مَا لَا يَسَعُ المُسْلِمَ جَهْلُهُ
Nnkan ti kòyẹ kí Musulumi má mọ ọn
اللَّجْنَةُ العِلْمِيَّةُ
بِرِئَاسَةِ الشُّؤُونِ الدِّينِيَّةِ بِالمَسْجِدِ الحَرَامِ وَالمَسْجِدِ النَّبَوِيِّ
Ìgbìmọ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lábẹ́ ìdarí ati ìṣàkóso àwọn olùmójútó ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní Mọ́ṣáláṣí Haram Makkah àti Mọ́ṣáláṣí Anabi
بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ
Nnkan ti kòyẹ kí Musulumi má mọ ọn
Ọrọ itisiwaju
Ọpẹ ni fun Ọlọhun Ọba gbogbo agbaye, ikẹ ati ọla ki ó máa bá ẹni tí a rán ní iṣẹ́ ki ó máa jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo àgbáyé, ikẹ ati ọla naa ki ó máa bá awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ (ọmọ lẹyìn rẹ akọkọ) ati ẹni tí ó bá tẹle ìlànà rẹ, tí ó sì mọna pẹlu ìtọ́sọ́nà rẹ titi di ọjọ ẹsan, lẹ́yìn náà:
Eleyi ni àkori ọrọ ní ṣókí, tí ó kó àwọn ohun pàtàkì tí Musulumi ní bukaata sí sínú níbi adisọkan rẹ̀, ìjọsìn rẹ̀, àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀, a ṣàá jọ fún àwọn olùṣàbẹ̀wò lọkùnrin àti lobìnrin sí Haram mejeeji (Haram Makkah ati Haram Madina) kí wọ́n lè ní ìmọ̀ àti òye nípa àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn, a ń retí lọ́dọ̀ Ọlọhun Alápọnle Olóore pé kí Ó fi ṣe àǹfààní, kí Ó sì ṣe é ní iṣẹ́ rere, kí ó sì jẹ́ nítorí Ojú rere Rẹ̀ nìkan, dájúdájú Òun ni Ẹni tí ó dára jùlọ tí a lè bèrè lọ́wọ́ Rẹ̀, àti Alapọnle jùlọ tí a lè ní ìrètí sí.
***
Ni orukọ Ọlọhun, Ọba Ajọkẹ aye, Ọba Aṣakẹ ọrun.
Ipinpin alakọkọ
Ohun tó jẹmọ́ Adisọkan
Iwadii alakọkọ: ìtumọ̀ Isilaamu àti àwọn origun rẹ̀:
Isilaamu : ni Jijuwọ-jusẹ silẹ fun Ọlọhun pẹlu gbigba A lọkan ṣoṣo, ati gbigba fun Un pẹlu itẹle aṣẹ Rẹ̀, ati ibọpa-bọsẹ kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹlẹbọ.
Awọn origun rẹ sì jẹ marun-un:
Akọkọ: Jijẹrii wipe ko si ẹni tí ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allahu, ( Ọlọhun ) ati pe dajudaju Muhammad òjíṣẹ́ Rẹ ni ṣe .
Ẹlẹẹkeji: Gbígbé Irun dúró.
Ẹlẹẹkẹta: Yiyọ saka.
Ẹlẹẹkẹrin: Gbígba Aawẹ Ramadan.
Ẹlẹẹkarun: Ṣíṣe Hajj, èyí ni ṣíṣe àbẹwò sí Ilé Ọlọ́hun fún ẹni tí ó bá ní ikapa ọ̀nà láti lọ.
Pataki imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo:
Mọ̀ dájú pé dájúdájú Ọlọ́hun ṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá kí wọ́n le jọ́sin fún Un, kí wọ́n sì má mu orogún kankan pẹ̀lú Rẹ̀. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَمَا خَلَقۡتُ ٱلۡجِنَّ وَٱلۡإِنسَ إِلَّا لِيَعۡبُدُونِ 56﴾
{Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi}. [Suuratudh Dhāriyāt: 56], Mimọ ijọsin yìí kolee rọrun ayaafi pẹlu ìmọ̀, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿فَٱعۡلَمۡ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مُتَقَلَّبَكُمۡ وَمَثۡوَىٰكُمۡ 19﴾
{Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùgbé yín}. [Surah Muhammad: 19], Ó sì bẹrẹ pẹlu ìmọ̀ ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ. Ohun pàtàkì jùlọ tí ó jẹ dandan fún Musulumi láti kọ́ ni ìmú Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo; nítorí pé òun ni ìpìlẹ àti gbòǹgbò ẹsin, Ẹsin kò leè dúró àyàfi pẹlu ìmú Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo, èyí sì ni ojúṣe ọranyan akọkọ fún Musulumi, òun sì ni ojúṣe ọranyan ìgbẹ̀yìn. Imú Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo ni origun akọkọ nínú àwọn origun Islam tí o jẹ ọranyan fún gbogbo Musulumi láti mọ̀ wọ́n àti láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn, wọ́n sì jẹ́ origun márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá nínú hadith Abdullahi ọmọ Umar ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji, o sọ pé: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ ati igẹ Ọlọhun maa ba a- nsọ pe:
«بُنِيَ الإسْلَامُ عَلَى خَمْسٍ: شَهَادَةِ أنْ لَا إلَهَ إلَّا اللَّهُ وأنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ، وَإقَامِ الصَّلَاةِ، وَإيتَاءِ الزَّكَاةِ، وَحَجِّ البَيْتِ، وصَوْمِ رَمَضَانَ».
«Wọ́n mọ Islaam pa lórí nǹkan márùn-ún: ìjẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọsìn ododo tọ́ sí àyàfi Allāhu, àti pé dájúdájú Muhammad òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, àti gbígbé irun dúró, àti yíyọ Zakah, àti ṣíṣe Hajj sí Ilé Ọlọ́run, àti gbígba ààwẹ̀ Ramadān»1.
O jẹ dandan fún Musulumi kí o kọ ìtumọ At-Taohīd;( imú Ọlọhun ní ọkan ṣoṣo) oun ni imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin, Kí ó má ṣe fi orogún papọ mọn Ọlọhun níbi ìjọsìn fún Un; ki baa jẹ iransẹ tí o sunmọ Ọlọhun tàbí anọbi tí wọ́n ranṣẹ .
Itumọ jijẹrii pe ko si ọlọhun ti ijọsin tọsi afi Allahu:
Oun ni pe ki ẹru kan fi rinlẹ pẹlu adisọkan tó duro sinsin pe dajudaju ko si ẹni ti a le jọsin fun lododo afi Ọlọhun. Kí ó jọsin fun Ọlọhun ní Oun nìkan ṣoṣo, kí ó sì ya A sọ́tọ̀ pẹ̀lú gbogbo oríṣiríṣi àwọn ìjọsìn; gẹ́gẹ́ bíi adua, ati ìbẹ̀rù, ati ìrètí, ati ìgbẹ́kẹ̀lé, ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ijẹrii ko lee wa si imuṣẹ ayafi pẹlu origun meji:
Akọkọ: Sísẹ aláìsí ipò-ọlọ́hun àti ijọsin fún ohun gbogbo yàtọ̀ sí Ọlọ́hun, nínú gbogbo àwọn orogún, àwọn òrìṣà, àti àwọn Tágúùtì.
Èkejì: Jíjẹ́rìí sí ìjẹ́-Ọlọ́hun àti ìjọsìn ododo fún Allah, Oun nìkan ṣoṣo, yàtọ̀ sí ohun mìíràn, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَلَقَدۡ بَعَثۡنَا فِي كُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولًا أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱجۡتَنِبُواْ ٱلطَّٰغُوتَ...﴾
{Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” } [Suratul Nahl: 36].
Ẹẹ wa ri awọn majẹmu (laa ilaaha illa Allāhu) oun ni:
Akọkọ: Imọ ti o lodi si aimọkan.
Ẹlẹẹkeji: Ìdánilójú tí ó pa ìyè méjì rẹ́.
Ẹlẹkẹta: Imọkanga tí ó lòdì sí Ṣiriki (ẹbọ ṣíṣe)
ẸIẹkẹrin: Ododo ti o lodi si irọ.
Ẹlẹẹkarun: Inifẹ tí ó lodi si ìkórira.
Ẹlẹkẹfa: Ìtẹríba tí ó pa gbígbéjùsílẹ̀ rẹ́.
Ẹlẹẹkeje: Gbígbà tí ó lòdì sí dídápadà.
ẸIẹkẹjọ: Sise aigbagbọ si gbogbo ohun ti a n jọsin fun yatọ si Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
Awọn majẹmu wọnyi dandan ni ki a ṣiṣẹ pẹlu wọn, ati pe wọn ti ko wọn jọ sinu ile orin meji ti n bọ yii:
Imọ ati amọdaju ati imọkanga ati ododo rẹ pẹlu ifẹ ati ijupa-jusẹ silẹ ati itẹwọgba a.
Wọn wá ṣe àlékún rẹ̀ sí mẹ́jọ tí ó jẹ́ iṣẹ́ kèfèrí rẹ sí gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ti ń jọ́sìn fún yàtọ̀ sí Allāhu.
Mimu ijẹrii ṣẹ yio jẹ pẹlu jijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati nini imọkanga si ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, nitori naa kò gbọdọ pe ẹnìkankan àyàfi Ọlọhun, ko si gbọdọ gbẹkẹle ẹnìkankan àyàfi Ọlọhun, ko si gbọdọ ran kan nnkan lọdọ ẹnìkankan àyàfi Ọlọhun, ko si gbọdọ kirun fún ẹnìkankan àyàfi fún Ọlọhun, ko si gbọdọ dúnbu ẹran fún ẹnìkankan àyàfi fún Ọlọhun, Ẹni tí ó mọ́, tí ọlá Rẹ̀ sì ga.
Nitori naa, nnkan ti awọn eeyan kan n ṣe gẹgẹbi rírọkiriká àwọn sàréè, ati wiwa iranlọwọ pẹlu awọn oku, ati kikepe wọn yàtọ̀ sí Ọlọhun; ẹbọ ni ninu ijọsin, Nitori naa, ọranyan ni kí a ṣọra kuro nibi iyẹn, kí a si ṣe ìkìlọ̀ nipa rẹ; nitori pe èyí jẹ́ irú iṣẹ́ àwọn olùṣẹbọ̀ nípa jíjọsin fún àwọn òrìṣà, àwọn òkúta, àti àwọn igi dipo Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, òun ni dida orogun pọ mọ Ọlọhun èyí tí a sọ àwọn iwe kalẹ̀, tí a sì rán àwọn Òjíṣẹ́ fún ṣíṣe ìkìlọ̀ kúrò nínú rẹ̀ àti kíkọ̀ rẹ̀.
Ìtumọ jijẹri wipe Muhammad òjíṣẹ Ọlọhun ni:
Titẹle e níbi ohun tí ó pa láṣẹ, gbigba a l'ododo níbi ohun tí ó sọ, jíjìnnà sí ohun tí ó kọ̀ tí ó sì tún léni jìnà sí i, àti pé kí a má jọ́sìn fún Ọlọ́hun ayaafi pẹ̀lú ohun tí Ó ṣe ní òfin. Musulumi ní lati fi rinlẹ pe dajudaju Muhammad ọmọ Abdullah tí o wa láti ìdíle Al-Quroshiyy Al-Haashimiyy: Ojiṣẹ Ọlọhun ni - ti ọla Rẹ ga- si gbogbo awọn ẹda pátá; nínú àwọn àlùjọ̀nú àti àwọn ènìyàn, gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡ جَمِيعًا...﴾
{Sọ pé: “Mo pé ẹyin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu ( Ọlọhun ) sí gbogbo yín pátápátá... } [Suratul A'raf: 158].
Ati pe Ọlọhun ran an láti kéde ẹsin Rẹ̀ ati láti tọ́ àwọn ẹda sọ́nà, gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe wi pe:
﴿وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ28﴾
{A kò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; ni oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀ bẹ}. [Suratu Sabai: 28]. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun tí Ọlá Rẹ ga ti sọ pé:
﴿وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا رَحۡمَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ 107﴾
{A kò rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo aye}. [Suuratul Anbiyaah: 107].
Ati pe nkan ti ijẹrii yii da lẹjọ ni pé: ki o maṣe ni lọ́kàn pe ojiṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a - ni ẹtọ kan ninu ijẹ́ Olúwa ati iṣakoso lori gbogbo agbaye, tabi ẹtọ kan ninu ijọsin, Dipo bẹẹ, ẹru ni - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wọn ko gbọdọ jọsin fun un, ati pe ojiṣẹ ni ti wọn ko gbọdọ pe e ni opurọ, Ati pe kò ní ìkápá ànfàní àti ìnira kankan fúnra rẹ tàbí fún ẹlòmíràn, àfi ohun tí Ọlọhun bá fẹ́. Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿قُل لَّآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ إِنِّي مَلَكٌۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ...﴾
{Sọ pé: “Èmi kò sọ fún yín pé àwọn apẹpé -ọrọ̀ Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fún yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí (:ibani sọrọ) ” } [Suratul An'am: 50].
Iwadii ẹlẹẹkejì: ìtumọ̀ Ìgbàgbọ́ ati awọn origun rẹ̀:
Igbagbọ: Oun ni fifi rinlẹ pẹlu ọkan, ati sisọ pẹlu ahọn, ati iṣẹ ọkan ati awọn oríkèé ara, a maa lekun pẹlu itẹle aṣẹ Ọlọhun, a si maa dinku pẹlu ìyapa Ọlọhun.
Igbagbọ jẹ majẹmu fun dídára ati itẹwọgba awọn ijọsin, Gẹgẹbi o se jasi pe ẹbọ ati aigbagbọ maa n ba gbogbo awọn iṣẹ ijọsin jẹ, Gẹgẹ bi o se jasi pe Ọlọhun kò ní gba irun láì sí aluwala, bẹẹni kò níí gba ìjọsìn láìní ìgbàgbọ. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ نَقِيرٗا 124﴾
{Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí fi (òdiwọ̀n) àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn}. [Suuratun Nisāi: 124].
O si ṣe alaye pe ẹbọ n ba iṣẹ jẹ, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pé:
﴿وَلَقَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ لَئِنۡ أَشۡرَكۡتَ لَيَحۡبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 65﴾
{Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ (pé) “Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, dájú dájú iṣẹ́ rẹ yóò bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.” } [Az-Zumar:65].
Awọn origun igbagbọ mẹfa ni: Ìní Igbagbọ sí Ọlọhun, ati awọn malaaikah Rẹ, ati awọn tira Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati kadara; ( eto Ọlọhun lórí gbogbo nkan tí o da ) èyí ti o daa nibẹ ati èyí ti o buru.
1) Nini igbagbọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kó awọn nkan mẹta kan sinu:
1- Nini igbagbọ is ijẹ Oluwa Rẹ:
Oun ni ṣiṣe Ọlọhun lọ́kan níbi àwọn iṣẹ Rẹ̀; gẹ́gẹ́ bíi ṣíṣẹ̀dá, àti pípèsè, àti ifunni ní isẹmi, àti pípa ni, Ko si Aṣẹ̀dá kankan afi Allahu (Ọlọhun ) , kò si Olupese kankan afi Allahu, kò si Asọni-dààyè kankan afi Allahu, kò si Asọni-di-òkú kankan afi Allahu, kò si si ẹni ti o n ṣàkóso ninu àgbáyé afi Oun, mimọ ni fun Un, Ọba ti ọla Rẹ ga.
A kò mọ ẹni kankan ninu ẹda ti wọn tako ijẹ Olúwa Ọlọhun- mimọ ni fun Un-, afi ko jẹ oní moto moto ti ko ni adisọkan nnkan ti o n sọ, Gẹgẹ bi o ṣe ṣẹlẹ si Fìrìáónà, nígbàtí o sọ fún awọn ìjọ rẹ pe:
﴿...أَنَا رَبُّكُمُ الْأَعْلَى﴾
{Èmi ni olúwa yín, ti o ga jùlọ. [Suuratun Nāziāt: 24], Ṣugbọn èyí tí o sọ un ko ti ibi adisọkan jáde, gẹgẹ bí Ọlọhun Ọba ti ọlá Rẹ ga ti sọ nípa Anọbi Musa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pe:
﴿قَالَ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَآ أَنزَلَ هَٰٓؤُلَآءِ إِلَّا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ بَصَآئِرَ وَإِنِّي لَأَظُنُّكَ يَٰفِرۡعَوۡنُ مَثۡبُورٗا 102﴾
{ (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Dájúdájú èmi náà lérò pé ẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon.” } [Al-Isrā’: 102], Ọlọhun Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنْفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا... ﴾
{Wọ́n fi àbòsí àti ìgbéraga takò ó, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni}. [An-Nam'l: 14].
Dajudaju awọn ẹda wọnyi ko gbọdọ ma ni Aṣẹda, Nítorí pé ko rọrun ki wọn mu ara wọn bẹ funra wọn; nitori pe nnkan ko le ṣẹda ara rẹ, ti ko si rọrun ki o maa bẹ ní ti ṣèèṣì; nitori pe gbogbo nnkan ti o ba n bẹ, dandan ni ki o ni ẹni ti o maa mu u bẹ, Torí pé bibẹ wọn lórí ètò ti o rẹwa yii ati ìbámu ti o se deede yii, eyi maa kọ̀ ki bibẹ wọn o ṣèèṣì, o di dandan ki wọn ni ẹni tí o maa mu wọn maa bẹ, Oun naa ni Allahu Oluwa awọn ẹda, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿أَمۡ خُلِقُواْ مِنۡ غَيۡرِ شَيۡءٍ أَمۡ هُمُ ٱلۡخَٰلِقُونَ 35 أَمۡ خَلَقُواْ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۚ بَل لَّا يُوقِنُونَ 36﴾
{Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn látara aisi nkankan? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni}. [At-Tūr: 35-36].
Àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ìjẹ Olúwa Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- rinlẹ, pẹlu ida nnkan papọ pẹlu Rẹ nibi ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si, èyí kò sì mú wọn wọ inú Islam. Anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si ba wọn jagun, o si sọ ẹjẹ wọn ati dukia wọn di ẹ̀tọ́; nítorí pé wọ́n mu orogun mọ Ọlọhun nínú ìjọsìn, Wọn si jọsin fun ẹlòmíràn papọ mọ Ọn; gẹgẹ bi àwọn ère, àwọn òkúta, àwọn Mọlaika ati àwọn mìíràn.
2- Nini ìgbàgbọ́ nínú níní ẹtọ sí ìjọsìn Rẹ:
Nini igbagbọ pẹlu ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si, o n túmọ̀ si pe: Dájúdájú Oun nikan ṣoṣo ni Ọlọhun ododo ti ko si orogun fun Un, (Al-Ilaahu) n túmọ̀ si (Al-Mahluuh), o n túmọ̀ si (Ẹni ti a n jọsin fun) ni ti ifẹ ati igbetobi ati ìtẹríba.
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ 163﴾
{Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run}. [Baqara: 163].
Gbogbo ẹni ti o ba mu Ọlọhun kan pẹlu Allahu, ti o n jọsin fun un yatọ si I; nini igbagbọ ninu ijẹ ẹni ti ijọsin ododo tọ si rẹ ti bajẹ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ 62﴾
{Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi}. [Hajj: 62].
Nitori idi eyi ni awọn ojiṣẹ (ikẹ Ọlọhun maa ba wọn) láti ọdọ Nuh titi de Muhammad (ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) ṣe n pe awọn ìjọ wọn síbi imu Ọlọhun lọkan ati sisin In ni Oun nikan ṣoṣo láì mu orogun mọ Ọn, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti ba nini ti awọn ọ̀ṣẹbọ ni awọn òrìṣà jẹ́, ti wọn n jọsin fun wọn pẹlu Ọlọhun- mimọ ni fun Un ti ọla Rẹ ga-, ti wọn si n wa àrànṣe pẹlu wọn, ti wọn si n wa iranlọwọ wọn, ìyẹn si jẹ́ pẹlu awijare ti laakaye méjì:
Akọkọ: Dajudaju ko si nnkankan ninu awọn nnkan ẹsa ini ẹtọ si ijọsin ododo lara awọn òrìṣà ti wọn mu yii, nnkan ti wọn da ni wọn, wọn ko lee da ẹda, ti wọn ko lee wa anfaani fun awọn olùjọsìn fún wọn, ti wọn ko lee mu inira kuro fun wọn, ti wọn ko si ni ikapa lori iṣẹmi, tabi iku, tabi ajinde, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗ لَّا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ وَلَا يَمۡلِكُونَ لِأَنفُسِهِمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا وَلَا يَمۡلِكُونَ مَوۡتٗا وَلَا حَيَوٰةٗ وَلَا نُشُورٗا 3﴾
{Àwọn aláìgbàgbọ́) ti mú awọn nnkan míràn yatọ sí Ọlọhun Allahu ni ọlọhun keekeke, àwọn tí kò lè dá nnkankan, A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde}. [Suuratul Fur’qaan: 3].
Ikeji: Dajudaju awọn ọ̀ṣẹbọ yii fi rinlẹ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni Adẹda Oludari-aye ni Oun nikan ṣoṣo, eleyii n ṣe e ni dandan fún wọn lati mu U ni ọkan ṣoṣo nibi títọ si ijọsin gẹgẹ bi wọn ṣe mu U ni ọkan ṣoṣo nibi ijẹ Oluwa fún gbogbo nkan, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe wi pe:
﴿قُل لِّمَنِ ٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهَآ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 84 سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ85 قُلۡ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلسَّبۡعِ وَرَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ 86 سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ 87 قُلْ مَنْ بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيْهِ إِنْ كُنْتُمْ تَعْلَمُونَ 88 سَيَقُولُونَ لِلَّهِ قُلْ فَأَنَّى تُسْحَرُونَ 89﴾
{Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti awọn tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu Ọlọhun ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?”
Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?” 86
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba àti ìkápá ọlá gbogbo nǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”88
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?” } [Surah Al-Mu’minûn: 84-89] Ti wọ́n bá ti jẹ́wọ́ Taoheedur-Rubuubiyyah; (imú Ọlọhun ní Olúwa gbogbo nkan) ó pọn dandan fún wọn kí wọ́n ya Ọlọ́hun -mímọ́ ni fún Un- sọ́tọ̀ pẹ̀lú ìjọsìn ní Oun nìkan ṣoṣo, kí wọ́n má sì ṣe fi ẹnikẹ́ni ṣe akẹgbẹ́ Rẹ̀ nínú ìjọsìn fun Un.
3- Nini igbagbọ pẹlu awọn orukọ ati awọn iroyin:
O n túmọ̀ si: Fifi nnkan ti Ọlọhun fi rinlẹ fun ara Rẹ rinlẹ ninu iwe Rẹ tii se Al-qurani. Tàbí èyí tí ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, fi rinlẹ fún Un nínu Sunna rẹ̀; nínú àwọn orúkọ àti àwọn ìròyìn, lọna to yẹ, tí o sì tọ sí Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga-, laisi ayipada tabi sisọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, Lai sí àpèjúwe, tàbí sise àfiwé, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَلِلَّهِ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ فَٱدۡعُوهُ بِهَاۖ وَذَرُواْ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ أَسۡمَٰٓئِهِۦۚ سَيُجۡزَوۡنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 180﴾
{Ti Allāhu Ọlọhun ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn tó ń darí àwọn orúkọ Rẹ̀ kọ ọ̀nà òdì tì. A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́}. [Al-A'raaf: 180], Ọlọhun Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ﴾
{Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran}. [Suuratu Shuuroh: 11].
Ọnàn mẹta ni ẹbọ Pin si:
1- Ẹbọ ńlá.
2- Ẹbọ kekere.
3- Ẹbọ tí ó pamọ.
1- Ẹbọ ńlá:
Àkoṣo rẹ ni: ṣiṣe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun ni dọgbandọgba pẹlu Ọlọhun nibi awọn ohun tó jẹ́ ẹ̀ṣà fun Ọlọhun. Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe wí pe:
﴿إِذۡ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 98﴾
{nígbà tí a fi nyín ṣe akẹgbẹ́, dédé pẹlu Olúwa gbogbo agbalaaye}. [Surah Ash-Shu`arâ’: 98].
Oun naa ni o ko yiyi ijọsin sí ọdọ ẹni ti o yatọ si Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - sínú . tabi didarí apakan rẹ sí ọdọ ẹlomiiran yatọ si I - mimọ ni fún Un -; Gẹgẹ bii adua, ati wiwa iranlọwọ, ati ṣíṣe ileri, ati didunbu, ati eyi ti o yatọ si i ninu awọn iran ìjọsìn.
Tabi ki o ko ṣiṣe ohun ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn - ṣe ni eewọ di ẹtọ sínú. tàbí ṣíṣe ohun tí Ó ṣe ní ẹtọ leewọ, tabi fifi ọranyan Ọlọhun Alagbara ati Ọlọla silẹ, Gẹ́gẹ́ bíi ṣiṣe ohun ti a mọ̀ ni dandan pe eewọ ni ninu ẹsin ni ẹtọ; gẹ́gẹ́ bíi ṣiṣe ṣina ( àgbèrè tabi panṣaga), tabi ọtí, tabi ṣiṣẹ obi mejeeji, tabi Riba (owó ele), tabi ohun ti o jọ bẹẹ ni ẹtọ.
tàbí ṣíṣe àwọn nǹkan dáradára tí Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe ní ẹtọ ni eewọ, tabi fífagilé ohun ti Ọlọhun ṣe ní ọranyàn; Gẹgẹbi nini adisọkan pé irun kiki kii se ọranyan, tàbí pé ààwẹ̀ gbígba kii se ọranyan, tàbí pé Zakā kii se ọranyan.
Ati pe ẹbọ ńlá yoo sọ bibajẹ iṣẹ rẹ ati ṣiṣe gbere ninu ina di dandan fun ẹni ti o ba ku le e lori, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe wí pe:
﴿...وَلَوۡ أَشۡرَكُواْ لَحَبِطَ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ﴾
{Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́}. [Suratul An'aam: 88].
Atipe ẹniti o ba ku lori rẹ, Ọlọhun kò níí ṣe aforijin fún un, bakannaa ni alujanna yóò jẹ eewọ fun un. Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe wi pe:
﴿إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُ...﴾
{Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. A sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí ó yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́... [An-Nisaai: 48], Ọlọhun Ọba- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...إِنَّهُۥ مَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ حَرَّمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ ٱلۡجَنَّةَ وَمَأۡوَىٰهُ ٱلنَّارُ...﴾
{Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀... } (Surah Al-Maa'ida: 72).
2- Ẹbọ kékeré:
Oun ni nkan ti o fi ẹsẹ rinlẹ pẹlu awọn ẹri ti wọn pe ni ẹbọ, ṣugbọn ti ko de ipo ẹbọ nla, eyii ni wọn n pe ni ẹbọ kekere; Gẹgẹ bii bibura pẹlu nnkan to yatọ si Ọlọhun; Gẹgẹ bii ibura pẹlu Kaaba ati awọn anabi ati afọkantan ati ìyè lagbaja ati irúu bẹ́ẹ̀ lọ, Gẹgẹ bi Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - ti sọ pe:
«مَنْ حَلَفَ بِغَيرِ اللهِ فَقَدْ كَفَرَ أَو أَشرَكَ».
Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ."2
O si lè di ẹbọ nla latara ohun tí ó wà nínú ọkàn ẹniti o bura, Ti o ba wa ninu ọkan ẹni ti o n bura pẹlu Anabi tabi Sheik bayii pe dajudaju o da gẹgẹ bii Ọlọhun, tabi pe a le pe e yatọ si Ọlọhun, tabi pe o n ṣakoso ọrọ ẹda ninu aye; dajudaju o ti di ẹbọ nla niyẹn, Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó fi nnkan ti o yàtọ̀ sí Ọlọ́hun bura kò bá ní èrò yíì nínú, ṣùgbọ́n tí ó kàn jẹ́ ohun tó ti mọ́ ọn lẹ́nu lati maa sọ nítorí pé ó ti di bárakú fún un; eleyi yóò má jẹ́ ẹbọ kekere, Èyí aa máa ṣẹlẹ̀ púpọ̀ ní àwọn agbègbè kan, èyí to ṣe dandan ni ṣíṣe àkíyèsí sí i, àti ṣíṣe isọni lára kúrò níbẹ̀, fún ṣíṣọ́ àti amojuto taohid ( imú Ọlọhun nikan ṣoṣo) àti ìdáàbòbò rẹ̀.
3- Ẹbọ ti o pamọ:
Oun ni eyi ti o maa n wa ninu ọkan, ti o jẹ karimi ṣiṣe; Bii ẹni ti n kirun tàbí ti n ka Al-Qur'an lati ṣe sekarimi fun awọn eniyan, tàbí ti n ṣe afọmọ ki wọn le yin in, tàbí ti n se ṣaara ki wọn le yin in, Eyi jẹ́ ohun tí ó n ba iṣẹ́ tí ó fi ṣehàn nínú rẹ̀ jẹ, yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ yòókù tí ó fi tọkàntọkàn ṣe fún Ọlọhun.
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
«الشِّرْكُ فِي هَذِهِ الْأُمَّةِ أَخْفَى مِنْ دَبِيبِ النَّمْلَةِ السَّودَاءِ عَلَى الصَّفَاةِ السَّودَاءِ فِي ظُلْمَةِ اللَّيْلِ، وَكَفَّارَتُهُ أَنْ يَقُولَ: "اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ أَنْ أُشْرِكَ بِكَ شَيْئًا وَأَنَا أَعْلَمُ، وَأَسْتَغْفِرُكَ مِنَ الذَّنْبِ الَّذِي لَا أَعْلَمُ».
ṣíṣe ẹbọ lọdọ awọn ìjọ wọnyí o pamọ ju wíwọ koja kòkòrò awurebe lórí àpata dúdú nínú okunkun birimu oru, ìtanràn rẹ̀ sì ni pé kí ó máa sọ pé: "Ọlọhun, dájúdájú mo sádi ọ pé kí n máa fi nǹkan kan ṣe ẹbọ sí ọ nígbà tí mo mọ̀, mo sì ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ rẹ fún ẹṣẹ̀ èyí tí èmi kò mọ̀"3.
Àwọn ìran aigbagbọ:
Ìran Kìíní: Aigbagbọ ńlá:
Òun ni ó máa ń sọ ibẹ gbére nínú iná di dandan, oríṣi marun ni o jẹ:
1- àìní ìgbàgbọ ipe Ọlọhun tàbí ọrọ Rẹ nírọ:
Óun ni pípe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, Èyí sì kéré lára àwọn aláìgbàgbọ́; nítorí pé Ọlọhun- ti Agbara ati Ọla Rẹ ga- ti kun àwọn ojiṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹri ti o foju hàn, Isesi àwọn tó ń pe òtítọ́ ní irọ́ wọ̀nyí ni gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ṣe ṣàpèjúwe wọn:
﴿وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنْفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا...﴾
{Wọ́n ṣe àtakò rẹ ni tí abosi, bẹẹ si ni ẹ̀mí wọn ní àmọ̀dájú pé òdodo ni}. [Suratul Nahl: 14].
2- Àìní ìgbàgbọ tí o jẹ ti iko jalẹ àti ìgbéraga:
Eyi ni o jẹ́ àpẹẹrẹ àìgbàgbọ́ ’Iblīs, nítorí pé kò tako àṣẹ Allāhu, ṣùgbọ́n ó fi ìkọ̀sílẹ̀ àti ìgbéraga pade ẹ. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 34﴾
{ (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́}. [Suratul Baqorah: 34].
3- Àìní igbagbọ ti isẹri kúrò lọdọ Ọlọhun:
Èleyiun nípe kí o sẹri igbọ́rọ rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀ kúrò níbi títẹ̀lé òdodo, nítorí náà, kò ní yíjú sí i, kò sì ní kà á sí, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعۡرَضَ عَنۡهَآۚ إِنَّا مِنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُنتَقِمُونَ22﴾
{Àti pé kò sí ẹni to ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Ọlọhun rẹ se ìrántí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (ọdaràn) }. [Suuratus Sajdah: 22].
Ní ti gigunri apakan; oun ni ìwà ìyapa Ọlọhun kìí ṣe ṣíṣe keferi; gẹgẹ bí ẹni tí ó gunri kuro níbi kíkọ́ apakan ninu awọn nnkan tí ó jẹ́ dandan ninu ẹsin; nínú àwọn òfin ààwẹ̀ tàbí Hajj àti bẹẹbẹẹ lọ.
4- Àìní ìgbàgbọ ti ìyè méjì:
Èyí ni pé kí ó máa ṣe iyemeji, kí ó má sì ní ìdánilójú lórí òdodo, kàkà bẹ́ẹ̀, iyemeji ni ó máa ṣe síi, gẹ́gẹ́ bí ọrọ Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga ti o sọ pe:
﴿وَدَخَلَ جَنَّتَهُ وَهُوَ ظَالِمٌ لِنَفْسِهِ قَالَ مَا أَظُنُّ أَنْ تَبِيدَ هَذِهِ أَبَدًا 35 وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِنْ رُدِدْتُ إِلَى رَبِّي لَأَجِدَنَّ خَيْرًا مِنْهَا مُنْقَلَبًا 36﴾
{Ó wọ inú oko rẹ̀ ní ẹni tí ó ń ṣàbòsí fún ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé.
Èmi kò sì lérò pé Àkókò (àjíǹde) náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá tiẹ̀ dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí tó dára ju èyí lọ}.
[Al-Kahf: 35-36].
5- Àìní ìgbàgbọ ti ṣẹ yín ṣọ ùn (olójú méjì bí ọbẹ):
Oun ni fifi igbagbọ han pẹlu ahọn, ati pípa aigbagbọ mọ pẹlu ọkan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَبِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَمَا هُم بِمُؤۡمِنِينَ 8﴾
{Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo}. [Al-baqarah: 8].
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ìran Aigbagbọ ńlá tí ó ń múni kúrò nínú Islam.
Oríṣi ẹlẹẹkeji: Aigbagbọ kékeré:
iran eleyii ni kò lee muni ṣe gbere ninu ina, Òun ni ohun tí a pè ní aigbagbọ nínú al-Qur'an àti Sunnah, láì ní àmì-ìdámọ̀ 'alif' àti 'lam', kàkà bẹ́ẹ̀, ó wá ní àìlódìídámọ̀. Àwọn àpèjúwe lori rẹ si pọ, ninu wọn ni: Hadith Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa bá a) sọ pé:
«اثْنَتَانِ فِي النَّاسِ هُمَا بِهِمْ كُفْرٌ: الطَّعْنُ فِي النَّسَبِ، وَالنِّيَاحَةُ عَلَى المَيِّتِ».
«Awọn eniyan meji wa laarin awọn eeyan ti o jẹ pe aigbagbọ wa lara awọn mejeeji: bubu ẹnu atẹ kan ìran, àti súnsun ẹkun aro lórí òkú»4.
2) Nini igbagbọ si awọn Malaika:
Wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dá ikọkọ Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- da wọn lati ara imọlẹ, Wọn si jẹ́ olùjọ́sin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Wọn kò sì ní nnkankan nínú àwọn nnkan ẹṣa ijẹ Olúwa àti àwọn nnkan ẹṣa ilẹtọ sí ìjọsìn ododo, Wọn kò sì níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn, Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn, Onka wọn pọ, ko si ẹni ti o mọ iye wọn afi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
Nini igbagbọ ninu awọn mọlaika ko awọn alamọri mẹrin sinu:
1- Nini igbagbọ ninu bibẹ wọn
2- Nini igbagbọ sí àwọn ti a mọ orúkọ wọn; gẹgẹ bii: Jibril, ati Mikail, ati Israfil, ati àwọn yooku. Ṣùgbọ́n awọn tí a kò bà mọ orúkọ rẹ, a maa ni igbagbọ ninu wọn lapapọ.
3- Nini igbagbọ ninu nnkan ti a mọ ninu awọn iroyin wọn, ti o wa ninu iwe Ọlọhun tii se Al-qurani ati ọrọ ojiṣẹ Ọlọhun àti ìlànà rẹ; Gẹgẹ bii iroyin Jibril, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun wa ni iro pe dajudaju oun ri i lori àwòrán rẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- da a le lori, iyẹ ọgọ́run-un mẹfa ni o n bẹ fun un, ti o si gba oju sanmọ.
4- Nini igbagbọ pẹlu nnkan ti a mọ ninu awọn iṣẹ wọn; gẹgẹ bii ṣíṣe afọmọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati jijọsin fun Un ni alẹ ati ọsan laisi ikosusu tabi ikọlẹ .
Ni àpẹrẹ: Jubril ni ẹni ifọkanbalẹ sí lọdọ tàbí alamojuto ibanisọrọ láti ọdọ Ọlọhun.
Israfil ni Alamojuto tí wọn gbé iṣẹ fifọn fèrè oníwo fún.
Malakul maot (iransẹ iku) ni Alamojuto gbigba awọn ẹ̀mí nigba iku.
Ati Maalik: oluṣọ ina. Ati Ridwaan: oluṣọ alijanna, ati awọn ẹlomiran yatọ si wọn.
3) Níní ìgbàgbọ́ sí àwọn tira:
Nnkan ti a gba lero pẹlu awọn tira ni: àwọn tira tí o tí sanmọ wa ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ wọn kalẹ fun awọn Ojiṣẹ Rẹ, ki wọn maa jẹ́ ìmọ̀nà fún gbogbo aráyé àti ìkẹ́ fún wọn, kí wọ́n le bà sori re ayé àti ọ̀run.
Nini igbagbọ sí awọn tira kó awọn nkan mẹrin sinu:
1- Nini igbagbọ pe dájúdájú wọn sọ ọ́ kalẹ̀ lati ọdọ Ọlọhun lododo.
2- Nini igbagbọ sí eyi ti a mọ orúkọ rẹ ninu wọn; gẹgẹ bii Kuraani ti a sọkalẹ fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Àti Ataoraata ti wọn sọkalẹ fún Anabi Musa - ki ìkẹ́ Ọlọ́hun máa bá a -, Ati Injil ti wọn sọkalẹ fun Anabi Isa - ki alaafia Ọlọhun maa ba a -, Ati Sabura ti wọn fun Anabi Daud- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-
Ṣùgbọ́n eyi ti a ko mọ orúkọ rẹ; a maa ni igbagbọ si lapapọ.
3- Gbigba awọn iro inu awọn tira náà gbọ lododo; gẹgẹ bii awọn iro inu Kuraani, ati awọn iro inu awọn tira ti wọn ko yi pada ninu awọn tira ìṣáájú.
4- Ṣíṣe iṣẹ pẹlu awọn idajọ eyi ti wọn kò parẹ ninu wọn ( tàbí ṣíṣe àmúlò rẹ ) , ati yiyọnu ati gbigba fun un, boya a gbọ ọgbọn tí o wa nibẹ ye ni tabi a ko gbọ ọ ye. ati pé gbogbo awọn tira iṣaaju ni wọn ti parẹ latara dide Kuraani ti o tobi nitori naa ko lẹ́tọ̀ọ́ lati maa ṣíṣe (tabi ṣíṣe àmúlò) eyikeyi idajọ ninu awọn idajọ awọn tira ìṣáájú ayaafi nnkan ti o ba ni alaafia ninu wọn, ti Kuraani Alapọnle tabi ilana Anabi si fi rinlẹ pe o lalaafia.
4) Níní ìgbàgbọ́ nínú àwọn Ojiṣẹ, kí àlàáfíà Ọlọ́hun máa bá wọn:
Ar-Rusul: Ni gbólóhùn tí wọn maa nlo fún ọpọ (Rosuul); oun ni ẹni ti a fi imisi ránṣẹ́ si ninu ẹda pẹlu ofin ti wọn si pa a láṣẹ lati jẹ iṣẹ naa, Akọkọ wọn ni anọbi Nuh- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ti igbẹyin wọn si jẹ anọbi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- Àti pé èdá-ènìyàn ni wọn tí A ṣẹ̀dá, Ko si nnkankan fun wọn ninu awọn nnkan ẹṣa ijọba Oluwa ati ini ẹtọ si ijọsin ododo.
Nini igbagbọ si awọn Ojiṣẹ kó awọn nnkan wọnyii sinu:
1- Nini igbagbọ pe dajudaju riran wọn ni iṣẹ jẹ ododo lati ọdọ Ọlọhun, ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si riran ọkan ninu wọn ni iṣẹ ti ṣe aigbagbọ si gbogbo wọn.
2- Nini igbagbọ si ẹni ti a mọ orúkọ rẹ ninu wọn pẹlu orúkọ rẹ, gẹgẹ bii: Muhammad, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa, ati Nuh, - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn-. Àwọn ni onípinnu to lagbara ninu àwọn Ojiṣẹ.
Ṣùgbọ́n ẹni ti a ko mọ orúkọ rẹ ninu wọn; a maa ni igbagbọ ninu rẹ lapapọ, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَ...﴾
{Àti pé dájúdájú ati rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn}. [Ghafir: 78].
3- Gbigbagbọ lotitọ sí nnkan ti o ni alaafia nipa awọn iroyin wọn - ki ọla Ọlọhun maa ba wọn - ki a si gba a gbọ lododo.
4- Ṣíṣe amulo ofin ẹni ti wọn ran si wa ninu wọn, oun naa ni opin wọn tinse Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.
5) Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin:
Oun ni ọjọ igbende, ìgbàtí wọn maa gbe ọmọniyan dide nibẹ fun iṣiro iṣẹ ati ẹsan, Wọn pe e ni orúkọ yẹn nitori pe ko si ọjọ miiran lẹyin rẹ, nigba ti awọn ara alujanna yoo maa ṣe gbere ninu awọn ibugbe wọn ti awọn ara ina naa yoo maa ṣe gbere ninu awọn ibugbe wọn.
Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin ko awọn alamọri mẹta kan sinu:
A- Nini igbagbọ ninu igbende:
Oun ni sisọ awọn òkú di alaaye nígbà tí wọ́n ba fọn fèrè ẹlẹẹkeji, ti awọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá, ni ẹni ti ko nii wọ bata, ni arin-hoho, ni ẹni tí wọn ko da abẹ fun rárá, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿كَمَا بَدَأْنَا أَوَّلَ خَلْقٍ نُعِيدُهُ وَعْدًا عَلَيْنَا إِنَّا كُنَّا فَاعِلِينَ 104﴾
{Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa ni a ti máa ṣe bẹ́ẹ̀}.
[Suuratul Anbiyaah: 104].
B- Nini igbagbọ ninu iṣiro-iṣẹ ati ẹsan:
Níbi tí a óò ti ṣe ìṣirò iṣẹ́ fún ẹrú, tí a ó sì san án ní ẹsan, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ 25 ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم 26﴾
{Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn. [Suuratul Gooshiyah: 25-26].
D- Nini igbagbọ ninu alujanna ati ina:
ati pe dajudaju awọn ni ibudesi gbere fun ẹda. Alujanna ni ọgba idẹra ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pese rẹ fun awọn olugbagbọ awọn olubẹru Ọlọhun ati awọn ti wọn tẹle Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ, kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a, O n bẹ ninu rẹ ohun ti oju kan o ri ri, ti eti kan o gbọ ri, ti ko si wa si ọkàn abara kankan ri.
Ṣùgbọ́n ina; Oun ni ilé ìyà, Èyí tí Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pa lese silẹ fun awọn alaigbagbọ, awọn ti wọn ṣe aigbagbọ si I ti wọn yapa awọn Ojiṣẹ Rẹ. Awọn oríṣiríṣi iya ni n bẹ nibẹ ti ko leè ṣe wuyẹ lori ẹmi tàbí ọkàn rárá.
6) Nini igbagbọ ninu kadara eyi to daa ninu ẹ ati eyi to buru:
Ohun ti wọ́n gbalero pẹlu Kadara ni : Ipebubu Ọlọhun - Alagbara ti O gbọnngbọn- fun ohun ti yio ṣẹlẹ àti ifi ètò sí nibamu si imọ Rẹ ti o ti ṣaaju, ti o si ba ọgbọn Rẹ mu.
Nini igbagbọ ninu kadara ko awọn alamọri mẹrin kan sinu:
1- Imọ: Oun ni nini igbagbọ ninu imọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati pe dajudaju Oun ni O ni imọ nipa nnkan to ti ṣẹlẹ ati nnkan ti o n bọ waa ṣẹlẹ ati bi o ṣe maa ṣẹlẹ, ni apapọ ati ifọsiwẹwẹ, ṣiwaju ati láéláé. Ati pe Oun- mimọ ni fun Un- ni Onimọ̀ nípa ohun tí kò sí, àti pé bí ó bá tilẹ̀ wà, o tí mọn bí yóò ṣe rí. Gẹgẹ bi Ọlọhun - mimọ ni fun Un - ṣe sọ pe:
﴿وَلَوۡ رُدُّواْ لَعَادُواْ لِمَا نُهُواْ عَنۡهُ ...﴾
{Tí o bá jẹ́ pé wọ́n bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn... }
[Al-An'aam 28].
2- Kíkọ àkọsílẹ̀: Óhun ni pé dájúdájú Ọlọhun -tí ọlá Rẹ̀ ga- ti kọ àwọn kàdàrá ( eto àti alaalẹ) gbogbo nǹkan sílẹ̀ títí di ọjọ́ ìgbénde, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّ ذَٰلِكَ فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ 70﴾
{Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāh láti ṣe}.
[Al-Hajj:70].
3- Fifẹ tí Ọlọhun fẹ́ nnkan: Oun ni níní ìgbàgbọ́ pé nnkankan ò níí ṣẹlẹ̀ nínú àgbáyé yìí àfi nkan tí Ọlọ́hun -Alágbára, Ọlọ́lá jùlọ- bá fẹ́, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَرَبُّكَ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُ وَيَخۡتَارُ ...﴾
{Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà}. [Al-Qasas:68]. Ati pe ọmọnìyàn ni fifẹ, kò sì jáde kúrò nínú fifẹ Ọlọhun, gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ pe:
﴿وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 29﴾
{Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá}. [At-Takwiir: 29].
4- Dida nnkan : Oun ni nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun- ti agbara ati ọla Rẹ ga- da awọn ẹda ati awọn iṣẹ́ wọn ati awọn ìṣe wọn, yala o jẹ́ rere ni tabi aburu, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ 62﴾
{Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo nǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí (Alamojuto) gbogbo n̄ǹkan}. [Zumar: 62]
Ati pe wọn ti ko àwọn ipò wọnyi jọ sinu ile orin yii:
Imọ, kikọ nkan silẹ Oluwa wa, fifẹ Rẹ, àti dida Rẹ, tíí ṣe mímú-wá sí wíwà àti ṣíṣẹ̀dá.
Ìwádìí ẹlẹẹkẹta: Ise dáadáa:
Iṣe Daadaa: origun kan ṣoṣo ni; oun ni ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba tilẹ ri I, dajudaju Oun n ri ẹ.
Èyí túmọ̀ sí pé: ki eniyan maa ṣe ohun ti Ọlọhun ṣe ni ijọsin fun un gẹ́gẹ́ bi ẹni pé o ń dúró níwájú Ọlọhun- Ológo àti Alápọ̀nlé-, nitori pe yoo sọ di dandan fun un láti ní ìpayà pípé àti láti dari ọkan padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ - mimọ ni fun Un-. yoo si se ni dandan fun un lati maa jọ́sìn ni ìbámu sí ilana Anabi - kí ikẹ àti ọlá Ọlọhun máa bá a -.
Iṣe dáadáa wà lórí ìpele méjì, àwọn olùṣe-dáadáa nínú iṣe dáadáa naa wà lórí ipò méjì tí ó yàtọ̀ síra wọn:
Ipele àkọ́kọ́: oun ni ó ga jùlọ, oun ni ipele ìfojúrí; Oun ni ki ẹru maa ṣe iṣẹ́ bii pe o n ri Ọlọhun pẹlu ọkan rẹ, ọkan naa yoo si maa tan imọlẹ pẹlu igbagbọ, titi ti ohun ikọkọ yoo fi di ohun àfojúrí.
Ipele ẹlẹẹkeji: ipele imọkanga ati inifuramọ pe oju Ọlọhun nto oun, Oun ni kí ẹrusin ṣiṣẹ́ lórí mímú wá sí àkíyèsí pé Ọlọhun ń rí i, tí Ó sì mọ̀ nípa rẹ̀. Tí ó bá ti ní àkíyèsí yìí, nígbà náà, ó jẹ́ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ní mímọ́ fún Ọlọhun Ọba Aleke ọla.
Ìwádìí ẹlẹẹkẹrin: Àkópọ̀ ṣoki lara àwọn ìpìlẹ̀ àwọn Ahlu-sunnah wal-jama'a:
Akọkọ: títẹ̀lé ohun ti o wa ninu Al-Qur’an ati Sunna ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gbangba, ati kí a má ti ọrọ ẹnikẹni ninu awọn eniyan ṣiwaju ọrọ Ọlọhun Ọba ati ọrọ ojiṣẹ Rẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a -.
Èkejì: Mímọ́ ọkàn wọn ati ẹnu wọn nípa àwọn saabe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a -, Wọn si ni adisọkan pe Khalifa (adari) lẹyin ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni Abu Bakr, lẹyin rẹ ni Umar, lẹyin rẹ ni Uthman, lẹyin rẹ ni Ali, ki Ọlọhun yọnu si gbogbo wọn.
Ìkẹta: Nini ifẹ àwọn ará ilé ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati rírọ̀ mọ́ wọn tàbí iba wọn se papọ ; àwọn ará ilé rẹ̀ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni àwọn ẹni rere nínú wọn ní adayanri.
Ikẹrin: Kí a máṣe ṣe àtakò awọn aṣiwaju ati awọn adari wa, ko da ki wọn ṣe abosi, A ó maa se adura daada ati titọrọ alaafia fun wọn, A ò sì gbọdọ máa sẹ epe fún wọn. Itẹle wọn jẹ dandan, o si wa ninu itẹle Ọlọhun -Alagbara ti O gbọnngbọn-, niwọn igba ti wọn ko ba paṣẹ sibi ṣiṣẹ Ọlọhun. Ti wọn ba paṣẹ ìyapa Ọlọhun, a kò gbọdọ̀ tẹlé wọn nígbà náà, Itẹle wọn níbi dáadáa yóò sì ku nínú ohun mìíràn.
Ẹlẹẹkarun: Gbígbàgbọ́ nínú àwọn iṣẹ́ iṣẹ-apọnle (karaamọ) àwọn wòlíì; oun ni àwọn nnkan eemọ tí Ọlọhun n mu ṣẹlẹ láti ọwọ́ wọn.
Ẹlẹẹkẹfa: wọn kò ní pe àwọn tí a jọ nkirun tí wọn kọjú sí ibudajukọ (Qiblah) ní kèfèrí nitori ìyapa Ọlọhun wọn tabi nitori àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ti wọn ṣe, Gẹgẹ bí àwọn Khawaarij ṣe n ṣe, Kàkà bẹẹ, ijẹ ọmọ-iya ninu ìgbàgbọ duro sinsin koda pẹlu awon ẹ̀ṣẹ̀, Wọn si maa n sọ nipa ẹlẹṣẹ pe: Onigbagbọ ni pẹlu igbagbọ rẹ, o si jẹ pokii pẹlu iyanla ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Ori-iwe ẹlẹẹkeji : Ohun tó jẹmọ́ awọn ijọsin
Abala Kini: Imọra:
Imọra ní ìtumọ̀ èdè: Ìmọ́tótó àti ìmọ́tónítóní kúrò níbi àwọn ẹgbin àfojúrí àti àìfojúrí.
Ní ìwòye ẹ̀sìn: mimu ẹgbin aifojuri kuro àti kikuro idọti. Imọra sì ni kọkọrọ irun, Fun idi eyi, dajudaju kikọ rẹ jẹ ọkan ninu awọn iṣẹ pataki ti o tobi julọ ninu alamọri ẹsin, ti o ṣe pe kikọ rẹ ati ṣiṣe amojuto rẹ jẹ dandan fun gbogbo Musulumi.
Alakọkọ: Àwọn ìpín omi:
1- Omi tó mọ́ kangá; ó tọ̀nà láti fi ṣe Imọra, Yálà kí o wà gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá rẹ̀; gẹgẹ bii omi òjò tabi akeremọdo tabi omi okun, Tabi ti nnkan ti o mọ ba ropọ mọ ọn, ti ko bori rẹ, ti ko si gba orukọ rẹ lọwọ rẹ.
2- Omi ẹgbin; lílò rẹ ko lẹtọ, kò ní gbé ẹgbin kuro, ko si nii mú idọti kúrò, Oun ni omi tí awọ rẹ, tàbí òórùn rẹ, tàbí itọwo rẹ yí padà pẹ̀lú ẹgbin (idọti).
Ẹlẹẹkeji: Idọti tàbí ẹgbin:
Ẹ̀gbin: Oun ni èérí kan pàtó, ti iru rẹ̀ n dena Irun; Gẹ́gẹ́ bí ìtọ̀, ìgbẹ́, ẹjẹ àti àwọn mìíràn, ó sì le wà lára, ni ààyè àti nínú aṣọ.
Ati pe ipilẹ gbogbo nnkan no pé o lẹtọ bẹẹni o si wa ni mimọ, Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹnu sọ pé ohun kan jẹ́ ẹgbin, dandan ni kí o mu ẹ̀rí wà lórí rẹ̀. Kii ṣe ara ẹgbin ni: kẹlẹmbẹ tàbí itọ, òógùn èèyàn, àti òógùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; kàkà bẹ́ẹ̀, nnkan ti o mọ ni wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ nnkan ìríra. Gbogbo ẹgbin ìdọ̀tí ni, ṣugbọn idakeji rẹ kori bẹ.
Ìpele mẹta ni n bẹ fun ẹ̀gbin:
Akọkọ: ẹ̀gbin t'o nipọn;
Gẹgẹ bii: ẹgbin ohun ti aja ti ẹnu bọ, Ọna ṣiṣe mimọ rẹ ni pe ki a fọ ọ ni ẹẹmeje ti a o sí fọ ọ lálákọ́kọ́ pẹlu erupẹ.
Ẹlẹẹkeji: Èérí tí wọ́n fúyẹ́:
Bíi ìtọ̀ ọmọdekunrin ọmọ-ọmú tí ó bá kan aṣọ àti nnkan tí ó jọ ọ́. Ọna mimọ rẹ ni ki a bu omi rin in titi yio fi kari rẹ, kò si ni bukata sí fífọ tabi fífún.
Ẹlẹẹkẹta: Ẹ̀gbin towa ni wọtun wansi:
Gẹgẹ bii itọ ọmọ ènìyàn àti igbẹ rẹ, àti púpọ̀ jùlọ nínú àwọn ẹ̀gbin, nígbàtí wọ́n bá bọ́ sí orí ààyè kan tàbí aṣọ kan àti irú wọn. Ọna ati mọ ọ ni: Mimu ara ẹgbin kúrò, tí o bá ní ara, ati mímọ́ ààyè rẹ pẹlu omi tabi àwọn nnkan míràn tí a fi ń mọ nnkan.
Ninu ohun ti ẹri duro le lori ìjẹ́-ẹgbin rẹ: ni
1- Itọ ọmọ-ènìyàn àti igbẹ rẹ̀.
2- Atọ Madiy àti Wadiy tí kò leè di ọmọ5.
3- Igbẹ nnkan ti a kii jẹ ẹran rẹ.
4- Ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ obìnrin.
5- Itọ́ ajá.
6- Ẹran-oku, a sì yọ kúrò nínú rẹ̀:
a- Ti eniyan ba ku.
B- Òkú ẹja ati eṣú.
C- Oku ẹranko ti ko ni ẹjẹ sísan; gẹgẹ bii eṣinṣin, èèrà, oyin, ati irúu tí o ba jọ .
D- Egungun oku nbete ati iwo rẹ, ati èékánná rẹ, ati irun rẹ, ati ìyẹ́ rẹ.
Bí a ṣe n mọ ẹgbin kúrò yii máa wáyé:
1- Pẹlu omi, oun si ni ìpìlẹ níbi mimọ ẹgbin kúrò, a kii si yipada kúrò lórí rẹ sí nnkan mìíràn.
2- Ohun tí Òfin ẹ̀sìn mú wá nípa bí ase le se afọmọ àwọn nǹkan ẹgbin tàbí èyí tí wọ́n sọ di ẹlẹ́gbin:
A- Awo ẹran-oku a maa di mímọ́ pẹlu ìfin.
b- Ṣiṣe imọra igba ti aja ba ti ẹnu bọ; ki a fọ ọ ni ẹẹmeje; ti àkọ́kọ́ ninu wọn yoo jẹ pẹlu erupẹ.
c- Mimọ aṣọ kúrò níbi nnkan ẹjẹ nkán oṣu; yoo waye pẹlu híha a, lẹyin naa pípa a pẹlu omi, lẹyin naa wíwọ́n ọn, ti àpá rẹ ba si ku lẹyin naa, kò buru.
d- Sísọ eti tàbí isalẹ aṣọ obìnrin di mímọ́; yoo maa waye pẹ̀lú ilẹ̀ mímọ́ tí ó bá tẹ̀lé e.
h- Mimọ aṣọ kúrò níbi ìtọ̀ ọmọkùnrin ọmọ-ọwọ́; yoo maa waye pẹ̀lú fífọn omi síi, àti pẹ̀lú fífọ aṣọ náà ti o jẹ ọmọbìnrin.
W- Mimọ aṣọ kuro lara madhiy; yoo maa waye pẹlu bibu omi rin oju ibẹ.
G- Sísọ ìsàlẹ̀ bàtà di mímọ́; yoo maa waye pẹ̀lú fifi gboo ilẹ̀ mímọ́.
k- Mimọ ilẹ kuro nibi ẹgbin; yoo maa waye pẹlu dida garawa omi kan si oju ààyè naa, tabi fifi silẹ titi yíò fi gbẹ pẹlu oorun tabi atẹgun, nigbati ipa ẹgbin naa ba ti lọ, o tidi mimọ.
Ẹkẹta: Nnkan ti ṣiṣe rẹ jẹ eewọ fun ẹlẹgbin lara:
Awọn nnkan ti o jẹ eewọ fun ẹni tí ó ní ẹgbin kekere tàbí nla lara:
1- Ìrun, bóyá ó jẹ ọranyan ni tàbí aṣegbọrẹ; Fun ohun ti o wa lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - pe dajudaju Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ pe:
«لَا يَقْبَلُ اللَّهُ صَلَاةً بِغَيْرِ طُهُورٍ».
«Ọlọhun o nii gba irun laisi imọra»6.
2- Gbigba Kuraani mu; Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu iwe ti Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - kọ fun Amru ọmọ Hazm, ninu eyiti o ti sọ pe:
«لَا يَمَسُّ الْقُرْآنَ إِلَّا طَاهِرٌ».
«Kò sí ẹni tó yẹ kó fọwọ́ kan al-Ƙur’ān àfi ẹni tí o ba wa ni mímọ́»7.
3- Rirọkirika Ilé Láéláé (Kaaba); Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«الطَّوَافُ بِالْبَيْتِ صَلَاةٌ، إِلَّا أَنَّ اللَّهَ أَبَاحَ فِيهِ الْكَلَامَ».
«Irọkirika ile Ọlọhun irun ni, ayafi pe Ọlọhun ti yọnda ọrọ sisọ ninu rẹ»8. Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si ti ṣe aluwala fun Tawaf ( irọkirika Ile Ọlọhun), O si jẹ nnkan ti o ní àlàfíà lati ọdọ rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o kọ̀ fun ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu kuro nibi irọkirika ile Oluwa titi ti yoo fi mọ.
Ṣugbọn awọn nnkan tí a ṣe ní eewọ fún ẹni tí ó ní ẹgbin ńlá lara, oun ni:
1- Kika Kuraani; Nítorí hadith Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i-: «Kò sí ohun kan tí ó máa n dí - Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọla Ọlọ́hun máa bá a - lọ́wọ́ nípa Kùránì, yàtọ̀ sí janaba»9.
2- Wíwà ní mọṣalaṣi láìní aluwala; nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡرَبُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمۡ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعۡلَمُواْ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغۡتَسِلُواْ...﴾
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀...} [An-Nisaa: 43].
Ti ẹni ti o ni ẹgbin nla ni ara ba ṣe aluwala; a yọnda fun un lati duro ninu mọ́sálásí, bẹẹ naa ni a yọnda fun ẹnití o ni ẹgbin nla ni ara lati kọja ninu mọsalasi lasan lai joko ninu rẹ.
Ẹlẹẹkẹrin: Awọn ẹkọ bibiya bukaata ( Titọ tàbí ṣíṣe igbansẹ]:
Awọn ohun ti o yẹ ní àsìkò bibiya bukaata (Ṣíṣe igbọnsẹ) :
1- Jijinna si awọn eniyan ati fifi ara pamọ́ fún wọn ni ibi aaye igbọnsẹ.
2- Ṣíṣe adura tí o wa fún wiwọle igbọnsẹ pe:
«اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنَ الْخُبْثِ وَالْخَبَائِثِ».
“Iwọ Ọlọhun mo fi O wa iṣọ kuro lọdọ awọn akọ alujannu ati awọn abo wọn”10.
O si jẹ dandan nigba bibiya bukaata (igbọnsẹ):
1- Mímọ́ra kúrò nínú ìtọ́.
2- Bibo ihoho.
O jẹ eewọ ní àsìkò ìgbọ̀nsẹ̀:
1- Didojukọ Qiblah tàbí kíkọyìn sí i.
2- Bibiya bukaata ní ojú ọ̀nà àwọn ènìyàn àti àwọn ibi gbogboogbò.
3- Títọ̀ sínú omi tí kò ṣàn ti o darogun.
Ó jẹ́ ohun àìfẹ́ nígbàtí a bá n bi'ya bukaata (se igbọnsẹ) :
1- Fífọwọ́ kan abẹ ọkunrin pẹlu ọwọ ọtun nígbàtí a bá ń yagbẹ tàbí tọ̀.
2- Fífi omi ṣe imọra ati fífi òkúta ṣe imọra pẹlu ọwọ ọtun.
3- A kórìíra (;wanko fẹ) ọ̀rọ̀ sísọ, pàápàá jùlọ pẹlu iranti Ọlọhun nígbà tí a ba nṣe igbọnsẹ.
Ẹlẹẹkarun: Àwọn ìlànà nípa Fífi omi ṣe imọra ati fífi òkúta ṣe imọra:
Al-Istinjā' ni : Mímú ipa ẹgbin ti o jade láti ojú ọ̀nà méjèèjì kúrò pẹ̀lú omi.
Al-Istijmaar ni : mímú ipasẹ̀ ẹgbin ti o jáde láti ojú ọ̀nà méjèèjì kúrò pẹlu nnkan ti o yàtọ̀ si omi; gẹgẹ bii àwọn òkúta àti àwọn aṣọ-ìnuwọ́.
Awọn majẹmu ohun ti o wa fún lílò òkúta tàbí nkan to yatọ sí omí fún imọra:
1- Kí ó jẹ́ nǹkan tí ó tọ́.
2- Kí o jẹ nǹkan ti o mọ.
3- Ki o jẹ nnkan ti a le fí mọ́ nkan.
4- Kí ó má jẹ egungun tàbí ìgbẹ́.
5- Ki o ma jẹ́ pẹlu nkankan ti o ni ọla àti ọwọ lára; gẹgẹ bi awọn iwe ti orukọ Ọlọhun -ti agbara ati ọla Rẹ ga- wa ninu wọn.
O si tọ ki a da imọra mọn lórí Istijmar nìkan pẹlu majẹmu meji:
1- Ki nǹkan tó jáde ma rékọjá ojú ọ̀nà rẹ̀ tí ngbà wa .
2- Ki mimọra jẹ pẹlu okuta mẹta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ti o le mọ nnkan.
Ẹkẹfa: Awọn idajọ ti o ní nṣe pẹlu aluwala:
Aluwala jẹ dandan fun awọn ijọsin mẹta:
1- Ìrun; bóyá ó jẹ ọranyan ni tàbí aṣegbọrẹ.
2- Gbigba Kuraani mu.
3- Rirọkirika ile Ọlọhun.
Awọn majẹmu aluwala:
1- Isilaamu ( ijẹ musulumi) .
2- Laakaye ( gbigbọn) .
3- Isẹ adayanri ( ida nkanmọ) .
4- Aniyan: ọkàn si ni ààyè rẹ , sísọ ọ́ jáde sì jẹ́ àdadaásílẹ̀, Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe aluwala, ó ti da aniyan niyẹn, Ṣugbọn ní ti fifọ awọn orikiriki aluwala pẹ̀lú èrò ìtura tàbí imọ́tótó; eleyi kò jẹ́ aluwala.
5- Mímu ìdájọ rẹ pẹlu rẹ: pé kí ó má ṣe ní aniyan láti dá a dúró títí imọra rẹ̀ yóò fi pé.
6- Pípari ohun ti n sọ aluwala di dandan, Ati pe wọn ṣe àyàfi kuro ninu ìyẹn: ẹni ti o ni itọ seré ti n san tí kò dá, ati ẹniti n ri ẹjẹ awaada.
7- Fífi omi ṣe imọra tàbí fífi òkúta ṣe imọra ṣíwájú rẹ̀, fún ẹni tí itọ tàbí igbẹ jáde lára rẹ̀.
8- Mímọ́ omi, àti ṣíṣe lẹtọ.
9- Yíyọ ohun tó bá lè dí omi láti kan awọ ara kúrò
10- Wiwọle asiko irun fun ẹni tí ó ní àìlówùù àìdáwọ́dúró.
Àwọn ọranyan aluwala:
1- Fifọ oju ti yiyọ ẹnu ati fifa omi si imu n bẹ ninu ẹ.
2- Fifọ ọwọ méjèèjì pẹlu igunwọ méjèèjì.
3- Pipa gbogbo ori, àti pé eti mejeeji n bẹ ninu ẹ.
4- Fifọ ẹsẹ mejeeji pẹlu kokosẹ mejeeji.
5- Ìtòlẹ́sẹẹsẹ laarin àwọn oríkèé aluwala.
6- ṣíṣe iṣẹ aluwala le rawọn: Kò gbọdọ̀ fi àlàfo tó pẹ́ sí àárín àwọn ẹ̀yà ara.
Bi a ṣe n ṣe aluwala:
1- Didarukọ Ọlọhun
2- Fifọ ọwọ mejeeji lẹẹmẹta.
3- Fifọ oju lẹẹmẹta, ti yiyọ ẹnu ati fifa omi si imu n bẹ ninu ẹ.
4- Fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji lẹẹmẹta, a o bẹrẹ pẹlu ọwọ ọtun lẹyin naa ni ọwọ osi.
5- Pipa ori mọ eti mejeeji.
6- Fifọ ẹsẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji lẹẹmẹta, a o bẹrẹ lati ẹsẹ ọtun lẹyin naa ẹsẹ òsì.
Awọn nnkan ti wọn n ba aluwala jẹ:
1. Nnkan ti o n jade láti ojú ọna mejeeji, bíi: itọ, iso, àti igbẹ.
2- Ẹgbin tó pọ̀ ti o n jade láti ara.
3- Yíyẹ̀ làákàyè pẹlu oorun tabi ohun miiran.
4- Gbigba oju-ara abi idi mu pẹlu ọwọ laisi gàgá.
5- Jíjẹ ẹran ràkúnmí.
6- Kikuro ninu Isilaamu, ki Ọlọhun sọ wa àti àwọn Musulumi nibi ìyẹn.
Ẹlẹẹkeje: awọn idajọ pipa ìbọ̀sẹ̀ aláwọ mejeeji ati ìbọ̀sẹ̀ olówùú:
1- Al-khuffu: Ni ohun ti wọn ba n wọ si ẹsẹ ti wọn ṣe latara awọ ati nkan ti o jọ ọ.
2- Ibọsẹ: Nnkan ti wọn maa n wọ̀ sí ẹsẹ mejeeji tí wọ́n ṣe latara irun àgùntàn tàbí òwú àti nkan tí ó jọ wọ́n.
Àwọn monjẹmu pípa bàtà aláwọ̀ tiko ni itilẹ àti ibọsẹ:
1- Kí o wọ méjèjì lẹyin imọra ti o pe.
2- Ki o bo ẹsẹ mejeeji pẹlu kokosẹ mejeeji.
3- Kí mejeeji o jẹ nnkan ti o mọ.
4- Ki pipa naa o jẹ laaarin àsìkò ti a ti fi gbedeke sí.
5- Ki fífi ọwọ pa jẹ níbi aluwala, kìí ṣe níbi iwẹ.
6- Ki abọsẹsẹ alawọ ati ohun tó jọ ọ́ jẹ́ nǹkan tí ó tọ́; tí ó bá jẹ́ nǹkan tí a fi ipá gbà tàbí ariiri fún ọkùnrin, kò lẹ́tọ̀ọ́ ki a fi ọwọ pa á, nítorí pé nǹkan èèwọ̀ ni a kò fi í gba ìrọ̀rùn.
Àsìkò pípa:
Fun ara ile: Ọjọ kan ati oru kan, àti fun arìnrìn-àjò: Ọjọ mẹta pẹlu àwọn oru wọn.
Bí ase má nfi ọwọ pá:
A óo rẹ ọwọ pẹlu omi gbẹdẹ, a óo sì pa lórí òkè ìbọ̀sẹ̀ olówùú tàbí ìbọ̀sẹ̀ aláwọ mejeeji, láti àwọn orí ọmọ-ika ẹsẹ̀ títí dé ojúgun, lẹ́ẹ̀kan.
Awọn nnkan ti o maa n ba pípa jẹ:
1- Pipari àsìkò pípa.
2- Bibọ ibọsẹ mejeeji tabi ọkan ninu ẹ.
3- Ṣiṣẹlẹ ẹgbin nla.
Ìdájọ́ Pípa ìbọ̀sẹ̀ aláwọ méjèèjì:
Dajudaju o jẹ́ iṣẹ idẹkùn fún ní , ṣíṣe rẹ̀ sì lóore ju bíbọ́ ibọsẹ alawọ mejeeji àti wíwẹ ẹsẹ mejeeji lọ; nitori iṣamulo iyọnda Ọlọhun - Alágbára àti Ọlọ́lá -, àti ikọṣe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, àti iyapa àwọn oni bidi'ah (aladadaalẹ) .
3- Fífi ọwọ pa awọn dídì oju egbo àti ojú ọgbẹ àti plasita:
Al-Jabā'iru: Oun ni nnkan ti wọn fi n so mọ́ egungun tó kán tabi tó fọ́; gẹgẹbii jibs ( iyẹpẹ amọn) tàbí àwọn igi àti nnkan tí ó jọ wọ́n.
Al-asaa'ibu: ni ohun tí a fi n wé mọ́ ọgbẹ tàbí egbò tàbí ìjóná; gẹgẹ bii aṣọ àti irú rẹ̀.
Al-Lusuuq: ni ohun ti a n lẹ mọ awọn ọgbẹ tabi awọn eéwo lati fi ṣe itọju wọn .
Ìdájọ́ fífi ọwọ pa lórí rẹ̀:
O lẹtọọ: nígbà tí a bá ní bùkáàtà sí pípe síi, pẹ̀lú májẹ̀mú pé kò gbọdọ̀ kọjá ibi bùkáàtà.
Kò sì tọ́: nígbàtí ìlò rẹ̀ bá parí, tàbí tí yíyọ ọ́ kúrò kò ní yọrí sí wàhálà tàbí ìpalára.
Bawo ni a o se fi ọwọ pa á lórí :
Yio fọ ayika rẹ, yio si pa a lati gbogbo igun rẹ Kò sì ní fi ọwọ pa èyí tó kọjá ojú ibi aluwala.
Ẹlẹẹkẹjọ: Awọn idajọ Tayammum ( aluwala o ní yẹpẹ )
Aluwala oni erùpẹ̀: ni pípa ojú àti ọwọ́ méjèèjì pẹ̀lú erùpẹ̀, pẹ̀lú àníyàn ìmọ́ra, ni ọnan kan pàtó.
Idajọ rẹ:
Ó di ọranyan láti ṣe tayammum rọpo aluwala àti iwẹ nígbàti koba sí omi, tàbí àìní ikapa láti lo omi.
Ọgbọn tí n bẹ nibi ṣiṣe é ni òfin:
Àlùwàlá oní erùpẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àmì-ìdámọ̀ ìjọ Anọbi, kí ikẹ Ọlọhun àti Ọla Rẹ máa ba a, Kò sì jẹ́ ohun tí a mọ̀ lọdọ àwọn ijọ àṣáájú, tí o jẹ ìgbà láàyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun fun ijọ yii, àti iṣe-rere láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sí i.
Àwọn ìṣesí tí a fi ṣe aluwala oni erùpẹ̀ ní òfin láti ṣe dipo aluwala olómi:
1- Tí a kò ba rí omi, yálà ní ìlú tàbí ní ìrìn-àjò, tí o wá a tí kò sì rí i.
2- Tí omi bá wà pẹ̀lú rẹ̀ tí ó ní bukata sí fún mímu tàbí láti fí se oúnjẹ, tí ó bá fi ṣe imọra, yíò pa bukata rẹ̀ lára tóbẹ́ẹ̀ tí yíò fi máa paya òùngbẹ fún ara rẹ̀, tàbí òùngbẹ ẹlòmíràn nínú ọmọ ènìyàn tàbí ẹranko tí ẹmi wọn jẹ́ ààbò.
3- Ti o ba n paya ipalara si ara rẹ pẹlu lilo omi latari àìsàn tabi aini tete ni iwosan.
4- Ti o ba kagara ati lo omi latari àìsàn ti ko jẹ ki o le gbera, ti ko si ni ẹni ti yíò ba a ṣe aluwala, ti o si n paya ki asiko o bọ mọ oun lọwọ.
5- Ti o ba nbẹru otutu pẹlu lilo omi, ti ko si ri nǹkan ti yio fi mú omi náà gbona , yio ṣe aluwala oni erupẹ, yio si kirun.
Bí a se má nṣe Aluwala oni erùpẹ̀:
Ki o fi ọwọ rẹ mejeeji lu erupẹ pẹlu àwọn ìka tí a yà sílẹ̀, lẹyin naa yóò fi inú àwọn ìka rẹ pa ojú rẹ, yóò sì fi atẹlẹwọ rẹ pa àwọn ọwọ́ rẹ mejeeji, kí ó sì jẹ́ kí pípa náà kan gbogbo ojú àti àwọn ọwọ́ mejeeji.
Awọn nnkan ti o maa n ba Aluwala elérùpẹ̀ jẹ́:
1- Wiwaye omi, ti o ba jẹ pe nitori aisi omi ni a fi ṣe é. Tàbí níní agbára lórí lílo omi, tí ó bá jẹ́ pé ìdí Aluwala elérùpẹ̀ jẹ́ ikagara kuro nibi lilo rẹ̀.
2- O maa n bajẹ pẹlu ọ̀kan nínú àwọn nnkan tí ó n ba aluwala jẹ, tàbí pẹlu ọ̀kan nínú àwọn nnkan tí ó n sọ ìwẹ di dandan, gẹ́gẹ́ bíi janaba, àti ẹjẹ nkan oṣù, àti ẹjẹ ìbímọ.
Idajọ ẹni ti o kagara lati lo omi ati Tayammum (aluwala o ní erupẹ) :
Ẹni tí kò bá rí omi àti erùpẹ̀, tàbí tí ó dé ipò tí kò ti ní ìkapa láti fi omi tàbí erùpẹ̀ kan ara rẹ̀; yíò kirun gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ̀ ṣe rí, láìsí aluwala tàbí tayammam; nítorí pé Ọlọhun kò ní fi ipá kan ẹ̀mí kankan ju agbára rẹ̀ lọ. Bí a bá tilẹ̀ wá gbà pé ó rí omi àti erùpẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, tàbí ó ní ikapá láti lò wọ́n; kò níí ṣe àtúnṣe ìrun tí ó ti kí síwájú; nítorí pé ó ti ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un, Nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿...فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُمۡ...﴾
{Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ}. [At-Tagoobun: 16], Àti nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«إِذَا أَمَرْتُكُمْ بِأَمْرٍ فَأْتُوا مِنْهُ مَا اسْتَطَعْتُمْ».
«Nígbàtí mo bá paṣẹ ohun kan fún yín, ẹ yáá se bí ẹ ba se ni ikapa to»11.
Àǹfààní: Tí o bá ṣe aluwala oniyẹpẹ fún ẹgbin ńlá (janaba), lẹ́yìn náà tí o wá rí omi; yíò wẹ.
Ìkẹsàn-án: Awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ obìnrin:
Akọkọ: Ẹjẹ nnkan oṣu:
Oun ni ẹjẹ adamọ ti o maa n jade lati isalẹ apo ibimọ ni awọn akoko ti a ti mọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jáde ní gbogbo oṣù fún ọjọ mẹfa tàbí ọjọ méje, ó sì lè ní àlékún tàbí ẹdínkù. Oṣu obìnrin a maa gun, a si maa kuru; gẹgẹ bi Ọlọhun ṣe gbé e kalẹ̀ nínú ìṣẹ̀dá.
Awọn idajọ obìnrin tí nṣe ẹjẹ nnkan oṣu:
1- Ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ko ni kirun, bẹẹ si ni ko nii gba awẹ nígbàtí o ba nṣe nnkan oṣu lọwọ, irun ati aawẹ rẹ kò sì ní àlàáfíà fún un.
2- Ẹni ti n ṣe nnkan oṣu yóò san aawẹ nikan pada ti o ba mọra kuro nibi nkan oṣù rẹ, bẹẹ ni ko ní san irun padà .
3- Kò lẹtọ fun un lati ṣe irọkirika ile Ọlọhun, Bẹẹ kò ní máa ka Kuraani, Kò si ní maa jokoo si inu mọsalasi. 4- Wọn ṣe e leewọ fun ọkọ rẹ lati ba a lopọ ni oju ara titi ti nnkan oṣu yoo fi da, ti yoo si wẹ.
5- Ó tọ́ fun ọkọ lati maa gbádùn ara iyawo rẹ ti o n ṣe nnkan oṣu laini ba a lopọ ni oju ara, gẹgẹbi ifẹnukonu, fifi ọwọ kan an, ati bẹẹbẹẹ lọ.
6- Ko tọ fún ọkọ rẹ ki o kọ ọ silẹ nígbàtí o nṣe nkan oṣù lọwọ.
Imọra ni dida ẹjẹ, ti ẹjẹ ba ti da; o ti mọra, akoko nnkan oṣu rẹ si ti pari, iwẹ si jẹ dandan fun un. Lẹyin naa, yoo tun maa ṣe awọn nkan ti wọn kọ fun un láti ṣe nitori nnkan oṣù.
Bí ó bá sì rí omi ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú tàbí omi alawọ iyeye lẹ́yìn imọra; kò níí kà á sí nǹkan kan.
Ẹlẹẹkeji: Ẹjẹ ìbímọ:
Oun ni ẹjẹ kan ti apo ibi maa n da fun bibimọn ati lẹyin rẹ, o si jẹ àṣẹ́kù ẹjẹ ti a sé mọ́ ni asiko oyun.
Ẹjẹ ibimọ da gẹgẹ bii ẹjẹ nnkan oṣu ninu ohun ti o jẹ ẹtọ; gẹgẹ bii ṣiṣe ìgbádùn pẹlu rẹ ni ohun ti o yato si ojú ara.
Ati ninu ohun ti o jẹ eewọ; gẹ́gẹ́ bíi ìbálòpọ̀ ní ojú ara, ati aawẹ gbígbà, ati irun kíkí, ati ìkọ̀sílẹ̀, ati Irọkirika, ati kíkà Al-kurani, ati dídúró nínú Mọṣáláṣí, Ati pe iwẹ jẹ dandan fun un nigba ti ẹjẹ rẹ ba da, gẹ́gẹ́ bíi ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.
Dida aawẹ padà jẹ dandan fún un, ṣùgbọ́n kò níí da irun padà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí n ṣe nnkan oṣù.
Àti pé àkókò rẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ni ogójì ọjọ́, Ti ẹjẹ ìbímọ ba da ṣiwaju ogoji ọjọ, ẹjẹ ìbímọ rẹ ti parí, yoo wẹ, yoo si kirun, yoo si maa ṣe ohun ti a ṣe ní eewọ fún un nítorí ẹjẹ ìbímọ.
Orí iṣẹ iwadi Keji: Irun kiki
Alakọkọ: Awọn idajọ irun pipe ati ikaamọ (igberun dúró) :
A gbé irun pipe kalẹ̀ ní ọdún àkọ́kọ́ lẹyin Ìṣípòpadà Ànábì lọ sí ìlu Modinah, Ìdí tí a fi ṣe e ni ìlànà òfin ìjọsìn: ni pé nígbàtí ó ṣòro fún wọn láti mọ àwọn àsìkò, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ lórí gbígbé àmì kan kalẹ̀ fún un. Ni a wa fi Adhan (ìrun pipe) yii han Abdullahi ọmọ Zaid - ki Ọlọhun yọnu si i - ninu ala, Wahyi si fidi rẹ mulẹ.
Al-Adhan ni ifunnimọ wiwọle asiko irun. Ikaamọ: oun ni ifunnimọ gbigbe irun duro.
Ati irun pipe ati igberun duro ni ọranyan alápamọ́wọ́ lori jamoh awọn ọkunrin fun awọn irun ọranyan, Méjèèjì ni o wa nínú ami tàbí ẹ̀sìn Islam tí ó hàn, nítorí náà kò yẹ láti dá wọn dúró.
Awọn majẹmu irun pípe:
1- Kí oluperun jẹ́ ọkùnrin.
2- Kí a ṣe ìpèrun letoleto.
3- Kí a ṣe ìpèrun ni titẹlerawọn.
4- kí piperun (Al-Adhan) waye lẹyin wiwọle asiko, Wọn yọ irun pípe alakọkọ irun ìdajì ati ti Jimoh kuro ninu iyẹn:
Awọn sunnah irun pipe:
1- Kí ẹni tí nperun fí ìka rẹ mejeeji sinu eti rẹ mejeeji.
2- Pipe irun ni ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò.
3- Yiyi si ọtun ati osi nígbàtí o ba dé bi «ẹ máa bọ kí ẹwa kirun, ẹ máa bọ kí ẹ wa la »; Ha'yala mejeeji.
4- ki o jẹ ẹni tí ohùn rẹ dun .
5- Kí ó máa fi sùúrù sọ àwọn ọ̀rọ̀ Adhan, láì fa ọ̀rọ̀ gun tàbí kí ó ṣe àseju nínú rẹ̀.
6- Ki o maa duro lori gbogbo gbólóhùn inú rẹ̀ kọọkan.
7- Didojukọ Qiblah nígbàtí o ba nperun .
Irun pipe jẹ gbolohun mẹẹdogun, gẹgẹbi Bilaal – ki Ọlọhun yọnu si i – ṣe maa n pe irun pipe niwaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni gbogbo igba.
Awọn gbolohun irun pipe ni:
(Allahu Akbar): Ọlọhun ni o tóbi julọ ni ẹẹmẹrin.
(Ash-hadu an laa ilaaha illallohu):mojẹripe kòsí ẹnikan tí o yẹ kí a fí ìjọsìn fún ayaafi Ọlọhun lẹ́ẹ̀mejì.
(Mo jẹri pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Allah ni): lẹẹmeji.
(Ẹ tara ṣaṣa lọ sibi irun kiki): ẹẹmeji,
(Ẹ tara ṣaṣa lọ sibi ere jijẹ ): A o sọ ọ ni ẹẹmeji.
Lẹyin naa yio sọ pe: (Allāhu akbar) ni ẹẹmeji.
Lẹyin naa yoo parí pẹlu (Laa ilaaha illallohu): lẹẹkan.
Yio si se alekun ni Al-fajri lẹ́yìn AYYA ALAL FALAAH pe: (AS-SOLAATU KHAIRUN MINAN- NAOM) ìtumọ rẹ ni pé : ìrun kiki lóore jù orun sisùn lọ lẹ́ẹ̀mejì; Nítorí pé àkókò tí àwọn ènìyàn sábà máa ń sùn ni.
Gbigbe ìrun duro náà, gbolohun mọkanla ni, tí á máa yára kà á, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: kí á yára nínú rẹ̀; nítorí pé o wa fún síso fún àwọn tó ti wà nílẹ̀ ni, kò wá sídìí fún fífi ìfàlọ̀ kà á.
Ìgbékalẹ̀ rẹ̀ lọ bayi pe:
(Allāhu Akbar) Ọlọhun lo tóbi julọ: ni igba meji.
(Ash-hadu an laa ilaaha illallohu) mojẹripe kòsí ẹnikan kan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún ayaafi Ọlọhun: ẹ'kan ṣoṣo.
(Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah) Mọ jẹri pe Muhammad òjíṣẹ Ọlọhun ni : ẹẹkan ṣoṣo .
(Ẹ tara ṣaṣa lọ sibi irun kiki.): ni ẹẹkan ṣoṣo.
(Ẹ tara ṣaṣa lọ sibi ere jijẹ): ni ẹẹkan. Ṣoṣo
(Irun ti duro): lẹ́ẹ̀mejì.
(Allāhu Akbar) Ọlọhun lo tóbi julọ: ni igba meji.
(Laa ilaaha illallohu) kòsí ẹni kan kan tí o yẹ kí a jọsin fún àyàfi Ọlọhun Allah: Lẹ́ẹ̀kan.
Ati pe o jẹ ohun ti o daa fun ẹni ti o ba gbọ irun pipe ki o maa sọ iru nkan ti oluperun n sọ, ayaafi nibi (Hayya ‘alas sọlāt), ati (Hayya ‘alal falāh) yio sọ pe: (Lā haola walā quwwata illā biLlāh) kòsí ète bẹẹ ni kò sí agbára kan àyàfi tí Ọlọhun, Lẹyin naa yio ṣe asalatu fun anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa yio sọ lẹyin iyẹn pe:
«اللهمَّ رَبَّ هَذِهِ الدَّعْوَةِ التَّامَّةِ، وَالصَّلَاةِ القَائِمَةِ، آتِ مُحَمَّدًا الوَسِيلَةَ وَالفَضِيلَةَ، وَابْعَثْهُ مَقَامًا مَحْمُودًا الَّذِي وَعَدْتَهُ، إِنَّكَ لَا تُخْلِفُ الْمِيعَادَ».
«ire Oluwa Oba ti O ni ipepe ti o pe yi, ati irun ti won gbe duro yi, fun anabi wa Muhammad ni aga wasila ati ola, atipe gbe e dide ni aye ẹyin eyiti O ti se adehun rẹ fun un, dajudaju Irẹ kii yẹ adehun»12.
O maa tún sọ pe:
«رَضِيتُ بِاللَّهِ رَبًّا، وَبِالْإِسْلَامِ دِينًا، وَبِمُحَمَّدٍ ﷺ نَبِيًّا».
«Mo yọ́nú sí Allaah ní Olúwa mi, mo yọ́nú sí Islaam ní ẹ̀sìn mi, mo sì yọ́nú sí Muhammad – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ní Ànábì mi»13.
Jijade kuro ninu mọsalasi lẹyin Adhan jẹ eewọ laini awijare tabi laini erongba lati pada sínú mọnsalasi.
Nigba dida irun meji papọ, irun pipe ẹyọkan ni a o lo, ati iqoomoh fun irun kọọkan.
Ẹlẹẹkeji: Ipo Irun àti ọlá rẹ̀:
Irun ni origun tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ jùlọ ninu awọn origun Isilaamu lẹyin ijẹrii mejeeji. Ó sì ní ipò pàtàkì, Nígbati o se pé Ọlọhun ti ṣe é ní ọranyan lé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ -kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- lórí ní òru Mi'raaj gigun sanmọ lọ, Èyí sì tọ́ka sí títóbi Rẹ̀ àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ijẹ ọranyan Rẹ̀ àti ipò Rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Allah Ọlọhun to gbangban to sí tóbi.
Awọn Hadiisi rẹpẹtẹ ti wa nipa ọla rẹ ati ijẹ ọranyan rẹ lori olúkúlùkù, Ati pe jíjẹ ọranyàn rẹ̀ jẹ́ ohun tí a mọ̀ láti inú ìpìlẹ̀ ẹsìn Islam.
Ninu ohun ti o n tọka si ìjẹ-dandan rẹ ati ìfẹsẹ-múlẹ̀ rẹ: awọn ẹri lati inu Tira ati Sunnah pọ, ninu wọn ni:
1- Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti O ga:
﴿...إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ كَانَتۡ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ كِتَٰبٗا مَّوۡقُوتٗا﴾
{Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo}. [An-Nisa 103]. O n túmọ̀ si: wọn se e ni ọran-anyan ninu awọn akoko ti Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣalaye.
2- ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ حُنَفَاءَ وَيُقِيمُوا الصَّلَاةَ...﴾
{Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn. Kí wọ́n kírun..}.
[Al-bayyinah: 5].
3- ati ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿فَإِنْ تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ...﴾
{Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n jẹ́ ... } [Suuratut Taobah: 11].
Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
«إِنَّ بَيْنَ الرَّجُلِ وَبَيْنَ الشِّرْكِ وَالْكُفْرِ تَرْكُ الصَّلَاةِ».
«Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ»14.
5- Láti ọdọ Buraida - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a- sọ pé:
«العَهْدُ الَّذِي بَيْنَنَا وَبَيْنَهُمُ الصَّلَاةُ، فَمَن تَرَكَهَا فَقَدْ كَفَرَ».
«Adehun ti n bẹ laarin wa ati laaarin wọn ni Irun, ẹnití o ba gbe e ju silẹ ti di keferi ( alaigbagbọ) »15.
Àwọn onimimọ si fohun ṣọkan pe alaigbagbọ ni ẹni ti o ba tako ọranyan rẹ̀, Ṣugbọn fún ẹni tí ó bá gbé e jù sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀lẹ àti àilákákún, èyí tí ó tọ̀nà jùlọ ni pé ó ti di aláìgbàgbọ́ pẹ̀lú, nítorí hadith sọhíhì tí ó ti ṣíwájú, àti nítorí ìfìmọ̀ṣọ̀kan àwọn Sọhābah lórí ìyẹn.
Ẹlẹẹkẹta: Awọn majẹmu irun:
1- Wíwọlé asiko rẹ:
Nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿...إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ كَانَتۡ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ كِتَٰبٗا مَّوۡقُوتٗا﴾
{...Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo}. [Suratu Nisai]. Iyẹn nipe: ọran-anyan ní àwọn àsìkò pàtó.
Àwọn àsìkò àwọn irun ọranyan náà niyi:
a- Irun Aarọ: lati yiyọ alufajari ( imọlẹ ìdajì ) si yiyọ oòrùn.
b- Zuhr (ìrun osan) : Lati igba ti oòrùn bá ti yẹ àtàrí titi di igba ti òjìji gbogbo nǹkan yóò fi dọ́gba pẹ̀lú rẹ̀ ní gígùn.
Asr: (ìrun irọlẹ) Lati igba ti akoko Zuhr ba ti pari titi di akoko ti oorun maa di aláwọ̀ ìyeyè, ati pe akoko làlúrí rẹ ni titi di wiwọ rẹ̀.
d- Magrib (;irun aṣalẹ) : Lati wiwọ oòrùn titi ti awonpapa pupa yóò fi wọlé.
h- Ishai (irun akisun) Lati ipari akoko Maghreb titi di idaji oru.
2- Bibo ihoho:
Oun ni ohun tí ó pọn dandan ní bíbò, tí híhàn rẹ̀ burú, tí a sì máa ń tìjú rẹ̀, Ati pe ihoho ọkunrin ni lati idodo titi de orunkun, Ati pe obìnrin, gbogbo ara rẹ ihoho ni ninu ìrun ayaafi oju rẹ, Yio si bo oju rẹ nígbàtí ó bá wà níbi tí àwọn ọkùnrin ajoji bá wà, ìyẹn ni pé: àwọn tí wọn kìí ṣe eléèwọ̀ rẹ̀.
3- Yiyago kuro nibi ẹgbin:
Ẹgbin ni : Oun ni ẹgbin ( idọti ) kan pàtó, ti irú rẹ̀ n dina irun; gẹgẹ bii itọ ati igbẹ ati ẹ̀jẹ̀ ati àwọn yooku, o si n wa ni ara ati ni ilẹ ati ni aṣọ.
4- Dida oju kọ qiblah:
Qibla ni Kaaba abiyi, a sọ ọ ni Qibla nitori idojukọ awọn eniyan si i.
Nitori naa, irun ko ni ní àlàáfíànlaisi dida oju kọ kiblah, Nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿...وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُ...﴾
{…Ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀…} [Suratul Baqorah: 144].
5- Aniyan: Ero atinu wa:
Ní ìtumọ̀ èdè: Gbigbero, àti ní ìtumọ̀ òfin ẹ̀sìn: ìpinnu lati se ìjọsìn fún isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga. Aaye rẹ̀ ni ọkan, kò sì nílò sí pípe e jáde lẹ́nu, kàkà bẹ́ẹ̀, adadaalẹ ni.
Ẹlẹẹkẹrin: Awọn origun irun kiki:
Origun mẹrinla ni:
Orígun Akọkọ: Diduro pẹlu ini ikapa:
Nítorí ọrọ Ọlọhun ti Ọlá Rẹ ga ti O sọ pe:
﴿...وَقُومُواْ لِلَّهِ قَٰنِتِينَ﴾
{…Kí ẹ sì dúró kírun fún Allāhu ní olùbẹ̀rù Rẹ̀ (láì sì níí sọ̀rọ̀ tó jẹmọ́ tayé lórí ìrun) }. [Al-Baqara:238], Àti hadith Imrān - ki Ọlọhun yọnu sí i - tí a gbé fo lọ̀dọ̀ Ànábi ṣoṣo pe :
«صَلِّ قَائِمًا، فَإِن لَمْ تَسْتَطِعْ فَقَاعِدًا، فَإِن لَمْ تَسْتَطِعْ فَعَلَى جَنْبٍ».
«Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ»16.
Ti ko ba ni ikapa lori iduro nitori aisan kan, yíò kirun gẹgẹ bi ìṣesí rẹ, ni ijokoo tabi ni ifẹgbẹlelẹ. Bi alaarẹ se wa nínú iṣesí rẹ ni: olùbẹ̀rù, oníhòhò, àti ẹni tí ó nílò jijokoo tàbí dídùbúlẹ̀ fún ìtọ́jú tí ó gba àìdide. Bakanna, a yọnda fun ẹniti n kirun lẹyin Imaamu ti agara da lati dide pe ki o ma duro, ti o ba ki irun lori ijoko, awọn ero ẹyin rẹ yio kirun lori ijoko pẹlu gẹgẹ bi itẹle fun imaamu wọn. Ó lẹtọ láti ṣe àwọn nafila ní ìjókòó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lágbára àti dìde dúró, ṣùgbọ́n ẹ̀san kò ní jẹ́ bíi ti ẹni tó dìde dúró.
Orígun Kejì: Kikabara iwọ inu irun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀:
Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«ثُمَّ اسْتَقْبِلِ الْقِبْلَةَ، وَكَبِّرْ».
«Lẹyin naa, doju kọ qiblah, ki o si sọ pe: “Allahu Akbar”»17.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé kí ó sọ pé: (Allāhu Akbar), kò sì sí ohun mìíràn tó tó yàtọ̀ sí i.
Origun ẹlẹẹkẹta: Kika Faatiha:
Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«لَا صَلَاةَ لِمَنْ لَمْ يَقْرَأْ بِفَاتِحَةِ الْكِتَابِ».
«Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha»18.
Origun Ikẹrin: Rukuu nínu gbogbo raka:
nítorí ọrọ Ọlọhun ti Ọlá Rẹ ga O sọ pe:
﴿يَاأَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا ارْكَعُوا وَاسْجُدُوا...﴾
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀... } [Al-Hajj: 77].
Origun ẹlẹẹkarun àti ẹlẹẹkẹfa:
Gbigbori soke kuro nibi itẹriba, ati diduro tọ gẹgẹ bi o ṣe wa ṣiwaju rẹ, nitori pe oun -ki Ọlọhun ṣe ikẹ ati igẹ rẹ fun un- tẹramọ ṣiṣe rẹ.
Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ fun ẹni ti o ṣe aṣiṣe ninu irun rẹ pe:
«ثُمَّ ارْفَعْ حَتَّى تَعْتَدِلَ قَائِمًا».
Lẹ́yìn náà, gbé orí rẹ sókè títí tí o fi dúró déédéé""19.
Òrigun keje: Fífi orí kan'lẹ̀ pẹ̀lú àwọn oríkèé ara méje:
Oun ni iwaju ori pẹlu imu, ati atẹlẹwọ mejeeji, ati orúnkún méjèèjì, ati awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«أُمِرْنَا أَنْ نَسْجُدَ عَلَى سَبْعَةِ أَعْظُمٍ: الجَبْهَةِ، وَأَشَارَ بِيدِهِ عَلَى أَنْفِهِ، وَالكَفَّيْنِ، وَالرُّكْبَتَيْنِ، وَأَطْرَافِ القَدَمَيْنِ».
«Wọn ti pawa laṣẹ ki a fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati atẹlẹwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji»20.
Origun kẹjọ: Gbigbe ori kúrò ni iforikanlẹ àti Ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji:
Nítorí hadith Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-:
«كَانَ النَّبِيُّ ﷺ إِذَا رَفَعَ رَأْسَهُ مِنَ السَّجْدَةِ، لَمْ يَسْجُدْ حَتَّى يَسْتَوِيَ جَالِسًا».
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹniti o jẹ pe, ti o ba gbe ori rẹ dide kuro nibi iforikanlẹ, ko ki n fori kanlẹ titi ti yoo fi joko tọ.21
Òrigun ẹlẹẹkẹsan: Ìfarabalẹ̀ ninu gbogbo àwọn Origun irun:
Oun ni ifaradabalẹ, koda bi o ba kere, nitori ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - fun ẹni ti o ṣàṣìṣe ninu irun rẹ pe:
«حَتَّى تَطْمَئِنَّ».
titi tí o fi balẹ̀ ""22.
Àwọn ọ̀pọ́ méjèèjì: Ẹlẹẹkẹwa àti Ẹlẹẹkọkanla:
Ataaya Igbẹyin àti ìjókòó rẹ̀: nitori hadiisi ọmọ Mas’hood – ki Ọlọhun yọnu si i – tí a gbé so mọ́ Ànábì (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a):
«إِذَا صَلَّى أَحَدُكُمْ فَلْيَقُلْ: التَّحِيَّاتُ لِلَّهِ وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ، السَّلَامُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللَّهِ الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ».
«Tí ọ̀kan nínú yín bá kirun, kí ó wí pé: (Attahiyyātu liLlāh, waṣ ṣolawaatu, wat tọyyibāt, as salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmotuLloohi wabarakātuHu, as salaamu alayna wa alaa ‘ibaadiLlāhis ṣoolihiina, ash’hadu allā ilaaha illa Allāhu, wa ash’hadu anna Muhammadan abduHu wa rọsūluHu (Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, àlàáfíà Ọlọhun kí ó máa bá ìwọ Ànábì àti ìkẹ́ Rẹ̀ àti àwọn ìbùkún Rẹ̀, àlàáfíà Ọlọhun kí ó máa bá àwa náà àti gbogbo àwọn ẹrúsìn Ọlọhun tí wọ́n jẹ́ ẹni rere, mo jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí ní òdodo àyàfi Allāh, mo sì tún jẹ́rìí pé Muhammad ẹrù Rẹ̀ ni, òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì ni))»23.
Origun ẹkejila: Ṣiṣe asalatu fun Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi ataya igbẹyin:
Pẹlu ki o sọ pe:
«اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ».
«Allahumo solli 'alaa Muhammadin»24، Ohun ti o ba si ju iyẹn lọ, Sunnah ( ìlànà anọbi) ni.
Orígun ẹlẹẹkẹtàlá: Ìtòlẹ́sẹẹsẹ láàrin àwọn orígun:
Nitori pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa nṣe é ni tito lerawọn. O sí sọ pe:
«صَلُّوا كَمَا رَأَيْتُمُونِي أُصَلِّي».
«Ẹ máa kirun gẹgẹ bí ẹ ṣe rí mi tí mo nkirun»25. O si ti kọ Ẹni tí ó ṣe àṣìṣe nínú irun rẹ̀ ní títò tẹle ara wọn pẹ̀lú 'Thummo' ( tí o túmọ sí : lẹyìn naa) .
Òrigun kẹrinla: Sisalamọ:
Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
««وَخِتَامُهَا التَّسْلِيمُ».
Ati ìparí rẹ̀ ni salamọ, ati ọrọ re ti o sọ pe:
«وَتَحْلِيلُهَا التَّسْلِيمُ».
«Àti ìparí rẹ̀ ni Taslīm ( kí a salamọ) ».26
Ẹlẹẹkarun-un: Awọn ọranyan irun:
Mẹjọ ni wọn:
1- Gbogbo kabara ( Gbígbé títóbi fún Ọlọhun) yàtọ̀ si kabara ibẹrẹ.
2- Gbolohun «Subhāna robbiyal ‘adhīm» ( ìtumọ : mimọ fún Olúwa mi tí o tóbi julọ) ni ẹẹkan ṣoṣo ni bi rukuu ( itẹriba tàbí itẹ k'ọkọ,) , O si jẹ Sunnah lati fi kun un dé ẹẹmẹta, oun ni pípé tí ó kéré jù, Àti sí mẹwaa, òun sì ni o ga jù nínú rẹ̀.
3- Gbólóhùn: «Sami‘a Allāhu liman hamidahu» (Ọlọhun gbọ òhun ẹni tí o yin) nibi gbigberi dide kuro ni rukuu; fun imaamu ati ẹni ti n da Irun ki.
4- Gbolohun: «Robbanā wa lakal hamdu» (Olúwa wa ) ni iduro taara lẹyin rukuu.
5- Gbolohun: «Subhāna robbiyal ’a‘lā» (mimọ fún Olúwa mi tí o ga jùlọ) ni ẹẹkan ni iforikanlẹ. O si jẹ sunna lati ṣe alekun rẹ de ẹẹmẹta.
6- Gbolohun: «Robbi igfir lī» (Olúwa mi, se aforijin fún mi) laarin iforikanlẹ mejeeji lẹẹkan, Ale fikun titi de ẹẹmẹta jẹ ohun ti o tọna.
7- Ataaya àkọ́kọ́; oun náà ni kí o wí pé:
«التَّحِيَّاتُ لِلَّهِ، وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ، السَّلَامُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللَّهِ الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ».
«At-Tahiyyātu lillāh, was-ṣalawātu wat-ṭayyibātu, as-salāmu ‘alayka ayyuhan-nabiyyu wa raḥmatullāhi wa barakātuhu, as-salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis-ṣāliḥīn, ash-hadu an lā ilāha illallāh, wa ash-hadu anna Muḥammadan ‘abduhu wa rasūluhu» (Gbogbo ìkíni, àwọn àdúrà, àti àwọn iṣẹ́ rere jẹ́ ti Allāh. Àlàáfíà, ìkẹ́ àti ìbùkún Allāh kí ó máa bá ìwọ Ànábì. Àlàáfíà kí ó máa bá àwa àti àwọn ẹrúsìn Allāh olùṣe-rere. Mo jẹ́rìí pé kò sí ẹni tí ó tọ́ sí ìjọsìn àfi Allāh, mo sì jẹ́rìí pé Muhammad jẹ́ ẹrúsìn àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀.)27.
8- Jíjókòó fun ataaya alakọ́kọ́.
Ẹlẹẹkẹfa: Awọn sunnah irun:
Awọn sunnah irun ni nkan gbígbé jù silẹ rẹ kii ba irun jẹ́, Wọ́n pín sí ọ̀nà méjì: Sunna ti ọ̀rọ̀, àti Sunna ti iṣẹ.
Alakọkọ: Àwọn Sunnah ti afi ẹnu se :
1- Adura iṣirun, o si ni awọn agbekalẹ, lara wọn ni:
«سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ، وَتَبَارَكَ اسْمُكَ، وَتَعَالى جَدُّكَ، وَلَا إِلٰهَ غَيْرُكَ».
«Subhānaka allāhumma wa bi amdika, wa tabāraka ismuka wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka» ( Mimọ fún Irẹ Ọlọhun, iwọ ní ẹyin tọ sí, bẹẹ sí ní mimọ ní fún orúkọ rẹ, bẹẹ ni títóbi rẹ ga , bẹẹ sí ní ko si Ọlọhun míràn ti o yẹ kí a fí ìjọsìn fún àyàafi Irẹ Ọlọhun28 .
2- Wiwa iṣọra ṣaaju kíkà Faatiha, Óun ni gbolohun wi pé: «A‘ūdhu billāhi minash Shaytānir rajīm» (Mo wa ìṣọra pẹlu Ọlọhun nípa satani {èsù} ẹni ẹkọ , ẹni egbe}).
3- Ṣiṣe bismillahi ṣaaju kika, Oun ni sísọpé: «Bismillahir Rahmonir Raheem». ( Mọ bẹrẹ pẹlu Orúkọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ aye Ọba asakẹ Ọrùn)
4- Ohun ti o ju ẹyọkan lọ nibi ṣiṣe afọmọ titẹkọkọrọ ati iforikanlẹ.
5- Nnkan ti o lekun lori ẹyọkan ninu gbolohun:
«رَبِّ اغْفِرْ لِي».
«Robbi igfir lī» Laarin iforikanlẹ mejeeji.
6- gbólóhùn:
«مِلْءَ السَّمَاوَاتِ، وَمِلْءَ الْأَرْضِ، وَمِلْءَ مَا بَيْنَهُمَا، وَمِلْءَ مَا شِئْتَ مِنْ شَيْءٍ بَعْدُ».
Ohun ti o kun awon sanmo, ati ohun ti o kun ile, ati kikun ohun to wa laarin awon mejeeji, ati kikun ohun ti O ba fe leyin re. Lẹyin ọrọ gbólóhùn:
«رَبَّنَا ولَكَ الحَمْدُ».
Robbanaa wa lakal-ham'd29. ( Olúwa wa ọpẹ àti ìyìn tí ẹ nii se )
7- Kika nkankan lẹyin Fātiha.
8- Gbólóhùn :
«اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنْ عَذَابِ جَهَنَّمَ، وَمِنْ عَذَابِ الْقَبْرِ، وَمِنْ فِتْنَةِ الْمَحْيَا وَالْمَمَاتِ، وَمِنْ فِتْنَةِ الْمَسِيحِ الدَّجَّالِ».
Ire Oluwa dajudaju emi wa isọ pelu Re kuro nibi iya jahanama, ati kuro nibi iya saare, ati kuro nibi fitina isemi aiye ati fitina ti iku, ati kuro nibi fitina Masiihud-Dajjaal30. Ati ohun ti a ba fi kun adua ṣiṣe nibi ataaya igbẹyin.
Ẹlẹẹkeji: Sunna tí o jẹ iṣẹ:
1- Gbigbe ọwọ mejeeji si deedee ejika mejeeji tabi eti mejeeji ni ààyè mẹrin lórí irun:
A- Níbi kabara iwọ inu irun.
b- Nibi rukuu( itẹ kọkọ).
j- Nibi gbigberi kúrò ni rukuu ( itẹriba) .
d- Nibi didide si rakaa ẹlẹẹkẹta.
2- Fifi ọwọ ọtun lori osi lori igbaaya nigbati a ba wa lórí ìdúró ṣíwájú kí a tio rukuu ( tẹriba ) ati lẹyin rẹ.
3- Ki o maa wo ààyè iforikanlẹ.
4- Gbigbe apa mejeeji jinna si ẹgbẹ mejeeji nibi iforikanlẹ.
5- Gbigbe ikun jina si itan mejeeji nibi iforikanlẹ mejeeji.
6- Jíjókòó le ori ẹsẹ níbi gbogbo ìjókòó lori irun, ayafi níbi ataya ìgbẹ̀yìn níbi irun olopo mẹta ati mẹrin.
7- At-Tawarruk ( kí a fí awẹ ìdí wa joko ) nibi ataaya Igbẹyin nibi irun olopo mẹta tabi olopo mẹrin.
Ẹlẹẹkeje: Àlàyé bí ase má nkirun
1- Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o ṣe wipe ti o ba ti fẹ kirun, yio doju kọ Al-kibla, yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji soke, yio si fi inu ika ọwọ rẹ mejeeji doju kọ Al-kibla, yóò si sọ pe:
«اللهُ أَكْبَرُ».
“Allahu Akbar”
Olohun tobi.
2- Lẹyin naa yio di osi rẹ mu pẹlu ọtun rẹ, yio si gbe awọn mejeeji lori aya rẹ.
3- Yoo wa ṣe adura isi irun, kii si i ṣe ẹniti o maa n wo mọn adura ibẹrẹ ìrun kan ṣoṣo. Gbogbo awọn adua iṣirun ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ ni o yẹ lati fi ṣi irun, lara wọn ni:
«سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ، وَتَبَارَكَ اسْمُكَ، وَتَعَالى جَدُّكَ، وَلَا إِلٰهَ غَيْرُكَ».
Mimo Re Ire Oluwa pelu ẹyin Re, atipe oruko Rẹ ni ibukun, ati wipe Ọlá Rẹ ga, atipe ko si eniti ijosin tosi yato si Iwo.
4- Lẹyin naa yio sọ pe:
«أَعُوذُ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ، بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ».
A'uudhu billahi minaa -sh- Shaitoonir Rajeem, (mọ wa isọ pẹlu Ọlọhun níbi aburú èsù ẹni ẹkọ ẹni egbe) Bismillahir Rahmonir Raheem (mosi nbẹrẹ irun pẹlu Orúkọ Ọlọhun Oba onikẹ láyé a sakẹ ọrùn.
5- Lẹyin naa yio ka Fātiha, ti o ba ka a tan, yio sọ pe: “Aamin”.
6- Lẹyin naa yio ka eyikeyi ti o ba rọ ọ lọrun ninu Al-Qur'āni, Yio si ka (Al-Qur'an) soke nibi irun Fajr, ati nibi rakah mejeeji akọkọ irun Magrib ati Ishai. Yóò si máa ṣe kíkà náà ní jẹjẹ ní ibi to yàtọ̀ sí ìyẹn. A maa fa raka akọkọ gun ju ẹlẹẹkeji lọ nibi gbogbo irun.
7- Lẹyin naa yio gbe ọwọ rẹ mejeeji soke gẹgẹ bi o ti gbe wọn soke nibi ṣiṣi irun, Lẹyin naa yoo sọ pe: «Allāhu Akbar», Yio si wo lọlẹ fun rukuu (itẹriba) , Yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji lórí orunkun rẹ mejeeji ti yio si ya awọn ọmọnika rẹ, yio si na ẹyin rẹ, yio si jẹ ki ori rẹ ṣe déédéé ẹyin rẹ; kii gbe e soke bẹẹni kii si rẹẹ silẹ. O maa tún sọ pe:
«سُبْحَانَ رَبِّيَ الْعَظِيمِ» مرةً.
Mimọ fún Oluwa mi ti O tobi, ni ẹẹkan ṣoṣo, Pipe ti o kere ju: ẹẹmẹta, gẹgẹ bi o ti ṣiwaju.
8- Lẹyin naa yoo gbe ori soke lẹniti yio maa sọ pe:
«سَمِعَ اللَّهُ لِمَنْ حَمِدَهُ».
Samihal-Lọọhu liman hamidah (Ọlọhun gbọ uhun ẹni tí o yín) Yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè gẹgẹ bi o ṣe gbe e nibi Itẹkọkọ.
9- Tí o ba ti dide dúró deede yóò sọ pe:
«اللَّهُمَّ رَبَّنَا وَلَكَ الْحَمْدُ، حَمْدًا كَثِيرًا طَيِّبًا مُبَارَكًا فِيهِ، مِلْءَ السَّمَاءِ، وَمِلْءَ الْأَرْضِ، وَمِلْءَ مَا بَيْنَهُمَا، وَمِلْءَ مَا شِئْتَ مِنْ شَيْءٍ بَعْدُ، أَهْلَ الثَّنَاءِ وَالْمَجْدِ، أَحَقُّ مَا قَالَ الْعَبْدُ، وَكُلُّنَا لَكَ عَبْدٌ، لَا مَانِعَ لِمَا أَعْطَيْتَ، وَلَا مُعْطِيَ لِمَا مَنَعْتَ، وَلَا يَنْفَعُ ذَا الْجَدِّ مِنْكَ الْجَدُّ» .
Allaahumma Rabbanaa walakalhamd hamdan kathiiran tayyiban mubaarakan fiih mil'as-samaa'i wamil'al ardi wamil'a maa baynahumaa wamil'a maa shi'ta min shay'in ba'du, ahlath-thanaai walmajdi, ahaqqu maa qaalal abdu wakullunaa laka abdu, laa maani'a limaa a'tayta walaa mu'tiya limaa mana'ta walaa yanfa'u dhal jaddi minkal jaddu. (Irẹ Ọlọhun Olúwa wà ni ọpẹ tọ sí, ìyìn àti ọpẹ́ tí o pọ, tí o sí mọn , tí ìbùkún wa níbẹ, tí yóò kún sanmọ, tí yóò kún ilẹ, tí yóò sí kún ààrin méjèjì, tí yóò sí kún nkán tí ọ bà tunfẹ kẹlẹ lẹyìn bẹ, iwọ ni ẹni ìyìn àti gíga, òun to lẹtọ jù tí ẹrú le máa sọ, gbogbo wa ni a jẹ ẹrù fún ọ, kò sí ẹ ni o fẹ kọ ọrẹ tí ọ ba fún ní , bẹẹ kòsí ẹ ni tí o le fún ní ni nkan tí o ba kọ láti fún ní, bẹẹ ni igbiyanju kan kò leè se ni ní anfani, ọdọ rẹ ni ifini se kò ngẹ wa . 31 A máa pẹ́ nínú diduro deede yii.
10- Lẹyin naa yio kabara, yio si dojúbolẹ̀ lati ṣe iforikanlẹ, kò sì níí gbe ọwọ́ rẹ méjèèjì sókè, A si maa nfori kanlẹ lori iwaju ori rẹ, ati imu rẹ, ati ọwọ rẹ mejeeji, ati orunkun rẹ mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji, A si maa fi ọmọ ika ọwọ rẹ ati ẹsẹ rẹ doju kọ Qiblat. O si máa nṣe dọgba nínú iforikanlẹ rẹ, Yoo gbe iwaju ori rẹ ati imu rẹ le ilẹ daadaa, Yoo fi àtẹ́lẹwọ́ rẹ tilẹ, yoo si gbe ìgbọ̀nwọ́ rẹ soke, Yíò sì yà apá rẹ mejeeji kúrò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ mejeeji, yio si gbé ikùn rẹ jìnà sí itan rẹ méjèèjì, àti yíya àwọn ìtàn rẹ̀ kúrò lára àwọn ojúgun rẹ̀. O maa n sọ ni iforikanlẹ rẹ pe:
«سُبْحَانَ رَبِّيَ الأَعْلَى».
Mimọ ni fun Oluwa mi, Ọba ti O ga julọ. lẹẹkan, pípé tí ó kéré jù ni ẹẹmẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣíwájú, Yóò si ṣe adura pẹ̀lú èyí tí ó wá.
11- Lẹyin naa yoo gbe ori soke lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», Lẹyin naa yoo tẹ ẹsẹ osi rẹ silẹ, yoo joko le e, yoo si gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke. A si maa gbe ọwọ rẹ mejeeji le itan rẹ mejeeji, lẹyin naa yio sọ pe,
«اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِي، وَارْحَمْنِي، وَاجْبُرْنِي، وَاهْدِنِي، وَارْزُقْنِي».
«Allaahummọ igfir lii, war'ham'nii, waj'bur'nii, wah'dinii, warzuknii» (Ọlọhun forí jìn mí, kí o sí k'ẹmi, kí o sí ṣe atunṣe mí, kí o sí fí ọnàn mí, kí o sí pẹ se fún mí).32
12- Lẹyin naa yio kabara yio si fi ori kanlẹ, yio si ṣe ninu ikeji gẹgẹ bi o ti ṣe ninu akọkọ.
13- Lẹyin naa yoo gbe ori rẹ soke lẹniti yio maa sọ pe: “Allāhu Akbar”, yoo si fi iwaju ẹsẹ rẹ dide, ti yoo si sinmi le orunkun rẹ ati itan rẹ méjèjì.
14- Tí o bá ti dúró dédé tan, yio wá bẹrẹ si ni ka Al-Quran. Yio sí ki raka keji gẹgẹ bii alakọkọ.
15- Lẹyin naa yio jókòó fun ataaya àkọ́kọ́ ni ìjókòó ìtẹ́lẹ̀, gẹgẹ bi o ṣe n joko laaarin iforikanlẹ mejeeji, Yoo si gbe ọwọ ọtun rẹ le itan ọtun rẹ, yoo si gbe ọwọ osi rẹ le itan osi rẹ, Yio si fi àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe bi oruka le ìka rẹ àárín. Yíò sì fi ìka ifabẹla rẹ tọka, yíò sì máa wò ó. O maa tún sọ pe:
«التَّحِيَّاتُ لِلَّهِ وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ، السَّلَامُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللَّهِ الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ».
«At-Tahiyyātu lillāhi was-ṣọlawātu wat-ṭọyyibātu, as-salāmu ‘alayka ayyuhan-nabiyyu wa raḥmatullāhi wa barakātuhu, as-salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis-ṣọlihīn, ash-hadu an lā ilāha illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, wa ash-hadu anna muhammadan ‘abduhu wa rasūluhu» (Gbogbo ìkíni, àdúrà àti àwọn ohun rere jẹ́ ti Allāh. Àlàáfíà, ìkẹ́ àti ìbùkún Allāh kí ó máa bá ìwọ Ànábì. Àlàáfíà kí ó máa bá àwa àti àwọn ẹrúsìn Allāh olódodo. Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó tọ́ sí ìjọsìn àyàfi Allāh, Òun nìkan ṣoṣo ni, kò ní akẹgbẹ́. Mo sì jẹ́rìí pé Muhammad jẹ́ ẹrúsìn àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀.) A si maa yara ka ìjókòó yii.
16- Lẹyin naa yio dide pẹlu kabara, yio si ki rakaa kẹta ati kẹrin, yio si mu awọn mejeeji fúyẹ́ ju awọn meji akọkọ lọ. yoo si ka Faatiha ninu awọn mejeeji.
17- Lẹyin naa, yoo joko ni ijoko At-Tawarruk (tí yóò fí awẹ ìdí rẹ le'lẹ) nibi ataaya Igbẹyin, Tawarruku ni ki o tẹ ẹsẹ rẹ osi silẹ, ki o si yọ ọ jade si ẹgbẹ ọtun, ki o gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke, ki o si fi idi rẹ le ilẹ.
18- Lẹyin naa yio ka Ataaya Igbẹyin, oun si ni: gẹgẹ bii Ataaya àkọ́kọ́, Yóò tún se alekun si pe:
«اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ، وَبَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ».
Irẹ Oluwa se ikẹ fun anabi Muhammad ati awon ara ile anabi Muhammad, gege bi O se se ikẹ fun awon ara ile anabi Ibrahim, dajudaju Iwo ni Oba Eleyin ti O gbonngbon, ki O si se ibukun fun anabi Muhammad ati awon ara ile anabi Muhammad, gege bi O se se ibukun fun awon ara ile anabi Ibrahim, dajudaju Ire ni Oba Eleyin, Oba ti O gbonngbon.
19- Yio si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi iya Jahannama, ati kuro nibi iya saare, ati kuro nibi fitina iye ati iku, ati kuro nibi fitina Masiihu Dajjal. Yóò si máa ṣe adua pẹlu àwọn adua tí ó wá lati inú Iwe Ọlọhun àti Sunna.
20- Lẹyin naa yio waa salamọ si ọtun rẹ, ti yio si maa sọ pe:
«السَّلَامُ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَةُ اللَّهِ».
As-salaamu alaykum warahmatul Lọọhi ( àlàfíà Ọlọhun àti ikẹ rẹ kí o máa bayin) Ati ni apa osi rẹ bẹẹ gẹgẹ; Yóò bẹrẹ salamọ bí ó ṣe dojúkọ Qiblah, yóò sì parí rẹ̀ nígbàtí yíyijú ṣegbe bá parí.
Ẹlẹẹkẹjọ: Awọn ohun ikorira lori irun:
1- Sisiju wo ẹgbẹ lai ní bukata si
2- Gbigbe ojú soke.
3- Pipa oju mọ́ ( tàbí didi ojú) láìnídìí.
4- Títẹ́ apa mejeeji sílẹ̀ nibi iforikanlẹ.
5- Dídì nkan mo ẹnu àti imú láì ni bukata si.
6- Kíkí irun nígbà tí itọ̀ tàbí igbẹ bá n kóni, tàbí níwájú oúnjẹ tí ó wu ni.
7- Fífi ọwọ nu ohun tí ó lẹ̀ mọ́ iwájú rẹ̀ àti imú rẹ̀ kuro látàrí ipa ifi-ori-kanlẹ, kò sì sí nto buru láti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ìparí irun.
8- Gbígbára lé ògiri tàbí ohun tó jọọ lórí ìdúró lọrùn láìnídìí.
Ẹlẹẹkẹsan-an: Awọn nnkan ti wọn n ba irún jẹ:
1- Jíjẹ ati mimu nkan .
2- Ọrọ sísọ tí kii se ará rẹ̀.
3- Ẹrin rírín àti ẹrin àháhá.
4- Gbigbe ọkan ninu awọn origun rẹ tabi awọn ọranyan rẹ ju silẹ ni ti amọọmọ ṣe.
5- Mí mọn mọn se àfikún Origun kan tàbí í raka.
6- Mímọ̀ọ́mọ̀ salamọ ṣíwájú Imāmu.
7- Lilọ-bibọ to pọ to tẹle ara wọn ti kii ṣe ara irun láìsí bukaata si.
8- Ṣiṣe ohun ti o lodi si ọkan ninu àwọn májẹ̀mú irun; gẹgẹ bi bibajẹ aluwala, ati ṣiṣi ihoho ará sile mọọmọ, ati yiyi pẹlu ara lọpọlọpọ kuro nibi ọgan-angan Qibla lai si dandan, ati gige ànìyàn.
Ẹlẹẹkẹwaa: Iforikanlẹ ti ìgbàgbé:
As-sahwu: ìgbàgbé ni, Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) ti se ìgbàgbé nínú irun rí; torí pé ìgbàgbé jẹ́ ara ìṣẹ̀dá ènìyàn, Ìgbàgbé rẹ sì jẹ́ lára pípé ìdẹ̀ra Ọlọhun lórí ìjọ rẹ àti àṣepé ẹsin wọn, kí wọn lè fi ṣe àwòkọ́ṣe nínú ohun tí Ó fi ṣe òfin fún wọn nígbà ìgbàgbé.
Awọn okunfa ti a fi n ṣe Iforikanlẹ ìgbàgbé:
1- Isesí alakọkọ:
Alekun nibi Irun, ó sì jẹ́ yálà alekun iṣe tàbí alekun ọrọ:
A- Alekun awọn iṣe: Ti alekun ba jẹ́ lati ara iru Irun: gẹ́gẹ́ bíi dide duro ni ipò jijoko, ati jijoko ni ipò dide duro, tabi o ṣe alekun rukuu tabi iforikanlẹ, ti o ba wa ṣe ìyẹn nitori ìgbàgbé; o maa ṣe iforikanlẹ ìgbàgbé.
B- Àfikún àwọn ọrọ sísọ: gẹ́gẹ́ bí kíkà nkán ní bi rukuu (itẹriba) àti iforikanlẹ,
Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀; ó jẹ́ ohun tí ó dára fún un láti ṣe Iforikanlẹ ìgbàgbé.
2- Ìsesí ẹlẹẹkeji:
Àdínkù nínú Irun nípa ìgbàgbé, ni ó le wa yé pẹ̀lú ọ̀kan nínú alamọri méjì:
A- Gbigbe origun kan ju silẹ: bi o ba jẹ pe origun yii jẹ Takbiratul-ihram, irun rẹ kò gbè, ati pe Sujudus-sahwi kò le e gbè é. Ṣugbọn ti o ba jẹ orígun mìíràn yàtọ̀ sí kabara al-ihram ( tí ibẹrẹ ìrun) gẹ́gẹ́ bí rukuu tàbí iforikanlẹ, ti o si ranti rẹ ṣíwájú ki o to bẹrẹ kika raka mìíràn; o jẹ dandan fun un lati pada, ki o wa ṣe é ati nǹkan ti o tẹle e.
Ti o ba si ranti rẹ lẹyin ti o ti bẹrẹ si ni keu ni rakah miiran, rakah ti o fi silẹ naa ti bajẹ, rakah ti o tẹle e yoo si duro ni ipo rẹ.
b- Gbigbe ọran-anyan ju silẹ: gẹ́gẹ́ bíi: gbigbagbe ataya àkọ́kọ́, tàbí ṣíṣe tasbiih (afọmọ fún Olohun) níbi irukúù.(itẹriba) Ninu irú ìsesí báyìí: yio ṣe iforikanlẹ ìgbàgbé.
3- Ìṣesí ẹlẹẹkẹta: Ìyè méjì:
Àpẹẹrẹ: ti o ba ṣe iyemeji boya o ki mẹta ni tabi mẹrin ninu irun Dhuri, ni ipo yii:
a- Ti adiyanju kan ba han si i, yoo gbe e ṣiṣẹ, yoo si fi ori kanlẹ fun igbagbe.
b- Pe ko si nkankan ti o fẹsẹmulẹ fun un, yio gbe e le ori amọdaju, yio si forikanlẹ igbagbe.
Ti iyemeji ba si jẹ lẹyin irun, tabi ti o jẹ ẹni ti o n ṣe iyemeji pupọ; ko ni kọbiara si iyemeji yẹn.
Àǹfàní: Iforikanlẹ ìgbàgbé yio waye ṣaaju salamọ: ti o ba jẹ nitori àdínkù, tabi nitori iyemeji ti nnkan kan kò si leke tàbí rinlẹ ni ọdọ rẹ. Yóò sì waye lẹ́yìn sísálámọ̀: tí ó bá jẹ́ nítorí àfikún, tàbí nítorí iyèméjì tí a ti mú èyí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ jùlọ, Àti pé ìgbà láàyè wa níbẹ̀, ti Ọlọhun tí o ga jùlọ bá fẹ́.
Ẹlẹẹkọkanla: Awọn asiko ti a kọ irun kiki nibẹ:
Ìpìlẹ̀ ni pé, irun kiki lẹ́tọ̀ ní gbogbo awọn asiko, Ṣugbọn Ofin Islam wá pẹlu ṣíṣe kiki irun ni eewọ ni awọn asiko kan, awọn naa si niyi:
1- Lẹyin irun alufajari ( Asuba ) titi ti oorun yoo fi yọ to yoo si ti ga ni odiwọn ọ̀kọ̀ kuro lori ilẹ nibi riri oju.
2- Nigbati oorun ba wa lori atari titi yoo fi yẹ, oun si ni asiko eewọ to kuru ju.
3- Lati àsìko irun Asri titi ti oorun o fi wọ, oun si ni asiko kikọ ti o gun julọ.
Awọn irun ti o yọnda lati ki ni awọn asiko tí wọn se Irun leewọ:
1- Sisan awọn ọran-anyan tí ó ti kọjá padà .
2- Irun tí ó ní ìdí, gẹ́gẹ́ bíi: Irun kiki Mọsalasi, àti Raka meji ti Tawaf, àti Irun Kusuufi, àti Irun Janasah.
3- Sisan Sunnah Al-fajri ( Irun aarọ ) lẹ́yìn Irun Al-fajri ( aarọ)
Ikejìlá: Irun janmọọn ( irun ala jọ kí papọ) :
Oun si jẹ́ ami ẹ̀sìn nla kan ninu awọn ami ẹ̀sìn Islam, oun naa si ni irun janmọọn ni awọn mọṣalaṣi, Dajudaju awọn Musulumi ti fẹnu kò papọ̀ lórí pé kíki àwọn irun maraarun-un nínú àwọn mọ́sálásí wà nínú àwọn iṣẹ́ ìgbọràn tí a tẹnumọ́ jùlọ àti àwọn iṣẹ́ àmúnisúnmọ́ tí ó tóbi jùlọ, kódà, òun ni èyí tí ó tóbi jùlọ nínú àwọn àmì ẹ̀sìn Islam.
1- Idajọ irun ni janmọ:
Irun janmọọn jẹ dandan ninu mọsalasi fun àwọn Irun ọranyan máàrún fún awọn ọkunrin ti o ni agbara, ni ilé ati ni ìrìn-àjò, ní ipò ifọkanbalẹ àti ní ipò ìpayà gẹ́gẹ́ bí àdáṣe-dandan.
Ẹ̀rí lórí ijẹ dandan irun janmọọn ni: Al-Qur'aani àti Sunnah, àti iṣe àwọn Musulumi láti ìran dé ìran, èyí tí àwọn ẹni ìkẹyìn gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣíwájú.
Ninu Tira: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti O ga ti o sọ pé :
﴿وَإِذَا كُنتَ فِيهِمۡ فَأَقَمۡتَ لَهُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَلۡتَقُمۡ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُم مَّعَكَ...﴾
{Nígbà tí ọ bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ... } [An-Nisaa 102]. Nígbàtí Ayah naa ṣe tọka si ìtẹnumọ́ ijẹ dandan irun janmọọn, Níbi tí a kò ti ṣe idẹkùn fún awọn Musulumi láti fi sílẹ̀ ní àsìkò ìbẹ̀rù, Ti ko ba jẹ ọran-anyan ni, àwíjàre tí ó yẹ jùlọ fún yíyẹ kúrò rẹ̀ ni ìbá jẹ́ àwíjàre ìbẹ̀rù. Fifi irun janmọọn silẹ ati imaa fa sẹyin nipa rẹ wa ninu awọn iroyin àti ise awọn munaafiki to gbajumọ julọ.
Ninu Sunnah: awọn Hadiisi pọ, ninu wọn ni:
Ohun to wa ninu tira Muslim tii ṣe sahiih
أَنَّ رَجُلًا أَعْمَى قَالَ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، لَيْسَ لِي قَائِدٌ يَقُودُنِي إِلَى الْمَسْجِدِ، فَسَأَلَهُ أَنْ يُرَخِّصَ لَهُ أَنْ يُصَلِّيَ فِي بَيْتِهِ، فَرَخَّصَ لَهُ، فَلَمَّا وَلَّى دَعَاهُ فَقَالَ: «هَلْ تَسْمَعُ النِّدَاءَ؟» قَالَ: نَعَمْ، قَالَ: «فَأَجِبْ».
pe Arakunrin afọju kan sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti yio fa mi wa si mọṣalaṣi, ni o wa bi i leere ki o ṣe ẹdẹ fun un ki o maa kirun ni inu ile rẹ, ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: «Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun»33.
Ni Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa paṣẹ fun un pe ki o maa wa si mọṣalaṣi lati kirun janmọọn ati ki o maa jẹ ipe, pẹlu pe o jẹ afọju ati pẹlu inira ti o maa n ba pade. Ni Èyí ba da lori pe irun janmọọn jẹ dandan.
2- Ohun ti a fi n ba Jama'ah:
A n ba jama'ah nípa biba rakah kan ninu irun pẹlu imaamu, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«مَنْ أَدْرَكَ رَكْعَةً مِنَ الصَّلَاةِ فَقَدْ أَدْرَكَ الصَّلَاةَ».
“Ẹni ti o ba ba rakah kan ninu irun ti ba irun”34.
3- Ohun ti a fi n ba raka:
A n ba rakah pẹlu biba Rukuu (itẹriba) , Ti ẹni ti o gbẹyin ba ba imamu rẹ lẹni ti o n rukuu (tí o tẹriba) : o jẹ dandan fun un ki o kabara ti ibẹrẹ irun lẹni ti o duro, lẹyin naa, yio wa kabara lẹẹkan si fun rukuu, yio si rukuu, Ti o ba si daa mọ lórí kabara ibẹrẹ irun nigba iduro rẹ, o ti to o fun kabara rukuu.
4- Àwọn àwíjàre tí ó ń jẹ́ kí ènìyàn gbé irun jámọ́ọ̀ ju silẹ:
1- Aisan, ti o ba nfa inira fun wiwa si jímọ̀ ati jama'ah.
2- Dídá itọ tabi igbẹ padà; nitori pe o maa n mu ìrẹlẹ ọkan lọ ninu irun, ati nitori ipalara ti o wa ninu rẹ fun ara.
3- Wíwà ounjẹ nígbà tí ebi bá n pa ènìyàn tàbí tí ọkàn rẹ̀ bá n fà sí i, lórí pé a kò níí sọ ọ́ di àṣà tàbí ẹ̀tàn láti fi yẹra fún irun janmọọn.
4- Ibẹru tí ó dájú lori ẹmi tabi dúkìá tabi nnkan miiran.
IKẹtàlá: Irun ní àsìkò ìpayà:
Irun ìpayà jẹ́ ohun tí a fi lélẹ̀ nínú gbogbo ogun jíjà tí ó bá lẹ́tọ̀ọ́, gẹ́gẹ́ bíi ogun jíjà sí àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn ọlọ̀tẹ̀, àti àwọn oníjàgìdíjagan, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọhun tí o Ọlá Rẹ ga julọ-:
﴿...إِنۡ خِفۡتُمۡ أَن يَفۡتِنَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ...﴾
{...tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fòòró yín... } [An-Nisaa:101], Sì fi èyí díwọ̀n àwọn yòókù nínú àwọn tí o lẹtọ láti gbé ogun tì wọ́n.
Wọn gbé Irun ìpayà kalẹ̀ pẹ̀lú majẹmu meji:
1) Ki ọta naa jẹ ẹni ti o lẹtọ lati pa tàbí láti kọjú ìjà sí.
2) kí ibẹ̀rù ìkọlù ọ̀tá sí àwọn musulumi lásìkò irun wa ye .
Ìròyìn Irun ìpayà
O ni awọn iroyin oríṣiríṣi; èyí tí o gbajumọ jù ninu rẹ ni gẹgẹ bi o ṣe wa ninu hadith Sahl -kí Ọlọhun yọnu si- ni:
أَنَّ طَائِفَةً صَفَّتْ مَعَ النَّبِي ﷺ، وَطَائِفَةً وِجَاهَ العَدُوِّ، فَصَلَّى بِالَّتِي مَعَهُ رَكْعَةً، ثُمَّ ثَبَتَ قَائِمًا، وَأَتَمُّوا لِأَنْفُسِهِمْ، ثُمَّ انْصَرَفُوا، وَصَفُّوا وِجَاهَ العَدُوِّ، وَجَاءَتِ الطَّائِفَةُ الأُخْرَى، فَصَلَّى بِهِمُ الرَّكْعَةَ الَّتِي بَقِيَتْ مِنْ صَلَاتِهِ، ثُمَّ ثَبَتَ جَالِسًا، وَأَتَمُّوا لِأَنْفُسِهِمْ، ثُمَّ سَلَّمَ بِهِمْ.
dajudaju ikọ kan to saafu pẹlu Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –, ti ikọ kan si daju kọ awọn ọta, o si ki rakaa kan pẹlu awọn ti wọn wa pẹlu rẹ, lẹyin naa ni o wa pẹ lori iduro, wọn parí iyoku funra wọn, lẹyin naa ni wọn kuro, ti wọn si to lẹniti wọn daju kọ awọn ọta, awọn ikọ keji naa si wa, o si ki rakaa kan ti o ṣẹku pẹlu wọn, lẹyin na ni o wa pẹ ni ijoko, ti wọn si pari ọkan ti o ku funra wọn, o si salamọ pẹlu wọn35.
A o se anfaani Irun ìpayà:
1- Pataki Ìrun nínu Ìsìlámù, àti pataki irun janmọọn, dájúdájú kò yẹ kúrò ní àwọn àkókò ìṣòro wọ̀nyí.
2- Gbigbe ìdààmú kuro fun ìjọ yii, ati ìrọ̀rùn ofin sharia, ati bibamu rẹ fun gbogbo àsìkò ati ibi gbogbo.
3- Pipe Sharia Isilaamu, àti pé ó ṣe ohun tó bá ipò kọ̀ọ̀kan mu ní òfin.
Ẹkẹrinla: Irun Jimọ:
Alakọkọ: idajọ rẹ̀:
Irun Jímọ̀ jẹ́ ọranyàn lórí gbogbo Mùsùlùmí ọkùnrin, tó ti bàlágà, tó ní làákàyè, olugbelu, tí kò ní àwíjàre.
Nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَوٰةِ مِن يَوۡمِ ٱلۡجُمُعَةِ فَٱسۡعَوۡاْ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَذَرُواْ ٱلۡبَيۡعَۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 9﴾
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀}. [Surah Al-Jumu`ah: 9].
Àti nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«لَيَنْتَهِيَنَّ أَقْوَامٌ عَنْ وَدْعِهِمُ الْجُمُعَاتِ، أَوْ لَيَخْتِمَنَّ اللَّهُ عَلَى قُلُوبِهِمْ، ثُمَّ لَيَكُونُنَّ مِنَ الْغَافِلِينَ».
«Àwọn ènìyàn kan gbọdọ̀ jáwọ́ níbi fífi irun jímọ̀ sílẹ̀, tàbí kí Ọlọhun fi edidi di ọkàn wọn pa, lẹ́yìn náà, wọn yóò wá wà lára àwọn afọ́núfọ́ra».36
Ẹlẹẹkeji: Awọn majẹmu ilalaafia Irun Jimọ kiki:
a) Akoko: Akoko rẹ jẹ gẹgẹ bi akoko Zuhr, Ko nii ni alaafia ṣiwaju asiko rẹ, bẹẹ ni ko si nii ni lẹyin jijade àsìko rẹ.
2) Ki àpapọ awọn jamoh wa níbẹ, iye ènìyàn tí ó kéré jù fún jamoh sì ni mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àbá tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. ko si nii ni alaafia lati ọdọ ẹni kan ṣoṣo, bẹẹni kii ṣe lati ọdọ eniyan meji.
3) Pé kí àwọn olùkírun jẹ́ olùgbélu tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, nínú àwọn ibùgbé tí a kọ́ pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ àṣà láti fi kọ́lé, Boya o jẹ simenti onirin, tabi awọn okuta, tabi amọ̀, ati nkan ti o yatọ si ìyẹn, Lórí èyí, kò ní tọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará aṣálẹ̀ oní àtíbàbà, àwọn tí kò ní ibùgbé kan pàtó, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń ṣí kiri láti máa tọpa koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
4) Kí ìwàásù méjì ṣáájú rẹ̀, nitori wíwo mọn tí Anọbi wo mọn -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn méjèjì.
Ẹlẹẹkẹta: Àwọn òrígùn khutuba Jímọ̀ méjèèjì:
1- Yinyin Ọlọhun àti Ijẹrii mejeeji.
2- Ṣíṣe asalaatu fun Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.
3- Pípaṣẹ, tàbí sísọ aṣọọlẹ ìbẹ̀rù Ọlọhun.
4- Kika díẹ̀ ninu Al-Qur'ān.
5- Ìwàásù.
Ẹlẹkẹrin: Àwọn ìfẹ́núṣe khutuba Jímọ̀ méjèjì.
1- ki khutuba waye lori minbari ( pepele) .
2- fífi ijoko ránpẹ́ sí aarin khutuba mejeeji . 3- Gbigba àdúrà ninu awọn mejeeji fun awọn musulumi ati fun awọn adari wọn.
4- Gígẹ́ mejeeji kúrú.
5- Sísalamọ Alufa si àwọn ènìyàn nígbàtí ó bá gun orí Mimbari.
Ẹkarun-un: Awọn nkan ti wọn fẹ ni ọjọ Jimọ:
1- Rirun pako
2- Lílo lọfinda tí a bá rí i.
3- Titete jáde lọ si ibi ikírun jímọ̀.
4- Ririn lọ si mọsalasi, kí a ma ṣe gun nkankan.
5- Sísúnmọ́ Imāmu.
6- Adua
7- Kika suratul kahf.
8- Ṣiṣe asalaatu fun Anabi ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
Ẹlẹkẹfa,: Àwọn ohun tí a kà léèwọ̀ fún ẹni tí ó wá sí Jumu'a:
1- Ọrọ sisọ jẹ eewọ ti Imaamu ba nṣe khutuba lọwọ ni ọjọ jimọh, nitori ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
«إِذَا قُلْتَ لِصَاحِبِكَ يَوْمَ الْجُمُعَةِ: أَنصِتْ، وَالْإِمَامُ يَخْطُبُ، فَقَدْ لَغَوتَ».
«Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ ni ọjọ jimọ pe: Dakẹ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ»37. Ìyẹn ni pé: o sọ ọ̀rọ̀ àìníláárí, ọ̀rọ̀ àìníláárí sì ni ẹ̀ṣẹ̀.
2- A kórìíra, a kò fẹ dída ọrùn àwọn ènìyàn kọjá, àfi bí ó bá jẹ́ Imọ́mù, tàbí dídá kọjá sí ààyè kan tí kò le dé bẹ̀ àfi pẹ̀lú bẹ́ẹ̀.
Biba Irun Jimọ:
Ẹni ti o ba ba rukū' pẹlu Imọmu ninu rakah keji ninu irun Jumu'ah; o ti ba Jumu'ah, yio si pari rẹ ni rakah meji ni . Ṣugbọn ti ko ba ba rukuu nínu rakah ikeji; irun Jimọh ti lọ ọ, yóò sí parí rẹ sí irun Zuhuri tí yóò kii rakah mẹrin, Bakanaa ẹni ti irun Jimoh ba bọ mọ ọn lọwọ nitori oorun tabi idi miiran; dajudaju yio ki i ni Zuhr.
Ẹkẹẹdogun: Irun àwọn ti wọn ni àwíjàre:
Èkíní: Irun aláìsàn:
Àkọ́kọ́: Dandan ni lori aláìsàn lati ki irun lori ibamu sí ìkápá rẹ ati bí o ṣeé rọ lọrùn. Ko lẹtọọ fun un lati lọ ọ lara tayọ asiko rẹ lopin igba ti laakaye rẹ ba ṣi wa.
Èkejì: Báwo ni aláìsàn ṣe maa kirun?
1- Ó jẹ́ ọ̀ranyàn lórí aláìsàn kí ó kirun ni iduro tí ó bá wà ní ìkápá idide láìsí wàhálà tàbí ìpalára, kí ó sì tẹ kọkọrọ, kí ó sì forí kanlẹ̀.
2- Tí titẹkọkọrọ tàbí iforikanlẹ bá ń ṣe ìpalára fún un, síbẹ̀ tí ó lágbára láti dúró; yio ṣe àfihàn tàbí itọka fún titẹkọkọrọ l'ẹni tí ó dúró, àti fún iforikanlẹ l'ẹni tí ó jókòó.
3- Tí kò bá wá ní ìkápá láti kirun ní ìdúró; yóò kirun ní ìjókòó, Sunnah ni ki o joko ni ijoko tarabuu ( iti ẹsẹ bọrawan ) dipo iduro, ki o si tẹriba fun rukuu, ki o si forikanlẹ sori ilẹ bi o ba rọrùn fún bẹ. Bí bẹẹ kọ, yio tẹriba fun iforikanlẹ, tí yio si rẹlẹ ju ti rukuu lọ.
4- Ti ko ba si ni ikapa lati ki irun ni ijokoo; yio ki i ni ifẹgbẹlelẹ, ti yio si da oju rẹ kọ Qibla, Ẹgbẹ́ ọtun si ni o l'ọla ju bi o ba rọrun, yio si maa fi eya ara ṣe àpẹẹrẹ tàbí itọka fun irukuu (itẹriba tabi itẹ kọkọ) ati iforikanlẹ.
5- Ti ko ba si ni ikapa lati ki irun ni ifẹgbẹlelẹ; yio ki irun ni idubulẹ sẹyin, (ifeyinlelẹ tàbí itakaka) ti ẹsẹ rẹ mejeeji yio si kọju si Qiblah, yio si maa se itọka fun rukuu (itẹriba) ati iforikanlẹ.
6- Tí kò bá rọrùn fún un láti fi ara rẹ júwe níbi rukuu ( itẹriba ) àti iforikanlẹ; yio fi orí rẹ júwe, tí ó bá sì ṣòro fún un; jijúwe náà ti kúrò lórí rẹ, yio si maa ṣe awọn iṣẹ́ irun naa ninu ọkàn rẹ, yio maa gbèrò awọn iṣe irun bíi rukuu, iforikanlẹ àti jíjókòó lórí ipò tí ó wà, yio si maa sọ awọn adua rẹ.
Aláìsàn yíò ṣe ohun ti o bá ni ìkápá láti ṣe nínú àwọn májẹ̀mú ìrun, gẹ́gẹ́ bíi: kíkọjú sí Al-Qiblah, ṣíṣe àlùwàlá pẹ̀lú omi, tàbí ṣíṣe aluwala pẹ̀lú erùpẹ̀ nígbà àìní-ìkápá, àti ṣíṣe ìmọ́ra kúrò nínú àwọn èérí. Tí kò bá sì ní ìkápá lórí nǹkan kan nínú awọn nkan tí a kà silẹ yí ; ó ti bọ́ mọ́ ọn lọ́rùn, yíò sì máa kirun gẹ́gẹ́ bí ìṣesí rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ dá ìrun dúró kọjá àsìkò rẹ̀.
8- Sunnah ( ìlànà anọbi) ni pe ki alaarẹ jokoo ni titakete ni ipo iduro ati titẹkọkọrọ, ati ni jijokoo atẹsẹlẹ ni awọn ipo yooku.
Ẹlẹẹkeji: Irun arìnrìn-àjò:
1- Lára àwọn oní-àwíjàre ni arìnrìn-àjò wa , a sì yọnda fún un láti din irun olopo mẹrin kù láti mẹrin sí rakaa meji, Niítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿وَإِذَا ضَرَبۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَقۡصُرُواْ مِنَ ٱلصَّلَوٰةِ...﴾
{Nígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti dín ìrun kù... } [An-Nisā': 101].
Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
«خَرَجْنَا مَعَ النَّبِيِّ ﷺ مِنَ الْمَدِينَةِ إِلَى مَكَّةَ، فَكَانَ يُصَلِّي رَكْعَتَيْنِ رَكْعَتَيْنِ، حَتَّى رَجَعْنَا إِلَى الْمَدِينَةِ».
«A jade pẹlu Anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Madina lọ si Makkah, o si n ki irun rakah meji rakah meji, titi ti a fi ṣẹri pada si Madina»38.
Dídin irun ku ma nbẹrẹ nígbàtí onirinajo bá jáde kúrò ní àárín ìlú rẹ; nítorípé Ọlọhun yọ̀ǹda dídin irun ku fún ẹni tí o bá se irin-ajo lórí ilẹ̀, Ati pe ṣaaju ki o to jáde kuro ni ilu rẹ, ko jẹ onirin-ajo, nitori pe anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kò ki nki bẹ ayafi tí o bá ti gbéra tí o sí ṣe irinajo.
2- Ibusọ ti onirinajo fẹ́ rin ti o si lẹtọ lati din irun kù ni ọgọrin kilomita fẹ́rẹ̀ tó.
3- Arinrin-ajo yóò máa ṣe àdínkù irun lórí ìrìn-àjò nígbàtí o ba nàpadàbọ̀ títí yóò fi wọ ìlú rẹ̀ tí ó ti kúrò.
4- Bí arìnrìn-àjò bá dé ìlú kan tí ó sì fẹ́ láti gbé níbẹ̀; ó ní ìsesí mẹ́ta:
A) Ki o ni aniyan diduo níbẹ ju ọjọ mẹrin lọ; o di dandan fun un lati pe irun rẹ láti ọjọ kinni tí o ti fìdí kalẹ̀ síbẹ̀, kò sì gbọdọ̀ lo àwọn ìrọ̀rùn irin-ajo.
b) Ki o gbero dídúró fun ọjọ mẹrin tàbí kí ó máà tó bẹ́ẹ̀, o wá ni ẹtọ fún un láti dín ìrun kù àti láti lo àwọn ìyọ̀ǹda ìrìn-àjò.
d) Ki o jasi pe kò gbero ibùgbé tí a fi gbedeke sí, ṣugbọn o le gbé fun ọjọ kan tabi ọjọ mẹwa gẹgẹ bi ibi naa ṣe ba a mu, tabi o ni idi kan fun ìtọ́jú tabi àyẹ̀wò, nigbati idi rẹ ba si pari, yio pada si ilu rẹ; Ó tọ́ fún un láti máa din irun kù, kí ó sì máa lo àwọn ìfúyẹ́ ìrìn-àjò títí yóò fi ṣerí padà, kódà bí àsìkò wíwà rẹ̀ bá tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́rin lọ.
5- Tí onirinajo bá kirun lẹ́yìn Imam tí ó wà nílé; ó jẹ́ dandan fún un láti kí irun náà pé, koda ti ko bá bá a àfi níbi gbólóhùn ijẹri ìgbẹ̀yìn.
6- Tí ẹni tí o wa nile bá kirun lẹyìn onirinajo tí o n din irun rẹ kù; ó jẹ dandan fún ẹni tí o wa nile láti ṣe àṣepé irun rẹ lẹyìn tí imaamu bá ti salámọ.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlógún: Irun yídì (Ọdún) méjèèjì:
Àwọn ọdún àwọn Musulumi, ọdún ti o jẹ ti Ọlọhun ni, Ọlọhun Oba ti O ga ṣe é ní òfin fún wọn, wọn kò sì ṣe é ní òfin láti ọ̀dọ̀ ara wọn, Kò sì sí odun kan àfi ọdún méjì péré, àwọn ni: Ọdún itunu ààwẹ̀, àti Ọdún Iléyá. Yatọ si àwọn ọdún àwọn keferi tabi àwọn ọdún adadaalẹ èyí tí Ọlọhun- ọba ti o ga- kò fi lélẹ̀, tí kò sì pa á láṣẹ, ṣùgbọ́n wọ́n fi lélẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ara wọn.
Ìdájọ́ irun yídì méjèèjì:
Aṣe-dandan lori apapọ ni, (ọrọyan tito) Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe é ní àṣe-má-ṣe, bẹẹni àwọn arole ẹni imọna- ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ- náà ṣe é ní àṣe-má-ṣe, Ó sì jẹ́ ara àwọn àmì ńláńlá ti ẹsìn àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó hàn.
Àsìkò Irun ọdun méjèèjì: Asiko irun ọdun yoo bẹrẹ lati igba ti oorun ba ti gbera soke ni odiwọn ọ̀kọ̀, iyẹn: ni nkan bii iṣẹju mẹẹdogun lẹyin yiyọ oòrùn, asiko rẹ yoo si pari nigba yíyẹ kúrò oòrùn ni àtàrí wa (ni àárín s'ọmọn)
Bi a ṣe n kirun yídì méjèèjì:
1- Yíò kabara ni rakaa alakọkọ, èyíun ni Takbīratul Ihrām,(igbe títóbi fún Ọlọhun ní ìbẹrẹ irun) lẹyin naa yíò ka adua ìṣírun, lẹyin naa yíò kabara ni ẹẹmẹfa, yíò máa gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè pẹ̀lú kabara kọ̀ọ̀kan, yíò sì yin Ọlọhun, yíò sì kí I, yíò sì ṣe asalatu fún Ànábì - ki ìkẹ́ Ọlọhun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a - láàrin àwọn kabara náà, lẹyin naa yíò wá ìsọ́, yíò sì sọ Bismillāh, yíò sì bẹ̀rẹ̀ kíkà.
2- Yio kabara (gbígbé títóbi fún Ọlọhun) ni ẹmaamarun nibi rakah ẹlẹẹkeji lẹyin kabara iyipada, lẹyin naa yio wa tọrọ aabo lọdọ Ọlọhun, yio si sọ Bismillahi, yio si bẹrẹ si ni ka keu, o si jẹ ohun ti o yẹ ki o ka Surah Al-A'laa nibi rakah alakọkọ lẹyin Faatiah, ati Surah Al-Ghaashiyah nibi ẹlẹẹkeji.
3- Ti Imāmu ba ti salama tan; yio gun ori minbari (pẹpẹ ibanisọrọ) yio wa ṣe khutubah meji, yio si joko laarin awọn mejeeji ijoko fufuyẹ kan, gẹgẹ bi o ṣe maa nṣe ninu khutubah Jum'ah.
Àwọn sunna yidi:
A- Wíwẹ̀ iwẹ .
B- Ṣíṣe ìmọ́tótó àti lilo lọfinda.
c- Jijẹun ṣaaju ijade fun ikirun ọdun itunu aawẹ, ati lẹyin ipadabọ ni ọdun ileya ninu ẹran ijọsin rẹ, ti o ba ni.
d- Jijade lọ sí ààyè ìkìrun ọdún ni ẹni ti o n rin.
f- Lilọ lati ojú ọ̀nà kan, ati pipada lati ojú ọ̀nà miiran.
k- Titete lọ si mọsalasi fun ero ẹyin yàtọ̀ sí Imam.
Kabara (gbígbé títóbi fún Ọlọhun) :
Wọn ṣe e ni sunna lati ṣe kabara (ìgbé Ọlọhun tobi) ni oru awọn ọdun mejeeji, ati ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul-Hijjah, ati ni awọn ọjọ ayyāmu-t-tashrīq (awan ọjọ igunran àti ipa ẹran) , orisi meji ni :
Ìran àkọ́kọ́: Kabara gbogbogbòò: Òun ni èyí tí a kò so mọ́ àsìkò kan pàtó.
1- Ní ti ọdún ìtunu ààwẹ̀: Láti ìgbà wiwọ oorun ní oru ọdún títí di bíbẹ̀rẹ̀ irun ọdún.
2- Ní ti ọdún iléyà: Láti ìwọ̀ oòrùn alẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ oṣù Dhul-Hijjah títí dé ìwọ̀ oòrùn ọjọ́ ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ Tashreeq (Iguran).
Oríṣi ikeji: Kabara (gbígbé Ọlọhun tobi) Atidimọ: Oun ni èyí tí a so mọ́ lẹ́yìn awọn irun ti a ṣe ni ọran-anyan.
1- Fun ẹni ti koṣe ṣe iṣe-hajji lọwọ: láti àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ Arafah títí di àsìkò Alasari ti ọjọ́ igunran tó kẹ́yìn.
2- Aláàárámù ( ẹni tí o sisẹ hajji lọwọ) : Lati irun zuhri ọjọ ọdun ileya titi di Asri ọjọ igunran to kẹyin.
Ẹlẹẹkẹtàdínlógún: Irun ti ọ̀sán ba di òru:
Itumọ ti òru ba di ọ̀sán àti ti ọ̀sán ba di òru ní :
Al-Kusūf ni : Ó jẹ́ píparẹ́ imọ́lẹ̀ òṣùpá tàbí apá kan nínú rẹ̀ ní alẹ́.
Ọsan didi òru: Oun ni píparẹ́ ìmọ́lẹ̀ oòrùn tàbí apá kan nínú rẹ̀ ní ọ̀sán.
Ìdájọ́ irun ti ọ̀sán ba di òru:
Sunnah tí a tẹnumọ́ (tí o kanpa) ni, iṣe Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- jẹ́ ẹri lórí ìyẹn, pẹ̀lú pé ó kirun rẹ̀ nígbàtí oòrùn ṣú ní àsìkò rẹ̀ -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-. Gẹgẹ bi aṣẹ rẹ ṣe tọka si i, ati pe àwọn onimimọ fohun ṣọkan lori dida a lẹsẹlẹ.
Asiko rẹ:
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán di òru tàbí òru dí ọ̀sán títí yóò fi túká, òun ni ìtúká òru dí ọ̀sán tàbí ọ̀sán dí òru pada.
Àpèjúwe rẹ:
Onka raka rẹ jẹ meji, a ó sì máa ke kíkà Quran jake nínú wọn, bí a ṣe nkirun rẹ sì nìyí:
A- Yio ṣe takbiiratul ihrọọm (gbígbé Ọlọhun tóbi tí ibẹrẹ) , yio ṣe adua isii Irun , yio ṣe isti'aadha, (ìwà idaabobo lọdọ Ọlọhun nípa èsù) yio ṣe bismiLlāhi, yio si ka Fātiha, lẹyin naa yio fa kika gun.
b- Lẹyinna ni o wa lọ si rukuu (itẹriba) kan ti o gun.
J- Lẹyin naa yíò gbé ori soke kuro nibi rukuu (iteriba) yíò sì máa sọ pé: "sami‘a llōhu liman hamidahu", (Ọlọhun gbọ ohun ẹni tí o yín) lẹyin naa yíò wá ka Sūratul Fātiha, lẹyin naa yíò wá ke kike kan ti o gun, ti ko si to ti àkọ́kọ́.
d- Lẹyinna yio ṣe rukuu (tẹriba) kan ti o gun, ti ko to rukuhu alakọkọ.
h- Lẹyin naa yio gbe ori rẹ soke lati rukuu, yio wa sọ pe: (Sami‘a Llāhu liman hamidahu) Ọlọhun tí gbọ òunh ẹni tí o yín.
w- Lẹyin naa ni yoo ṣe iforikanlẹ meji ti o gun.
z- Lẹyin naa yio dide fun raka keji, èyí tíí yóò kí gẹgẹ bii raka alakọkọ, ṣùgbọ́n yio kuru ju u lọ.
Àwọn Sunnah rẹ̀ ni:
A) Pipepe fún un pẹlu gbolohun: (Irun janmọọn).
B) Ki a ki irun pẹlu awọn akojọpọ eniyan ni jama'ah.
J) Pípẹ́ ninu irun níbi iduro, titẹriba, ati fifori kanlẹ rẹ̀.
d) Ki raka ẹlẹẹkeji kuru ju takọkọ lọ.
h) Síse ìrántí (Ìwàásù) lẹ́yìn rẹ̀, àti ṣiṣenilojukokoro lori ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìgbọràn àti gbigbe àwọn iṣẹ́ búburú silẹ.
W) Pípọ̀ ni ṣíṣe adua, ìrawọ́-ẹbẹ, títọrọ àforíjìn àti sadaqa.
Ẹlẹẹkẹjidinlogun: Irun wíwá ki òjò ó rọ̀:
1) Al-Istisqaa ni : títọrọ òjò rírọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun Ọba giga ní àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀.
Asiko tí a gbé Irun wíwá ki òjò ó rọ̀ kalẹ̀:
O wa ni ìlànà òfin ẹṣin kí a kirun itọrọ ojo nigba ti oda ba da laye, ti ojo ba dawo duro, ti didawo duro rẹ si fa ipalara, ko si ọna abayọ fun wọn bikoṣepe ki wọn dirẹbẹ si Oluwa wọn, ki wọn si bẹ Ẹ fun ojo, ki wọn si wa iranlọwọ Rẹ pẹlu oniran-n-ran idirẹbẹ.
A- Nígbà mìíràn pẹ̀lú irun kíkì ní jama'ah, tàbí ní adáwà.
B- Ati pe nigba miran, Imāmu a máa ṣe adura ninu khutubah Jumu‘a, ti àwọn Musulumi yíò sì máa ṣe amin si adura rẹ.
D- Ati pé nigba miiran, pẹlu adua ni eyikeyi akoko, láì sí kirun, bẹ́ẹ̀ni láì sí khutbah.
Ìdájọ́ irun wíwá ki òjò ó rọ̀:
Sunnah ti o fẹsẹmulẹ (a kan nípa) ni nigbati idi rẹ ba wa, nitori iṣe Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a), gẹgẹ bi o ti wa ninu ọrọ Abdullahi ọmọ Zaid - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé:
«خَرَجَ النَّبِيُّ ﷺ إِلَى الْمُصَلَّى، فَاسْتَسْقَى، وَاسْتَقْبَلَ الْقِبْلَةَ، وَقَلَبَ رِدَاءَهُ، وَصَلَّى رَكْعَتَيْنِ».
Anọbi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lọ aaye ikirun, o si ṣe adua itọrọ-ojo, o si kọju si Qiblah, o si yi aṣọ rẹ sodi, o si kí irun rakah meji.39
Bi a ṣe n ki irun wíwá ki òjò ó rọ̀:
Bí a ṣe ń ki irun wíwá ki òjò ó rọ̀ ní ààyè rẹ̀ dà bíi irun yídì. O jẹ́ ohun tí a fẹ́ràn láti kii ní ààyè ìkìrun ọdún gẹ́gẹ́ bíi irun ọdun, àwọn ìlànà rẹ̀ sì dàbí ti irun ọdun; nípa iye àwọn raka, gbigbe ohun soke pẹlu kika, kíkí i ṣíwájú khutubah, àti àwọn kabara àfikún ní raka alakọkọ àti ikejì ṣíwájú kika, Gẹgẹ bi o ti ṣiwaju ni alaye ninu Irun ọdun méjèèjì. Yio si ṣe khutubah kan.
Ẹlẹẹkọkandinlogun: Awọn idajọ isinku:
Alakọkọ: Fún ẹni tí ó bá wà lọ́dọ̀ ẹniti npọkaka iku:
1- Ó jẹ́ ìṣe-suna fún ẹni tí ó bá wà lọ́dọ̀ ẹniti npọkaka iku láti nu ú ní gbolohun: «Laa ilaaha illal’loohu». (Kòsí ẹni kan kan tí o yẹ kí a fí ìjọsìn fún ayaafi Ọlọhun Allah)
2- Sunnah ni kí á dojú rẹ̀ kọ Qiblah.
3- Kí ó yẹ́jú.
4- Bibo òkú pẹ̀lú aṣọ lẹ́yìn ikú rẹ̀ jẹ́ ìṣe tí ó dára.
5- O si yẹ yiyara ninu ṣiṣe ètò rẹ.
6- Ati ṣiṣe yara fun bibiya awọn gbese rẹ.
7- A ó wẹ òkú, a ó sì ṣe kàfàánì fún un, ọranyan àdà-jẹ sì ni àwọn méjèèjì.
Ẹlẹẹkeji: Àwọn òfin ikirun si oku lara:
Idajọ rẹ ni pe: Ọranyan Alápamọ́wọ́.
Awọn majẹmu rẹ̀:
1) Didojukọ Qiblah.
2) Bibo ihoho.
3) Jíjìnnà sí idọti.
4) Imọra olùkírun àti òkú.
5) Ìsìlámù olùkirun àti ẹni tí a ń kirun fún.
6) Wíwà níbi ìsìnkú rẹ̀ tí ó bá wà ní ìlú.
7) Kí ó jẹ́ ẹni tí a fi àṣẹ fún ní iṣẹ́.
Awọn origun rẹ̀:
1) Dídúró nínú rẹ̀.
2) Awọn kabara mẹrin.
3) Kika Faatiha.
4) Ṣiṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
5- Ṣiṣe adura fun oku.
6- Títò lẹ́sẹẹsẹ
7- Sisalamọ.
Àwọn Sunnah rẹ̀ ni:
1) Gbigbe ọwọ mejeeji soke pẹlu gbogbo kabara.
2) Ṣiṣe ahuuzubillahi.
3) Ṣiṣe adura fun ara rẹ àti fun àwọn Musulumi.
4) Kika keu jẹẹjẹ.
5) Diduro diẹ lẹyin kikabara kẹrin ati ṣiwaju sisalamọ.
6) Gbigbe ọwọ ọtun lori osi lori igbaaya.
7) Wiwo si apa ọtun nibi sisalamọ.
Àpèjúwe rẹ:
Ki Imaam ati adakirun duro nibi aya ọkunrin ati aarin obinrin, ki o si kabara lati fi bẹrẹ irun, ki o si wa isadi lọdọ Ọlọhun, ki o ma si ka adua ifisii, ki o si pe orukọ Ọlọhun, ki o si ka Suuratul-Faatiha.
Lẹyin naa yio kabara, yóò si ṣe asalatu fun Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, lẹyin naa yio kabara, yóò si ṣe adua fun okú pẹlu ohun ti o fi ẹsẹ rinlẹ; Bíi ọrọ Anọbi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa bá a- tí o sọ pé:
«اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِحَيِّنَا وَمَيِّتِنَا، وَصَغِيرِنَا وَكَبِيرِنَا، وَذَكَرِنَا وَأُنثَانَا، وَشَاهِدِنَا وَغَائِبِنَا، اللَّهُمَّ مَنْ أَحْيَيْتَهُ مِنَّا فَأَحْيِهِ عَلَى الإِيمَانِ، وَمَنْ تَوَفَّيْتَهُ مِنَّا فَتَوَفَّهُ عَلَى الإِسْلَامِ، اللَّهُمَّ لَا تَحْرِمْنَا أَجْرَهُ، وَلَا تُضِلَّنَا بَعْدَهُ».
Ọlọhun forijin aláayè wa àti òkú wa, àti ọmọ kékeré wa àti agbalagba wa, àti ọkùnrin wa àti obìnrin wa, àti ẹni t'owa níbẹ̀ àti ẹni tí kòsí níbẹ̀. Olohun, ẹni tí O bá dá ẹ̀mí rẹ̀ sí nínú wa, bá ni jẹ́ kí ó máa ṣèmí lórí ìgbàgbọ́, ẹni tí O bá sì pa nínú wa, bá ni pa á sórí ẹ̀sìn Islam. Olohun, má ṣe dù wá ní ẹ̀san rẹ̀, má sì jẹ́ kí a sọnù lẹ́yìn rẹ̀.40
ati ọrọ Ọlọhun ti o sọ pe:
«اللَّهُمَّ اغْفِرْ لَهُ وَارْحَمْهُ، وَعَافِهِ وَاعْفُ عَنْهُ، وَأَكْرِمْ نُزُلَهُ، وَوَسِّعْ مَدْخَلَهُ، وَاغْسِلْهُ بِالْمَاءِ وَالثلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِ مِنَ الْخَطَايَا كَمَا نَقَّيْتَ الثَّوْبَ الْأَبْيَضَ مِنَ الدَّنَسِ، وَأَبْدِلْهُ دَارًا خَيْرًا مِنْ دَارِهِ، وَأَهْلًا خَيْرًا مِنْ أَهْلِهِ، وَزَوْجًا خَيْرًا مِنْ زَوْجِهِ، وَأَدْخِلْهُ الْجَنَّةَ، وَأَعِذْهُ مِنْ عَذَابِ الْقَبْرِ، وَمِنْ عَذَابِ النَّارِ».
Olohun ba ni forijin in, ki O si ba ni kẹ ẹ, ba ni fun un ni ilera, ba ni ṣe amojukuro fun un, bani pon isokale re sinu saare re le, bani fe iho inu saare re fun un, bani fo o mo pelu omi ati yinyin ati omi ti o tutu, Olohun bani mo on kuro ninu ese gege bi a se maa n mo aso funfun kuro nibi egbin, Olohun bani fi ile to daaju ile re lo ropo fun un, ati awon ara ile to dara ju ara ile re lo, ati aya ti o dara ju aya re lo, Olohun bani mu u wo alujanna, ba ni so o kuro nibi iya saare ati iya ina.41 Lẹyin naa yóò ṣe Alloohu Akbar, yóò si dúró díẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, lẹyin naa yóò wá salamọ ni ẹẹkan si apa ọtun.
Ìpín Kẹta: Zakaat
1- Ìtumọ̀ Zakah àti ipò rẹ̀:
Sàká ní èdè: ìdàgbàsókè àti àlékún.
Sàká ní ìlànà òfin: ẹ̀tọ́ kan tí ó jẹ́ ọranyan nínú àwọn dúkìá kan pàtó fún àwùjọ kan pàtó.
Oun ni origun kẹta ninu awọn origun Isilaamu, O si jẹ alábàákẹ́gbẹ́ irun ninu Alukurani ni aye mejilelọgọrin, eyi to n tọka si titobi ọla rẹ.
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ...﴾
{Ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh... } [Suuratul-Baqarah: 43].
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
«بُنِيَ الإِسْلَامُ عَلَى خَمْسٍ: شَهَادَةِ أَنْ لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّـهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّـهِ، وَإِقَامِ الصَّلَاةِ، وَإِيتَاءِ الزَّكَاةِ، وَحَجِّ الْبَيْتِ، وَصَوْمِ رَمَضَانَ».
«Wọ́n mọ Islam lórí nkan márùn-ún: Ijẹrii pé kò sí ẹni tí ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu, àti pé Muhammad ojiṣẹ Ọlọ́run ni, àti gbígbé irun dúró, àti yíyọ Zakah, àti ṣíṣe haji sí Ilé Ọlọ́hun, àti gbígba aawẹ Ramadan»42.
Awọn Musulumi fi ẹnu ko lori jijẹ ọranyan rẹ, Àti lórí àìgbàgbọ́ ẹni tí ó tako ọranyan rẹ̀, Ati gbígbógunti ẹni tí ó dínà yíyọ ọ rẹ̀.
2- Àwọn májẹ̀mú jíjẹ́ dandan saka:
A) Ominira: Ko jẹ dandan le ẹru; nitori pe ko ni dúkìá, ohun ti o wa lọwọ rẹ si jẹ ti olowo rẹ, nitori naa Zakah rẹ wa lori olowo rẹ.
b) Isilaamu: ko jẹ dandan fún alaigbagbọ; nítorí pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìsúnmọ́ àti ìgbọràn, alaigbagbọ kò sí lára àwọn oní-ìsúnmọ́ àti ìgbọràn.
J) Níní an-Nisaab: Kò jẹ dandan lórí èyí tí kò tó an-Nisaab, òun sì ni odiwọn tí a mọ̀ nínú dukia.
d) Pípé ìní: pé kí dúkìá jẹ́ ti ẹni náà ní ìní pípé àti àṣepé, kò sí Zakaat níbi dúkìá tí ìní rẹ̀ kò fìdí kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi gbèsè al-Kitabah.
(E) Pípe ọdún kan lórí dukia: Nítorí hadith Aisha -ki Ọlọhun yọnu si i- tí wọ́n fà á dé ọ̀dọ̀ Ànábì:
«لَا زَكَاةَ فِي مَالٍ حَتَّى يَحُولَ عَلَيْهِ الْحَوْلُ».
«Kò sí Saka nínú dúkìá kan títí tí ọdún kan yóò fi yípo lórí rẹ̀»43.
3- Awọn dukia ti Zakah yiyọ jẹ dandan ninu wọn:
Àkọ́kọ́: Awọn ẹran-ọ̀sìn,
Àwọn náà ni Ràkúnmí àti Maalu àti Aguntan pẹ̀lú Ewúrẹ́, Zakah sì jẹ dandan lórí wọn pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú méjì:
1- Ki a sin wọn fun wàrà ati ìbísí, kìí ṣe fun iṣẹ.
2- Kí o jẹ́ ẹran ọ̀sìn tó ń jẹko kiri (ìyẹn ni pé: tó ń jẹko fúnra rẹ̀), Zakah kò jẹ dandan lori àwọn ẹranko tí a n fún ní oúnjẹ tí olówó rẹ̀ rà fún un, tàbí tí ó kójọ láti inú koríko tàbí ohun mìíràn, Ati pe ko si Zakah lori eyiti o n jẹko fun apakan ọdun ti kii ṣe gbogbo rẹ tabi eyiti o pọ ju ninu rẹ.
4- Àwọn Niṣāb (awọn iye ẹran nkan ọsin tí a le ni) lórí àwọn ẹran-ọ̀sìn:
1- Zakat lori awọn ràkúnmí:
Tí àwọn monjẹmu bá pé; nínú gbogbo ràkúnmí márùn-ún, aguntan kan ni ó jẹ́ dandan, nínú mẹ́wàá aguntan méjì, nínú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún aguntan mẹ́ta, àti nínú ogún aguntan mẹ́rin, Gẹgẹ bi Sunnah anọbi ati Ijmaa' (ipanupọ awọn alufa) ṣe tọka si i. Ti o ba to marundinlọgbọn, ninu rẹ ni bintu makhaad, (Ọmọ àgùntàn obìnrin tí ó jẹ́ ọmọ ọdún kan ti o si ti wọ ọdun keji, ti a ko ba si ri i, ibnu labuun (akọ ọmọ rankunmi ti o le ni odún meji) to ni ipo rẹ.
Ti rakunmi ba pe mẹrindinlogoji; ọranyan ni ki a yọ abo rakunmi kan ti o ti pe ọdun meji ninu rẹ.
Ti o ba ti pe mẹ́fàlélógójì; ḥiqqah ni o jẹ ọranyàn ninu rẹ, oun naa ni eyi ti o ti pe ọdún mẹ́ta.
To ba si jẹ pe iye rakunmi ba pe ọkanlelọgọta; ọranyan ni ki a fun ni rakunmi abo kan to ti pe ọdun mẹrin.
Tí àpapọ̀ iye àwọn ràkúnmí bá tó mẹ́rìndínlọ́gọ́rin; bintu labuun méjì ni ó di oranyan lati yọ nínú rẹ̀.
Tí ràkúnmí bá tó mọ́kàn léláàádọ́rùn-ún; Hiqqah (abo rankunmi ti o tile ní odún mẹta) méjì ni ó jẹ dandan nínú rẹ̀.
Tí àpapọ̀ onka ràkúnmí bá ti kọja ọgọfa pẹ̀lú ẹyọ kan, abo ràkúnmí ọlọ́dún méjì mẹ́ta ni ó jẹ ọranyan láti mú jade nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nínú gbogbo ogójì ni abo ràkúnmí ọlọ́dún méjì kan, àti nínú gbogbo aadọta ni abo ràkúnmí ọlọ́dún mẹ́ta kan.
2- Zakat lori àwọn màlúù:
Ó jẹ́ ọranyàn nínú rẹ̀ tí àwọn majẹmú bá pé, tí ó bá tó ọgbọ̀n: Tabī' tàbí Tabī'ah; (òun sì ni èyí tí ọdún kan ti pé fún, tí ó sì ti wọ ọdún èkejì).
Kò sì sí nǹkan kan tí a fẹ yọ nínú maalu tí kò pé ọgbọn .
Tí ó bá pé ogójì; ọranyan ni àgbà maalu kan nínú rẹ̀, oun naa ni: èyí tí ó ti pé ọdún méjì.
Ti àpapọ̀ maalu ba le si ogoji; ọmọ maalu akọ tabi abo ti o ti pe ọdun kan ni o jẹ ọranyan ni gbogbo ọgbọọgbọn ninu wọn, ati abo maalu ti o ti pe ọdun meji ni gbogbo ogoji.
3- Zakat lori àgùntàn:
Bí àpapọ̀ iye àwọn ẹran àgùntàn bá tó ogójì, yálà ó jẹ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́, ẹran kan ni Zaka rẹ̀, èyí tí í ṣe àgùntàn ọlọ́ṣù mẹ́fà, tàbí abo ewúrẹ́.
Atipe ko si zakah ninu àgùntàn tí iye wọn bá kere sí ogoji. Bí àpapọ̀ àwọn àgùntàn bá dé ọgọ́rùn-ún kan àti mọ́kànlélógún, àgùntàn méjì ni ó pọn dandan nínú rẹ̀. Tí ó bá dé igba ó le ókan; àgùntàn mẹta ni ó jẹ́ dandan nínú rẹ̀.
Lẹyin naa, ọranyàn a wa fidi mulẹ ninu rẹ lẹyin iwon yii, a o si maa yọ ẹran ewúrẹ kan fun gbogbo ọgọrun-un, ninu irinwo, a o yọ ẹran ewúrẹ mẹrin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Èkejì: Sàká nǹkan ti n jade lati inu ilẹ̀:
Ohun ti o n jade lati inu ilẹ jẹ oriṣi meji:
1) Awọn irugbin ati awọn eso
2- Àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì ilẹ
Oríṣi alakọkọ: Awọn irugbin ati awọn eso
Zakah jẹ dandan nínú àwọn kóró; bíi: Àlìkámà àti Ọkà bálì àti Ìrẹsì. Àti nínú àwọn èso; gẹ́gẹ́ bí: dàbínù àti sabíìbù, Zakat kii se é ọranyàn lórí àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù; gẹ́gẹ́ bí àwọn èso-inú-èpo àti ewébẹ̀.
Àwọn májẹ̀mú jíjẹ́ dandan láti yọ Sàká lórí àwọn kóró àti àwọn eso:
1) Pé kí ó jẹ́ ohun tí a nfi pamọ́: kò sí Zakah lórí ohun tí a kò fi pamọ́ bíi àwọn èso àti àwọn ẹ̀fọ́ tàbí èwebẹ.
2) Kí o jẹ́ nkan tí a fi òṣùwọ̀n wọ̀n: Ko si Zakah lórí ohun tí a n tà nípa kíkà tàbí wíwọ̀n; gẹ́gẹ́ bíi Bàrà, Àlùbọ́sà, Rùmọ́ní, àti àwọn mìíràn.
3) Ki o to an-Nisaab: eyiti i ṣe apo maarun, ko si zakah ninu ohun ti o ba kere si iyẹn.
4) Kí Nisab (ondiwan tí o yẹ kí o pé) jẹ́ ohun ìní ẹni ní àsìkò tí Zakat náà jẹ ọranyan.
Ẹnití o ba padà ni nkan wọnyi lẹhin àsìkò tí Zakah ti jẹ dandan, kọja Zakah ko jẹ dandan le e lori, gẹgẹbi kí o pá da ra a tàbí tí wọn ba fi ta a lọrẹ lẹhin ìkórè rẹ.
Àkókò jíjẹ dandan Zakah rẹ:
Sàká jẹ dandan nibi àwọn kóró àti àwọn eso tí ó bá tí bẹ̀rẹ̀ síí dára tàbí wúlò , Atipe àmì ìfarahàn didaa rẹ ni nbọ wa yii:
a- Nípa kóró: nígbà tí ó bá le, tí ó sì yigbí, tí ó sì di líle.
B- Ní ti eso ọpẹ: nígbà tí ó bá pọ́n tàbí tí ó ba pupa rẹsu rẹsu.
c- Nínú èso àjàrà: Ni kí ó rọ̀, kí ó sì dùn.
Òndiwan tí a le yọ Zakat nínú rẹ ni :
Òndiwan tí a le yọ Zakat nínú rẹ fún ọkà àti èso: apo maarun, Wọsqi si jẹ́ ọgọta Saa', An-Nisaab (Òndiwan tí a le yọ Zakat nínú rẹ) yóò wá jẹ́ ọọdunrun sọọ'in ti anabi, odiwọn rẹ ní Kilogramu sì jẹ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 900 Kilogiramu.
Odiwọn Zakah tí ó jẹ́ dandan nínu rẹ̀:
Ìdákan nínú mẹ́wàá jẹ́ ọ̀ranyàn lórí ohun tí a bomi rin láìsí wàhálà tàbí ìnáwó; gẹ́gẹ́ bí èyí tí a fi omi òjò àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbin.
Ati pe idaji idakan ninu ida mẹwa ni o pọndandan nibi eyiti a fi omi gbìn pẹlu inawo ati wahala; gẹgẹbi èyítí a n fún l'omi pẹlu omi tí a fà jáde láti inú àwọn kàǹga àti àwọn odò nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé.
Oríṣi ẹlẹẹkeji: Àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì:
Lára àwọn iran nkan ti o n jade nínú ilẹ ni: awọn alumoni, Oun ni ohun tí a bá hu jáde láti inú ilẹ̀, tí kì í ṣe àdámọ́ ilẹ̀; gẹ́gẹ́ bíi Wura, Fadaka, irin, àti àwọn òkúta oníyebíye.
Àkókò jíjẹ́ dandan yiyọ Sàká nínú rẹ̀:
Tí ó bá ti níi ní ìkáwọ́, tí ó sì di ìní rẹ̀; kí ó yọ Saka rẹ̀ jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nítorí pé kò pọn dandan kí ọdún kan kọjá lé e lórí. Odiwọn rẹ ni odiwọn wura ati fadaka, a o sì yọ ìdámẹrin ìdámẹwa jáde ninu iye rẹ.
Ẹlẹẹkẹta: Zakaat owó:
Awon owo ni: Wura ati Fadaka ati awon owo oní takanda, Zakaat wọn si jẹ dandan, “Ẹri ni: Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنْفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُمْ بِعَذَابٍ أَلِيمٍ﴾
{Àwọn tó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, tí wọn kò sì máa ná an sí ojú-ọ̀nà Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro}. [At-Taobah 34].
Atipe ninu hadith:
«مَا مِنْ صَاحِبِ ذَهَبٍ وَلَا فِضَّةٍ لَا يُؤَدِّي فِيهَا حَقَّهَا؛ إِلَّا إِذَا كَانَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ صُفِّحَتْ لَهُ صَفَائِحُ مِنْ نَارٍ».
“Kò sí oní wúrà tàbí fàdákà kan tí kò san ẹ̀tọ́ tí ó wà nínú rẹ̀; bí kò ṣe pé ní Ọjọ́ igbende, wọn yóò sọ wọ́n di àwọn pẹlẹbẹ iná fún un”44.
Àwọn onímọ̀ ti fẹnu kò lórí jíjẹ́ dandan Zaka nínú wúrà àti fàdákà, àwọn owó oní takada náà sì ní ìdájọ́ wúrà àti fàdákà; nítorí pé ó ti dípò wọn nínú eto ìbáṣe owó.
Nisọbu (Òndiwan tí a le yọ Zakat) Zakah nínú owó, àti odiwọn ohun tó jẹ́ dandan nínú rẹ̀:
Oun ni odiwọn wúrà tàbí fàdákà; nítorí pé ó ti dipò wọn ní ipò owó, tí o bá sì ti tó odiwọn ìkan nínú wọn, Zaka ti jẹ dandan nínú rẹ̀. Ohun tó sì wọ́pọ̀ ni ṣíṣe ìdíwọ̀n owó oní takanda lónìí pẹ̀lú fàdákà; nítorí pé ó rọju ju wúrà lọ, fádaka yóò sì máa tó odiwọn rẹ̀ ṣíwájú tí Wura. Ti Musulumi ba ni ohun ti o se deede iye (595) giraamu ninu Fàdákà, ti odun kan si ti koja lori rẹ, Zakah yíyọ ti di dandan ninu rẹ. Ati pe iye giramu Fadaka a maa yí padà láti ìgbà dé ìgbà, nítorínáà, ẹnikẹni tí o bá ní owó díẹ̀ tí kò mọ̀ bóyá o ti tó odìwọn tàbí kò tó, kí o bèèrè lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò Fadaka nípa iye giramu Fadaka kan, lẹ́yìn náà kí o fi náà pẹ̀lú (595), èsì rẹ̀ ni odìwọn náà.
Anfaani: Ti eniyan ba fẹ yọ Zakah dukia rẹ; kí ó pin an-Nisaab si ogójì, ohun ti o ba jade ninu rẹ ni odiwọn ti o jẹ dandan.
Ẹkẹrin: Zakat lori awọn nkan ti a pèsè kalẹ fún òwò-ṣíṣe:
Ó jẹ́ ohun tí a pese kalẹ̀ fún kátàkárà láti jẹ èrè, Àwọn nnkan tí a fi ń ṣe òwò ko gbogbo irú dúkìá yàtọ̀ sí owó sí nu, gẹ́gẹ́ bíi àwọn ọkọ̀, aṣọ, aṣọ-ìrán, irin, igi, àti àwọn nnkan mìíràn tí a pèsè kalẹ̀ fún òwò ṣíṣe.
Àwọn májẹ̀mú tí saka fi jẹ́ dandan lórí àwọn nkan tí a pèsè kalẹ̀ fún òwò-ṣíṣe:
1- Ki o ni i nípasẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bíi títà, gbígbà yá, àti yàtọ̀ sí ìyẹn nínú àwọn ọ̀nà ìjẹ-ìmu.
2- Ki o jẹ pe o ni pẹlu aniyan okoowo; nipa gbigbero lati fi ṣ'owo jere, nitori pe gbogbo iṣẹ n bẹ pẹlu aniyan, okoowo si jẹ iṣẹ, o si di dandan ki aniyan farapọ mọ gẹgẹ bii awọn iṣẹ yooku.
3- Kí iye rẹ tó ìwọ̀n Nisab nínu ọ̀kan nínú àwọn owó méjèjì.
4- Pípe ọdún kan lórí rẹ̀, èyí sì ni rirẹkọja ọdún.
Ìlànà yíyọ Zakah àwọn nkan ti a pèsè kalẹ fún òwò-ṣíṣe:
ni pé a a maa díyele àwọn nnkan òwò nígbàtí ọdún bá pé pẹ̀lú ọ̀kan nínú owó méjèèjì, ìyẹn wúrà tàbí fàdákà, Tí a bá díyele é, tí o sì tó odiwọn tí zaka wọ̀ pẹ̀lú ọ̀kan nínú wúrà tàbí fàdákà; a o yọ idamẹrin idamẹwa nínú iye rẹ̀.
Ẹkarun-un: Yíyọ jákáà:
Saara (itọrẹ aanu) ti o jẹ ọranyan ni ipari oṣu Ramadan, Wọ́n sọ ọ́ di ọran-anyan ní ọdún kejì Hijirah.
Idajọ rẹ:
Jáàka ìtùnú aawẹ jẹ́ dandan lórí gbogbo Mùsùlùmí tó ní oúnjẹ tó pọ̀ ju èyí tó máa tó òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ ní ọjọ́ ọdún àti òru rẹ̀. O jẹ dandan fun gbogbo Musulumi; akọ ni o, tabi abo, ọmọdé ni o, tabi àgbàlagbà, ọmọlúwàbí ni o, tabi ẹrú, Nítorí hadiith:
«فَرَضَ رَسُولُ اللَّهِ ﷺ زَكَاةَ الْفِطْرِ عَلَى الْعَبْدِ وَالْحُرِّ، وَالذَّكَرِ وَالْأُنثَى، وَالصَّغِيرِ وَالْكَبِيرِ، مِنَ الْمُسْلِمِينَ».
«Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ṣe zakah itunu aawẹ ni dandan lori ẹrù ati ọmọluwabi, ati ọkùnrin ati obìnrin, ati ọmọ kékeré ati àgbàlagbà, ti wọn jẹ musulumi.»45 Farḍ sì ni ìtumọ̀ sí: Ó se é ní dandan, ó sì se é ní ọranyan.
Ọgbọn tí n bẹ nibi ṣiṣe é ni òfin:
Ọmọ Abbaas - ki Ọlọhun ba wa yọnu si awọn mejeeji - sọ pe:
«فَرَضَ رَسُولُ اللَّهِ ﷺ زَكَاةَ الْفِطْرِ؛ طُهْرَةً لِلصَّائِمِ مِنَ اللَّغْوِ وَالرَّفَثِ، وَطُعْمَةً لِلْمَسَاكِينِ».
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe zakah itunu aawẹ ni dandan; ìwẹ̀nùmọ́ fún aláàwẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, àti oúnjẹ fún àwọn mẹ̀kúnnù.46.
Àsìkò didi ọranyan rẹ̀ àti yíyọ ọ́ jáde:
Yíyọ jákáà yóò di ọranyan pẹ̀lú ìwọ̀ oòrùn alẹ́ ọdún. A sì nífẹ̀ẹ́ sí kí a yọọ́ ní ọjọ́ ọdún, ṣíwájú kí a to lọ kí irun ọdún. Kò sí lẹtọọ lati lọ ọ lara tayọ irun ọdun, Ti o ba lọ ọ lara tayọ ẹyin Irun ọdun; o jẹ dandan fun un lati san an pada, o si jẹ ẹlẹṣẹ pẹlu lilọ ọ lara tayọ asiko ti a pinnu fun un.
O sí lẹtọ lati yọọ ni ọdún ku ọjọ kan tàbí ọjọ méjì.
Odiwọn rẹ̀ àti ohun tí a ń yọ nínú rẹ̀:
Sọọhun kan ninu oúnjẹ tí ó jẹ́ ounjẹ àwọn ará ìlú; gẹ́gẹ́ bíi ìrẹsì, dabinu, àlìkámà tàbí àwọn mìíràn. Odiwọn Sọọ'in ni : o fẹ́ẹ̀ tó kilogiramu mẹta. Fífi owó san dípò rẹ̀ kò tọ́; nítorí pé ó lòdì sí àṣẹ Òjíṣẹ́ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
Yíyọ Sàká àti àwọn tí a maa fún un:
Asiko yiyọ rẹ:
Yiyọ saka jẹ dandan ni yara yara ti asiko jijẹ dandan rẹ ba de. Lilọ ọ́ lara kò sì lẹ́tọ̀ọ́ ayafi fún àìríṣe, gẹ́gẹ́ bíi pé kí owó náà wà ní ìlú kan tó jìnnà sí i tí kò sì sí ẹni tí yóò fi ṣe aṣojú.
Aaye yiyọ rẹ:
Ohun to dára jùlọ ni yiyọ Zakah ní ìlú tí owó náà wà, O lẹtọ lati gbe e kuro ni ilu ti dukia naa wa si ilu miiran ni awọn ipo kan:
A- Tí kò bá sí aláìní tí o ní bukata sí Zakah nínú ìlú.
B- Tí ìbátan tí o ní bukata bá wà ní ìlú mìíràn.
c- Tí anfaani kan tí òfin ẹṣin mú bá wà nínú pé kí a gbé e lọ sí ibòmíràn, gẹ́gẹ́ bíi: gbígbé e lọ sí àwọn agbègbè àwọn Musulumi tí àjálù ìyàn àti Omiyale ti ṣẹlẹ̀ sí.
Saka si jẹ dandan nínú dúkìá ọmọ kékeré àti wèrè, nitori àwọn ẹ̀rí alapapọ, awọn alámòójútó wọn lórí dúkìá ni yóò sì gba iṣẹ́ yíyọ rẹ̀ fún wọn. Kò sì lẹtọ láti yọ Zakah àfi pẹ̀lú àníyàn, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«إِنَّمَا الْأَعْمَالُ بِالنِّيَّاتِ».
Dajudaju gbogbo ise nbe pẹlu aniyan" (èròngbà)47.
Àwọn ti a maa fun ni saka:
Mẹjọ ni àwọn ìran tí a n fun ní Sàká:
Iran akọkọ: awọn alaini:
Awọn ni awọn ti ko ni ibugbe, ounjẹ ati aṣọ ti o to, odiwọn Zakah ti a o fun wọn ni ohun ti yoo to wọn, ti yoo si to awọn ti wọn n bọ fun ọdun kan.
Iran ikeji: Awọn mẹkunnu:
Àwọn ni àwọn tí wọ́n rí èyí tó pọ̀ jùlọ nínú àìtó, ṣùgbọ́n wọn kò rí àṣepé rẹ̀, bíi ẹni tí ó ní owó-oṣù, ṣùgbọ́n tí kò tó o fún ọdún kan.
Odiwọn tí wọn yóò máa yọ nínú Zakah: ìtó wọn pátápátá àti ìtó àwọn tí wọ́n ń pèsè fún fún ọdún kan.
Iran ẹlẹẹkẹta: Àwọn ti wọn ṣiṣẹ lórí rẹ̀:
Àwọn ni àwọn tí adarí fi iṣẹ́ gbígba Zakāh lé lọ́wọ́, tàbí tí wọ́n ń mójú tó titọju rẹ , láti mímu dé ọdọ awọn aláìní.
Odiwọn ti a o fun wọn ninu Zakah: odiwọn owo-ọya wọn lori iṣẹ wọn, níwọ̀n ìgbà tí wọn kò bá ní owo-ọya tàbí owo-oṣù láti ọ̀dọ̀ ìjọba.
Iran ẹlẹẹkẹrin: àwọn tí a fẹ́ fa ọkàn wọn mọ́ra:
Àwọn ni gbogbo ẹni tí a fi ń fún ní ẹ̀bùn pẹ̀lú ìrètí pé: kí ó gba Isilaamu, tàbí kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ le síi, tàbí kí a lé dawọ ibi rẹ̀ dúro fún àwọn Musulumi.
Ìwọ̀n ohun tí a óo fún wọn nínú Sàká: ní ìwọ̀nba ohun tí a óo fi fa ọkàn wọn sọ́dọ̀ wa .
Iran ẹlẹẹkarun: Àwọn ẹrú:
Ohun ti a n gbà ni àfojúsùn pẹlu rẹ ni: ìtúsílẹ̀ àwọn ẹrú ati àwọn Mukaatibina. (Awọn ẹrú tí wọn ní àsìkò itusilẹ ṣugbọn tí wọn kò rí owo san)
Al-Mukaatab: Oun ni ẹrú tí ó ra ara rẹ̀ lati ọdọ olowo rẹ, Ó sì tún kan ìràpadà àwọn ẹlẹ́wọ̀n Musulumi ní ojú ogun.
Iran ẹkẹfàá: Àwọn onígbèsè, oríṣi méjì ni wọ́n:
Alakọkọ: Ẹni tí gbèsè wà ní ọrùn rẹ̀ fún àìní ara rẹ̀, tí kò sì rí ohun tí yíó fi san gbèsè rẹ̀, A o sì fún un ní ohun tí yóò tó láti san gbèsè rẹ̀.
Ikeji: Ẹni ti gbèsè wà lórí rẹ̀ nítorí ṣíṣe àtúnṣe láàrin àwọn eeyan, A óò sì fún un ní ohun tí yóò fi san gbèsè rẹ̀, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ abọrọ.
Iran ẹlẹẹkeje: Lójú ọ̀nà Ọlọ́hun:
Àwọn ni wọ́n ń jagun sí ojú ọ̀nà Ọlọhun.
Odiwọn tí a óò fún wọn nínú Sàká: ohun tí yóò tó wọn fún ijagun lójú ọ̀nà Ọlọ́hun; bí ohun ìgùn, nkan ijagun, oúnjẹ àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Iran ẹlẹẹkẹjọ: Ibnu Sabiili:
Òun ni arinrin-ajo tí owó ìná rẹ̀ ti tán, tàbí tí wọ́n jí owo rẹ gbé , tí kò sì ku owó kankan mọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò fi dé ìlú rẹ̀.
Odiwọn ohun ti a o fun un ninu Zakah ni iye ti yoo gbe e de ilu rẹ, koda bi o tilẹ jẹ ọlọrọ ninu ilu rẹ.
Àkòrí kẹrin: Aawẹ:
Aawẹ ni:
Ṣiṣe ijọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu kikoraro kuro nibi awọn nnkan ti wọn le ba aawẹ jẹ lati igba ti alufajari ba ti yọ ,(tí imọlẹ ìdajì) titi di igba ti oorun yoo fi wọ.
Oun si ni origun kan ninu awọn origun Isilaamu, Ọranyan kan nínú àwọn ọranyan Ọlọhun Ọba, Ohun tí mímọ̀ rẹ̀ jẹ́ dandan nínú ẹsin ni . Tira Ọlọhun, ati Sunnah, ati ipanupọ awọn Musulumi si tọka si ijẹ ọranyan rẹ.
Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿شَهۡرُ رَمَضَانَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ فِيهِ ٱلۡقُرۡءَانُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡفُرۡقَانِۚ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ ٱلشَّهۡرَ فَلۡيَصُمۡهُ...﴾
{Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀ (tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú yín tí oṣù náà bá bá láyé (nínú ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ara), kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà.} [Suuratul Baqorah: 185].
Awọn majẹmu ìjijẹ ọranyan gbigba àwẹ̀ Ramadan:
1- Isilaamu; Aawẹ ko si nii ni alaafia lati ọdọ alaigbagbọ.
2- Bibalaga (dídì ẹni ọkunrin tàbí ẹni obìnrin) ; ko jẹ ọranyan lori ọmọde, Aawẹ gbigba tọ́ lati ọdọ ọmọde ti o ti moye, o si jẹ́ iṣẹ àṣepọ́nlé fun un.
3- Laakaye: aawẹ kò jẹ́ dandan lórí were, kò sì níí ní àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; nítorí àìsí Aniyan.
4- Nini agbára lori rẹ, Kii ṣe dandan fun alaisan ti ko le e gba tàbí tí o kagara, tabi fun arinrin-ajo, Atipe wọn yíò san án padà nígbàtí ìdíwọ́ bá kúrò: àìsàn àti ìrìn-àjò. Wọn si ṣe dida ẹjẹ nnkan oṣu ati ẹjẹ ìbímọ ni majẹmu fun nini àlàáfíà rẹ lọdọ obinrin.
Wíwọlẹ tàbí bibẹrẹ oṣù Ramadan máa ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kan nínú nǹkan méjì:
A- Riri iletesu oṣu Ramadan, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«صُومُوا لِرُؤْيَتِهِ، وَأفْطِرُوا لِرُؤْيَتِهِ».
Ẹ gba aawẹ nígbàtí ẹ bá rí i, kí ẹ sì tunu nígbàtí ẹ bá rí i "48.
B- Kíka oṣù Sha'baan pé ọgbọ̀n ọjọ́, èyí ni tí a kò bá rí iletesu Ramadan, tàbí tí ẹsujo tàbí kurukuru tàbí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ bá kọdí rírí rẹ̀, fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ - kí ìkẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a -:
«فَإِنْ غُمَّ عَلَيْكُمْ؛ فَأَكْمِلُوا عِدَّةَ شَعْبَانَ ثَلَاثِينَ يَوْمًا».
«ti kurukuru ba wa bo o fun yin; ẹ ka oṣù sha'abaan pé ọgbọ̀n ọjọ́»49
Ànìyàn nínú aawẹ:
Aawẹ da gẹgẹbi awọn ijọsin yooku, ko ni pé ayafi pẹlu aniyan, Asiko ọranyan dídá aniyan nínú aawẹ ọranyan yàtọ̀ si ti omiiran, atipe alaye rẹ si ni onbọ yí:
Alakọkọ: Aawẹ ọranyan; gẹgẹ́ bíi aawẹ Ramadan tàbí àrọ́pò (tí a San padà ) tàbí ẹjẹ́, gbígbé aniyan rẹ̀ jẹ́ ọranyan ní alẹ́ ṣaaju jijade imọlẹ ìdajì ( Al-Fajari) Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«مَن لَمْ يُبَيِّتْ الصِّيَامَ مِنَ اللَّيْلِ فَلَا صِيَامَ لَهُ».
«Ẹni tí kò bá da aníyàn aawẹ láti alẹ́, kò sí aawẹ fún un.»50.
Ẹlẹẹkeji ni: Aawẹ agbagbọrẹ, ó sì tọ́ kí ènìyàn mu àníyàn rẹ̀ wa ni ọ̀sán, Pẹ̀lú monjẹmu pé kí ó má ti jẹ ohun tí ó n ba ààwè jẹ́ lẹyin yiyọ alufajari ( imọlẹ ìdajì).
Awọn nnkan ti wọn n ba awẹ jẹ:
Akọkọ: Ibalopọ ọkọ àti àyà: Nigbakigba ti o ba se ibalopọ, aawẹ rẹ ti bajẹ, o si jẹ ọranyan fun un lati san gbese ọjọ naa ti o se ibalopọ ninu rẹ, Ó sì gbọdọ̀ ṣe ìtanràn pẹ̀lú sísan aawẹ ọjọ náà , òun náà ni: bibọ okun lọrun ẹru, ti ko ba ri, yio gba aawẹ oṣu meji tẹle ara wọn, Tí kò bá sì ní agbára rẹ̀ nítorí àwáwí ẹ̀sìn kan, ó máa bọ́ ọgọ́ta alaini, alaini kọ̀ọ̀kan yóò gba ìdajì Saih kan ninu oúnjẹ tí wọ́n máa ń jẹ ní ìlú.
Ikeji: Jijade atọ: nitori fífi ẹnu kò, tàbí fífi ọwọ kan lara, tàbí fífi ọwọ́ dá àtọ̀ sára, tàbí wíwo léraléra, gbígbà ààwẹ̀ náà padà nìkan ni ó wà lórí rẹ̀ láì san Kaffārah; ( ìtanràn ); nítorí pé ibalopọ nìkan ni Kaffārah wà fún. Niti ẹni ti o n sun, ti o ba la ala ti o si da àtọ sara; ko si nnkankan lọrun rẹ; nitoripe eleyii kii ṣe erongba rẹ, yoo wẹ iwẹ janabah.
Ẹlẹẹkẹta: Mimọọmọ jẹun ati mimọọmọ mu: nítorí ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe:
﴿...وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ ٱلۡخَيۡطُ ٱلۡأَبۡيَضُ مِنَ ٱلۡخَيۡطِ ٱلۡأَسۡوَدِ مِنَ ٱلۡفَجۡرِۖ ثُمَّ أَتِمُّواْ ٱلصِّيَامَ إِلَى ٱلَّيۡلِ...﴾
{Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ óò fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) nípasẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ òdodo. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́... } [Suuratul Baqara: 187].
Ṣugbọn ẹni tí o bá jẹun tàbí mumi pẹlu ìgbà gbé; kò sì nkankan tí yio ṣe si i. Nítorí hadiith:
«مَن نَسِيَ وَهُوَ صَائِمٌ، فَأَكَلَ أَوْ شَرِبَ، فَلْيُتِمَّ صَوْمَهُ، فَإِنَّمَا أَطْعَمَهُ اللَّهُ وَسَقَاهُ».
«Ẹniti o ba gbagbe wipe oun ngba aawẹ ti o wa jẹ tabi ti o mu, ki o ya pe aawẹ rẹ; toripe dajudaju Ọlọhun ni O fun un ni jijẹ atipe Ọun naa ni O tun fun un ni mimu»51.
Ẹlẹẹkẹrin ni: Mímọọmọ mú eebi jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí eebi bá gbé láìjẹ́ ìfẹ́-inú rẹ̀ péé jáde ; kò ní ba aawẹ rẹ̀ jẹ́, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«مَنْ ذَرَعَهُ الْقَيءُ فَلَيْسَ عَلَيْهِ قَضَاءٌ، وَمَن اسْتَقَاءَ عَمْدًا فَلْيَقْضِ».
«Ẹnikẹ́ni tí èèbì bá gbé , kò sí àsan fún un, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ bì, kí ó san án padà»52.
Ẹlẹkaarun: Mímu ẹ̀jẹ̀ jáde lára; nípasẹ̀ gbígbẹ ẹ̀jẹ̀, tàbí fífa ẹ̀jẹ̀ nínú iṣan, tàbí fífa ẹ̀jẹ̀ láti fi ṣè itọrẹ fún gbígba aláìsàn là; gbogbo èyí ni ó máa ń ba ààwẹ̀ jẹ́. Ní ti gbigba ẹjẹ diẹ jade fún àyẹ̀wò; dajudaju eyi ko nii lapa lara aawẹ, Bẹẹ gẹgẹ ni jidade ẹjẹ láìjẹ́ pé ó fẹ́; bíi ẹjẹ imú ( amurun ) tàbí ọgbẹ́ tàbí yíyọ eyín; èyí ko nii lapa lara awẹ.
Àwọn ti a yọnda fun lati má gba aawẹ nínú Ramadan:
Apá Kìíní: Àwọn ti a yọnda fun lati má gba àwẹ̀, tí o sì jẹ dandan fun wọn lati san gbèsè rẹ̀, àwọn ni:
Akọkọ: Alaisan ti aisan rẹ jẹ eyi ti a n reti iwosan rẹ, ti yio si ri inira lati ara awẹ tabi ti yio ṣoro fun un.
Ẹlẹẹkeji: Arinrin-ajo; boya o rí ìṣòro ni orí irin-ajo tàbí kò rí ìṣòro.
Ẹri lori awọn mejeeji ni: Ọ̀rọ̀ Ọba ti ọla Rẹ ga-:
﴿...وَمَن كَانَ مَرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَ...﴾
{...Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn...} [Al-Baqara 185].
Ẹlẹẹkẹta: Oloyun tabi ẹni tí n fún ọmọ lọ́yàn, ti aawẹ ba jẹ inira fun awọn mejeeji, tabi ti o ba n ṣe ìpalára fun wọn tabi fun ọmọ wọn, awọn mejeeji si wa ni ipò alaisan, awọn wọnyi o yọnda fun wọn lati já aawẹ, Ṣugbọn dida awẹ padà maa jẹ dandan fun awọn mejeeji ni asiko miiran.
Ẹlẹkẹrin: Ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu ati ẹni ti n ri ẹ̀jẹ̀ ìbímọ, kí awọn méjèjì fi aawẹ silẹ jẹ dandan fun wọn. Aawẹ awọn mejeeji ko ni alaafia, sisan rẹ pada si jẹ dandan fun awọn mejeeji ninu awọn ọjọ miiran.
Ipin (abala) ẹlẹẹkeji: Àwọn ti o lẹtọ fún láti má gba aawẹ tí ó sì jẹ dandan fun wọn lati san ìtanràn láìsí níí san aawẹ padà àwọn ni:
Ekini: Alaisan ti aisan rẹ ko ni ireti imularada mọ.
Ẹlẹẹkeji: Agbalagba ti ko le gba awẹ.
Àwọn wọ̀nyí yóò máa tu àwẹ̀, wọn yóò sì máa fún mẹ̀kúnnù kan ní oúnjẹ jẹ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú oṣù Ramadan. Ṣùgbọ́n ti agbalagba ba dé ipò ìdàrúgbó, gbogbo ẹrù ẹ̀sìn ti bọ kúrò lórí rẹ̀; yio si ja awẹ, kò si sí nǹkan kan lórí rẹ̀.
Àkókò rírọ gbèsè aawẹ ati idajọ lilọ ọ lara:
Sisan aawẹ Ramadan pada jẹ́ dandan laarin rẹ ati Ramadan ti o tẹle e. Ohun to l'ọla julọ ni yiyara sisan an padà. Ko lẹtọ láti lọ sisan pada aawẹ náà lara di ẹyin Ramadan keji. wọn gba ẹgbawa lati ọdọ Aisha - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
«كَانَ يَكُونُ عَلَيَّ الصَّوْمُ مِنْ رَمَضَانَ، فَمَا أَسْتَطِيعُ أَنْ أَقْضِيَ إِلَّا فِي شَعْبَانَ لِمَكَانِ رَسُولِ اللهِ ﷺ».
«Mo maa n jẹ aawẹ Ramadan, ti mi ko nii ni ikapa lati gba a pada afi ninu Sha'ban nitori ipo ojiṣe Ọlọhun – Ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –»53.
Ẹni tí ó bá lọ sisan pada di ẹyin Ramadan tí ó tẹ̀le, ìsesí méjì ni ó wà fún un:
1- Ki o lọ ọ lara fun àwíjàre ti Shari'ah, gẹgẹ bii: ki aisan o tẹsiwaju lara rẹ di Ramadan keji, sisan rẹ pada nikan ni o jẹ dandan fun un.
2- Ki o lọ ọ lara lai si awijare, o ti jẹ ẹlẹṣẹ, o si jẹ dandan fun un lati ronupiwada, ki o san an pada, ki o si fun alani kan ni ounjẹ jẹ fun ọjọ kọọkan.
Aawẹ agbagbọrẹ fún ẹni tí ó ní aawẹ tí o fẹ san padà :
Ẹnikẹni tí o ba ni aawẹ Ramadan ní gbèsè; ohun tó lọ́lá jùlọ ni kí ó yára láti san án, sájú aawẹ agbagbọrẹ, Ṣùgbọ́n bí aawẹ agbagbọrẹ bá jẹ́ èyí tí àsìkò rẹ̀ máa ń kọjá lọ -gẹ́gẹ́ bíi aawẹ Arafah àti Ashura-; yíó gba àwọn wọ̀nyẹn ṣáájú sisan awẹ padà; nítorí pé àsìkò sisan awẹ padà fẹ̀, ṣùgbọ́n ti Arafah àti Ashura máa ń kọjá lọ. Ṣugbọn, koni tii gba aawẹ mẹfa ti Shawwal ayaafi lẹyin sisan awẹ pada.
Aawẹ ti o jẹ eewọ:
1- Gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu, ati ọjọ ọdun ileya; nitori pe a kọ ọ.
2- Gbigba aawẹ awọn ọjọ Tashreeq (ọjọ mẹta lẹyìn ọjọ Ọdun iléyá) nínu oṣù Dhul-Hijjah, Bí kò ṣe pé fún ẹni tí yóò ṣe TAMATTUHU ( iṣẹ haj àti KIRỌỌNU nínu iṣẹ́ Hajj, tí kò bá rí ẹran adaya, Awọn ọjọ Tashreeq ni: Ọjọ kọkanla, kejila, àti kẹtala ninu oṣu Dhul-Hijjah.
3- ọjọ iyemeji nítorí iyemeji, òun ni ọjọ ọgbọn ninu oṣu Sha'ban, Ti oru rẹ ba jẹ oru ẹsujo tabi eruku ti o kọdi riri oṣu.
Nnkan ti a korira aawẹ rẹ:
A- Dídá gba aawẹ nínú Oṣu Rajab. B- Yiyà ọjọ Jimoh sọ́tọ̀ fun Awẹ, nitori pé wọn tí kọọ ṣíṣe bẹ. Ti o ba gbà aawẹ ọjọ kan ṣiwaju rẹ tabi lẹyin rẹ, kikọ naa ti kuro.
Àwọn ọjọ tí ó jẹ́ Sunnah láti gbààwẹ̀:
A- Ọjọ́ mẹfa nínú oṣù Shawwal. b- Gbigba aawẹ ọjọ mẹsan oṣù Dhul-Hijjah, èyí tí ó sì ṣe pàtàkì jùlọ nínú rẹ̀ ni ọjọ Arafa, àfi fún aláàji; kò jẹ́ ìlànà fún un láti gba aawẹ rẹ̀, gbigba aawẹ rẹ̀ sì maa npa ẹṣẹ ọdún méjì rẹ́. c- Gbigba aawẹ ọjọ mẹta ni gbogbo oṣu, awọn ọjọ ti o si lọla ju ni: ọjọ kẹtala, ọjọ kerinla, ati ọjọ kẹẹdogun. 4- Gbigba aawẹ ọjọ aje ati ọjọbọ ni gbogbo ọsẹ, nitori pe Anabi -ki ikẹ ati ọla maa ba a- maa n gba aawẹ wọn; nitori pe a maa n gbe iṣẹ awọn ẹru kalẹ ninu awọn ọjọ mejeeji naa.
Aawẹ agbagbọrẹ:
A- Aawẹ Daaud, ki ikẹ Ọlọhun maa ba a, o jẹ ẹniti o maa ngba aawẹ ni ọjọ kan ti o si maa ntunu ni ọjọ kan.
B- Gbigba aawẹ oṣù Ọlọhun, Muharam, oun ni oṣù tó lọlá jùlọ tí a fẹ́ràn kí á gbà aawẹ nínú rẹ̀, èyí tó sì ṣe pàtàkì jùlọ nínú rẹ̀ ni: gbigba aawẹ ọjọ Ashura, tíí ṣe ọjọ kẹwa oṣù Muharam, a ó sì gbà aawẹ ọjọ kẹsán pẹ̀lú rẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pé:
«لَئِنْ بَقِيتُ إِلَى قَابِلٍ لَأَصُومَنَّ التَّاسِعَ».
«Ti mo ba wa laaye titi di ọdun to n bọ, dájúdájú emi o gba aawẹ ọjọ kẹsan-an»54. O si maa n pa ẹṣẹ ọdun ti o ṣaaju rẹ ni.
Àkòrí karùn-ún: Hajj ati Umra
Hajj ní ìtumọ̀ èdè ni : Èrò. Ní ìṣe ẹ̀sìn: lílọ sí ile Ọlọhun abeewọ àti àwọn ibi ijọsin ní asiko kan pàtó láti ṣe àwọn iṣẹ ijọsin kan pàtó.
Umrah: Ní ìtumọ̀ èdè ni: Ìse abẹ̀wò.
Nípa ti òfin ẹ̀sìn: Ṣíṣabẹwo ile abọwọ ní eyikeyi àsìkò lati lè ṣe awọn iṣẹ́ ìjọsìn pato.
Hajj jẹ́ ọkan ninu awọn origun Isilaamu ati ninu awọn ipilẹ rẹ ti o tobi, Wọ́n sì ṣe é ní ọranyan ní ọdún kẹsán Hijirah (tí anọbi àti awàn Musulumi jáde kúrò ni Makkah lọsí Madinah) , Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe Hajj ẹẹkan pere; oun naa ni (hajj idagbere) fun aye.
Hajj jẹ dandan ni ẹẹkan ninu ọjọ ori fun ẹni ti o ba lagbara, Èyí tó bá sì lekun jù bẹẹ lọ, iṣẹ́ aṣegbọrẹ ni. Ní ti Umurah, o jẹ dandan ní ìbámu sí ọrọ ọpọlọpọ ninu awọn onimimọ, Fun ẹri ọrọ rẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe: Ṣe jijagun wà fún àwọn obìnrin ni? O sọ pe:
«نَعَمْ، عَلَيْهِنَّ جِهَادٌ لَا قِتَالَ فِيهِ: الْحَجُّ وَالْعُمْرَةُ».
«Bẹẹni, jihad wa fun wọn tí kò ní jijagun ninu rẹ: Hajj ati Umrah»55.
Awọn majẹmu ìwà-dandan Haji àti Umura:
1-Jijẹ Musulumi
2-Ni ni laakaye
3- Ìbàlágà ( Dídì ijẹ ẹni obìnrin tàbí ọkùnrin);
4- Ominira
5- Níní agbára tàbí ìkápá
Obìnrin yóò se alekun monjẹmu ẹlẹẹkẹfà kún fun ; èyí sì ni wíwà abeewọ tí yóò bá a rin ìrìn-àjò láti ṣe é, nitoripe kò lẹtọ fun-un lati rin irin-ajo laisi mahram (abeewọ), boya irin-ajo Hajj ni o tabi omiran, Nítorí ọrọ anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ máa ba a tí o sọ pé:
«لَا تُسَافِرُ الْمَرْأَةُ إِلَّا مَعَ ذِي مَحْرَمٍ، وَلَا يَدْخُلُ عَلَيْهَا رَجُلٌ إِلَّا وَمَعَهَا مَحْرَمٌ».
«Obinrin kò gbọdọ rin ìrìn-àjò ayafi ki abeewọ wà pẹlu rẹ, bẹẹni ọkunrin kan kò gbọdọ wọle tọọ ayafi ki abeewọ wà pẹlu rẹ»56.
abeewọ obinrin ni: ọkọ rẹ, tabi ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere; Nípa ìbátan ẹbí; gẹgẹbi ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ lọkunrin, àti bàbá rẹ̀, àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò bàbá rẹ̀ lọkunrin, àti ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ lọkunrin, àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ìyá rẹ̀ lọkunrin, Tabi nitori idi kan ti o yọnda; gẹgẹ bi ọmọ-iya ti wọn jọ mu ọyàn, tabi nipa ìbátan ìgbéyàwó; gẹgẹ bi ọkọ iya rẹ ati ọmọkunrin ọkọ rẹ.
Níní agbára: òun náà ni agbára nípa ti owó àti ti ara, nípa pé kí ó lè gun nkan, kí ó sì lè fara da ìrìn-àjò, kí ó sì ní owó tó máa tó o ní lílọ àti ní bíbọ̀, Ati pe ó sì rí ohun tí yóò tó àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn tí ninawo wọn jẹ dandan lé e lórí títí yóò fi padà sọ́dọ̀ wọn.
Ki ọna Hajj si jẹ ọna ààbò lori ẹmi ati dukia rẹ.
Ẹnikẹni tí ó bá lágbára pẹ̀lú owó rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ara rẹ̀ kò lágbára, nítorí pé ó jẹ́ arúgbó tó ti gbó tàbí tí ó ń ṣe aarẹ tí kò sí ìrètí pé yóò sàn; ó pọndandan fún un láti wá ẹni tí yóò bá a ṣe Hajj àti Umurah.
Wọn ṣe majẹmu meji lára ẹni tí ìdúró rẹ̀ yíò tọ́ nínú Hajj àti Umrah:
1- Kí ó jẹ́ ẹni tí ṣíṣe iṣẹ́ ọ̀ranyàn Hajj rẹ̀ yóò tọ̀nà, èyíun ni Musulumi, tó ti bàlágà, tó sì ní làákàyè.
2- Ki o ti ṣe Haji ẹsin Islam fún ara rẹ̀.
Awọn miqaat (awan ààyè ibẹrẹ iṣẹ Hajj) fun gbigbe harami:
Al-Mawaqit: ni ọpọ ọrọ Miqat. Ní ìtumọ̀ èdè: ó jẹ́ Ààlà. Ní ìtumọ̀ ẹ̀sìn: ó jẹ́ ààyè ìjọsìn tàbí àsìkò rẹ̀.
Hajj ní àwọn àsìkò àti àwọn ààyè fún ìgbé-áràmí:
A- Àwọn àkókò gbèdéke: Ọlọhun mẹ́nubà wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pé:
﴿ٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ...﴾
{Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí wọ́n ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà... } [Al-Baqara 197].
Àwọn oṣù wọnyi ni: Shawwaal, Dhul-Qa'dah, àti ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ oṣù Dhul-Hijjah.
B- Al-Mawaqit Al-Makaniyyah: ni awọn ààlà tí kò lẹ́tọ̀ọ́ fún aláájò láti kọjá wọn lọ sí Makkah láì gbé harami, Báyìí ni wọ́n rí:
1- zulu hulayfah: miqoti ( ààyè ibẹrẹ isẹ Haji ) ti àwọn ará ìlú mẹdina.
2- Al-juhfatu ni ibi ìgbé aníyan àwọn ará ìlú Sham ati Egypt ati Morocco.
3- Qarnul-Manaazil: ti a mọ si As-sayl nisinyii; Miqoti àwọn ará Najd.
4- Zaatu ir'kin: Miqoti àwọn ará ìlú Iraq.
5- Yalamlam: Ibùdó ìgbe arami àwọn ará ìlú Yemen.
Ẹnikẹ́ni tí ibùgbé rẹ̀ kò de àwọn ààyè harami wọ̀nyí; dájúdájú yóò gbé harami fún Hajj àti Umrah láti ibùgbé rẹ̀. Ati pé awọn ará Makkah; Makkah ni wọn yóò ti da aniyan, wọn kò sì nílò láti jáde lọ sí ààyè harami fún ìgbé harami. Àmọ́ fún ti Umrah; wọn yóò jáde lọ sí ibi to súnmọ́ jùlọ ní ẹyin ilu Makkah, wọn yóò sì dàníyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe Hajj tàbí Umrah gbọ́dọ̀ gbé harami láti àwọn ààyè tí Anabi - kí ikẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - ti ṣe adayanrí rẹ, àwọn ààyè wọ̀nyí sì ni Meeqat tí àlàyé rẹ ti ṣíwájú, Ẹnikẹni ti o fẹ ṣe Hajj tabi Umrah, ko lẹtọọ fun un lati kọja awọn aaye naa lai gbe arami.
- Ẹnikẹni tí o bá gba awọn aaye harami tí a mẹnuba kọja tí kìí ṣe àwọn ará ibẹ̀, yóò gbé harami láti ibẹ̀.
- Ẹnikẹni tí ọ̀nà rẹ bá lọ sí Makkah, tí kò sì gba ọkan nínú àwọn ààyè harami tí a mẹ́nukàn wọnyi kọjá, yálà lórí ilẹ̀, tàbí lórí omi, tàbí lójú òfuurufú; yóò gbé harami tí o bá ti dé ọkọkan ààyè harami tí o súnmọ́ ọn jùlọ. Nítorí ọ̀rọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i-: «Ẹ wo ìtọ́sọ́nà rẹ̀ láti ojú ọ̀nà yín»57.
- Ẹni tí ó bá ń rin ìrìn-àjò iṣẹ́ ìjọsìn Hajj tàbí Umrah pẹ̀lú ọkọ òfurufú, dandan ni fún un láti daníyan iṣẹ́ ìjọsìn nígbàtí ọkọ òfurufú bá rekọjá ní ògángán Meeqat tí ó wà ní ojú ọ̀nà rẹ̀, Kò lẹtọ fún láti lọ idaniyan iṣẹ ijọsin lára di ìgbà tí ọkọ òfurufú yóò sọkalẹ ní ibùdókọ Ofurufu.
Gbígbé áràmí:
Ohun ni aniyan lati wọ inu iṣẹ ijọsin Hajj àti Umrah. Ní ti Hajj, oun naa ni aniyan lati wọ inu Hajj, Ati ninu Umurah, aniyan lati wọ inu Umurah ni. Kò ní wọ ìdè ìjọsìn àfi tí ó bá ṣe aniyan láti wọ inú iṣẹ́ ìjọsìn. Ṣùgbọ́n ní ti wíwọ aṣọ Arami lásán láìsí aniyan, kò nijẹ́ gbígbé Arami.
Awọn ohun tí a fẹ fún gbígbé aramii:
1- Wíwẹ̀ gbogbo ara ṣíwájú dídániyan
2- Kí ọkùnrin lo turare (lọfinda) sí ara rẹ̀, kìí ṣe sí ara aṣọ arami rẹ̀.
3- ki ó gbé Arami pẹ̀lú ìró àti ìdàbora funfun méjì àti sálúbàtà méjì.
4- Ki o gbé arami rẹ lórí nkan igun, tí ó dojú kọ Qiblah.
Àwọn ìran iṣẹ́ hajj:
A fun aláramì ni àṣàyàn láti yan èyíkéyìí tí ó bá wù ú nínú àwọn ìran gbígbé arami mẹ́ta, àwọn náà ni:
1- Tamattu'; òhun ni kí ó gbé harami fún Umrah nínú àwọn oṣù ìjọsìn Hajj, kí ó sì parí rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ó wá gbé harami fún Hajj ní ọdún kan náà.
2- Al-Ifraad; èyí ni pé kí a gbe harami fún iṣẹ́ ìjọsìn Hajj nìkan láti ibi Meeqat, yóò sì máa bẹ pẹ̀lú harami rẹ̀ títí yóò fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìjọsìn Hajj tán.
3- Al-Qiraan; ohun ni kí a gbe harami Hajj àti Umrah papọ, tàbí kí a gbe harami Umrah, lẹyìn náà kí a wá da Hajj mọọ kí o tó bẹrẹ irọkirika rẹ, yóò sì daniyan Umrah àti Hajj láti ibi Miiqaati, tàbí kí o tó bẹrẹ irọkirika ti Umrah, yóò sì ṣe irọkirika fún wọn, yóò sì ṣe ipọsẹsẹ.
Ó sì jẹ́ ọranyan lórí ẹni tó ń ṣe hajji Tamattu'i àti ti Kirọọnu láti ṣe itanran, tí kò bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùgbé agbègbè Mọ́sálásí Harami.
Èyí tó lọ́lá jùlọ nínú àwọn ìjọsìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni: Ṣíṣe pẹlu igbadun; nítorí pé Anabi (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) pa àwọn saabe rẹ̀ láṣẹ pẹ̀lú ẹ58. Lẹ́yìn rẹ̀ ni alase papọ; nítorí pé ìjọsìn Hajj àti Umrah ni, lẹ́yìn rẹ̀ ni aladaṣe.
j) Tí o ba ti gbé harami fun ọkan nínú àwọn iṣẹ ìjọsìn wọnyi tán; yóò pe Talbiyah lẹsẹkẹsẹ, yóò si sọ pé:
«لَبَّيْكَ اللَّهُمَّ لَبَّيْكَ، لَبَّيْكَ لَا شَرِيكَ لَكَ لَبَّيْكَ، إِنَّ الْحَمْدَ وَالنِّعْمَةَ لَكَ وَالْمُلْكَ لَا شَرِيكَ لَكَ».
Labbaikal laahummo labbaik, labbaika laa sheriika laka labbaik, innal amda, wan ni'imata, laka wal mul'k, laa sheriika lak. ( Mọ jẹ ìpe rẹ Irẹ Ọlọhun, mọ jẹ ìpe rẹ lajẹ tún jẹ, kò sí orogún fún irẹ Ọlọhun, dájú dájú gbogbo ọpẹ tirẹ ni ati idẹra àti ọlá tirẹ Ọlọhun nii se , kòsí orogún tàbí ẹnìkejì fún Ọ)59
Sunnah ni, o si jẹ́ nkan tí wọ́n fẹ lati maa ṣe e lọpọlọpọ, ọkunrin yoo maa sọ ọ soke, awọn obinrin yoo si maa sọ ọ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.
Asiko rẹ: O maa n bẹrẹ lẹyin Ihram, ipari asiko rẹ si ni bi o se nbọ yi:
Àkọ́kọ́: ẹni tí nṣe Umrah yóò jáwọ́ nínú rẹ̀ ṣáájú kí o tó bẹrẹ irọkirika.
Ẹkejì: Alalaaji yoo jáwọ́ nínú rẹ̀ nígbàtí ó bá bẹ̀rẹ̀ sini jù oko Jamarat al-Aqaba ni ọjọ Ọdun.
Awọn nkan tí o jẹ eewọ fún gbígbé aṣọ iṣẹ ìjọsìn Umrah wọ:
1- Eewọ alakọkọ: Fifa Irun tàbí gige e kúrò tàbí fifaa tu níbi èyí k'eyi ààyè nínú ara rẹ.
Èèwọ̀ ẹlẹẹkeji: Gige àwọn èékánná ọwọ́ tàbí ti ẹsẹ̀ láìní àwáwí, ṣùgbọ́n bí èékánná kan bá já, tí ó sì yọ ọ́ kúrò, kò sí itanran lórí rẹ̀.
Eewọ ìkẹta: Fífi nkan bo orí ọkùnrin èyí tí yóò lemọ pẹki pẹki, gẹgẹbi: fìlà àti lawani.
Eewọ kẹrin: Wíwọ aṣọ rírán fún ọkùnrin mọ́ ara rẹ̀ tàbí apá kan lára rẹ̀; gẹ́gẹ́ bíi ẹwu, lawani, tàbí ṣòkòtò. Nǹkan tí a rán: ni ohun ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀yà ara, gẹ́gẹ́ bíi Khuffu mejeeji, ìbọwọ́, àti Ibọsẹ, Àmọ́ obinrin, yóò máa wọ aṣọ tí ó bá wù ú nígbà harami nítorí pé ó nílò láti bo ara, ayaafi pé kò níí wọ iboju, yóò sì bo ojú rẹ̀ pẹ̀lú nkan míràn yàtọ̀ sí i bíi iborun àti jilbab nígbà tí àwọn ọkùnrin àjèjì bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, Kí ó má sì wọ ibọwọ ọwọ méjèjì sí ọwọ́ rẹ̀ méjèjì.
Eewọ ikarun-un: Lọfinda; nitori pe ẹni tí Alarami, a fẹ ki o jinna si igbadun ati ọṣọ aye ati awọn adun rẹ, ki o si kọju si ọrun.
Èèwọ̀ ìkẹfà: Pipa ẹranko orilẹ àti dídẹ ẹ lọ́dẹ, Oníhárami kò ní dẹ ìgbẹ́, kò sì ní ran ẹlòmíràn lọ́wọ́ lórí rẹ̀, kò sì ní dunbú rẹ̀.
O si jẹ eewọ fun ẹnití o gbe harami lati jẹ nínú ohun tí ó pa, tàbí tí a pa nítorí rẹ̀, tàbí tí ó ṣe ìkúnlọ́wọ́ lórí pípa rẹ̀; nítorí pé ó dàbí òkú ẹran fún un.
Ṣùgbọ́n ní ti odò dídẹ; wọn kò ṣe é ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó wà nínú aṣọ harami láti dọdẹ rẹ̀. Wọn kò sì ṣe pípa ẹran abẹ́lé ní èèwọ̀ fún un, gẹ́gẹ́ bíi adìyẹ àti àwọn ẹran ọ̀sìn; nítorí pé kì í ṣe ẹran ìgbẹ́.
Eewọ Ẹlẹẹkeje: Ṣíṣe iyigi fún ara rẹ tàbí fún ẹlòmíràn, tàbí jíjẹ́ ẹlẹ́rìí.
Eewọ kẹjọ: Ibalopọ; ẹnikẹni ti o bá ṣe ibalopọ ṣiwaju ibo-harami silẹ alakọkọ; Hajj rẹ̀ ti bajẹ, ó sì gbọdọ tẹsiwaju kí ó parí iṣẹ́ Hajj rẹ̀, yóò sì san án padà ní ọdún tó nbọ̀, ó sì gbọdọ pa ràkúnmí kan. Ti o ba jẹ lẹyin ìtúsílẹ̀ àkọ́kọ́; iṣẹ́ ìsìn rẹ ko nii bajẹ, ẹran kan si wa lori rẹ.
Obinrin sì dọ́gba pẹ̀lú ọkùnrin nípa rẹ, tí ó bá jẹ́ pé ó gbà láti jẹ kí ọkọ re sunmọ.
Eewọ kẹsan-an: Fífi ara kan obìnrin lai dé abẹ. Ko tọ fun ẹni tí o gbé harami lati fi ara kan obìnrin, nítorí pé ó jẹ́ ọ̀nà sí ibalopọ tí ó jẹ́ eewọ. Ohun tí a sì n pe ni fífi ara kan ara ni: fífi ara kan obìnrin pẹlu ero igbadun ara.
Umrah
A- Awọn origun Umrah:
1- Gbigbe arami.
2- Rirọkirika ile Ọlọhun.
3- pipọ ṣẹṣẹ
B- Awọn ọranyan Umrah:
1- Gbigbe arami lati ibi Miqoti ti o yẹ.
2- Fifa irun tàbí gige ẹ.
Bi a ṣe n ṣe umura:
Ohun àkọ́kọ́ tí ẹni tí ó ń ṣe Umrah yóò ṣe ni pé, yóò yípo ní ẹẹmeje, yóò bẹ̀rẹ̀ láti ibi hajar aswad, yóò sì parí rẹ̀ síbẹ̀. Kí ó sì jẹ́ ẹni tí ó mọra nígbà irọkirika ile Oluwa rẹ, tí ó bo ihoho rẹ láti ìdodo dé orúkún. Ó jẹ́ Sunnah fún un láti ṣe ipakaja ní gbogbo ìgbà irọkirika ilé Ọlọhun; èyí sì ni pé kí ó ṣí ejika rẹ ọ̀tún sílẹ̀, kí ó sì fi aṣọ ilodi rẹ sábẹ́ abiya rẹ, kí ó sì gbé etí aṣọ ilodi rẹ méjèèjì lé ejika rẹ tí òsì, Tí o bá parí ipaara keje tán; yóò fi ipakaja sílẹ̀, yóò sì fi aṣọ ilodi rẹ bo ejika rẹ méjèèjì.
Yóò kojú sí òkúta dúdú náà, tí o bá ní ànfàní láti fi ẹnu kòó, yóò fi ẹnu kòó, tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, yóò fi ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún kan án tí o bá rọrùn, yóò sì fi ẹnu kòó ọwọ́ rẹ̀, Tí kò bá rọrùn fún un láti fọwọ́ kan òkúta dúdú náà, yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè yóò sì fi tọ́ka sí i, yóò sì sọ pé: (Ọlọ́hun ni ó tóbi jùlọ) lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, kò sì níí fi ẹnu ko ọwọ́ rẹ̀, kò sì níí dúró. Lẹ́yìn náà yóò máa bá irọkirika rẹ̀ lọ, yóò fi Kaaba sí apá òsì rẹ̀, nínú ìlànà anọbi ni kí ó pọ ṣẹṣẹ níbi ipoyi mẹta àkọ́kọ́, Ipọ ṣẹṣẹ ni: iyara rìn pẹlu kí igbesẹ sunmọra wọn.
Tí o bá kọjá níbi origun Al-yamaani -èyí tí í ṣe origun kẹrin ilé Kaaba- tí o bá rọrùn fún un, yóò fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kàn án láì ṣe takbīr, láì sì fi ẹnu kò ó. Tí kò bá sì rọrùn fún un láti fi ọwọ́ kàn án, yóò kọjá lọ, kò ní tọ́ka sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣe takbīr. Yoo maa tún sọ laarin origun Al-Yamaani àti òkúta dúdú pe:
﴿...رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ حَسَنَةٗ وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ﴾
{Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná}. [Suratul Baqara: 201].
Tí o bá parí irọkirika ile Ọlọhun tan, yóò kirun raka méjì lẹyìn ààyè ìdúró anọbi Ibrahim tí o ba rọrun bẹ, tí kò ba rọrun, yóò kí i ni èyí k'eyi ààyè nínú Mọsalasi Al-Haram, Ó sì jẹ́ sunnah pé kí ó ka Sūrah (Al-Kaafirun) lẹ́yìn Faatihà níbi raka alakọkọ, Yóò si ka Sūrah (al-Ikhlās) níbi raka ẹlẹẹkeji lẹyin fātiha, Lẹ́yìn náà, yóò kọjú sí Mas'haa (ààyè ipọ ṣẹṣẹ) yóò sì ṣe ipọsẹsẹ láàrin Sọfa àti Marwah ní ipaara méje; lílọrẹ̀ jẹ́ ipaara kan, bẹ́ẹ̀ ni ìpadàrẹ̀ náà tún jẹ́ ipaara kan.
Yíò bẹrẹ Ipọsẹsẹ ní Sọfa, yíò gùn ún, tàbí kí ó dúró níbẹ̀, gígùn Sọfa sì dára jù tí ó bá rọrùn, Nigba naa ni yio wa ke ọrọ Ọlọhun ti Ọlá Rẹ ga pé:
﴿إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِ...﴾
{Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu... }. [Al-baqarah: 158].
Wọ́n si fẹ kí o da oju kọ Kiblah, yio wa yin Ọlọhun, yio si gbe é tobi, yio si sọ pé:
«لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ، وَاللَّهُ أَكْبَرُ، لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ، يُحْيِي وَيُمِيتُ، وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، لَا إِلٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَحْدَهُ، أَنْجَزَ وَعْدَهُ، وَنَصَرَ عَبْدَهُ، وَهَزَمَ الْأَحْزَابَ وَحْدَهُ».
«Kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah, Allah sì ni Ẹni Tí ó Tóbi Jùlọ, kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un, Òun l'ó ni ìkápá àti ìyìn, Ó ń sọni di ààyè, Ó sì ń pa ni, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan, kòsí ẹni kankan tí o yẹ kí a fi ìjọsìn fún àyàfi Allah nìkan ṣoṣo, Ó pé àdéhùn Rẹ̀, Ó sì ran ẹrú Rẹ̀ lọ́wọ́, Ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun ní Òun nìkan ṣoṣo»60. Lẹyin naa yio tọrọ adua pẹlu eyi ti o ba rọrun fun un ni ẹni ti o ngbe ọwọ rẹ méjèjì sókè, yio si ṣe àtúnwí ìrántí yii ati adua yii lẹẹmẹta, Lẹyìn náà yóò Sọkalẹ, yóò sì máa rìn lọ sí Marwah, títí yóò fi dé ibì àsiá (ami) àkọ́kọ́, ọkùnrin yóò sì yara rìn daada títí yóò fi dé ibì àsiá (ami) ẹlẹẹkeji, Ní ti obìnrin, a kò pa á láṣẹ fún un láti yàrá láàrin àwọn àmì méjèèjì, nítorí pé hoho ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, rírìn ni a pa láṣẹ fún un níbi gbogbo ipọsẹsẹ náà. Lẹyin naa yoo rin, yoo si gun oke Marwah tabi ki o duro ni ẹgbẹ rẹ, gbigun un si loore ju ti o ba rọrun fun un lati ṣe bẹẹ, yoo sọ, yoo si ṣe lori oke Marwah gẹgẹ bi o ti sọ, ti o si ṣe lori oke Safa, ayafi kika ayah naa, eyi si ni gbolohun Ọlọhun pe:
﴿إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِ...﴾
{Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu... }. Èyí, ìlànà ni nígbàtí a bá n gùn òkè Safa nínu ipoyi alakọkọ nìkan. Lẹyìn náà ni yóò Sọkalẹ, yóò sì máa rìn ní ibi ìrìn, yóò sì máa yára ní ibi ìyára, títí yóò fi dé Sọfa. Yoo ṣe ìyẹn ni ẹẹmeeje, lilọ rẹ jẹ ipaara kan, bẹẹ ni ipada rẹ naa jẹ ipaara kan. Ó sì jẹ́ fífẹ́ kí ó máa ṣe ìrántí Ọlọhun àti adura ní ọpọlọpọ pẹ̀lú èyí tí ó bá rọrùn fún un, Ati pe ki o jẹ́ ẹnití o mọ́ra kuro nibi ẹgbin kekere ati nla, tí o bá tilẹ̀ ṣe é láìsí imọra, ó tó fun un, Bẹẹ gẹgẹ ti obinrin ba ri nnkan oṣu tabi ti o n se ẹjẹ ibimọ lẹyin irọkirika ile Oluwa; yoo sa safa ati mariwa, iyẹn si yoo to fun un; nitori pe imọra kii ṣe majẹmu fun sisa safa ati mariwa, ṣugbọn o jẹ ohun ti o dara lati ṣe ninu rẹ.
Tí o ba ti parí ipọsẹsẹ; yóò fa irun orí rẹ tàbí kí o gẹ ẹ, fífa irun fún ọkùnrin sì dáa jù.
Pẹlu bayi yóò jasi pe ó ti ṣe àṣepé iṣẹ́ ìjọsìn Umrah.
Hajj
A- Awọn origun Hajj:
1- Gbigbe arami.
2- Diduro si oke arafa
3– Tawaaful Ifaadọ.
4- Ipọsẹsẹ.
B- Awọn ọranyan iṣẹ Hajj:
1- Gbigbe arami láti Meeqat.
2- Diduro si oke arafa ni ọjọ kẹsan-an osu Dhul-Hijjah titi di ìwọ̀ oòrùn fun ẹni ti o duro níbẹ̀ ní ọ̀sán.
3- Sisun mọju ni Muzdalifah ni alẹ ọjọ kẹwaa oṣu Dhul-Hijjah titi di aarin oru.
4- Sisun mọju ni Mina ni awọn alẹ ọjọ́ Tashreeq.
5- Sísọ òkúta Jimār.
6- Fifa irun orí tàbí kí a gẹ ẹ.
7- Irọkirika tí idagbere.
Bi a ṣe n ṣe ìjọsìn hajj:
Kí Mùsùlùmí gbé ohùn rẹ̀ sókè pẹ̀lú aniyan Hajj nìkan ṣoṣo nígbàtí ó bá dé ibùdó àràmí (Miqat), pàápàá tí àsìkò bá kúrú. Tí ó bá dé Makkah, yóò ṣe irọkirika àti ipọsẹsẹ, yóò sì máa bẹ pẹ̀lú harami rẹ títí yóò fi forí lé Àràfá ní ọjọ́ kẹsàn-án, ọjọ́ Àràfá, yóò sì máa wà níbẹ̀ títí di ìwọ̀ oòrùn,
Lẹyinna ni yóò kúrò níbẹ̀ pẹlu pípe Talbiyah lọ sí Muzdalifah, yóò sì wà níbẹ̀ títí yóò fi kirun aarọ, lẹyinna ni yóò wà níbẹ̀ yóò máa ṣe iranti Ọlọhun, yóò máa pe Talbiyah, yóò sì máa ṣe adua títí ilẹ yóò fi mọn.
Tí ilẹ ba ti mọ yóò darí sí Múná kí oòrùn tó yọ, yóò sì jù òkúta méje sí Haqabah, lẹyìn náà yóò fa irun orí rẹ tàbí kí o gẹ, kí o fàá lọ dáa jù.
Lẹyìn náà yóò ṣe Tọwafu Ifadọh, ipọsẹsẹ àkọ́kọ́ yẹn yóò sì tó fún un, pẹlu bayi ni ìjọsìn Hajj rẹ ti parí, tí yóò sì ti bọ aṣọ harami silẹ pátápátá.
Ó ku fún un láti ju Jamarat ní ọjọ́ kọkànlá àti ọjọ́ kejìlá, tí ó bá fẹ́ kánjú; yóò ju àwọn Jamarat mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Jamarat kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú òkúta méje, yóò máa gbé Ọlọ́hun tóbi pẹ̀lú òkúta kọ̀ọ̀kan. Yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ó kéré jù, tí ó tẹ̀lé Mọ́sálásí al-Khayf, lẹ́yìn náà èyí tí ó wà láàrin, lẹ́yìn náà Jamratul Aqaba, èyí tó jẹ́ ìkẹyìn. Yóò ju Jamarat kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú òkúta méje. Tí o bá sì fẹ́ láti lọra lẹ́yìn ọjọ Kejìlá; yóò sọ oko ni ọjọ kẹtala gẹgẹ bí o ṣe sọ ọ́ ni ọjọ Kejìlá àti ọjọ kọkànlá.
Àsìkò oko sísọ ni lẹ́yìn tí oòrùn bá yatarí ní àwọn ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Tí o bá kúrò ní ọjọ kejìlá kí oòrùn tó wọ̀, kò sí ìyọnu; Tí o bá sì lọra títí yóò fi sọ oko ní ọjọ kẹtàlá lẹ́yìn ti òrun ba yẹ kuro latari, èyí ni ó lọ́lá jùlọ, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun Atóbilọ́lá:
﴿...فَمَن تَعَجَّلَ فِي يَوۡمَيۡنِ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِ وَمَن تَأَخَّرَ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۖ لِمَنِ ٱتَّقَىٰ...﴾
{Ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu)}.
[Al-Baqorah: 203].
Tí o bá sì fẹ́ rin ìrìn àjò, yóò ṣe irọkirika ìdágbére ní ẹẹmeeje láìsí Sa'y Ipọsẹṣẹ
Ohun tí ó lọlá jù, tí kò bá ní ẹran ìtọrẹ: ni kí ó gbé harami fún Umrah tamattu', lẹ́yìn náà kí ó ṣe labbaika fún Hajj ní ọjọ́ kẹjọ, kí ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ Hajj tí a ti mẹ́nukàn ṣáájú. Tí ó bá sì gbé harami fún Hajj àti Umrah pọ̀, kò sí aburu nibẹ, wọ́n sì ń pè é ní Qiran, òhun ni kí a gbé harami fún Umrah àti Hajj papọ̀ pẹ̀lú irọkirika kan àti ipọsẹsẹ kan.
Ori iwe ẹlẹẹkẹta:
Ohun tó jẹmọ́ ibara-ẹni-lo
Àwọn onimimọ, ki Ọlọhun ti ọla Rẹ ga kẹ wọn, ti ṣàlàyé imọ ti kikọ rẹ jẹ ọranyan lori olúkúlùkù, Wọn si sọrọ nipa iwọn èyí tí kíkọ́ rẹ̀ jẹ́ ọranyan fún gbogbo Mùsùlùmí, Wọn si mẹnuba ninu rẹ: kíkọ àwọn ofin ìṣòwò fún ẹni tí ó ń ṣòwò, Ki o má baà kó sinu nǹkan eewọ tàbí rìbá (owo ele) láìmọ̀, Wọ́n sì ti gbà wá lọ́dọ̀ díẹ̀ nínú àwọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn- ohun tí ó fi ìdí èyí múlẹ̀.
Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: «Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàjà ní ọjà wa àfi ẹni tí ó ti ní àgbọ́yé nínú ẹ̀sìn»61.
Ni ‘Aliy ọmọ Abu Tọọlib- ki Ọlọhun yọnu si i- ba sọ pe: «Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣòwò kí ó tó ní òye nípa ẹ̀sìn; yóò tẹrí bọ inú èlé, yóò sì tún tẹrí bọ ọ́, yóò sì tún tẹrí bọ ọ́. ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé: ó ti bọ́ sínú èlé»62.
Ibnu 'Aabidiin sọ, gẹgẹ bi o ti gba a wa lati ọdọ Al-'Allaamiy pe: Wọ́n si ṣe ni ọranyan lórí gbogbo ẹni tí wọ́n là ẹṣin bọ lọrùn ọkùnrin àti obìnrin lẹ́yìn kíkọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ ẹsin àti ìmọ̀na, kíkọ́ ìmọ̀ nípa àluwala, ìwẹ́, ìrun àti ààwẹ̀, àti ìmọ̀ Zakā fún ẹnití o bá ní iye tí Zakā ti wá lé lórí, àti Hajji fún ẹnití o bá di ọranyan lé lórí, àti òwò ṣíṣe fún àwọn oníṣòwò, kí wọn le ṣọ́ra fún àwọn nkan afura àti àwọn nkan tí a kórìíra nínú gbogbo ìbáṣepọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, àti gbogbo ẹnití o bá ń ṣe iṣẹ́ kan, a sọ ìmọ̀ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀ di ọranyan lé e lórí kí o le jìnnà sí ohun èèwọ̀ nínú rẹ̀"63.
Imam An-Nawawi tun sọ - ki Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba wa ṣe ikẹ Rẹ fun un- pe: Ní ti kata-kara, ìgbéyàwó, àti irúfẹ́ẹ wọn tí kò jẹ́ dandan ní ìpìlẹ̀ṣẹ̀, ó jẹ́ èèwọ̀ láti dáwọ́lé wọn àfi lẹ́hìn mímọ majẹmu wọn"64.
Iwọnyi si ni apakan ninu awọn ọfin ti o jọmọ awọn ibaṣepọ ti owó, èyí tí Òfin Ẹ̀sìn Ìsìláàmù mú wá:
1- Ṣíṣe gbogbo ohun ti anfaani pátápátá tabi eyi ti o pọ̀ju wa ninu rẹ ní ẹtọ; gẹgẹ bii tita awọn nnkan ti a ṣe ni ẹtọ ati ríra wọn, ati Iṣẹ́ ìyá, ati Ṣuf'ah65.
2- Jijẹ ofin fun gbogbo ohun ti o jẹ imudaju fun awọn iwọ̀ awọn eeyan ati sisọ wọn; gẹgẹ bi ohun-ògo ati mimu ẹlẹrii.
3. Jíjẹ́ ẹtọ gbogbo ohun ti o ni anfaani fun awọn oníṣe adehun mejeeji; bíi fífagilé adehun, àṣàyàn àti awọn majẹmu nínú kata-kara.
4- Kíkọ̀ ṣíṣe àbòsí sí àwọn ènìyàn, àti jíjẹ dúkìá wọn ni ọ̀nà ti ko tọ; gẹ́gẹ́ bíi èlé, gbígbà nnkan nípa ipá, àti ìfipamọ́ ọjà.
5- Jije ofin fun gbogbo ohun tí ó ní iran ara ẹni lọwọ lori daadaa; gẹ́gẹ́ bíi awin, ohun ìyá, àti ohun afipamọ-sini-lọwọ.
6- Kíkọ̀ gbogbo nkan ti o ní jíjẹ dukia ninu láìsí iṣẹ́, tàbí ànfàní, tàbí wàhálà; gẹ́gẹ́ bíi tẹtẹ ati èlé.
7- Dídí gbogbo ajọṣepọ lọ́nà tí àìmọ̀ àti èrú bá gbilẹ̀ nínú rẹ̀; bíi títà ohun tí ènìyàn kò ní, àti títà ohun tí a kò mọ̀.
8- Dídènà gbogbo nkan ti o jẹ arekerèké lori eewọ; gẹgẹ bi tita Al-'Inah66.
9- Dídènà ohun tí ó n´ múni rojú kúrò níbi ìgbọràn sí Allāh, gẹ́gẹ́ bíi títà lẹ́yìn ìpè Jumu‘a ẹlẹẹkeji.
10- kíkọdi gbogbo ohun tó ní ìpalára nínú, tàbí tí ó ń ṣe sàbàbí dídá ọ̀tá sílẹ̀ láàrin àwọn Musulumi; gẹ́gẹ́ bíi títà àwọn nǹkan èèwọ̀, àti títà tí ènìyàn yóò máa ta ọjà lórí ọjà ọmọ-ìyá rẹ̀.
Ati pe nigba ti idajọ ọrọ kan bá rú Mùsùlùmí lójú, yio beere lọ́dọ̀ àwọn onimimọ nipa rẹ, kò sì níí dáwọ́lé e àfi lẹ́yìn mímọ idajọ ẹsin ninu rẹ, Gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe:
﴿...فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِنْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ﴾
{Ẹ yáá bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí ( oní mimọ) tí ẹ̀yin kò bá mọ̀}. [Suuratun Nahl: 43].
Eyi ni ohun tí ó rọrùn láti ko jọ, Ati pe Ọlọhun ni A n bẹ ki O pese fun wa ni imọ onanfaani ati iṣẹ rere, Oun ni Ọba Ọlọrẹ Onikẹ. Ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba Anabi wa Muhammad, ati awọn arale rẹ ati awọn saabe rẹ, kí ọlà púpọ̀ si maa bá wọn.
***
Index
Ọrọ itisiwaju 2
Ipinpin alakọkọ 3
Ohun tó jẹmọ́ Adisọkan 3
Iwadii alakọkọ: ìtumọ̀ Isilaamu àti àwọn origun rẹ̀: 3
Pataki imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo: 3
Itumọ jijẹrii pe ko si ọlọhun ti ijọsin tọsi afi Allahu: 5
Ẹẹ wa ri awọn majẹmu (laa ilaaha illa Allāhu) oun ni: 6
Ìtumọ jijẹri wipe Muhammad òjíṣẹ Ọlọhun ni: 7
Iwadii ẹlẹẹkejì: ìtumọ̀ Ìgbàgbọ́ ati awọn origun rẹ̀: 8
1) Nini igbagbọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kó awọn nkan mẹta kan sinu: 10
1- Nini igbagbọ is ijẹ Oluwa Rẹ: 10
2- Nini ìgbàgbọ́ nínú níní ẹtọ sí ìjọsìn Rẹ: 12
3- Nini igbagbọ pẹlu awọn orukọ ati awọn iroyin: 14
2) Nini igbagbọ si awọn Malaika: 21
3) Níní ìgbàgbọ́ sí àwọn tira: 22
4) Níní ìgbàgbọ́ nínú àwọn Ojiṣẹ, kí àlàáfíà Ọlọ́hun máa bá wọn: 24
5) Nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin: 25
A- Nini igbagbọ ninu igbende: 25
B- Nini igbagbọ ninu iṣiro-iṣẹ ati ẹsan: 25
D- Nini igbagbọ ninu alujanna ati ina: 26
6) Nini igbagbọ ninu kadara eyi to daa ninu ẹ ati eyi to buru: 26
Ìwádìí ẹlẹẹkẹta: Ise dáadáa: 28
Ìwádìí ẹlẹẹkẹrin: Àkópọ̀ ṣoki lara àwọn ìpìlẹ̀ àwọn Ahlu-sunnah wal-jama'a: 29
Ori-iwe ẹlẹẹkeji : Ohun tó jẹmọ́ awọn ijọsin 30
Abala Kini: Imọra: 30
Alakọkọ: Àwọn ìpín omi: 31
Ẹlẹẹkeji: Idọti tàbí ẹgbin: 31
Ẹkẹta: Nnkan ti ṣiṣe rẹ jẹ eewọ fun ẹlẹgbin lara: 33
Ẹlẹẹkẹrin: Awọn ẹkọ bibiya bukaata ( Titọ tàbí ṣíṣe igbansẹ]: 35
Ẹlẹẹkarun: Àwọn ìlànà nípa Fífi omi ṣe imọra ati fífi òkúta ṣe imọra: 36
Ẹkẹfa: Awọn idajọ ti o ní nṣe pẹlu aluwala: 37
Ẹlẹẹkeje: awọn idajọ pipa ìbọ̀sẹ̀ aláwọ mejeeji ati ìbọ̀sẹ̀ olówùú: 39
Ẹlẹẹkẹjọ: Awọn idajọ Tayammum ( aluwala o ní yẹpẹ ) 41
Ìkẹsàn-án: Awọn idajọ ẹjẹ nnkan oṣu ati ìbímọ obìnrin: 43
Orí iṣẹ iwadi Keji: Irun kiki 45
Alakọkọ: Awọn idajọ irun pipe ati ikaamọ ( igberun dúró) : 45
Ẹlẹẹkeji: Ipo Irun àti ọlá rẹ̀: 48
Ẹlẹẹkẹta: Awọn majẹmu irun: 50
Ẹlẹẹkẹrin: Awọn origun irun kiki: 52
Ẹlẹẹkarun-un: Awọn ọranyan irun: 57
Ẹlẹẹkẹfa: Awọn sunnah irun: 58
Ẹlẹẹkeje: Àlàyé bí ase má nkirun 60
Ẹlẹẹkẹjọ: Awọn ohun ikorira lori irun: 66
Ẹlẹẹkẹsan-an: Awọn nnkan ti wọn n ba irún jẹ: 67
Ẹlẹẹkẹwaa: Iforikanlẹ ti ìgbàgbé: 67
Ẹlẹẹkọkanla: Awọn asiko ti a kọ irun kiki nibẹ: 69
Ikejìlá: Irun janmọọn ( irun ala jọ kí papọ) : 69
IKẹtàlá: Irun ní àsìkò ìpayà: 72
Ìròyìn Irun ìpayà 73
Ẹkẹrinla: Irun Jimọ: 74
Ẹkarun-un: Awọn nkan ti wọn fẹ ni ọjọ Jimọ: 76
Biba Irun Jimọ: 76
Ẹkẹẹdogun: Irun àwọn ti wọn ni àwíjàre: 77
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlógún: Irun yídì (Ọdún) méjèèjì: 80
Ẹlẹẹkẹtàdínlógún: Irun ti ọ̀sán ba di òru: 82
Ẹlẹẹkẹjidinlogun: Irun wíwá ki òjò ó rọ̀: 84
Ẹlẹẹkọkandinlogun: Awọn idajọ isinku: 85
Ìpín Kẹta: Zakaat 88
1- Ìtumọ̀ Zakah àti ipò rẹ̀: 88
2- Àwọn májẹ̀mú jíjẹ́ dandan saka: 89
3- Awọn dukia ti Zakah yiyọ jẹ dandan ninu wọn: 90
Àkòrí kẹrin: Aawẹ: 101
Awọn majẹmu ìjijẹ ọranyan gbigba àwẹ̀ Ramadan: 102
Àkòrí karùn-ún: Hajj ati Umra 109
Awọn majẹmu ìwà-dandan Haji àti Umura: 110
Awọn miqaat ( awan ààyè ibẹrẹ iṣẹ Hajj) fun gbigbe harami: 112
Gbígbé áràmí: 113
Umrah 117
Hajj 121
Ori iwe ẹlẹẹkẹta: 123
Ohun tó jẹmọ́ ibara-ẹni-lo 123
***
yo227v3.0 - 07/07/2026
Ahmad lo gbe e jáde nínú tira Musnad rẹ, pẹlu ounka (6072), ati Tirmiziy pẹlu ounka (1535), o si sọ pé: Hadiisi naa dáa.
Bukhari ni o gbe e jade ninu tira Al-Adab Al-Mufrad pẹlu onka (716), àti Ahmad ninu Al-Musnad pẹlu onka (19606), àti Ad-Diyā' Al-Maqdisiy ninu Al-Ahādīth Al-Mukhtārah (1/ 150), ti Al’albāniy sì sọ wipe o ni àlàáfíà ninu Sahīh Al-Jāmi' As-Saghīr pẹlu onka (3731).
Muslim ni o gbe e jade (121), ati Ahmad ninu Al-Musnad (10434).
(Al-Madhy) ni : Omi ti kò ki, ti kò sì ní àwọ̀, o maa n jade nigba ere-ìfẹ́ tàbí ríránńtí ibalopọ tàbí gbígbèrò rẹ̀ tàbí wíwòran tàbí àwọn nnkan míràn bẹ́ẹ̀. O sì maa n jade ní ṣíṣẹ́ẹ́rẹ́ṣẹ́ẹ́rẹ́, bóyá a kò tiẹ̀ ní mọ̀ pé ó n jade. (Al-Wady): Oun ni omi funfun ti o ki, ti o maa n jade lẹ́yìn itọ́, tàbí nígbà tí a bá gbé nnkan tó wúwo.
Muslim ni o gbe e jade (224).
Mālik ni o gbe e jáde ninu Al-Muwatto' (680 ati 219), ati Ad-Daarimiy (312), ati ‘Abdurrozzāq ninu Musonnof rẹ (1328), ti Al’albāniy sì sọ pé o ni àlàáfíà ninu tira Irwā'ul Golīl (122).
An-Nasā’iy ni o gbe e jade (12808), ati ’Ahmad (15423), ti Al-’Albāniy sì sọ pé o ni àlàáfíà ninu Irwā’ul Golīl (121).
Ibnu Mājah ni o gbe e jáde (594), ati Ibnu Hibbān (799), ti Al’albāniy sì sọ pé o jẹ́ aláìlera ninu Ḍọ‘īfu Sunani Tirmidhiy (146).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (142), ati Muslim pẹlu ounka (122).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (7288), ati Muslim pẹlu ounka (6066).
Ọlọla wa Olumọ agba Abdul Azeez ọmọ Bāz - ki Ọlọhun kẹ ẹ - sọ nínú àkójọpọ̀ àwọn ìdáhùn rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn (29/ 141) pé: (Aafa aladiisi Bay'hakiy fi kún un pẹ̀lú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kálẹ̀ tó dára láti ẹnu Jaabir lẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà: «Èyí tí O ti ṣe àdéhùn fún un»: «Dájúdájú Ìwọ kì í yẹ àdéhùn»).
Tirmidhiy ni o gbe e jade, pẹlu ounka (2635).
Muslim ni o gbe e jade (82).
Tirmiziy ni o gbe e jade (265), o si sọ pé: o dáa, o ni àlàáfíà, o si jẹ goriib, ti Albaaniy sì sọ pé o ni àlàáfíà nínú tira SOHIIHUT-TAR'GIIBI WAT-TAR'HIIB.
Bukhari ni o gbe e jade (1117).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (6251), ati Muslim pẹlu ounka (884).
Bukhōriy ni o gbe e jáde pẹlu ounka (756), àti Musilim pẹlu ounka (872).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (793), ati Muslim pẹlu ounka (398).
Bukhari ni o gbe e jade (812) ati Muslim (490).
Muslim ni o gbe e jade (498).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (724), ati Muslim pẹlu ounka (398).
Bukhari ni o gbe e jade (797), ati Muslim (402).
Tirmidhiy ni o gbe e jade, pẹlu ounka (839).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (6008).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1110).
Bukhari ni o gbe e jade, pẹlu ounka (835).
Bukhōriy ni o gbe e jáde, pẹlu ounka (743), àti Muslim, pẹlu ounka (399).
Tirmidhiy ni o gbe e jade, pẹlu ounka (266).
Muslim ni o gbe e jade (588).
Abu Daa'ud ni o gbe e jade, pẹlu ounka (5168).
Tirmidhiy ni o gbe e jade, pẹlu ounka (284).
Muslim ni o gbe e jade (1484).
Bukhari ni o gbe e jade (609) ati Muslim (602).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (4130), ati Muslim pẹlu ounka (842).
Muslim ni o gbe e jade (865).
Bukhōriy ni o gbe e jáde pẹlu ounka (934), ati Muslim pẹlu ounka (851).
Bukhōriy ni o gbe e jáde, pẹlu ounka (1081), ati Muslim pẹlu ounka (693).
Al-Bukhari ni o gbe e jade, pẹlu ounka (1012), àti Musilim, pẹlu ounka (894).
Abu Daa'ud ni o gbe e jade (3201), ati Tirmiziy (1024), o sọ pé: Hadiisi naa dáa o si ni àlàáfíà.
Muslim ni o gbe e jade (962).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (8), ati Muslim pẹlu ounka (111).
Ibnu Mājah ni o gbe e jáde (1792), ati Tirmidhiy (63) ati (631).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1402), àti Muslim pẹlu ounka (2287).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1432), àti Musilim pẹlu ounka (984).
Abu Dāud ni o gbe e jáde (1609), ati Ibnu Mājah (1827), ti Al’albāniy sì sọ pé o ni àlàáfíà ninu Ṣọhīhu Abī Dāud (1609).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu onka (1), àti Muslim pẹlu onka (1907).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1810), àti Muslim pẹlu ounka (1086).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1909).
Ahmad ni o gbe e jade (26457), ati Abu Dawood (2454), ati An-Nasaa'iy (2331), gbólóhùn yii si ni ti ẹ̀.
Bukhōriy ni o gbe e jade (6669), ati Muslim (2709).
Abu Daa'ud ni o gbe e jáde (2380), ati Tirmiziy (719), ati Ibnu Maajah (676).
Al-Bukhari Logbaa, pẹlu ounka (1849), àti Musilim, pẹlu ounka (1846).
Muslim ni o gbe e jade (1134).
Ahmad ni o gbe e jade (25198), ati An-Nasaa'iy (2627), ati Ibnu Mājah (2901).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1862), ati Muslim pẹlu ounka (1341).
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu ounka (1531).
Muslim ni o gbe e jade pẹlu ounka (1211).
Bukhōriy ni o gbe e jáde, pẹlu ounka (1549).
Muslim ni o gbe e jade, pẹlu ounka (1218).
Tirmiziy ni o gbe e jade (487), o sọ pé: o dáa o sì jẹ́ gorīb, ti Al’albāniy sì sọ pé o dáa.
Wo: Mughnil Muhtāj (2/22).
Haashiyah Ibn 'Aabideen (1/ 42).
Wo: Al-Majmū' (1/ 50).
Oun ti wọn n pé ni «ash-Shuf'ah» ni: ẹtọ tí alájọṣepọ̀ ní láti gba ipin alájọṣepọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó ti di tirẹ̀ pẹ̀lú pàṣípààrọ̀ dukia.
Tita Al-'Iinah: Oun ni ki eniyan ta nkankan fun ẹlomiran ni owo awin, ti yio si gbe e le e lọwọ, leyin naa, ki o ra a pada siwaju gbigba owo naa pẹlu owo ti o din ju owo ti o koko ta a lesekese.
Bukhari ni o gbe e jade pẹlu onka (8).