oṣu”. [Bukhari ati Muslim ni o gba a wa]. "

Wọn ko fẹ fun ẹni tí o n ṣe nnkan oṣu nigba irọkirika idagbere lati wa sibi ilẹkun mọsalasi abọwọ lati ṣe adua; nitori pe iyẹn ko wa lati ọdọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, àti pé awọn ijọsin jẹ nkan ti a mọ pa lori nkan to wa. Bi ko ṣe pe nkan to wa lati ọdọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọka si iyapa si iyẹn,"

فَفِي قِصَّةِ صَفِيَّةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا، حِينَ حَاضَتْ بَعْدَ طَوَافِ الْإِفَاضَةِ، أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ لَهَا: «فَلْتَنْفِرْ إِذًا». مُتَّفَقٌ عَلَيْهِ.

Nínú itan Sofiyyah -ki Ọlọhun yọnu si i- nigba ti o ṣe nnkan oṣu lẹyin tawaful ifādoh (irọkirika ile Oluwa ti o jẹ ti hajj) pe Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe “ki o yaa maa lọ nigba naa”. Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa."

"Ko si pàṣẹ pẹlu wiwa sibi ilẹkun mọsalasi abọwọ, ka ni pe iyẹn jẹ nkan ti wọn ṣe l'ofin ni ko ba ṣe alaye ẹ." Àmọ́ irọkirika ile Oluwa ti hajj ati umra ko le bọ fun un, bi ko ṣe pe o maa rọkirika ile Oluwa to ba ti mọra."

"Idajọ ẹlẹẹkarun-un: Iwa ni mọsalasi: Wọ́n ṣe ni eewọ fun ẹni tí ó ń ṣe nnkan oṣu lati wa ni mọsalasi titi dori aaye ikirun ọdun, wọn ṣe e ni eewọ fun un lati duro nibẹ,"

لِحَدِيثِ أُمِّ عَطِيَّةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا: أَنَّهَا سَمِعَتِ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ: «يَخْرُجُ الْعَوَاتِقُ وَذَوَاتُ الْخُدُورِ وَالْحُيَّضُ». وَفِيهِ: «يَعْتَزِلُ الْحُيَّضُ الْمُصَلَّى». مُتَّفَقٌ عَلَيْهِ.

"Fun hadiisi Ummu A'tiyyah -ki Ọlọhun yọnu si i- pe: O gbọ ti Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ki awọn ọdọbinrin ti wọn ṣẹṣẹ bàlágà, ati awọn ti wọn maa n wà nínú ilé lẹ́yìn gàgá, ati awọn ti n ri ẹjẹ nkan oṣù o jade”, o wa nibẹ pe: “Ki awọn ti wọn n se nnkan oṣu si yẹba kuro ni aaye ti wọn ti n kirun”. Bukhari ati Muslim ni wọ́n gba a wa. "

"Idajọ ẹlẹẹkẹfa: Ibalopo: Wọn ṣe e leewọ fun ọkọ rẹ lati ba a lopọ, wọn si se gbigba a laaye leewọ fun un nibi iyẹn;"

﴿وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡمَحِيضِۖ قُلۡ هُوَ أَذٗى فَٱعۡتَزِلُواْ ٱلنِّسَآءَ فِي ٱلۡمَحِيضِ وَلَا تَقۡرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطۡهُرۡنَ...

Fun ọrọ Ọba -ti ọla Rẹ ga-: {Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra}[Al-Baqarah: 222] "Nkan ti a gba lero pẹlu "Al-mahiid" ni akoko nnkan oṣu ati aaye rẹ, oun naa ni oju ara obinrin; "

وَلِقَوْلِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «اصْنَعُوا كُلَّ شَيْءٍ إِلَّا النِّكَاحَ». يَعْنِي: الْجِمَاعَ. رَوَاهُ مُسْلِمٌ.

"Ati fun ọrọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: “Ẹ ṣe gbogbo nnkan (pẹlu iyawo yin) ayaafi nikāh”. Ìyẹn tumọ si: Ibalopo. Muslim ni o gba a wa; " Ati pe nitoripe awọn Musulumi panu pọ lori ṣíṣe leewọ biba ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù ni ibalopo ni ojú ara rẹ.

Nitori naa ko lẹtọọ fun ọmọnìyàn ti o gbagbọ ninu Ọlọhun ati ọjọ ìkẹhìn ki o gboya lori ṣíṣe àlámọ̀rí ti wọn kọ yii, eyi ti tira Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati sunnah òjíṣẹ́ Rẹ - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ipanupọ gbogbo Musulumi tọka lori kikọ kuro níbẹ̀, ti yíò sì máa bẹ ninu ẹnití o tako Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ti o si tun tẹ̀lé ọ̀nà t’ó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. O sọ ninu tira al-Majmū‘u sharhu al-muhaddhab ojú ewé: 374, idi 2, wipe: Ash-shāfi‘iy - ki Ọlọhun kẹ ẹ - sọ pe: “Ẹni tí ó ba ṣe ìyẹn ti da ẹṣẹ ńlá”. Àwọn eeyan wa ati awọn mìíràn sọ pé ẹni tí o ba ṣe biba ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù sun ni ẹtọ, wọn maa dajọ pé kèfèrí ni”. Ọrọ An-Nawawiy ti pari.

Ati pe wọn ti ṣe e ni ẹtọ fún un - ọpẹ si ni fún Ọlọhun - nkan ti yíò fi maa dẹkun adùn ara rẹ yatọ sí ibalopọ, gẹgẹ bii ifẹnukonu, ati didimọ, ati isunmọ ara ẹni ni ibi ti o yatọ sí oju-ara, ṣugbọn eyiti o dara julọ ni ki o ma sunmọ ọn ni ibi ti o wa laarin idodo ati orunkun àyàfi ki o jẹ lẹyin gaga.

لِقَوْلِ عَائِشَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا: «كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَأْمُرُنِي فَأَتَّزِرُ، فَيُبَاشِرُنِي وَأَنَا حَائِضٌ». مُتَّفَقٌ عَلَيْهِ.

Fún ọrọ Aaisha - ki Ọlọhun yọnu sí i - ti o sọ pe: “Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹnití máa n pa mi láṣẹ pe ki n ró ìró, yio sí máa sunmọ mi (ba mi ṣeré) ti mo ṣì jẹ ẹnití n ṣe nkan oṣù lọwọ.

Ìdájọ Ẹlẹẹkeje: Ikọsilẹ: O jẹ eewọ fún ọkọ ki o kọ ẹnití n ṣe nkan oṣù silẹ ni àsìkò ti n ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ.

Fun gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe:

﴿يَاأَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاء فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ...

{Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe òǹkà ọjọ́ opó fún ìkọ̀sílẹ̀ wọn.} [At-talāq: 1]. Ìyẹn ni pé: Ni àsìkò ti wọn o fi daju kọ onka ọjọ opo ti a ti mọ nígbà ikọsilẹ, ìyẹn ko le ṣẹlẹ àyàfi ti o ba kọ ọ silẹ ni aboyún tàbí ni ẹnití o mọra láìsí ibalopọ. Nítorí pé ti wọn ba kọ ọ silẹ ni àsìkò riri ẹjẹ nkan oṣù, ko daju kọ onka ọjọ opo ikọsilẹ latari wipe ẹjẹ nkan oṣù ti wọn kọ ọ silẹ ninu rẹ wọn o nii ka a mọ onka ọjọ opo ikọsilẹ, ti wọn ba sí tún kọ ọ silẹ ni ẹnití o wa ni mimọ lẹyin ibalopọ, onka ọjọ opo ikọsilẹ ti yíò daju kọ ko nii fi ojú hàn ni eyi ti o ṣe wipe wọn o nii mọ boya o ti lóyún latara ibalopọ náà, ti yíò fi wa ṣe onka rẹ pẹlu oyun, tabi boya ko ni oyún ti yíò ṣe onka rẹ pẹlu ẹjẹ nkan oṣù. Nitori naa nígbà tí ko ti si amọdaju ninu iran onka, ikọsilẹ jẹ eewọ fún un títí tí àlámọ̀rí naa o fi fi ojú han.

Nitori naa kikọ ẹnití n ṣe nkan oṣù silẹ ni àsìkò ti n ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ eewọ ni fún aayah ti o ṣaaju.

وَلِمَا ثَبَتَ فِي الصَّحِيحَيْنِ وَغَيْرِهِمَا مِنْ حَدِيثِ ابْنِ عُمَرَ: «أَنَّهُ طَلَّقَ امْرَأَتَهُ وَهِيَ حَائِضٌ، فَأَخْبَرَ عُمَرُ بِذَلِكَ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَتَغَيَّظَ فِيهِ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَقَالَ: مُرْهُ فَلْيُرَاجِعْهَا، ثُمَّ لِيُمْسِكْهَا حَتَّى تَطْهُرَ، ثُمَّ تَحِيضَ، ثُمَّ تَطْهُرَ، ثُمَّ إِنْ شَاءَ أَمْسَكَ بَعْدُ، وَإِنْ شَاءَ طَلَّقَ قَبْلَ أَنْ يَمَسَّ، فَتِلْكَ الْعِدَّةُ الَّتِي أَمَرَ اللَّهُ أَنْ تُطَلَّقَ لَهَا النِّسَاءُ».

Ati fún eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu Ṣohīhi mejeeji ati eyi ti o yatọ sí àwọn méjèèjì ninu hadīth ọmọ ‘Umar wipe “Dajudaju o kọ ìyàwó rẹ silẹ l’ẹniti n rí ẹjẹ nkan oṣù rẹ lọwọ, ‘Umar wa fún Anabi – kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ní ìró nipa ìyẹn, ti òjíṣẹ Ọlọhun – kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sí binu sí i, o si sọ pe: “Pa a laṣẹ ki o gba a pada (kí o fa igi le kikọ yẹn) lẹyin naa ki o mu un dání (ko sì wà lọdọ rẹ) titi ti yíò fi mọra, ti yíò sì tún rí ẹjẹ nkan oṣù rẹ, lẹyin naa yíò mọra, lẹyin naa ti o ba fẹ kí o mu un dání lẹyin ìgbà yẹn, ti o ba si wu u ki o kọ ọ silẹ síwájú kí o to sunmọ ọn, ìyẹn ni onka opo ikọsilẹ ti Ọlọhun pàṣẹ kí wọn kọ àwọn obìnrin silẹ fún. Nitori naa ti okunrin ba kọ ìyàwó rẹ silẹ l’ẹniti n rí ẹjẹ nkan oṣù rẹ lọwọ, ẹlẹṣẹ ni, o sí jẹ dandan fún un kí o tuuba lọ sí ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, kí o si da a pada sí abẹ ààbò rẹ ki o fi le kọ ọ ni kikọ ti o ba òfin mu ti o ṣe kongẹ àṣẹ Ọlọhun ati òjíṣẹ́ Rẹ, yíò waa fi í sílẹ lẹyin ti o ba gba a pada titi yíò fi mọra kuro nibi ẹjẹ nkan oṣù ti o kọ ọ silẹ ninu rẹ, lẹyin naa yíò tun ri ẹjẹ nkan oṣù míràn, lẹyin naa ti o ba ti mọra, tí o ba wù u ki o fi í sílẹ̀, ti o ba si wù u ki o kọ ọ síwájú kí o to ba a ni ibalopo. Ati pe wọn ṣe àyàfi nibi ijẹ eewọ ikọ obinrin silẹ ninu ẹjẹ nkan oṣù awọn àlámọ̀rí mẹta kan:

Àkọ́kọ́: Ti ikọsilẹ ba wáyé ṣíwájú kí o to da wa pẹlu rẹ, tabi ki o to sunmọ ọn, ko si aburú nibi ki o kọ ọ lẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ lọwọ. Nítorí pé kò sí onka ọjọ opo ikọsilẹ kankan fún un nigba naa, kikọ ọ silẹ o si nii jẹ ìyapa.

Fun ọrọ Ọlọhun ti o sọ pe:

﴿...فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ...

{ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe òǹkà ọjọ́ opó fún ìkọ̀sílẹ̀ wọn.} [At-talāq: 1].

Ẹlẹẹkeji: Ti ẹjẹ nkan oṣù yẹn ba wa ni àsìkò oyún, alaye idi ìyẹn tí sáájú.

Ẹlẹẹkẹta: Ti ikọsilẹ ba jẹ lori gbigba nkan (bi owo lọwọ ìyàwó), dajudaju ko si aburú nibi ki o kọ ọ lẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù lọwọ.

Gẹ́gẹ́ bíi ki ifanfa ati ìbáṣepọ̀ tí kò dára o wáyé láàrín ọkọ àti ìyàwó, kí ọkọ o wa gba nkankan láti kọ ọ silẹ, o lẹ́tọ̀ọ́, kódà kí o jẹ ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù lọwọ.

لِحَدِيثِ ابْنِ عَبَّاسٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا: أَنَّ امْرَأَةَ ثَابِتِ بْنِ قَيْسِ بْنِ شَمَّاسٍ جَاءَتْ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَالَتْ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنِّي مَا أَعْتِبُ عَلَيْهِ فِي خُلُقٍ وَلَا دِينٍ، وَلَكِنْ أَكْرَهُ الْكُفْرَ فِي الْإِسْلَامِ. فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَتَرُدِّينَ عَلَيْهِ حَدِيقَتَهُ؟» قَالَتْ: نَعَمْ. فَقَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «اقْبَلِ الْحَدِيقَةَ، وَطَلِّقْهَا تَطْلِيقَةً». [رَوَاهُ الْبُخَارِيُّ].

Fun hadīth ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu sí àwọn méjèèjì – dajudaju ìyàwó Thābit ọmọ Qaysi ọmọ Shammās wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o wa sọ pé: Irẹ òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju emi o bu u nibi iwa ati ẹsin, ṣugbọn mo n korira ṣiṣe aigbagbọ nínú Isilaamu. Ni Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pé: “Ṣe wàá da ọgbà oko rẹ pada fún un?”, O sọ pe: Bẹẹni. Ni ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pé: “Gba ọgbà oko pada ki o si kọ ọ ni ikọsilẹ ẹẹkan pere” [Bukhōriy lo gbe e jáde]. Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si béèrè wipe: Ǹjẹ́ o jẹ ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù lọwọ àbí ẹnití o wa ni imọra? Ati pe torí pé ikọsilẹ yii jẹ ìgba-ara-ẹni-silẹ lati ọdọ obinrin naa; nitori naa o lẹ́tọ̀ọ́ nígbà tí a ba bukaata sí i lori èyíkéyìí ìṣesí ti o ba jẹ.

O sọ ninu tira Al-Mugniy lẹniti n sọ idi ìní ẹ̀tọ́ khul'u (ki obinrin tu ara rẹ sílẹ kúrò labẹ ọkọ pẹlu dídá nkan ti o gbà lọwọ ọkọ rẹ padà) ni àsìkò ti n ri ẹjẹ nkan oṣù lọwọ. Ojú ewé: 52 idi 7, atẹjade mim. nítorí pé kikọ kuro nibi ikọsilẹ ni àsìkò riri ẹjẹ nkan oṣù jẹ latari inira ti yíò máa ṣẹlẹ sí i (obìnrin) pẹlu gígùn onka ọjọ opo fún ikọsilẹ rẹ, ati pe khul'u wa fún mímú inira ti o n ṣẹlẹ si i pẹlu ibalopọ ti ko dára ati wiwa pẹlu ẹnití o korira ti ko sì nífẹ̀ẹ́ kuro, ati pe ìyẹn tobi ju inira gígùn onka ọjọ opo fún ikọsilẹ rẹ lọ; nitori naa o tọ ki a ti eyi ti o ga jù nínú mejeeji danu pẹlu eyi ti o kere; fún ìdí èyí ni Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o fi béèrè lọwọ arabinrin ti o ṣe khul'u yẹn nipa ìṣesí rẹ.

Ṣùgbọ́n titakoko ìgbéyàwó obìnrin tí n ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ lọwọ, kò sí aburú níbẹ̀; torí pé ìpìlẹ̀ ni wipe ẹtọ ni, ko sì sí ẹrí kankan lórí kikọ ọ, ṣugbọn mímú ọkọ wọlé tọ ọ lẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù lọwọ nílò ki a woye si i. Ti a ba fi ọkàn balẹ pe ko nii bá a ni ajọṣepọ, ko si aburú níbẹ̀, bibẹẹkọ ko gbọdọ wọlé tọ ọ titi ti yíò fi mọra, ni ipaya ki o ma ko sinu nkan ti wọn kọ.

"Idajọ ẹlẹẹkẹjọ: Iwoyesi onka ọjọ ikọsilẹ pẹlu rẹ -iyẹn tumọ si: Nǹkan oṣu-: Ti ọkunrin ba kọ iyawo rẹ lẹyin ti o ti ba a lopọ tabi wa ni kọlọfin pẹlu ẹ, o ti jẹ dandan le e lori lati ṣe opo ikọsilẹ fun nnkan oṣu mẹta to pe, ti o ba wa ninu awọn ti wọn maa n ṣe nnkan oṣu, ti ko si loyun; "

Fun ọrọ Ọba -ti ọla Rẹ ga-:

﴿وَٱلۡمُطَلَّقَٰتُ يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ ثَلَٰثَةَ قُرُوٓءٖ...

{Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóra ró fún n̄ǹkan oṣù mẹ́ta} [Al-Baqarah:228] "itumọ iyẹn ni: Nǹkan oṣu mẹta "Ti o ba jẹ oloyun, onka ọjọ opo ikọsilẹ rẹ di asiko ti yio fi bi oyun inu rẹ patapata, boya asiko yẹn gun ni tabi o kere;"

Fun ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga to sọ pe:

﴿...وَأُوْلَاتُ الأَحْمَالِ أَجَلُهُنَّ أَن يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ...

{Àwọn olóyún, ìparí òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn ni pé kí wọ́n bí oyún inú wọn.} [At-talāq: 4]. "Ti o ba wa wa ninu awọn ti wọn kii ṣe nnkan oṣu gẹgẹ bi ọmọ kekere ti koi tii bẹrẹ nnkan oṣu ati ẹniti o ti jakan kuro nibi nnkan oṣu ṣiṣe nitori ogbo tabi iṣẹ́ abẹ kan ti o mu apo ibi ẹ kuro, tabi nnkan to yatọ si iyẹn ninu nnkan ti wọn o lero ipada nnkan oṣu pẹlu rẹ, onka ọjọ opo ikọsilẹ rẹ maa jẹ oṣu mẹta; "

"Fun ọrọ Ọba -ti ọla Rẹ ga:

﴿وَاللَّائِي يَئِسْنَ مِنَ الْمَحِيضِ مِن نِّسَائِكُمْ إِنِ ارْتَبْتُمْ فَعِدَّتُهُنَّ ثَلَاثَةُ أَشْهُرٍ وَاللَّائِي لَمْ يَحِضْنَ...

{ Àwọn obìnrin t’ó ti sọ̀rètí nù nípa n̄ǹkan oṣù ṣíṣe nínú àwọn obìnrin yín, tí ẹ bá ṣeyèméjì, òǹkà ọjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ wọn ni oṣù mẹ́ta. (Bẹ́ẹ̀ náà ni fún) àwọn tí kò tí ì máa ṣe n̄ǹkan oṣù} [At-Talâq:4] "Ti o ba wa wa ninu awọn to n ṣe nnkan oṣu sugbọn nnkan oṣu dawọ duro fun idi kan ti a mọ gẹ́gẹ́ bíi aisan ati ifọmọlọyan, yio maa bẹ ninu opo ikọsilẹ koda ki asiko naa o gun titi ti nnkan oṣu fi maa ṣeri pada, yio wa ṣe onka opo ikọsilẹ pẹlu ẹ," "Ti okunfa naa ba wa kuro ti ẹjẹ nnkan oṣu o si pada pẹlu pe ki o la kuro nibi aisan tabi ki o pari ifọmọlọyan ki ẹjẹ nkan oṣù o si wa ni idaduro, nigba naa yio ṣe opo ikọsilẹ fun ọdun kan gbako latari kí kúrò okunfa naa," Eyi naa ni ọrọ to ni alaafia, ti awọn ipilẹ sharia si ba a mu," "Nítorí pé ti okùnfà ba ti kuro ti ẹjẹ nnkan oṣu o si pada, o ti da gẹgẹ bii ẹni tí nnkan oṣu rẹ dawọ duro laini idi kankan ti a mọ, ti nnkan oṣu rẹ ba dawọ duro laini idi kankan ti a mọ, nitori naa yio ṣe onka opo ikọsilẹ fun ọdun kan gbako, oṣu mẹsan-an fun oyun ni ti aibaamọ; nítorí pé oun ni asiko oyun lọpọ igba, ati oṣu mẹta fun opo ikọsilẹ. "

"Sugbọn ti ikọsilẹ ba waye lẹyin yigi ṣíwájú ibalopọ ati iwa ni kọlọfin, ko si opo ikọsilẹ nibẹ rara, ko si pẹlu ẹjẹ nnkan oṣu ko si si nnkan mii yatọ si i;"

"Fun ọrọ Ọba -ti ọla Rẹ ga:

﴿يَاأَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نَكَحْتُمُ الْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِن قَبْلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمْ عَلَيْهِنَّ مِنْ عِدَّةٍ تَعْتَدُّونَهَا...

{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fun yín} [Al-Ahzâb: 49]

"Idajọ ẹlẹẹkẹsan: Didajọ pẹlu mimọ apo ibi, ìyẹn tumọ si wipe: Pẹ̀lú pípa sofo rẹ kuro nibi oyun, àti pé eleyii wọn bukaata si i ni gbogbo igba ti wọn ba ti ni bukaata si didajọ pẹlu mimọ apo ibi, awọn ọrọ ẹsin si n bẹ fun-un :"

"Ninu ẹ: Ti ẹnikan ba ku fun obinrin kan ti oyun rẹ maa jẹ ogun rẹ, ti o si wa ni ẹniti o ti ni ọkọ, dajudaju ọkọ rẹ o nii ba a lopọ titi ti yio fi ṣe nnkan oṣu, tabi ti oyun rẹ o fi han, ti oyun rẹ ba han, a maa dajọ pẹlu jijẹ ogun rẹ (oyun) nitori idajọ wa pẹlu bibẹ rẹ nigba iku ẹniti yio mu un jẹ ogun, ti o ba si ṣe nnkan oṣu a maa dajọ pẹlu aini jẹ ogun rẹ; nitori idajọ wa pẹlu mimọ apo ibi pẹlu nnkan oṣu. "

"Idajọ ẹlẹẹkẹwaa: Ìjẹ́ dandan iwẹ: Yoo maa jẹ dandan fun ẹniti o n ṣe nnkan oṣu ti o ba ti mọra lati wẹ pẹlu mimọ gbogbo ara;"

لِقَوْلِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِفَاطِمَةَ بِنْتِ أَبِي حُبَيْشٍ: «فَإِذَا أَقْبَلَتِ الْحَيْضَةُ فَدَعِي الصَّلَاةَ، وَإِذَا أَدْبَرَتْ فَاغْتَسِلِي وَصَلِّي» [رَوَاهُ الْبُخَارِيُّ].

"Fun ọrọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- to sọ fun Fatima ọmọ Abu hubaysh pe: “Ti nnkan oṣu ba ti wa fi irun silẹ, ti o ba ti wa lọ ki o wẹ ki o si kirun” [Bukhari ni o gba a wa]."

"Eyi ti o kere julọ ti o jẹ dandan nibi iwẹ ni ki o fi omi kari gbogbo ara rẹ titi de ibi nnkan to wa labẹ irun, eyi to si lọla julọ ni ki o jẹ lori alaye (iroyin) ti o wa ninu hadiisi "

«عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ حَيْثُ سَأَلَتْهُ أَسْمَاءُ بِنْتُ شَكَلٍ عَنْ غُسْلِ الْمَحِيضِ، فَقَالَ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «تَأْخُذُ إِحْدَاكُنَّ مَاءَهَا وَسِدْرَتَهَا فَتَطَهَّرُ فَتُحْسِنُ الطُّهُورَ، ثُمَّ تَصُبُّ عَلَى رَأْسِهَا فَتَدْلُكُهُ دَلْكًا شَدِيدًا، حَتَّى تَبْلُغَ شُؤُونَ رَأْسِهَا، ثُمَّ تَصُبُّ عَلَيْهَا الْمَاءَ، ثُمَّ تَأْخُذُ فُرْصَةً مُمَسَّكَةً - أَيْ: قِطْعَةَ قُمَاشٍ فِيهَا مِسْكٌ - فَتَطَهَّرُ بِهَا»، فَقَالَتْ أَسْمَاءُ: كَيْفَ تَطَهَّرُ بِهَا؟ فَقَالَ: «سُبْحَانَ اللَّهِ!»، فَقَالَتْ عَائِشَةُ لَهَا: تَتَبَّعِينَ أَثَرَ الدَّمِ». [رَوَاهُ مُسْلِمٌ].

"Lati ọdọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti A'smau ọmọ Shakl bi i lere nipa iwẹ nnkan oṣu, o wa sọ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: “Ẹni kọọkan ninu yin o maa bu omi rẹ ati ewe sidru rẹ, yio wa maa ṣe imọra ti yio si ṣe imọra daadaa, lẹyin naa yio wa da omi si ori rẹ ti yio si fi ọwọ gbo o gidi gan, titi ti yio fi de ìsàlẹ̀ ori rẹ, lẹyin naa yio wa da omi si i, lẹyin naa yio wa mu firsoh mumassakah - itumọ rẹ ni: Egige aṣọ fẹlẹfẹlẹ kan ti turari al-misk wa lara rẹ - yio wa mọra pẹlu ẹ”, A'smau wa sọ pe: Báwo ni yio ṣe mọra pẹlu ẹ? O sọ pe: “Mímọ́ ni fun Ọlọhun”, Aa'ishah wa sọ fun un pe: Wa tẹle oripa ẹjẹ. [Muslim lo gba a wa]. "

Titu irun ori o si jẹ dandan, ayaafi ti o ba jẹ nkan ti wọn di le gan-an leyiti o n paya ki omi ma de ìsàlẹ̀ rẹ;"

لِمَا فِي صَحِيحِ مُسْلِمٍ مِنْ حَدِيثِ أُمِّ سَلَمَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا أَنَّهَا سَأَلَتِ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَتْ: إِنِّي امْرَأَةٌ أَشُدُّ شَعْرَ رَأْسِي، أَفَأَنْقُضُهُ لِغُسْلِ الْجَنَابَةِ؟ وَفِي رِوَايَةٍ: لِلْحَيْضَةِ وَالْجَنَابَةِ؟ فَقَالَ: «لَا، إِنَّمَا يَكْفِيكِ أَنْ تَحْثِيَ عَلَى رَأْسِكِ ثَلَاثَ حَثَيَاتٍ، ثُمَّ تُفِيضِينَ عَلَيْكِ الْمَاءَ فَتَطْهُرِينَ».

Fun nkan to wa ninu sohiihu Muslim ninu hadiisi Ummu salamoh -ki Ọlọhun yọnu si i- pe dajudaju o bi Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere, o wa sọ pe: Mo jẹ obinrin ti mo maa n di irun ori le gidi gan-an, njẹ maa tu u fun iwẹ janaba? Ninu ẹgbawa mii: Fún iwẹ nnkan oṣu ati janaba? O sọ pe: “Rara, bi ko ṣe pe o ti to ẹ ki o da omi si ori rẹ lẹẹmẹta lẹyin naa ki o da omi si ara rẹ, ti o ba ti ṣe bẹ́ẹ̀ o ti mọra”. "

Ti ẹniti n ṣe nnkan oṣu ba mọra ni akoko irun, o jẹ dandan fun un lati yara lọ wẹ ki o le ba kiki irun ni asiko ẹ, ti o ba wa ni irin-ajo ti ko si omi lọdọ rẹ tabi omi wa lọdọ rẹ sugbọn o n bẹru inira pẹlu lilo o, tabi o jẹ alaisan ti omi maa ko inira ba a, dajudaju yio ṣe imọra oni-erupẹ lati fi ṣe ijirọ fun iwẹ titi ti nnkan to kọ fun un o fi kuro, lẹyin naa yio wa wẹ. "

"Dajudaju apakan ninu awọn obinrin maa n mọra ni akoko irun, yoo si maa lọ iwẹ lara titi di asiko mii ti yio maa sọ pe: Pípé imọra o rọrun fun oun ni asiko yii, sugbọn èyí o ki n ṣe ẹri kankan tabi idiwọ (awijare) kankan; " "nítorí pé o rọrun fun un lati ge iwẹ kuru si eyi to kere julọ ni dandan, ti yio si ki irun ni asiko ẹ, lẹyin naa ti asiko to pọ ba ti wa fun un yio mọra ni imọra to pe."

Ipin karun: Nibi ẹjẹ àwáàdá ati awọn idajọ rẹ.

Al-Istihādho: Itẹsiwaju wiwa ẹjẹ obinrin l'eyi ti ko nii da ni igba kankan tabi ki o da fun igba diẹ, gẹ́gẹ́ bí ọjọ kan tabi ọjọ meji ninu oṣu.

Ẹri ìṣesí àkọ́kọ́ tí ẹjẹ o nii da rara ni nkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu Ṣohīhi al-bukhari lati ọdọ Aaisha - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:

«قَالَتْ فَاطِمَةُ بِنْتُ أَبِي حُبَيْشٍ لِرَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنِّي لَا أَطْهُرُ». وَفِي رِوَايَةٍ: «أُسْتَحَاضُ فَلَا أَطْهُرُ».

“Fātimah ọmọ Abi Hubaysh sọ fún Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, emi kii sí ni imọra. Ninu ẹgbawa kan: Mo maa n ri ẹjẹ awaada ti mi o si ki n mọra”.

Ẹri ìṣesí keji ti ẹjẹ o ki n da àyàfi fun igba diẹ ni hadīth Hamnah ọmọ Jahsh nígbà tí o wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o si sọ pe:

«يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنِّي أُسْتَحَاضُ حَيْضَةً كَثِيرَةً شَدِيدَةً». [الْحَدِيثُ.. رَوَاهُ أَحْمَدُ وَأَبُو دَاوُدَ وَالتِّرْمِذِيُّ وَصَحَّحَهُ، وَنُقِلَ عَنِ الْإِمَامِ أَحْمَدَ تَصْحِيحُهُ، وَعَنِ الْبُخَارِيِّ تَحْسِينُهُ].

“Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju emi jẹ ẹnití maa n ri ẹjẹ nkan oṣù awaada ti si maa n pọ gidi gan” [Hadīth... Ahmad ni o gba a wa ati Abu Daūd ati Tirmidhiy ti o si ni o ni alaafia, wọn si gba ini alaafia rẹ wa lati ọdọ Imām Ahmad ti wọn gba dida rẹ wa lati ọdọ Al-bukhari.

Awọn ìṣesí ẹjẹ awaada:

Ìṣesí mẹta ni n bẹ fun ẹnití n ri ẹjẹ awaada:

Ìṣesí Àkọ́kọ́: Ki onka riri ẹjẹ nkan oṣù ti a ti mọ wa fun un ṣíwájú ẹjẹ awaada, ti o ba ri bẹ́ẹ̀, ẹni yii a maa ṣẹri pada sí igba riri ẹjẹ nkan oṣù ti a ti mọ ṣaaju, ti yio sì maa jókòó ninu rẹ ti awọn idajọ ẹnití n ri ẹjẹ nkan oṣù a si maa bẹ fun un, èyí tí o ba ti wa yatọ si i, ẹjẹ awaada niyẹn, ti awọn idajọ ẹjẹ awaada o si maa bẹ fun un.

Apejuwe iyẹn ni arabinrin kan ti ẹjẹ nkan oṣù rẹ maa n wa fun ọjọ mẹfa ni ibẹrẹ oṣù, lẹyin naa ni ẹjẹ awaada ba ṣẹlẹ si i, ni ẹjẹ rẹ ba n wa láìdúró, ti o ba ri bẹ́ẹ̀, ẹjẹ nkan oṣù rẹ ọjọ mẹfa ni ibẹrẹ oṣù ni yio maa jẹ, èyí tí o ba ti wa yatọ si i, ẹjẹ awaada niyẹn.

لِحَدِيثِ عَائِشَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا أَنَّ فَاطِمَةَ بِنْتَ أَبِي حُبَيْشٍ قَالَتْ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنِّي أُسْتَحَاضُ فَلَا أَطْهُرُ، أَفَأَدَعُ الصَّلَاةَ؟ قَالَ: «لَا، إِنَّ ذَلِكِ عِرْقٌ، وَلَكِنْ دَعِي الصَّلَاةَ قَدْرَ الْأَيَّامِ الَّتِي كُنْتِ تَحِيضِينَ فِيهَا، ثُمَّ اغْتَسِلِي وَصَلِّي». رَوَاهُ الْبُخَارِيُّ.

Fun hadīth Aaisha - ki Ọlọhun yọnu sí i - pe dajudaju Fātimah ọmọ Abi Hubaysh sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju emi jẹ ẹnití maa n ri ẹjẹ awaada ti mi o si ki n wa ni imọra, njẹ mo le fi Irun silẹ? O sọ pe: “Rárá, dajudaju ìyẹn ẹjẹ iṣan ni, ṣugbọn gbe Irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣù rẹ, lẹyin naa ki o wẹ ki o si kirun”. Bukhārī ni o gba a wa.

وَفِي صَحِيحِ مُسْلِمٍ: أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ لِأُمِّ حَبِيبَةَ بِنْتِ جَحْشٍ: «امْكُثِي قَدْرَ مَا كَانَتْ تَحْبِسُكِ حَيْضَتُكِ، ثُمَّ اغْتَسِلِي وَصَلِّي».

O wa ninu Sọhīhu Muslim pe: Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ fun Ummu Habībah ọmọ Jahsh wipe: “ko ara ro fun odiwọn igba ti ẹjẹ nkan oṣù rẹ fi maa n da ọ jókòó, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun”. Lori eleyii, ẹnití n ri ẹjẹ awaada ti o ti ni ọjọ riri ẹjẹ nkan oṣù rẹ ti a ti mọ a maa jókòó ni odiwọn ọjọ riri ẹjẹ nkan oṣù rẹ, lẹyin naa yio wẹ yio si tun kirun, ko si nii bikita nipa ẹjẹ ti o ba n ri nigba naa.

Ìṣesí Ẹlẹẹkeji: Ki o ma si onka riri ẹjẹ nkan oṣù fun un ṣíwájú ẹjẹ awaada pẹlu ki ẹjẹ awaada yẹn o jẹ nkan ti n lọ laiduro lati akọkọ ti o ri ẹjẹ ni ibẹrẹ alamọri rẹ, ti o ba ri bẹ́ẹ̀, eleyii a maa ṣe amulo ṣiṣe adayanri ti ẹjẹ nkan oṣù rẹ o si maa jẹ eyiti o ba da yatọ pẹlu didudu, tabi kiki, tabi oorun, ti awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù o si maa bẹ fun un, èyí tí o ba ti yatọ si i ẹjẹ awaada ni ti awọn idajọ ẹjẹ awaada o maa bẹ fun un.

Apejuwe iyẹn ni obinrin kan ti o ri ẹjẹ ni akọkọ igba ti o ri i, ti o wa n lọ bẹẹ pẹlu rẹ, ṣugbọn o maa n ri i ni dudu fun ọjọ mẹwa ti si maa n ri i ni pupa fun awọn ọjọ yoku, tabi ki o ri i ni kiki fun ọjọ mẹwa ki o si ri i ni sísàn fun ọjọ yoku, tabi ki o ri i fun ọjọ mẹwa ti o ni oorun ẹjẹ nkan oṣù ki o si ri i fun ọjọ yoku laini oorun, to ba ri bẹ́ẹ̀, ẹjẹ nkan oṣù rẹ ni dudu nibi apejuwe àkọ́kọ́, ati kiki nibi apejuwe ẹlẹẹkeji, ati èyí tí o ni oorun nibi apejuwe ẹlẹẹkẹta, èyí tí o ba ti yatọ si iyẹn, ẹjẹ awaada ni;

لِقَوْلِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِفَاطِمَةَ بِنْتِ أَبِي حُبَيْشٍ: «إِذَا كَانَ دَمُ الْحَيْضَةِ فَإِنَّهُ أَسْوَدُ يُعْرَفُ، فَإِذَا كَانَ ذَلِكِ فَأَمْسِكِي عَنِ الصَّلَاةِ، فَإِذَا كَانَ الْآخَرُ فَتَوَضَّئِي وَصَلِّي؛ فَإِنَّمَا هُوَ عِرْقٌ». [رَوَاهُ أَبُو دَاوُدَ وَالنَّسَائِيُّ، وَصَحَّحَهُ ابْنُ حِبَّانَ وَالْحَاكِمُ].

Fún gbolohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti o sọ fun Fātimah ọmọ Abi Hubaysh pe: “Ti o ba jẹ ẹjẹ nkan oṣù dajudaju dudu ti o ni òórùn ni, ti o ba ti wa jẹ ìyẹn kí o yaa ko ara duro nibi Irun ti o ba ti wa jẹ omiran kí o yaa ṣe aluwala ki o si kirun; tori pé iṣan ni”. [Abu Daaud ati An-Nasaaiy ni won gba a wa, Ibnu Hibbaan ati Al-Haakim so pe o ni alaafia] Hadiisi yìí, bi o ti ẹ jẹ wipe akiyesi n bẹ nibi sanadu rẹ ati ọrọ inu rẹ, pẹlu bẹẹ awọn olumọ ṣe amulo rẹ- ki Ọlọhun kẹ wọn- ati pe o daa ju ki a pada sibi ìṣesí ọgọọrọ awọn obinrin lọ.

Ìṣesí Ẹlẹẹkẹta: ki o ma si onka riri ẹjẹ nkan oṣù fun un, ki o si ma ni adayanri kankan ti o dara pẹlu wipe ki ẹjẹ awaada yẹn o jẹ nkan ti n lọ laiduro lati akọkọ ti o ri ẹjẹ, ti ẹjẹ rẹ si wa lori iroyin kan tabi lori awọn iroyin ti ko ni ètò ti ko rọrun ki o jẹ ẹjẹ nkan oṣù. To ba ri bẹ́ẹ̀, eleyii o maa ṣe amulo ìṣesí ọgọọrọ awọn obinrin ti onka ẹjẹ nkan oṣù rẹ o si maa jẹ ọjọ mẹfa tabi ọjọ meje ní gbogbo oṣù, ti yio maa bẹrẹ lati akọkọ igba ti o ri ẹjẹ nibẹ, eyi ti o ba ti wa yatọ si i ẹjẹ awaada ni.

Apejuwe iyẹn ni ki o ri ẹjẹ ni akọkọ igba ti o ri i ni ọjọ karùn-ún ninu oṣù ki o wa maa lọ bẹẹ pẹlu rẹ láìsí adayanri kan ti o le fi jẹ ẹjẹ nkan oṣù, bíi àwọ̀ tabi nkan mìíràn tí ó yàtọ̀ si I; nitori naa ẹjẹ nkan oṣù rẹ o maa jẹ ọjọ mẹfa tabi ọjọ meje ninu gbogbo oṣù ti yio maa bẹrẹ ni ọjọ karùn-ún ninu gbogbo oṣù.

لِحَدِيثِ حَمْنَةَ بِنْتِ جَحْشٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا أَنَّهَا قَالَتْ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، إِنِّي أُسْتَحَاضُ حَيْضَةً كَبِيرَةً شَدِيدَةً، فَمَا تَرَى فِيهَا؟ قَدْ مَنَعَتْنِي الصَّلَاةَ وَالصِّيَامَ، فَقَالَ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أَنْعَتُ لَكِ (أَصِفُ لَكِ اسْتِعْمَالَ) الْكُرْسُفَ (وَهُوَ الْقُطْنُ)، تَضَعِينَهُ عَلَى الْفَرْجِ، فَإِنَّهُ يُذْهِبُ الدَّمَ»، قَالَتْ: هُوَ أَكْثَرُ مِنْ ذَلِكَ. وَفِيهِ قَالَ: «إِنَّمَا هَذِهِ رَكْضَةٌ مِنْ رَكْضَاتِ الشَّيْطَانِ، فَتَحَيَّضِي سِتَّةَ أَيَّامٍ أَوْ سَبْعَةً فِي عِلْمِ اللَّهِ تَعَالَى، ثُمَّ اغْتَسِلِي حَتَّى إِذَا رَأَيْتِ أَنَّكِ قَدْ طَهُرْتِ وَاسْتَنْقَأْتِ، فَصَلِّي أَرْبَعًا وَعِشْرِينَ أَوْ ثَلَاثًا وَعِشْرِينَ لَيْلَةً وَأَيَّامَهَا، وَصُومِي». الْحَدِيثُ. [رَوَاهُ أَحْمَدُ وَأَبُو دَاوُدَ وَالتِّرْمِذِيُّ وَصَحَّحَهُ، وَنُقِلَ عَنْ أَحْمَدَ أَنَّهُ صَحَّحَهُ، وَعَنِ الْبُخَارِيِّ أَنَّهُ حَسَّنَهُ].

Fun hadīth Hamnah ọmọ Jahsh – ki Ọlọhun yọnu si i– wipe dajudaju o sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju emi jẹ ẹnití maa n ri ẹjẹ awaada ti o si pọ gan, ki ni o ri si i? Ko jẹ ki n kirun, ko si jẹ ki n gba aawẹ. Ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ pe: “Maa royin fun ọ lilo Al-Kursuf (oun naa ni òwú) o maa fi lé oju ara rẹ, torí pé o maa da ẹjẹ duro”, o sọ pe: O pọ ju ìyẹn lọ. O wa sọ nibẹ pe: Shaytān ni o fi ẹsẹ̀ gba a ní inú, nitori naa ki o ṣe nǹkan oṣù fún ọjọ mẹfa tabi ọjọ meje ninu imọ Ọlọhun, lẹyin naa ki o wa wẹ titi ti waa fi ri wipe o ti mọra tí o si ti mọ tonitoni, ki o wa ki irun fun ọjọ́ mẹrinlelogun tabi mẹtalelogun, kí o si tun gba aawẹ”. Ahmad ati Abu Daud ati Tirimidhi ni wọn gba a wa, Tirimidhi si sọ pe o ni àlàáfíà, wọn sọ pe Ahmad naa sọ pé ó ni àlàáfíà, Bukhari naa si sọ pé ó dáa.

Gbólóhùn rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe: “Ọjọ́ mẹfa tabi ọjọ meje”, kii ṣe fun sisẹsa, bi ko ṣe wipe fun ṣiṣe igbiyanju ni, nitori naa yio woye si èyí tí o sunmọ julọ si iṣesi rẹ ninu awọn ti o jọ ọ ni ìṣẹ̀dá ti o si sunmọ ọn ni ọjọ-ori ati ibi, ati èyí tí o sunmọ ẹjẹ nkan oṣù julọ ninu ẹjẹ rẹ, ati nkan ti o jọ ìyẹn ninu awọn iwoyesi. Nitori naa ti o ba jẹ wipe èyí tí o sunmọ julọ ni ki o jẹ ọjọ mẹfa yio ṣe e ni ọjọ mẹfa, ti o ba si jẹ wipe eyiti o sunmọ julọ ni ọjọ meje yio ṣe e ni ọjọ meje.

Ìṣesí ẹnití o jọ ẹnití n ri ẹjẹ awaada:

O le ṣẹlẹ si Obinrin okunfa kan ti yio fa ki ẹjẹ o maa san jade ni oju ara rẹ, gẹgẹ bii iṣẹ abẹ ṣiṣe si ile-ọmọ tabi sí ibi tí o sunmọ ọn, eleyii iran meji ni:

"Iran àkọ́kọ́: Ki o mọ pe ko rọrun fun oun lati ṣe nnkan oṣu lẹyin iṣẹ abẹ naa gẹgẹ bii ki iṣe-abẹ naa o jẹ yiyọ apo ibi kuro lódidi tabi ki o di i leyiti o jẹ wipe ẹjẹ o nii da lati ibẹ, iru obinrin yii awọn idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada o nii fi ẹsẹ rinlẹ fun un, bi ko ṣe pe idajọ rẹ ni idajọ ẹniti o ri awọ pupa rusurusu tabi awọ kurukuru (adapọ) tabi itutu lẹyin imọra, nitori naa ko nii fi irun silẹ, kò sì nii fi aawẹ silẹ, ko si nii kọ ibalopọ pẹlu rẹ, iwẹ o si nii jẹ dandan latara ẹjẹ yii, sugbọn fifọ ẹjẹ naa maa jẹ dandan fun un ni asiko gbogbo irun, ati ki o we oju ara pẹlu egige aṣọ kan ati nkan to jọ ọ; lati kọdi jijade ẹjẹ, lẹyin naa yio ṣe aluwala fun irun, ko si nii ṣe aluwala fun un ayaafi lẹyin wiwọle asiko ẹ, ti asiko ba n bẹ fun un, gẹ́gẹ́ bíi awọn irun ọranyan marun-un, bi bẹẹ kọ yio maa ṣe aluwala ni igba ti o bá ti gbero lati ki irun gẹ́gẹ́ bíi nafila ti ko ni àsìkò ati onka. "

"Iran ẹlẹẹkeji: Ki o ma ni imọ nipa idawọduro nnkan oṣu rẹ lẹyin iṣẹ-abẹ, bi ko ṣe pe o rọrun lati ṣe nnkan oṣu, eleyii idajọ rẹ ni idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada, nkan ti n tọka lori nkan ti a darukọ ni ọrọ rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- to sọ fun Fatimah ọmọ Abu Hubaysh:

إِنَّمَا ذَلِكِ عِرْقٌ وَلَيْسَ بِالْحَيْضَةِ، فَإِذَا أَقْبَلَتِ الْحَيْضَةُ فَاتْرُكِي الصَّلَاةَ

“Bi ko ṣe pe iyẹn jẹ ẹjẹ iṣan, ko kii ṣe ẹjẹ nnkan oṣu, ti ẹjẹ nnkan oṣu ba ti wa ki o yaa fi irun silẹ”. " Dajudaju ọrọ rẹ pe: “Ti ẹjẹ nnkan oṣu ba ti wa”, n ṣe anfaani pe dajudaju idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada maa n bẹ fun ẹniti o ni nnkan oṣu to rọrun to ni wiwa ati lilọ, sugbọn ẹniti ko si nnkan oṣu ti o rọrun fun un, ẹjẹ rẹ maa jẹ ẹjẹ iṣan ni gbogbo igba."

"Awọn idajọ ẹjẹ awaada: "

"A ti mọ ninu nnkan to ṣíwájú igba ti ẹjẹ a maa jẹ nnkan oṣu ati igba ti yio maa jẹ awaada, nitori naa igba ti o ba ti jẹ nnkan oṣu awọn idajọ nnkan oṣu maa fi ẹsẹ rinlẹ fun un, igba ti o ba si jẹ awaada awọn idajọ awaada maa fi ẹsẹ rinlẹ fun un. "

"Didarukọ eyi ti o ṣe koko ninu awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu si ti ṣíwájú. "

"Sugbọn awọn idajọ ẹjẹ awaada da bii awọn idajọ mimọ, ko si iyatọ laarin ẹniti n ri ẹjẹ awaada ati awọn to wa ni mimọ afi nibi nnkan ti o n bọ yii: "

Àkọ́kọ́: Ijẹ dandan aluwala fun un fun gbogbo irun kọọkan, "

لِقَوْلِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِفَاطِمَةَ بِنْتِ أَبِي حُبَيْشٍ: «ثُمَّ تَوَضَّئِي لِكُلِّ صَلَاةٍ». رَوَاهُ الْبُخَارِيُّ فِي بَابِ غَسْلِ الدَّمِ.

"Fun ọrọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- to sọ fun Fatimah ọmọ Abu Hubaysh pe: “Lẹyin naa ki o ṣe aluwala fun gbogbo irun kọọkan”. Bukhari ni o gba a wa ni abala fifọ ẹjẹ, " "Itumọ iyẹn ni pe ko nii ṣe aluwala fun irun to ni asiko ayaafi lẹyin wiwọle asiko rẹ. " "Sugbọn ti o ba jẹ irun ti ko ni asiko, o ma maa ṣe aluwala ti o ba ti gbero lati ki i. "

"Ẹlẹẹkeji: Ti o bá ti fẹ ṣe aluwala yio maa fọ oripa ẹjẹ, ti yio si we egige aṣọ kan mọ oju ara lori owu ki ẹjẹ le baa duro; "

لِقَوْلِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِحَمْنَةَ: «أَنْعَتُ لَكِ الْكُرْسُفَ فَإِنَّهُ يُذْهِبُ الدَّمَ». قَالَتْ: فَإِنَّهُ أَكْثَرُ مِنْ ذَلِكَ. قَالَ: «فَاتَّخِذِي ثَوْبًا». قَالَتْ: هُوَ أَكْثَرُ مِنْ ذَلِكَ. قَالَ: «فَتَلَجَّمِي». الْحَدِيثُ.

Fun ọrọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- to sọ fun Hamnah pe: “Maa ṣàlàyé kursufu (owu) fun ọ; nitori pe o maa n da ẹjẹ duro”, o sọ pe: O pọ ju iyẹn lọ, o sọ pe “Lo aṣọ”, o sọ pe: o pọ ju iyẹn lọ, o sọ pe: “We aṣọ mọ ọn ngba naa”. hadiisi, " "Nnkan ti o ba jade lẹyin iyẹn ko nii ko inira ba a; fun ọrọ Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- to sọ fun Fatimah ọmọ Abu Hubaysh pe:"

«اجْتَنِبِي الصَّلَاةَ أَيَّامَ حَيْضِكِ، ثُمَّ اغْتَسِلِي وَتَوَضَّئِي لِكُلِّ صَلَاةٍ، ثُمَّ صَلِّي، وَإِنْ قَطَرَ الدَّمُ عَلَى الْحَصِيرِ». [رَوَاهُ أَحْمَدُ وَابْنُ مَاجَهْ].

Jìnà si irun ni awọn ọjọ ti o fi n ṣe nnkan oṣu rẹ, lẹyin naa ki o wẹ ki o si ṣe aluwala fun irun kọọkan, lẹyin naa ki o kirun, koda ki ẹjẹ kan si ori ẹni”. [Ahmad ati Ibn maajah ni wọn gba a wa]. "

"Ẹlẹẹkẹta: Ibalopọ, awọn onimimọ ti yapa ẹnu nipa lilẹtọọ rẹ ti ko ba paya sina pẹlu gbigbe e ju silẹ, eyi to tọ ni lilẹtọọ rẹ; nitori pe awọn obinrin to pọ ti wọn to mẹ́wàá tabi ju bẹẹ lọ ti wọn rí ẹjẹ awaada ni aye Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti Ọlọhun ati ojisẹ o si kọ ibalopọ pẹlu wọn, " "Bi ko ṣe wipe o wa ninu ọrọ -Ọba ti ọla Rẹ ga- to sọ pe: {Ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù}[Al-Baqarah: 222] ẹri lori wipe ko jẹ dandan lati yẹra fun wọn nibi nkan to yatọ si i; nitori pe irun kiki tọ lati ọdọ rẹ, ibalopọ si fuyẹ ju u lọ, àti pé wiwọn ibalopọ rẹ lori ibalopọ ẹniti n ṣe nnkan oṣu ko ni alaafia; nitori pe awọn mejeeji o ri bákannáà koda lọdọ awọn to sọ pẹ eewọ ni, iṣe afiwọn o si nii ni alaafia pẹlu iyatọ. "

Abala ẹlẹẹkẹfa: Nipa ẹjẹ ibimọ ati idajọ rẹ "

"An-Nifās ni: Ẹjẹ kan ti apo ibi maa n da a latari ibimọ ni, o le jẹ pẹlu rẹ tabi lẹyin rẹ tabi ṣíwájú rẹ pẹlu ọjọ meji tabi ọjọ mẹta pẹlu ìrọbí. "

"Sheikh-l-Islam Ibn Taimiyyah sọ pe: " “Nǹkan ti o ba n ri nígbà tí o ba bẹrẹ si nii n rọbi ni ẹjẹ ibimọ”. Ko si de e pẹlu ọjọ meji tabi ọjọ mẹta, àti pé nnkan ti o gba lero ni: Ìrọbí ti ibimọ o tẹle e, ti ko ba ri bẹ́ẹ̀, ko ki n ṣe ẹjẹ ibimọ. Awọn onimimọ si tun yapa pe: Ǹjẹ́ aala wa fun un nipa eyi to kere julọ ati eyi to pọ julọ?. " Sheikh Taqiyyu-d-deen sọ ninu iwe rẹ to kọ nipa awọn orukọ ti Ọba Aṣofin so awọn idajọ pọ mọ wọn pe (oju ewe:37): “Ẹjẹ ibimọ o ni aala fun eyi to kere julọ nibẹ tabi fun eyi to pọ julọ, ka ni pe wọn kadara ki obinrin ri ẹjẹ fun nkan to ju ogoji tabi ọgọta tabi aadọrin ọjọ lọ ti o wa da, ẹjẹ ibimọ ni, sugbọn ti o ba so pọ, ẹjẹ burúkú ni, nigba naa aala ni ogoji; nitori pe oun ni opin eyiti o pọ ju ti awọn ẹgbawa wa pẹlu ẹ.

Mo sọ pe: Lórí èyí, ti ẹjẹ rẹ ba le si ogoji ọjọ, ti adamọ si n bẹ fun un pẹlu dida rẹ lẹyin rẹ, tabi awọn ami isunmọ dida han nibẹ, o maa duro titi yio fi da, ti ko ba ri bẹẹ yio wẹ ti ogoji ọjọ ba ti pe; nitori pe oun ni eyi to pọ julọ, àyàfi ti o ba ṣe kongẹ akoko nnkan oṣu rẹ, yio wa duro titi ti akoko nnkan oṣu o fi pari, ti o ba ti da lẹyin iyẹn, o tọ ki o da gẹgẹ bi iṣesi fun un, ti o si maa lo o ni ọjọ iwaju,

ti o ba wa tẹsiwaju, o ti di ẹniti n ri ẹjẹ awaada nìyẹn, yio si ṣẹri pada si ibi awọn idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada ti o ti ṣaaju, " Ti obinrin ba mọra pẹlu dida ẹjẹ rẹ, o ti di ẹnití o mọ, koda ko jẹ ṣíwájú ogoji ọjọ, nigba naa yio wẹ yio si kirun yio si gba aawẹ, ọkọ rẹ o si tun maa ba a ni ibalopo, ayaafi kí dida yẹn o ma to ọjọ kan, to ba ri bẹ́ẹ̀, ko si idajọ kankan fún un, o wi i ninu tira Al-Mugniy.

Ẹ̀jẹ̀ ìbímọ ko nii maa fi idi mulẹ ayaafi ti o ba bi nkan ti jijẹ ẹda eeyan fi oju han ninu rẹ, ti o ba wa bi i ni nkan ti o walẹ funra rẹ ti o si kere ti ijẹ ẹda eeyan o si han nibẹ, ẹjẹ rẹ kii ṣe ẹjẹ ibimọ, bi ko ṣe wipe ẹjẹ iṣan ni, idajọ rẹ o si maa jẹ idajọ ẹniti n ri ẹjẹ awaada, igba to kere ju ti ijẹ ẹda eeyan le fi oju han nibẹ ni ọgọrin ọjọ lati ibẹrẹ oyun, èyí tí o si pọ ju ni aadọrun ọjọ.

Al-Majdu Ibnu Taymiyah sọ pe: Igbakigba ti o ba ri ẹjẹ ni ọjọ kan to ṣaaju jijẹ irora ọmọ, ko nii kọ ibi ara si i, ti o ba wa lẹyin rẹ yio ko ara ro nibi irun ati aawẹ, lẹyin naa ti ọrọ ba han lẹyin ti o bimọ ni iyapa si nkan ti o fi ojú hàn yio pada ti yio si da gbogbo nkan ti fi sile pada, amọ ti ko ba han idajọ eyi ti o fi oju han yẹn ni yio maa tẹsiwaju ko si nii si adapada kankan. O gbe e wa lati ọdọ rẹ ninu tira Sharhul ’Iqnā‘.

Awọn idajọ ẹjẹ ibimọ:

Awọn idajọ ẹjẹ ibimọ da gẹgẹ bii awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù ni ọgbọọgba ayaafi nibi awọn nkan ti n bọ yii:

Àkọ́kọ́: Onka ọjọ opo ikọsilẹ pẹlu ikọsilẹ ni wọn o fi woye si i, kii ṣe pẹlu ẹjẹ ibimọ; torí pé dajudaju ti ikọsilẹ ba waye ṣíwájú ibimọ, onka ọjọ opo ikọsilẹ maa pari pẹlu ibimọ kii ṣe pẹlu ẹjẹ ibimọ, amọ ti ikọsilẹ ba waye lẹyin ibimọ yio reti ipada ẹjẹ nkan oṣù gẹ́gẹ́ bí o ti ṣaaju.

Ẹlẹẹkeji: Asiko ’Īlā’u wọn o maa ka asiko riri ẹjẹ nkan oṣù mọ ọn wọn o si nii ka asiko riri ẹjẹ ibimọ mọ ọn.

Al’Īlā’u ni: kí ọkùnrin o bura lori gbigbe ibalopo pẹlu iyawo rẹ ju silẹ titi lailai tabi fún ìgbà tí o le ni oṣù mẹẹrin, ti o ba wa bura ti o (iyawo) si bi i leere fun ibalopo, wọn yio fun un ni gbedeke oṣù mẹẹrin lati igba ti o ti búra, ti o ba ti wa pe, wọn yio fi ipa mu un lati ṣe ibalopo tabi ṣe ipinya pẹlu fifẹ bẹẹ iyawo, ati pe asiko yii ti ẹjẹ ibimọ ba de ba obinrin, wọn o nii ka a mọ ọn, wọn sì maa ṣe afikun lori oṣù mẹẹrin yẹn ni odiwọn igba rẹ (ẹjẹ ibimọ), yatọ sí ẹjẹ nkan oṣù, wọn maa ka igba rẹ fún ọkọ.

Ẹlẹẹkẹta: Bí bàlágà o maa ṣẹlẹ pẹlu riri ẹjẹ nkan oṣù, ti ko si nii maa ṣẹlẹ pẹlu riri ẹjẹ ibimọ; torí pé dajudaju obinrin o le loyun titi ti yio fi maa ri atọ, nitori naa bí bàlágà o maa ṣẹlẹ pẹlu riri atọ ti o maa ṣaaju oyun.

Ẹlẹẹkẹrin: Dajudaju ẹjẹ nkan oṣù ti o ba da, lẹyin naa ni o tun wa pada laarin ìṣesí rẹ, ẹjẹ nkan oṣù ni to daju, gẹ́gẹ́ bíi kí ìṣesí rẹ o jẹ ọjọ mẹjọ, kí o wa ri ẹjẹ fun ọjọ mẹẹrin, lẹyin naa ki o wa duro fun ọjọ meji, lẹyin naa ki o wa pada ni ọjọ keje ati ọjọ kẹjọ, èyí ti o pada yii, ẹjẹ nkan oṣù ni to daju ti awọn idajọ ẹjẹ nkan oṣù si rinlẹ fun un. Àmọ́ ẹjẹ ibimọ, ti o ba da ṣíwájú ogoji ọjọ, lẹyin naa ti o wa pada nínú ogoji ọjọ́ naa, iyemeji wa nibẹ; nítorí naa o jẹ dandan fun un ki o maa kirun ki o si maa gba aawẹ ọranyan to ni asiko ni asiko rẹ, àti pé eewọ ni fun un nkan ti o jẹ eewọ fun ẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù yatọ si awọn nkan ti o jẹ dandan, àti pé yio maa san pada lẹyin ti o ba ti mọra awọn nkan ti o ṣe ninu ẹjẹ yẹn ni awọn nkan ti o jẹ dandan fun ẹniti n ri ẹjẹ nkan oṣù ko san an pada. Eleyii ni o gbajugbaja lọdọ awọn olumọ fiqhu ninu awọn Hanābilah.

Èyí tí o bọ si oju rẹ ni wipe dajudaju ti ẹjẹ ba pada wa ni asiko ti o rọrun ki o jẹ ẹjẹ ibimọ, ẹjẹ ibimọ ni, bi bẹẹ kọ ẹjẹ nkan oṣù ni ayaafi ti o ba n lọ pẹlu rẹ ti ko dawọ duro, nigba naa yio jẹ ẹjẹ awaada.

Èyí sunmọ nkan ti o gbe wa ninu Al-Mugniy lati ọdọ Imām Mālik - ki Ọlọhun kẹ ẹ - l'eyiti o sọ pe: Mālik si sọ pe: “Ti o ba ri ẹjẹ lẹyin ọjọ meji tabi ọjọ mẹta - ìyẹn ni pé: Lẹ́yìn ti o ti da - ẹjẹ ibimọ ni, bi bẹẹ kọ ẹjẹ nkan oṣù ni”. O pari. Oun ni ibamu si nkan ti Shaykhul Islām Ibnu Taymiyah sa l'ẹsa - ki Ọlọhun kẹ ẹ.

Ko si ninu awọn ẹjẹ nkan ti a n ṣe iyemeji ninu rẹ pẹlu ibamu si nkan ti n ṣẹlẹ, ṣugbọn iyemeji yẹn alamọri kan ti o nii ṣe pẹ̀lú nǹkan ti a ba ṣe afiti rẹ si ni, ti awọn eeyan maa n yapa nibẹ ni ibamu si imọ wọn ati agbọye wọn, ati pé o nbẹ ninu Tira Ọlọhun ati Sunnah Anabi alaye gbogbo nkan, àti pe Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ko ṣe ni dandan lori ẹnikẹni ki o gba aawẹ ni ẹẹmeji, tabi ki o ṣe tawāf (pipooyi ile Ọlọhun) ni igba meji, ayaafi ki o jẹ wipe àáyẹ wa nibi alakọkọọ, ti ko si rọrun lati tun un ṣe ayaafi pẹlu si san an pada, amọ ti ẹru ba ti ṣe nkan ti o kapa ninu iwọ ti wọn la bọ ọ lọrun ni ibamu si ìkápá rẹ, ọrùn rẹ ti mọ.

Gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun tí ọla Rẹ ga ṣe sọ:

﴿لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَا...

{Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀.} [Baqorah: 286].

O tun sọ:

﴿فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ...

{Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ} [At-Tagābun: 16].

Iyatọ ẹlẹẹkarun-un laarin ẹjẹ nkan oṣù ati ẹjẹ ibimọ: Níbi ẹjẹ nkan oṣù, ti o ba mọra ṣíwájú ki o to pari ìṣesí rẹ (onka), o lẹ́tọ̀ọ́ fun ọkọ rẹ ki ni ibalopọ pẹlu rẹ laisi ìkórìíra nibẹ, amọ nibi ẹjẹ ibimọ, ti o ba mọra ṣíwájú ogoji ọjọ, wọn koriira fun ọkọ rẹ ko ni ibalopo pẹlu rẹ, ni èyí tí o gbajugbaja ninu ìròrí (Hanābilah), àti pé èyí tí o bọ si oju rẹ ni wipe wọn ko koriira fun un lati ni ibalopo pẹlu rẹ. Oun si ni ọrọ ọgọọrọ awọn olumọ; torí pé dajudaju ìkórìíra, idajọ ofin ẹsin ni ti o si bukaata si ẹri ofin ẹsin. Ko si si ẹri kankan nibi alamọri yii tayọ eyiti Imām Ahmad sọ lati ọdọ Uthmān ọmọ Abil ‘Ās wipe dajudaju iyawo rẹ wa ba a ṣíwájú ogoji ọjọ, o si sọ pe: Má sunmọ mi. Èyí ko sọ ìkórìíra di dandan; torí pé dajudaju o ṣeeṣe ki ìyẹn o wa lati ọdọ rẹ lori ojupọna aibaamọ ni ipaya wipe koi (iyawo re) tii ni amọdaju imọra, tabi ki ẹjẹ o ma lọ wa latari ibalopọ, tabi fun nkan ti o yatọ si iyẹn ninu awọn idi. Ọlọhun lo ni imọ julọ.

Ipin Ẹlẹẹkeje: Nibi lilọ nkan ti o le dẹkun riri ẹjẹ nkan oṣù tabi ti o le fa a wa, ati nkan ti o le dẹkun nini oyun tabi ti o le mu un walẹ.

Ki obìnrin o lo nǹkan ti yio dẹkun riri ẹjẹ nkan oṣù lẹ́tọ̀ọ́ pẹlu majẹmu meji:

Àkọ́kọ́: ki wọn o ma paya inira ti yio ṣẹlẹ si i, ti wọn ba wa paya inira ti yíò ṣẹlẹ̀ si i latara ìyẹn, ko lẹ́tọ̀ọ́.

Fun gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga to sọ pe:

﴿...وَلَا تُلۡقُواْ بِأَيۡدِيكُمۡ إِلَى ٱلتَّهۡلُكَةِ...

{Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun}

[Al-Baqorah: 195].

﴿...وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُمۡ رَحِيمٗا

{Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín} [An-Nisā’i: 29].

Ẹlẹẹkeji: ki iyẹn o jẹ pẹlu iyọnda ọkọ ti o ba ni asopọ pẹlu rẹ, gẹ́gẹ́ bíi ki o jẹ ẹniti n ṣe onka ọjọ opo ikọsilẹ lọdọ rẹ lọna to ṣe wipe nina ọwọ fun un jẹ dandan le e lori, ti yio waa lọ lo nkan ti yio da wiwa ẹjẹ nkan oṣù rẹ duro; ki asiko le baa gun si i, ki inawo rẹ si tun le pọ fún un, nigba naa ko lẹ́tọ̀ọ́ fun un lati lo nkan ti yio kodi wiwa ẹjẹ nkan oṣù ayaafi pẹlu iyọnda rẹ. Bẹẹ naa ni ti o ba rinlẹ wipe dajudaju ki kọdi wiwa ẹjẹ nkan oṣù yio kọdi oyun nini, nigba naa ko si ibuyẹ nibi iyọnda ọkọ, ti o ba ti wa rinlẹ pe o le kọdi oyun, ohun ti o dara ju ni ki á má lò ó, ayaafi ti a ba bukaata si i; torí pé fífi adamọ sílẹ̀ lori bi o ṣe wà ni o sunmọ ki àlàáfíà ati ìlera o wà dáadáa.

Amọ lilo nkan ti yio maa fa ẹjẹ nkan oṣù wa, o lẹ́tọ̀ọ́ pẹlu majẹmu meji bákannáà:

Àkọ́kọ́: ki o ma da ọgbọn lati ti ọranyan kan ṣubú pẹlu rẹ, gẹgẹ bii ki o lo o nígbà tí Ramadan sunmọ, ki o le baa ma gba aawẹ, tabi lati fi ma ki irun, ati nkan ti o jọ ìyẹn.

Ẹlẹẹkeji: ki iyẹn o jẹ pẹlu iyọnda ọkọ; torí pé wiwa ẹjẹ nkan oṣù yio maa kọ fun un kuro níbi igbadun to pe, ko wa lẹ́tọ̀ọ́ lati lo nkan ti yio kọdi ẹtọ rẹ ayaafi pẹlu iyọnu rẹ, ti o ba wa jẹ ẹnití wọn ti kọ silẹ, dajudaju o n bẹ ninu rẹ (lilo nkan ti o le fa ẹjẹ nkan oṣù wa) kikanju ti ẹtọ ọkọ danu nibi ìgbàpadà ti ìgbàpadà ba n bẹ fun un.

Amọ lilo nkan ti o le kọdi oyun nini, iran meji ni:

Àkọ́kọ́: Ki o kọdi rẹ ni ikọdi ti yio maa lọ titi láé, eleyii ko lẹ́tọ̀ọ́; torí pé dajudaju yio da oyun nini duro ti bíbí ọmọ si maa kere, o si yapa si erongba aṣòfin nibi pipọ ijọ Isilaamu; ati pe àwọn ọmọ rẹ ti n bẹ le kú, ti yio waa wa ni opo ti ko nii si ọmọ kankan fun un.

Ẹlẹẹkeji: ki o kọdi i ni ikọdi to ni asiko, gẹ́gẹ́ bíi ki obinrin o jẹ ẹniti maa n ni oyun pupọ, ti oyun si maa n le ni ara rẹ; nitori naa yio jẹ dandan fun un ki o fi eto si oyun rẹ ni ẹẹkan ni gbogbo ọdun meji meji, tabi nkan ti o jọ ìyẹn, eleyii ni ẹtọ, pẹlu majẹmu ki ọkọ o yọnda rẹ fun un, ki o si ma si inira kankan fun un pẹlu rẹ. Ẹri rẹ ni pe awọn Saabe jẹ ẹniti maa n da atọ si ita oju ara awọn iyawo wọn ni igba aye Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - latari ki awọn iyawo wọn o ma baa ni oyún, ti wọn o si kọ fun wọn kuro nibi iyẹn, ati pe nkan ti n jẹ Al‘Azlu ni ki o maa ba iyawo rẹ lopọ ki o wa yọ nkan ọmọkunrin rẹ ni asiko ti o fẹ da atọ, ki o wa da atọ si ita oju ara.

Amọ lilo nkan ti o le mu oyun walẹ, oun naa iran meji ni:

Àkọ́kọ́: ki o gbero bi ba a jẹ nibi mi mu un walẹ, eewọ ni èyí ti o ba jẹ lẹyin fifẹ ẹmi si i, ti ko ni iyemeji; torí pé ipa ẹmi ti o jẹ eewọ lọna aitọ ni, ati pe pipa ẹmi ti o jẹ eewọ, eewọ ni pẹlu tira Ọlọhun ati sunnah Anabi ati ipanupọ gbogbo Musulumi. Amọ ti o ba jẹ ṣíwájú fifẹ ẹmi si i ni, awọn olumọ yapa lori ilẹtọọ rẹ, o si n bẹ ninu wọn awọn ti wọn ṣe e lẹ́tọ̀ọ́, o si tun wa ninu wọn awọn ti wọn kọ ọ, o si tun wa ninu wọn awọn to sọ pe: O lẹ́tọ̀ọ́ ti ko ba tii di ẹjẹ kiki, ìyẹn ni pe: Ti ogoji ọjọ o ba tii re kọja lori rẹ, o si tun wa ninu wọn awọn ti wọn sọ pe: O lẹ́tọ̀ọ́ lopin igba ti ijẹ ẹda eeyan o ba tíì fi ojú hàn nibẹ.

Èyí tí ó fini lọkan balẹ ju ni kikọ kuro nibi mi mu un walẹ ayaafi fun bukaata kan, gẹ́gẹ́ bíi ki iya o jẹ alaisan ti ko si lee fi ara da oyun tabi nkan ti o jọ iyẹn, nigba naa ni mimu un walẹ ni ẹtọ ayaafi ti igba ti o rọrun ki jijẹ ẹda eeyan o ti kọja lori rẹ, to ba ri bẹ́ẹ̀, wọn kọ ọ, Ọlọhun ni O ni imọ julọ.

Ẹlẹẹkeji: ki o ma gbero bi ba a jẹ nibi mi mu un walẹ, bii ki o jẹ ẹniti n gbero mi mu un walẹ nígbà tí asiko oyun ti tan ti àsìkò ibimọ si ti sunmọ, eleyii ni ẹtọ, pẹlu majẹmu ki o ma jẹ wipe inira n bẹ nibẹ fun iya, ati fun ọmọ, ki alamọri naa o si ma bukaata si iṣẹ abẹ, ti o ba bukaata si iṣẹ abẹ ìṣesí mẹẹrin ni n bẹ fun un:

Àkọ́kọ́: Ki iya jẹ ẹniti n sẹmi ki oyun naa si maa sẹmi, ti o ba ri bẹ́ẹ̀, iṣẹ abẹ o lẹ́tọ̀ọ́ ayaafi ti o ba di dandan, gẹ́gẹ́ bíi ki ibimọ rẹ o nira; nitori naa ki o wa bukaata si iṣẹ abẹ, iyẹn ri bẹ́ẹ̀ latari wipe ara jẹ àmàánnà lọdọ ẹru, ko si gbọdọ lo pẹlu rẹ pẹlu nkan ti wọn n paya lara rẹ ayaafi fun anfaani ti o tobi; àti pé dajudaju ó ṣeéṣe ki wọn lero wipe ko si aburu nibẹ ki aburu o si wa nibẹ.

Ẹlẹẹkeji: Ki iya o jẹ oku ki oyun naa si jẹ oku, to ba ri bẹ́ẹ̀, ko lẹ́tọ̀ọ́ ṣiṣe iṣẹ abẹ lati gbe e jáde; tori pé ko ni anfaani.

Ẹlẹẹkẹta: Ki iya o jẹ ẹni ti n sẹmi ti oyun si jẹ oku, to ba ri bẹ́ẹ̀, o lẹ́tọ̀ọ́ ṣiṣe iṣẹ abẹ lati gbe e jáde, ayaafi ti wọn ba n paya inira lori iya; torí pé nkan ti o fi ojú hàn - Ọlọhun ni O si ni imọ julọ - ni pé dájúdájú ti oyun ba ti ku ko sunmọ ki o jade lai ṣe iṣẹ abẹ, ki o wa maa wa bẹẹ ninu ikun rẹ yio maa kọdi rẹ nibi oyun ti n bọ, yio si tun maa ni i lara, àti pé o ṣeeṣe ki o maa bẹ l'ẹniti ko nii ni ọkọ ti o ba jẹ ẹniti n ṣe opo ọkọ to ṣaaju.

Ẹlẹẹkẹrin: Ki iya o jẹ oku ki oyun si maa sẹmi, ti o ba jẹ wipe wọn o rankan yiye rẹ, ko lẹ́tọ̀ọ́ ṣiṣe iṣẹ abẹ.

Amọ ti wọn ba n rankan yiye rẹ, ti o ba jẹ wipe apa kan rẹ ti jade wọn o la inu iya lati gbe eyiti to ku rẹ jade, ti ikankan o ba si tii jade ninu rẹ awọn eeyan wa - ki Ọlọhun kẹ wọn - ti sọ pe: Wọn o nii la ikun iya lati gbe e jade; tori pé iṣeni ni ìṣekúṣe ni, eyiti o wa bọ soju rẹ ni pe dajudaju wọn yio la ikun ti jijade rẹ o ba le waye lai si i. Eyi ni ohun tí Ibnu Hubayrah ṣẹsa, o sọ ninu tira Al’Insōfu pe: Òun ni o leke ju.

Mo sọ pe: Pàápàá julọ ni akoko ti a wa yii, dajudaju ṣiṣe iṣẹ abẹ kii ṣe iṣeni-ni-iṣekuṣe; torí pé dajudaju wọn maa la ikun lẹyin naa wọn o si ran an pada, ati pe dajudaju ini ọ̀wọ̀ alaaye tobi ju ini ọ̀wọ̀ oku lọ; àti pé lila ẹniti a n sọ kuro nibi iparun dandan ni, oyun si nìyí, eeyan ti a n sọ ni; tori pe dandan ni ki a la a. Ọlọhun ni O ni imọ julọ.

Akiyesi: Nibi awọn iṣesi ti ṣiṣẹ oyun ti lẹ́tọ̀ọ́ nibẹ ninu nnkan to ṣaaju, ko si ibuyẹ nibi gbigba iyọnda ẹniti o ni oyun nibi iyẹn gẹgẹ bii ọkọ. "

Ibi ni nnkan ti a gbero lati kọ pari si nipa akori ọrọ pataki yii, a si ti ṣe e ni ṣoki ninu rẹ lori awọn ipilẹ ọrọ ẹsin ati awọn ofin rẹ, bi ki ba ṣe bẹẹ ni, awọn ẹka rẹ ati awọn ifọsiwẹwẹ rẹ, ati nnkan ti o n ṣẹlẹ si awọn obinrin ninu ìyẹn jẹ agbami kan ti ko ni bèbè etíkun. Sugbọn ẹniti o ba ni imọ amọdaju maa ni ikapa lati da awọn ẹka pada si awọn ipilẹ rẹ, ati lati da awọn ẹyọ pada si awọn odindi rẹ, ati awọn ofin rẹ, ti yio si maa wọn awọn nnkan pẹlu awọn iru wọn. "

"Ki oluṣẹ idajọ ẹsin lọ mọ pe oun ni alagata laarin Ọlọhun ati awọn ẹda Rẹ nibi imu nnkan ti Ojisẹ Rẹ mu wa de ogongo, ati ṣiṣe alaye rẹ fun awọn ẹda, ati pe oun ni ẹniti wọn o maa bi nipa nnkan to wa ninu iwe Ọlọhun ati ilana Anabi; nitori pe mejeeji ni ipilẹ meji to ṣe pe wọn ṣe agbọye mejeeji ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu wọn ni dandan fun ẹrusin Ọlọhun, " Gbogbo nnkan to ba yapa iwe Ọlọhun ati ilana Anabi aṣiṣe ni, dida a pada sọdọ ẹniti o sọ ọ jẹ dandan, ti ṣiṣe iṣẹ pẹlu ẹ ko si lẹ́tọ̀ọ́, bo ti lẹ jẹ wipe ẹniti o sọ ọ lẹ jẹ ẹniti o ni awijare ti o jẹ olugbinyanju ti wọn o si san an lẹsan igbiyanju rẹ, sugbọn ẹniti o yatọ si i ti o si mọ nipa aṣiṣe rẹ ko lẹ́tọ̀ọ́ fun un lati gba a wọle."

"O jẹ dandan fun oluṣe-idajọ-ẹsin (mufti) lati mọ aniyan kanga fun Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ati lati maa wa iranlọwọ pẹlu Rẹ nibi gbogbo iṣẹlẹ ti o ba n ṣẹlẹ si i, ki o si maa tọrọ lọdọ Rẹ -ti ọla Rẹ ga- iduroṣinṣin ati iṣe kongẹ eyiti o tọ "

O jẹ dandan fun un lati jẹ pe ki aye iwoyesi rẹ jẹ nnkan to wa ninu iwe Ọlọhun ati ilana Anabi, ti yio waa maa woye ti yio si maa ṣe ìwádìí nibẹ, tabi ninu nnkan ti wọn maa wa ikunlọwọ pẹlu rẹ ninu ọrọ àwọn onimimọ lori agbọye mejeeji."

Àti pé lọpọ igba ni ọrọ kan le waye ninu awọn ọrọ ẹsin, ti ọmọnìyàn o si maa ṣe ìwádìí nipa rẹ nibi nǹkan to ni ikapa rẹ ninu ọrọ awọn onimimọ, lẹyin naa ko nii ri nnkan ti ẹmi rẹ o balẹ si i nibi idajọ rẹ, o si ṣee ṣe ki o ma ri ọrọ kankan fun un rara, ". "Ti o ba wa pada sinu iwe Ọlọhun ati ilana Anabi, idajọ mejeeji yio han si i ni nnkan to sunmọ to si fojuhan, ìyẹn ni ìbámu si imọkanga ati imọ ati agbọye. "

"O jẹ dandan fun oluṣẹ idajọ ẹsin siṣe pẹlẹ nibi idajọ nigba iruju, ko si ma ṣe kánjú, melomelo idajọ to kanju nibẹ, lẹyin naa ni o wa han si i lẹyin iwoyesi ranpẹ pe oun ṣe aṣiṣe nibẹ, ti yio wàá ka abamọ lori rẹ, ti o si ṣee ṣe ki o ma kapa lati le nnkan to ti ṣe idajọ rẹ ba mọ!. "

Àti pé ti awọn ba ti mọ pẹlẹpẹlẹ ati ifidi-ọrọ-mulẹ mọ oluṣẹ idajọ ẹsin, wọn yio fi ọkan tan ọrọ rẹ, wọn si maa ka a kun, ti wọn ba wa ri i ni oluyara (nibi ṣiṣe idajọ ọrọ ẹsin), ti oluyara si maa n pọ ni aṣiṣe, wọn o nii ni ifọkantan si nnkan to ba dajọ pẹlu rẹ, yio waa di - pẹlu iyara rẹ ati aṣiṣe rẹ - ẹniti o ti kọ fun ara rẹ to si tun kọ fun ẹlòmíràn nnkan ti o n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ ati nnkan ti o tọna. "

A n beere lọdọ Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- lati fi awa ati awọn ọmọ-iya wa to jẹ musulumi mọna lọ sí oju-ọna Rẹ to duro tọ, ki O si kun wa lọ́wọ́ pẹlu akolekan Rẹ, ki O si ṣọ wa nibi awọn aṣiṣe pẹlu àmójútó Rẹ, dajudaju Oun ni Ọlọrẹ Alapọn-ọnle; -ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati ọla fun Anọbi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ lapapọ. Ọpẹ ni fun Ọlọhun ti o ṣe pe pẹlu idẹra Rẹ ni awọn daada fi maa n pe. "

"O parí lati ọwọ ẹniti n bukaata si Ọlọhun".

"Muhammad Solih Al-Uthaymīn"

"Ni iyalẹta ọjọ Jimọh"

"Ọjọ kẹrinla oṣu Sha‘ban ọdun 1392 A.H "

 

 

 

***

Index

 

Ipin àkọ́kọ́: Nibi itumọ Al-Haydu (ẹjẹ nkan oṣù) ati ọgbọn ti n bẹ nibẹ. 4

Ipin keji: Nibi igba riri ẹjẹ nkan oṣù ati asiko rẹ. 5

Ìpín kẹta: Nípa awọn nǹkan ti maa n ṣẹlẹ̀ sí ẹjẹ nkan oṣù lójijì. 14

Orí kẹrin: Nípa awọn idajọ nnkan oṣu" 18

Ipin karun: Nibi ẹjẹ àwáàdá ati awọn idajọ rẹ. 36

Abala ẹlẹẹkẹfa: Nipa ẹjẹ ibimọ ati idajọ rẹ " 44

Ipin Ẹlẹẹkeje: Nibi lilọ nkan ti o le dẹkun riri ẹjẹ nkan oṣù tabi ti o le fa a wa, ati nkan ti o le dẹkun nini oyun tabi ti o le mu un walẹ. 49

 

***

 

 

yo130v1.0 - 07/07/2026