كَيْفِيَّةُ صَلَاةِ النَّبِيِّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ
Bí Anabi (kí ikẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a) ṣe ń kirun
لِفَضِيلَةِ الشَّيْخِ العَلَّامَةِ
عَبْدِ العَزِيزِ بْنِ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ بَازٍ
غَفَرَ اللَّهُ لَهُ وَلِوَالِدَيْهِ وَلِلْمُسْلِمِينَ
Samaahatush Shaikh , oní mimọ àgbà
Abdul Azeez ọmọ Abdullah ọmọ Bāz
بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ
Bí Anabi (kí ikẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a) ṣe ń kirun
Ni orukọ Ọlọhun Ọba Ajọke aye Aṣakẹ ọrun
Gbogbo iyin ti Ọlọhun ni ní Oun nikan ṣoṣo, ikẹ ati ọla kó maa bá ẹrú Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ, Anabi wa Muhammad, ati awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ, lẹ́yìn náà:
Awọn gbolohun ṣoki wọnyii ni o jẹ alaye bí Ànábì - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a se má nkirun -, tí mo fẹ́ gbé é síwájú gbogbo Musulumi lọkunrin àti lobinrin, kí gbogbo ẹni tí ó bá yẹ̀ ẹ́ wò ó lè sa ipá láti fi ṣe àwòkọ́ṣe nípa rẹ̀; nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pé:
(صَلُّوا كَمَا رَأَيْتُمُونِي أُصَلِّي).
(Ẹ máa kirun gẹgẹ bí ẹ ṣe rí mi tí mo nkirun) 1. Fún olùkàwé ni àlàyé èyí:
1- Yio ṣe aluwala ni pípé, èyí ni ṣíṣe é gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ti pa á láṣẹ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ - Mímọ́ àti Gíga - :
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قُمۡتُمۡ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ فَٱغۡسِلُواْ وُجُوهَكُمۡ وَأَيۡدِيَكُمۡ إِلَى ٱلۡمَرَافِقِ وَٱمۡسَحُواْ بِرُءُوسِكُمۡ وَأَرۡجُلَكُمۡ إِلَى ٱلۡكَعۡبَيۡنِ...﴾.
( Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá( nùu orí yín ) orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. [Al-Mâ'idah: 6]. Aayah, ( orí ọrọ ẹsẹ)
ati ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba – to sọ pe:
(لَا تُقْبَلُ صَلَاةٌ بِغَيْرِ طُهُورٍ).
(Ọlọhun o nii gba irun laisi imọra)2.
ati ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - tí o sọ fun ẹni ti o ṣe aṣiṣe ninu irun rẹ:
(إِذَا قُمْتَ إِلَى الصَّلَاةِ، فَأَسْبِغِ الْوُضُوءَ).
(Nígbà tí ọ bá fẹ́ kirun, ṣe àṣepé Aluwala)3.
2- Ẹni ti o fẹ kirun yíò dojukọ Al-kibla, ( ibudajukọ ) oun naa ni Ka'ba, níbikíbi tí ó wà pẹ̀lú gbogbo ara rẹ̀, tí yíò sì da aniyan sí inú ọkàn rẹ̀ láti kii irun tí ó bá fẹ́, yálà irun ọ̀ranyàn ni tàbí àfikún ( alekun nafilah ) , kò sì ní sọ aniyan náà pẹ̀lú ahọ́n rẹ̀; nítorí wípé sísọ ọ́ jáde pẹ̀lú ahọ́n kò jẹ́ ohun tí a pa ní làṣẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, bidiaa ni ( adadaalẹ ni ) , nítoripé Ànábì - ki ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a - kò sọ aniyan jáde, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn Sahaba rẹ̀ - kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn. Yíò sì gbé sutra ( òunh ni gágá) kalẹ̀ níwájú rẹ̀ tí yíò máa kirun sí, tí ó bá jẹ́ Imāmu tàbí ẹni tí ń da kirun, dída ojú kọ Al-kibla sì jẹ́ òfin nínú irun àyàfi nínú àwọn ọ̀rọ̀ kan tí a yọ kúrò tí a mọ̀ tí ó sì hàn kedere nínú àwọn ìwé àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ni .
3- Yio kabara ( gbígbé títóbi fún Ọlọhun ) iwọ irun, yio sọ pe: Allahu Akbar, oju rẹ yio si maa wo ibi iforikanlẹ rẹ.
"4- Yio gbe ọwọ rẹ mejeeji soke nibi kikabara titi de ejika rẹ mejeeji tabi titi de eti rẹ mejeeji."
5- Yio gbe ọwọ rẹ lori aya rẹ, ọwọ ọtun rẹ lori atẹlẹwọ osi rẹ, ọrùn ọwọ́ rẹ, ati apá rẹ; nítorí pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ﷺ.ki ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ máa ba a.
6- Sunna ( ilana Anobi ni) kí á ka Adura ìṣírun, óhun ni :
(اللَّهُمَّ بَاعِدْ بَيْنِي وبيْنَ خَطَايَايَ، كَمَا بَاعَدْتَ بَيْنَ المَشْرِقِ وَالمَغْرِبِ، اللَّهُمَّ نَقِّنِي مِنَ الخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ، اللَّهُمَّ اغْسِلْ خَطَايَايَ بِالمَاءِ وَالثَّلْجِ وَالبَرَدِ).
(Allaahummọ baa'id baynii wa bayna khatọọyaaya, kamaa baa'adta baynal mashriqi wal magrib, Allaahummọ naqqinii minal-khatọọyaa kamaa yunaqqọth-thaobul ab'yadu minad-danas, Allaahummọg-sil khatọọyaaya bil-maa'i wath-thalji wal-baradi).èyí tí túmọ sí pé : ( Irẹ Ọlọhun mọn sáà gbé mí jinan sí awan aṣiṣe mí, gẹgẹ bí o se gbe ibuyọ oòrùn jìnà sí ibuwọ rẹ , Irẹ Ọlọhun fọ mí mọn kúrò níbi aṣiṣe mí gẹgẹ bí wàn se má nfọ aṣọ fún fún mọ níbi ẹgbin àti idọti, Irẹ Ọlọhun mọn sáà wẹ mi níbi aṣiṣe mí pẹlu omi, yìnyín àti pẹlú èérí yín yín).4
Ti o ba si fẹ́, o le tún sọ dipo ìyẹn pe:
(سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وبِحَمْدِكَ، وَتَبَارَكَ اسْمُكَ، وَتَعَالَى جَدُّكَ، ولَا إلَهَ غَيْرُكَ).
(Mimo Re Ire Oluwa pelu iyin Re, atipe oruko Re ni ibukun, ati wipe ola Re ga, atipe ko si eniti ijosin tosi yato si Iwo)5, Ati pé tí o bá mú àwọn adua iṣirun mìíràn wá tí ó fi ẹsẹ̀ rinlẹ láti ọ̀dọ̀ Anabi -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, kò sí ìyọnu. Èyí tí ó sì dára jùlọ ni pé kí ó ṣe èyí ní ẹẹkan, kí ó sì ṣe èkejì nígbà mìíràn; nítorí pé ìyẹn pé jùlọ nínú títọ ipasẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóò sọ pé: ‘AUDHU BILLAAHI MINASH-SHAYTAANI-R-RAJIIMI, BISMI-LLAAHI-R-RAHMAANI-R-RAHIIM’, yóò sì ka Suuratul Faatiha, nítorí ọrọ rẹ pé:
(لَا صَلَاةَ لِمَنْ لَمْ يَقْرَأْ بفَاتِحَةِ الكِتَابِ).
(Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha)6. Yio sọ lẹyin rẹ - Āmīn - ni ohùn rara nibi Irun asoke, ati ni ikọkọ nibi Irun abẹnu. Lẹyin naa yio ka eyikeyi ti o ba rọ ọ lọrun ninu Al-Qur'āni, ohun ti o si dara ju ni ki o ka lẹyin Faatiah nibi Irun Zuhr, Asr, ati Isha ninu aarin-aarin Al-Mufassal, ati nibi Irun Al-fajri ninu awọn gigun rẹ, ati nibi Irun Magrib ni igba miran ninu awọn gigun rẹ, ati ni igba miran ninu awọn kukuru rẹ, lati fi ṣiṣẹ pẹlu awọn hadiith ti o wa lori iyẹn.
7- Yio rukuu pẹlu pípe takbir ( gbígbé títóbi fún Ọlọhun) , yio gbe ọwọ rẹ mejeeji si ẹgbẹ ejika rẹ mejeeji tabi eti rẹ mejeeji, yio si jẹ ki ori rẹ ati ẹyin rẹ wa ni dọgba dọgba, yio gbe ọwọ rẹ mejeeji lori orunkun rẹ mejeeji ti awọn ika ọwọ rẹ yio si wa ni yíyà síra wọn, yio si ni ifarabalẹ sí rukuu ( itẹriba ) rẹ, yio si sọ pe: Subhaana Robbiyal Azeem. ( Mimọ fún Olúwa mí tí otobi) Ohun to si dara julọ ni ki o tun un sọ ni ẹẹmẹta tabi ju bẹẹ lọ, o si jẹ ohun ti a fẹran ki o tun sọ pẹlu iyẹn pe:
(سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ، اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِي).
(SUBHAANAKALLAAHUMMA WABIHAMDIKA, ALLAAHUMMAGFIR LII (Mimọ fun Irẹ Ọlọhun Oba ati pẹlu ẹyin Rẹ, Irẹ Ọlọhun, forijin mi))7
8- Yio gbe ori rẹ soke lati inu rukuu ( itẹriba ) , l'ẹniti o n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji tàbí etí rẹ mejeeji, l'ẹniti yio maa sọ pe: Samihal-Lọọhu liman hamidah( Ọlọhun tí gbọ òunh ẹni to fí ìyìn fún) Ti o ba jẹ imaamu tabi ẹni ti n da Irun ki, yio si sọ nígbà tí o n dide pe:
(رَبَّنَا وَلَكَ الحَمْدُ حَمْدًا كَثِيرًا طَيِّبًا مُبَارَكًا فِيهِ مِلْءَ السَّمَواتِ ومِلْءَ الأرضِ، ومِلْءَ مَا شِئتَ مِنْ شَيءٍ بَعْدُ).
Rọbbanaa wa lakal hamdu, hamdan kasiirọn toyyiban mubaarọkan fiihi mil'assamaawaati wamil'al ardi, wamil'a maa shi'ta min shay'in ba'du8. ìtumọ rẹ (Irẹ Olúwa wà ni ọpẹ àti ìyìn tọ sí , ìyìn tí o pọ tí o sí mọ, tí o kún fún ìbùkún, tí o kún oke , sanmọ àti ilẹ, tí o sí kún ààyè tí nbẹ láàrin méjèjì)
Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ ero ẹyin imam ni , yóò máa sọ nígbà tí ó bá ń gbéra didé pé: Robbanaa wa laKal hamdu ( Irẹ Olúwa wa irẹ ni ọpẹ àti ìyìn tọ sí) , títí dé òpin àwọn ohun tí ó ti ṣíwájú. Bí olúkúlùkù nínú wọn bá sì ṣe àfikún -mo ní lọ́kàn: imam, ero ẹyin imam, àti oluda-irun-ki-
(أَهْلَ الثَّنَاءِ وَالْمجْدِ، أَحَقُّ مَا قَالَ العَبْدُ، وَكُلُّنَا لَكَ عَبْدٌ: اللَّهُمَّ لَا مَانِعَ لِمَا أعْطَيْتَ، وَلَا مُعْطِيَ لِمَا مَنَعْتَ، ولَا يَنْفَعُ ذَا الجَدِّ مِنْكَ الجَدُّ).
(Ire ni O ni eẹo si iyin ati iyi, O ni ẹtọ si i ju ohun ti ẹrú n so lo, atipe gbogbo wa ẹrú Re ni wa. Irẹ Oluwa, kosi oludena fun nkan ti O ba fun ni, atipe kosi olufunni ni ohun ti O ba kọ funni atipe ọrọ kole wulo fun ọlọrọ ni ọdọ Re)9. O si jẹ eyi ti o daa nitori orinlẹ bẹ lati ọdọ rẹ.
Wọn fẹ kí olúkúlùkù wọn – ìyẹn ni Imọmu, ẹni tí nkirun lẹyìn imamu àti ẹni tí n dá kirun – fi ọwọ́ rẹ̀ sórí igbaaya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe lori ìduro rẹ̀ ṣíwájú rukuu (itẹriba) , nítorí ohun tó fìdí èyí múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nínú hadith Wā'il ọmọ Hujr àti Sahl ọmọ Sa'd, kí Ọlọhun yọ́nú sí awọn méjèèjì.
9- Yio wa forikanlẹ pẹlu kabara( gbígbé títóbi fún Ọlọhun) , yio si mú orunkun rẹ mejeeji lọ lẹ ṣiwaju ọwọ rẹ mejeeji bi o ba rọrun fun u lati ṣe bẹẹ, ti o ba si ṣoro fun u yio mú ọwọ rẹ mejeeji lọ lẹ ṣiwaju orunkun rẹ mejeeji, yio si koju awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ ati ti ọwọ rẹ si Qibla, ti yio si pa awọn ọmọnika ọwọ rẹ pọ ti yio si na wọn, yio si wa lori oríkèé ara rẹ mejeje: Iwaju ori pẹlu imu, atẹlẹwọ mejeeji, orunkun mejeeji, ati inu awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji, yio si sọ pe: Subhaana Robbiyal A'lā( mimọ fún Oluwa mí tí o ga jùlọ, Sunnah ni ki o sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta tabi ju bẹẹ lọ, o si jẹ ohun ti o dara ki o sọ pẹlu iyẹn pe:
(سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ رَبَّنا وَبِحَمْدِكَ، اللَّهُمَّ اغْفِرْ لِي).
SUBHAANAKALLAAHUMMA RABBANAA WABIHAMDIKA, ALLAAHUMMAGFIR LII (Mimo fun Irẹ Oluwa mi, Ire Oluwa, Oluwa wa ati pe iyin ni ti Re, Irẹ Oluwa, fi orijin mi) Ati ki o si maa ṣe adura ni ọpọlọpọ nitori ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe:
(أَمَّا الرُّكُوعُ، فَعَظِّمُوا فِيهِ الرَّبَّ، وَأَمَّا السُّجُودُ، فَاجْتَهِدُوا فِي الدُّعَاءِ، فَقَمِنٌ أَنْ يُسْتَجَابَ لَكُمْ).
(Ti ẹ ba ti wa ni rukuu ( iteriba ) ki ẹ gbe Ọluwa tobi nibẹ, ti ẹ ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ gbìyànjú láti ṣe adua nibẹ, nkan ti o tọ́ ni ki wọn gba adua yin)10.
Yio sì béèrè lọwọ Oluwa rẹ ninu oore aye ati ti ọjọ ikẹhin. Ki baa jẹ ọranyan ni tabi irun àfikún, yoo si ya apá rẹ mejeeji kuro lara ẹgbẹ rẹ mejeeji, ati ikun rẹ kuro lara itan rẹ mejeeji, ati itan rẹ mejeeji kuro lara ojúgun rẹ mejeeji, yoo si gbe ìwọ́ apá rẹ mejeeji soke kuro lori ilẹ nitori ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -:
(اعْتَدِلُوا في السُّجُودِ، ولَا يَبْسُطْ أحَدُكُمْ ذِرَاعَيْهِ انْبِسَاطَ الكَلْبِ).
(E ṣe deede nibi iforikanlẹ, ati pe ẹ ma da ọwọ yin delẹ ni idadelẹ ti aja)11.
10- Yoo gbe ori rẹ soke lẹniti yoo maa sọ pe: “Allahu Akbar”,( Ọlọhun ní o tóbi julọ) yoo si tẹ ẹsẹ osi rẹ silẹ, yoo joko le e, yoo si gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke, yoo si gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan rẹ mejeeji ati orunkun rẹ mejeeji, yoo si sọ pe:
(رَبِّ اغْفِرْ لِي وَارْحَمْنِي وَاهْدِنِي وَارْزُقْنِي وَعَافِنِي وَاجْبُرْنِي).
(Robbi igfir lī, warhamnī, wahdinī, warzuqnī, wa ‘āfinī, wajburnī) ìtumọ rẹ: Irẹ Oluwa mi se aforijin fún mí, kí o sí kẹ mí, kí o se amọna mí , kí o sí pèsè ijẹẹmu fún mí, kí o sí fún mi ni ìlera, ki o sí ṣe àtúnṣe mi12. Yio si fara balẹ̀ nibi ìjókòlẹ yii.
11- Yio si forikanlẹ ẹlẹẹkeji ni ẹni tí yóò gbé títóbi fún Ọlọhun, yio si ṣe gẹgẹ bi o ti ṣe ninu iforikanlẹ akọkọ nínú rẹ.
12- Yio gbe ori rẹ soke pẹlu kabara ( gbígbé títóbi fún Ọlọhun ) rẹ, yio si joko ijoko fúfuyẹ kan gẹgẹ bi ijoko laarin iforibalẹ mejeeji, a si n pe e ni ijoko isinmi, o si jẹ ohun ti o yẹ, ti o ba si fi silẹ, ko si aburu fun un, kò si iranti tabi adua kankan ninu rẹ. Lẹyin naa yio dide duro fun raka keji, ni ẹni ti o maa fi ara ti orikun rẹ mejeeji ti o ba rọrun fun un, ti o ba si ṣoro fun un, yio fi ara ti ilẹ. Lẹyin naa yio ka Faatiah ati ohun ti o ba rọrun fun un ninu Al-Qur’an lẹyin Faatiah, lẹyin naa yio ṣe gẹgẹ bi o ṣe ṣe nibi raka alakọkọ.
13- Bí Irun bá jẹ́ olopo méjì -ìyẹn rakaa meji- gẹ́gẹ́ bíi Irun Alfajir, Jimọ àti àwọn ọdún méjèèjì, yíò jókòó lẹ́yìn tí ó bá gbé orí rẹ̀ kúrò níbi iforikanlẹ ẹlẹẹkeji, yíò na ẹsẹ ọ̀tún rẹ̀, yíò sì tẹ ẹsẹ òsì rẹ̀ sílẹ̀. Yíò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí itan ọ̀tún rẹ̀, tí yíò ká gbogbo àwọn ọmọ ìka rẹ̀ pọ̀ àyàfi ìka odun-unlabẹ, èyí tí yíò máa fi tọ́ka sí ìjẹ́-ọ̀kanṣoṣo Ọlọ́hun. Bí ó bá sì ká kurumbete àti ìka oruka-yẹmi láti inú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó sì so àtàǹpàkò rẹ̀ pọ̀ mọ́ ògáájúwọ̀n-lọ bí òrùka, tí ó sì tọ́ka pẹ̀lú ìka odun-unlabẹ, ìyẹn náà dára; nítorí pé àwọn ìrí méjèèjì yí fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ﷺ. Ohun tí ó sì dára jùlọ ni pé kí ó máa ṣe èyí nígbà kan, kí ó sì máa ṣe èkejì nígbà míràn. Yíò sì gbé ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí itan òsì rẹ̀ àti orúnkún rẹ̀, lẹ́yìn náà yíò ka ataaya níbi ìjókòó yí, òun náà ni:
(التَّحِيَّاتُ للهِ وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ، السَّلَامُ عَلَيْكَ أيُّها النَّبيُّ وَرَحْمَةُ اللهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ الله الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إلَهَ إلَّا اللهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ).
(Gbogbo kíkí ti Ọlọhun ni, gbogbo Ikẹ àti gbogbo ohun rere tí Ọlọhun ni, àlàáfíà Ọlọhun kí ó máa bá ọ ìwọ Ànábì, àti ìkẹ́ Rẹ̀ àti àwọn oore Rẹ̀, àlàáfíà Ọlọhun kí ó máa bá àwa náà àti gbogbo àwọn ẹrúsin Ọlọhun tí wọ́n jẹ́ ẹni ire, mo jẹ́rìí wípé kò sí ẹni tí ìjọsìn òdodo tọ́ sí àyàfi Allāh, mo sì tún jẹ́rìí wípé Muhammad ẹrú Rẹ̀ ni, òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì ni pẹ̀lú). Lẹyin naa yio sọ pe:
(اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى إِبْرَاهِيمَ وَعَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ؛ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ، وَبَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا بَارَكْتَ عَلَى إِبْرَاهِيمَ وَعَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ؛ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ).
(Ọlọhun se ikẹ fún Anọbi Muhammad àti fún àwọn ará ilé Anọbi Muhammad, gẹ́gẹ́ bí O ti se ikẹ fún Anọbi Ibrahim àti àwọn ará ilé Anọbi Ibrahim; dájúdájú Ìwọ ni Ọba Ẹlẹ́yìn, Ọba tí Ó gbọ̀ngbọ̀n. Kí O sì se ìbùkún fún Anọbi Muhammad àti fún àwọn ará ilé Anọbi Muhammad, gẹ́gẹ́ bí O ti se ìbùkún fún Anọbi Ibrahim àti àwọn ará ilé Anọbi Ibrahim; dájúdájú Irẹ ni Ọba tí a nfi iyìn fún Ọba tí Ó gbọ̀ngbọ̀n)13.
Yio si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro ninu nkan mẹrin, ti yio si maa sọ pe:
(اللَّهُمَّ إنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنْ عَذَابِ جَهَنَّمَ، وَمِنْ عَذَابِ القَبْرِ، وَمِنْ فِتْنَةِ المَحْيَا وَالْمَمَاتِ، وَمِنْ شَرِّ فِتْنَةِ المَسِيحِ الدَّجَّالِ).
Irẹ Oluwa dajudaju emi wa isọ pẹlu Re kuro nibi iya jahanama, ati kuro nibi iya saare, ati kuro nibi fitina( idamu) isemi aiye ati fitina( wahala ) ti iku, ati kuro nibi aburu fitina ( idamu) Masiihud-Dajjaal14.
Lẹ́yìn náà yóò ṣe àdúrà pẹ̀lú bibere ohun tí ó bá fẹ́ nínú oore ayé àti ti ọjọ́ ìkẹhìn, tí ó bá sì ṣe àdúrà fún àwọn òbí rẹ̀ tàbí ẹlòmíràn yàtọ̀ sí wọn nínú àwọn Mùsùlùmí kò burú - yálà irun náà jẹ́ èyí tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn tàbí àfíkún-; fún gbogbogbò ọ̀rọ̀ Ànábì -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a- nínú hadíìsì Ibn Mas'uud -kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- nígbàtí ó kọ́ ọ ní Tashahhud ( gbólóhùn ijẹri):
(ثُمَّ لِيَتَخَيَّرْ مِنَ الدُّعَاءِ بَعْدُ أَعْجَبَهُ إِلَيْهِ فَيَدْعُو).
«Lẹyin naa ki o ṣẹsa ninu adua eyiti o wu u julọ, ki o si gbadura»15. Ninu gbolohun mìíràn:
(ثُمَّ لِيَخْتَرْ مِنْ الْمَسْأَلَةِ مَا شَاءَ).
(Lẹyin naa, ki o ṣe ẹṣa ninu ibeere ti o ba fẹ lọdọ Ọlọhun)16.
Èyí sì kó gbogbo nnkan ti o maa ṣe ẹru ni anfaani ni aye ati ọrun. Lẹyin naa yio waa salamọ si apá ọtun rẹ ati osi rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe: "As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi", "As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi " ( ikẹ Ọlọhun àti ọlá rẹ máa bayin gbe )
14- Tí Irun naa ba jẹ olopo mẹta, oniraka‘a mẹta bi ti Magrib, tabi oniraka‘a mẹrin bi ti Zuhr, Asri ati Ishai, yíò ka atayah ( gbólóhùn ijẹri ) ti a mẹnuba siwaju pẹlu asalatu fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –, lẹyin naa yíò dide duro, yíò gbarale orunkun rẹ mejeeji, yíò gbe ọwọ rẹ mejeeji si egbe ejika rẹ mejeeji tabi eti rẹ mejeeji, yíò sọ pe: Allahu Akbar. Yíò si gbe awọn mejeeji – ìyẹn ọwọ rẹ – le aya rẹ gẹgẹbi o ti ṣiwaju, yíò si ka Faatiah nikan. Ti o ba si ka afikun si Faatiah ni raka‘a kẹta ati kẹrin ti Zuhr ni igba miiran kò buru, latari ifẹsẹrinlẹ ohun ti o nfihan iyẹn lati ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lati inu hadiith Baba Sa‘iid – ki Ọlọhun yọnu si i. Ti o ba si fi asalatu ṣiṣe fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – silẹ lẹyin atayah alakọkọ, kò buru; nitori pe ohun ti o yẹ ni ṣiṣe ni, kii ṣe ọranyan ni atayah alakọkọ. Lẹyin naa yíò ṣe atayah lẹyin raka‘a kẹta ti Magrib ati lẹyin raka‘a kẹrin ti Zuhr, Asri ati Ishai gẹgẹbi o ti ṣiwaju ninu Irun oniraka‘a meji. Lẹyin naa yíò salamọ sí ọtún rẹ, lẹyin naa sí osi rẹ, yíò si tọrọ aforijin lọdọ Ọlọhun ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yíò sọ pe:
(اللَّهُمَّ أَنْتَ السَّلَامُ وَمِنْكَ السَّلَامُ، تَبَارَكْتَ يا ذَا الجَلَالِ وَالإِكْرَامِ).
“Allahumma anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam Tabaarak'ta yaa zal Jalaali Wal ikraam”. ( Mo pe iwọ Oluwa mi! Iwọ ni Ọba alaafia, ọdọ Rẹ si ni alaafia ti nwa, Gbigbọn-n-gbọn Rẹ, Iwọ Ọba ti O ni titobi ati apọnle)17. Síwaju Ki o to kọjú si awọn eeyan, ti o ba jẹ pé imaamu ( asíwájú) ni yio wa sọ pe:
(لَا إِلَهَ إلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَه، لَهُ المُلْكُ، وَلَهُ الحَمْدُ، وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيءٍ قَدِيرٌ، لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إلَّا بِاللهِ، اللَّهُمَّ لَا مَانِعَ لِمَا أَعْطَيْتَ، وَلَا مُعْطِيَ لِمَا مَنَعْتَ، وَلَا يَنْفَعُ ذَا الجَدِّ مِنْكَ الجَدُّ، لَا إلَهَ إلَّا اللهُ، وَلَا نَعْبُدُ إلَّا إيَّاهُ، لَهُ النِّعْمَةُ وَلَهُ الفَضْلُ، وَلَهُ الثَّنَاءُ الحَسَنُ، لَا إلَهَ إلَّا الله مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَو كَرِهَ الكَافِرُونَ) .
(Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti Ẹ ni iyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan, ko si ọgbọn ko si agbara ayafi pelu Allaah, Ọlọhun, ko si eni ti o le di ohun ti O ba funni, atipe ko si eni ti o le funni ni ohun ti O ba dina, atipe ọlá ọlọlá ko le se e lanfani lọdọ Rẹ, ko si ẹnití ijọsin tọ si ayafi Allaah, atipe awa ko nii sin ẹlomiran yato si I. Ti Ẹ ni ike nse, ti Ẹ ni ọla nse atipe ti Ẹ ni e
iyin to rẹ wa nse, ko si eniti ijosin tọ si ayafi Allaah ni ẹnití a nse afomo ẹṣin fun Un, koda ki awon keferi o korira bee)18.
Yio ṣe afọmọ fun Ọlọhun ni igba mẹtalelọgbọn, yio si dupẹ fun Un bakanna, yio si gbe titobi fun Un bakanna, yio si sọ ni ẹkun ọgọrun pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka islaHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr. Yio si ka Āyatul-Kursiy, ati Qul Huwa LLāhu ahad, ati Qul a'ūdhu bi Rabbil-falaq, ati Qul a'ūdhu bi Rabbin-nās ni ẹyin gbogbo irun kọọkan. A si gba ni iyanju lati tun awọn suurah mẹtẹẹta wọnyi ka ni igba mẹta lẹyin irun Fajr ati irun Magrib; nitori awọn hadith ti o fi idi rẹ mulẹ nipa wọn lati ọdọ Anabi ﷺ. Gbogbo awọn àdhikār wọnyi si jẹ sunnah, wọn kii ṣe ọranyan.
Ó jẹ́ súnà fún gbogbo Mùsùlùmí ọkùnrin àti obìnrin láti kí rakah mẹ́rin ṣíwájú irun Zuh'r àti rakah méjì lẹ́yìn rẹ̀, rakah méjì lẹ́yìn irun Magrib, rakah méjì lẹ́yìn irun Ishai, àti rakah méjì ṣíwájú irun Fajr. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ rakah méjìlá. Àwọn rakah wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní Rawaatib; nítorí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a - máa ń kí wọ́n déédéé nígbà tí kò bá sí lórí ìrìn-àjò. Ṣugbọn lori irin ajo, o maa n gbe wọn silẹ ayafi irun naafilah asunba ati irun naafilah witiri, nítorí pé oun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n tẹramọ awọn mejeeji boya o wa nile ni o tabi ori irin ajo. Eyí tí o dà jù ni ki a ki awọn irun naafilah wọnyi ati witiri nile, ṣugbọn bí ó bá ki wọ́n ní Mọṣalaṣi kò burú; fún ọrọ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe:
(أفْضَلُ صَلَاةِ المَرْءِ في بَيْتِهِ، إلَّا الصَّلَاةَ المَكْتُوبَةَ).
(Irun ti o daa julọ fun eniyan ni ile rẹ, ayafi Irun ọranyan)19.
Ati títẹ̀ramọ́ awọn rakaah yii wa ninu awọn okunfa wiwọ alujanna fun ọ̀rọ̀ Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe:
(مَنْ صَلَّى اثْنَتَيْ عَشْرَةَ رَكْعَةً فِي يَومٍ وَلَيْلَةٍ، بُنِيَ لَه بِهِنَّ بَيْتٌ فِي الجَنَّةِ) .
(Ẹnikeni ti o ba ki Raka'a mejila ni ojumọ ati alẹ, Ọlọhun yóò kọ ile kan fun un ninu Alujannah)20.
Bí ó bá sì ki rak'a mẹrin síwájú irun Asr, ati rak'a meji síwájú irun Maghrib, ati rak'a meji síwájú irun Isha, ó dára; nítorí pé hadith ti fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Anọbi (kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a) tó tọ́ka sí ìyẹn. Tí ó bá sì tún ki rak'a mẹrin lẹ́yìn irun Dhur àti rak'a mẹrin síwájú rẹ̀, ó dára; látarí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (kí ìkẹ́ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a) pé:
(مَنْ حَافَظَ عَلَى أَرْبَعِ رَكَعَاتٍ قَبْلَ الظُّهْرِ، وَأَرْبَعٍ بَعْدَهَا حَرَّمَهُ اللَّهُ عَلَى النَّارِ).
(Enikeni tí o bá samojuto irun rak'a mẹrin síwájú irun ọsán ati merin leyin rẹ Ọlọhun yóò ṣe wíwọ ina leewọ fún) 21. Itumọ rẹ ni wipe yio se alekun rakaah meji lori Sunnah Raatibah ( òun ni nafilah síwájú tàbí lẹyìn ìrun ọranyan) lẹyin irun Oosan; nitori wipe Sunnah Raatibah jẹ rakaah mẹrin siwaju rẹ ati meji lẹyin rẹ. Ti o ba si se alekun rakaah meji lẹyin rẹ, yoo ti se ohun ti a mẹnuba ninu hadiith Ummu Abiibah - ki Ọlọhun yọnu si i -.
Ọlọhun ni Ọba Olufiniṣekongẹ, ki Ọlọhun ba wa ṣe ikẹ ati igẹ fun Anọbi wa Muhammad ọmọ Abdullah, ati awọn ara ile rẹ, ati awọn saabe rẹ, ati awọn olutẹle rẹ pẹlu iṣe rere titi di ọjọ ẹsan.
***
yo395v2.1 - 10/03/2026
Muslim lo gba wa pẹlu ounka (224).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (5782).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (744), àti Muslim, pẹlu onka (598).
Muslim lo gba wa, pẹlu onka (399).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (756).
Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (817), àti Muslim, pẹlu onka (484).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (711), àti Muslim, pẹlu onka (598).
Muslim lo gba wa, pẹlu onka (477).
Muslim lo gba wa, pẹlu onka (479).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (788), àti Muslim, pẹlu onka (493).
At-tirmidhi lo gba wa, pẹlu onka (284), àti Abu Daud, pẹlu onka (850), àti Ibn Maajah, pẹlu onka (898).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu ounka (797), àti Musilim, pẹlu ounka (402).
Al-Bukhari lo gba wa, pẹlu onka (1311), àti Muslim, pẹlu onka (588).
An-nasahi lo gba wa, pẹlu ounka (1298) .
Muslim lo gba a wa, pẹlu ounka (402).
Muslim lo gbaa wa, pẹlu ounka (591).
Musilim lo gbaa wa, pẹlu ounka (402)
Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (6860).
Muslim logbaa wa, pẹlu ounka (728).
Ahmad l'o gba wa, pẹlu onka (25547), àti At-tirmidh, pẹlu onka (393), àti Abu Daud, pẹlu onka (1077).
Al-Bukhari lo gba a wa, pẹlu onka (605).