الوَسَائِلُ المُفِيْدَةُ لِلحَيَاةِ السَّعِيْدَةِ
Àwọn ọ̀nà tó ṣàǹfààní fún ìgbésí ayé oriire ( tàbí ìdùnnú)
الشَّيْخُ عَبْدُ الرَّحمَنِ بْنُ نَاصِرٍ السَّعْدِيُّ
رَحِمَهُ اللهُ
Iwe tí
Sheik Abdurrahman bin Nosir As-Sa'di (ki Ọlọhun saanu fun) kọ
بِسْمِ اللهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ
Àwọn ọ̀nà tó ṣàǹfààní fún ìgbésí ayé oriire ( tàbí ìdùnnú)
Ọrọ itisiwaju
Gbogbo ọpẹ n jẹ ti Ọlọhun ti o lẹtọ sí gbogbo ọpẹ , mo si n jẹrii pe ko si Ọlọhun ti ijọsin tọ si afi Allahu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, mo si n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni Ojiṣẹ Rẹ si ni, kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ maa ba a ati awọn ará ilé rẹ àti awọn saabe rẹ.
Lẹyin eyi: dájúdájú isinmi ọkàn, ati ibalẹ rẹ ati idunnu rẹ ati kíkúrò àwọn ẹdun-ọkàn àti ìbànújẹ́ rẹ̀, ohun ni ìfojúsùn fun gbogbo ẹnikẹni, ati pe pẹlu rẹ ni a fi n ri ìgbésí ayé tí ó mọ, ti idunnu ati ayọ si pe perepere, fun idi eyi o ni awọn okunfa ti ẹsin, ati awọn okunfa ti ti adamọ, ati awọn okunfa ti iṣẹ ṣiṣe, kò sì ṣe é ṣe kí gbogbo rẹ̀ kó papọ̀ ayafi fún àwọn olùgbàgbọ́, ṣùgbọ́n àwọn tí kì í ṣe wọ́n, dájúdájú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ọ̀nà kan àti okùnfà tí àwọn ọlọ́gbọ́n wọn ń sa ipá lé lórí, dájúdájú ó ti bọ fún wọn ní àwọn ọ̀nà tí ó ṣe ànfààní jùlọ, tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ jùlọ, tí ó sì dára jùlọ ní ipò àti ní ìgbẹ̀yìn.
Ṣùgbọ́n emi yóò mẹnu ba nínú iwe mi yìí àwọn okùnfà tí ó wá sí mi ní ẹmi fún ìfojúsùn gíga jùlọ yìí, èyí tí olúkúlùkù ń sápá fún.
Nínú wọn ni ẹni tí ó ṣe àṣeyọrí eyi to pọ̀ ninu rẹ̀, tí ó sì gbé ìgbési ayé ìtura, ó sì ní ìgbésí ayé rere. Ó sì tún wà nínú wọn ẹni tí ó kùnà nínú gbogbo rẹ̀ pátápátá, tí ó sì gbé ìgbésí ayé ìpọ́njú, ó sì lo ìgbésí ayé àwọn onípọ̀njú. Ó sì tún wà nínú wọn ẹni tí ó wà láàrin méjì, ni ibamu bí wọ́n ba se fi ṣe kongẹ to. Ọlọhun ni Olufiniṣekongẹ, Ẹni tí a n wá ìrànwọ́ Rẹ̀ lórí gbogbo ohun rere, àti lórí dídènà gbogbo aburú.
Apá ọrọ kan : Igbagbọ ati iṣẹ rere
Ati okùnfà ti o tobi julọ fun un, ati orísun rẹ̀, ati ìpìlẹ̀ rẹ̀ ni Igbagbọ ati iṣẹ rere, Ọlọhun- ọba ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 97﴾
«Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ lọ » Suuratun Nahl: 97.
Bẹẹ ni Ọlọ́hun tí ọlá Rẹ̀ ga fún wa niro, Ó sì ṣe àdéhùn fún ẹni tí ó pa ìgbàgbọ́ ní òdodo àti iṣẹ́ rere pọ̀, pé ìgbésí ayé rere ń bẹ fún un ní ilé ayé yìí, àti ẹ̀san rere ní ilé ayé yìí àti ní Ilé-ìgbẹ̀yìn.
Okunfa èleyí sì ti hàn kedere, nítorí pé àwọn onígbàgbọ́ sí Ọlọ́hun ní ìgbàgbọ́ òdodo, èyí tí ó máa ń so eso iṣẹ́ rere, tí ó sì ń ṣe àtúnṣe fún àwọn ọkàn àti ìwà àti ayé àti ọ̀run, wọ́n ní àwọn ìpìlẹ̀ tí wọ́n fi máa ń gba gbogbo ohun tó bá dé bá wọn nínú àwọn okunfa ìdùnnú àti ayọ̀, àti àwọn okunfa àníyàn, ìṣòro ọkàn àti ìbànújẹ́.
Wọ́n a máa gba àwọn ohun ayọ̀ àti ìdùnnú pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, àti dídúpẹ́ lórí rẹ̀, àti lílo rẹ̀ sí ohun tí ó ṣàǹfààní; Tí wọ́n bá sì lò ó ní ọ̀nà yìí, yóò mú inú dídùn sí i wá fún wọn, àti ìfojúsó̟nà sí pípẹ́ rẹ̀ àti ìbùkún rẹ̀, àti ìrètí ẹ̀san àwọn olùdúpẹ́; àwọn nǹkan ńlá tí ó tayọ pẹ̀lú àwọn dáadáa àti ìbùkún rẹ̀ ju àwọn ìdùnnú wọ̀nyí lọ, èyí tí ó se pé eléyìí jẹ́ èso rẹ̀.
Wọn a máa koju àwọn ohun tí kowu wàn àti àwọn ìnira, àti ìbànújẹ́ ọkàn pẹ̀lú gbígbógunti ohun tí wọ́n bá le gbógunti, àti sise ohun tí wọ́n bá le ṣe ni fufuyẹ, àti ṣíṣe sùúrù to dara lórí ohun tí kò sí ọ̀nà àbáyọ fún wọn nínú rẹ̀. Pẹ̀lú èyí, wọ́n máa ń rí àwọn ọ̀ràn ńláńlá gbà láti inú ipa àwọn ohun ìkóríra bíi àwọn gbígbógunti tó wúlò, àti àwọn ìrírí àti okun, àti láti inú sùúrù àti ríretí ẹsan; àwọn ọ̀ràn tí ó máa ń jẹ́ kí àwọn ohun ìkóríra pòórá, tí àwọn ìdùnnú àti àwọn ìrètí rere yóò sì rọ́pò wọn, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà sí oore àjùlọ Ọlọ́hun àti ẹsan Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ànábì ﷺ ṣe sọ nípa èyí nínú hadiith tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ pé ó sọ pé:
(عَجَبًا لِأَمْرِ الْمُؤْمِنِ، إِنَّ أَمْرَهُ كُلَّهُ خَيْرٌ، إِنْ أَصَابَتْهُ سَرَّاءُ شَكَرَ فَكَانَ خَيْرًا لَهُ، وَإِنْ أَصَابَتْهُ ضَرَّاءُ صَبَرَ فَكَانَ خَيْرًا لَهُ، وَلَيْسَ ذَلِكَ لِأَحَدٍ إِلَّا لِلْمُؤْمِنِ).
«Eemọ ni alamọri ( ọrọ ) olugbagbọ òdodo jẹ, dajudaju gbogbo alamọri rẹ ni onja sí oore , ti idunu ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ, ti yio si ja sí oore fun un, ti inira ba si ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru, ti yio si jasi oore fun un, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi olugbagbọ òdodo» Muslim ni o gba a wa.
Bayi ni Anabi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - se sọ pe dajudaju olugbagbọ òdodo ni ẹni tí e èrè rẹ ati oore rẹ ati èso awọn iṣẹ rẹ yóò ma pọ si i ni ilọpo-ilọpo ninu gbogbo nnkan ti o ba ba a ṣẹlẹ sí ninu idunnu ati inira; Nitori eyi, o maa ri eniyan meji ti adanwo kan ba ṣẹlẹ si wọn ninu awọn adanwo oore tabi ibi, wọn yoo si yàtọ̀ si ara wọn pẹlu ìyàtọ̀ nla nipa bi wọn ṣe gba a, ìyẹn si ni gẹgẹ bi ìyàtọ̀ wọn ninu igbagbọ ati iṣẹ rere wọn . Ẹni tí a sàpèjúwe rẹ̀ pẹ̀lú ìroyin méjèèjì yí a máa gba oore àti aburú pẹ̀lú ohun tí a ti mẹ́nu bà nínú idupẹ àti níní ifarada àti ohun tí ó bá tẹ̀lé wọn; idunnu àti ayọ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀ fún un, ìbànújẹ́, ìrora ọkàn, àníyàn, ìhámọ́ àyà, àti ìpọ́njú ìgbésí ayé yóò sì kúrò, ìgbé-ayé to dára yóò sì pé fún un ní ilé ayé yii. Ẹlòmíràn yóò máa gba àwọn ohun tí o nifẹ sí pẹ̀lú ìwà ayọpọra àti ìdùnnú kọja aala, àti ìgbéraga àti ìtayọ ẹnu ààlà ti Ìwà rẹ̀ a wá wọ, yóò sì máa gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹranko ṣe n gbà á pẹ̀lú ojúkòkòrò àti ìwàrà-wàrà, àti ọ̀kanjúà pẹ̀lú èyí, ọkàn rẹ̀ kò ní balẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ọkan rẹ yóò Pin yẹlẹ yẹlẹ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nàn: ọkàn rẹ̀ yóò túká nípa ti ìbẹ̀rù kí àwọn nkán tí o ní sí má se bọ lọwọ rẹ̀, àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdènà tí ó sábà máa n yọrí sí i, àti nípa ti pé àwọn ẹ̀mí kìí dúró níbi kan, bíkòṣe pé wọ́n á máa ní ìfẹ́ àfẹ́jù sí àwọn nǹkan mìíràn, èyí tí ó lè ṣẹlẹ̀ tí ó sì lè má ṣẹlẹ̀. Tí ó bá tilẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ ní gbígbà pé ó ti ṣẹlẹ̀, òun pẹ̀lú yóò máa dààmú nítorí àwọn ọ̀nà tí a mẹ́nu bà wọ̀nyí. Yóò sì máa gba àwọn nǹkan tiko fẹ pẹ̀lú àìbalẹ̀ ọkàn, ìkanra, ìbẹ̀rù àti ìsúnì. Má si ṣe bèèrè nípa ohun tó n ṣẹlẹ̀ sí i nínú ìpọ́njú ayé, àti nípa àwọn àìsàn ọpọlọ àti ti iṣan-ara, àti nípa ìbẹ̀rù èyí tó lè sọ ọ́ dé ipò tó burú jùlọ àti àwọn ohun ìyọlẹ́nu tó le jùlọ; nítorí pé kò retí ẹ̀san kan, kò sì ní sùúrù tí yóò tù ú nínú, tí yóò sì mú nǹkan rọrùn fún un.
Gbogbo èleyí ni atiri rí pẹ̀lú ìrírí, tí a bá mú àpẹrẹ kan nínú irú èyí, tí a ṣe àṣàrò lé lórí, tí a sì fi wé ìṣesí àwọn ènìyàn, a óò rí ìyàtọ̀ ńlá láàrin olugbagbọ òdodo tí ó n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ohun tí ìgbàgbọ́ rẹ pè è sí, àti ẹni tí kò rí bẹ́ẹ̀. Èyí náà ni pé ẹsin maa n sení ni ojúkòkòrò tó lágbára síi ítẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìpèsè àti ini itẹlọrun sí ọlá Ọlọhun àti oniruru apọnle rẹ .
Nígbàtí wan bá fi àdánwò bíi àìsàn tàbí òṣì dán an olugbagbọ òdodo wò, tàbí irú rẹ̀ nínú àwọn ipò tí gbogbo ènìyàn o lè máa bára rẹ, dájúdájú - pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn àti yíyọnu sí ohun tí Ọlọ́hun pín fún un - ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, kì í fi ọkàn rẹ̀ wá ọ̀ràn kan tí a kò kádàrá fún un, ó máa ń wo ẹni tí ó wà nísàlẹ̀ rẹ̀, kì í sì í wo ẹni tí ó wà lókè rẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ìdùnnú rẹ̀, ayọ̀ rẹ̀ àti ìsinmi rẹ̀ yóò pọ̀ ju ti ẹni tí ó ní gbogbo àwọn ohun amáyédẹrùn, bí a kò bá fún un ní ìtẹ́lọ́rùn.
Gẹ́gẹ́ bi wa se rí ẹni tí kò se isẹ tí ìgbàgbọ bere fún tí wan bá fi àdánwò òṣì kan tàbí tí ó bá pàdánù díẹ̀ nínú àwọn ohun amúlò ti ilé-ayé, ọ ọ rí i nínú ìbànújẹ́ àti ìpọ́njú pátápátá.
Apẹẹrẹ miran ni pe: Ti awọn okunfa ibẹru ba ṣẹlẹ, ti awọn nnkan adanilamu ba si de ba ọmọniyan, o maa ri ẹni tí igbagbọ rẹ lalaafia ti ọkàn rẹ duro ṣinṣin, ti ẹmi rẹ balẹ, ti o ni agbara lori idari ati iṣakoso alamọri ti o ba a lojiji yii pẹlu ohun ti o wa ni ikapa rẹ ninu ironu, ọrọ, ati iṣe, ti o ti mura ẹmi rẹ silẹ fun nnkan adanilamu ti o de ba a yii. Ati pe iru awọn ipo wọnyi maa n fun ọmọniyan ni isinmi, ti o si maa n mu ọkàn rẹ duro ṣinṣin.
Gẹgẹ bẹẹ naa ni ọ ṣe maa rí aláìní ìgbàgbọ́ ní ìdàkejì ipò yii: tí awọn ìbẹ̀rù bá dé, ọkàn rẹ̀ yóò dàrú, iṣan ara rẹ̀ yóò sì fà lọ, àwọn èrò rẹ̀ yóò sì túká, ìbẹ̀rù àti ìpayà á sì wọ̀ ọ́, ìbẹ̀rù òde á sì pa pọ̀ mọ́ àníyàn inú, èyí tí a kò le sọ bí ìjìǹlẹ̀ rẹ̀ ṣe tó. Irúfẹ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tí wọn kò bá ní àwọn okunfa àdánidá kan tí ó nílò ìdánrawò púpọ̀, agbára wọn yóò wó palẹ̀, iṣan ara wọn yóò sì fà lọ. Ìyẹn sì jẹ́ nítorí àìní ìgbàgbọ́, èyí tí ó máa ń gbé ni ró lórí sùúrù, pàápàá jùlọ ní àwọn ipò tó le koko, àti àwọn ipò ìbànújẹ́ àti ìdààmú.
Oniwa-rere ati ẹlẹṣẹ ( pooki ) , Olugbagbọ ati alaigbagbọ ni wọn jọ pin ninu riri igboyà àsisẹ rí gbà, ati ninu adamọ ti o maa n mu awọn ibẹru rọ ti o si n sọ wọ́n di irọrun, ṣugbọn Olugbagbọ fi yàtọ̀ pẹlu agbara igbagbọ rẹ ati suuru rẹ ati gbigbarale Ọlọhun ati fifẹkẹle E, ati ìrètí ẹ̀san Rẹ̀ - awọn ọran ti o n ṣe afikun si igboyà rẹ, ti o si n mu ìpọ́njú ibẹru fúyẹ́ fun un, ti o si n sọ awọn iṣoro di irọrun fun un, gẹgẹ bi Ọlọhun Alagaa julọ ṣe sọ pe:
﴿...إِن تَكُونُواْ تَأۡلَمُونَ فَإِنَّهُمۡ يَأۡلَمُونَ كَمَا تَأۡلَمُونَۖ وَتَرۡجُونَ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا يَرۡجُونَ...﴾
(Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora rẹ̀. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu.) An-Nisaa 104 Ti ìrànlọ́wọ́ Ọlọhun àti ìsẹlẹru iranlọwọ Rẹ̀ tí yanon ọtọ yóò ṣẹlẹ sí wàn àti àtìlẹ́yìn Rẹ̀, ohun tí ó máa ń fọ́n àwọn ìbẹ̀rù ká. Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga si sọ pe:
﴿...وَٱصۡبِرُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلصَّٰبِرِينَ﴾
« Ẹ ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù. [Al-Anfaal: 46].
Ṣiṣe dáadáa si ẹda pẹlu ọrọ ati iṣẹ Lara awọn okunfa ti o n mu ibanujẹ, ìrora ọkàn ati àníyàn kuro, ni ṣíṣe daadaa sí àwọn èèyàn pẹlu ọ̀rọ̀ ati iṣẹ́, àti oríṣiríṣi iṣẹ́ oore. Gbogbo rẹ̀ pátá jẹ́ oore àti ṣíṣe daadaa, Ọlọ́hun a sì má fi èyí ti àwọn ìbànújẹ́ àti ìrora ọkàn kúrò fún ẹni rere àti òṣìkà gẹ́gẹ́ bíi rẹ̀, ṣùgbọ́n mu'mini ni ó ni ipin àti ogún tó pé jùlọ nínú rẹ̀. Ó sì yàtọ̀ sí elòmíràn pẹ̀lú pé ṣíṣe daadaa rẹ̀ jáde wá látara ìṣemímọ́ àti gbígbérò ẹsan Rẹ̀.
Ọlọhun yóò sọ ṣíṣe oore di irọrun fún un nítorí oore tí ó ń retí, Yóò sì ti aburu danu fún un pẹ̀lú ìfọkànsìn àti ríretí ẹ̀san Rẹ̀, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴿لَّا خَيۡرَ فِي كَثِيرٖ مِّن نَّجۡوَىٰهُمۡ إِلَّا مَنۡ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوۡ مَعۡرُوفٍ أَوۡ إِصۡلَٰحِۭ بَيۡنَ ٱلنَّاسِۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِ فَسَوۡفَ نُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا 114﴾
«Kò sí oore kan nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa ọrẹ tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá» . Sūratun Nisā’: 114.
Ọlọhun tí ọlá Rẹ ga ti fi to wa leti pe gbogbo awọn iṣẹ wọnyi oore ni lati ọdọ ẹni ti o ṣe é, oore si n fa oore, o si n ti aburu sẹyin, ati pe dajudaju olugbagbọ ti n wa ẹsan lọdọ Rẹ, Ọlọhun yoo fun un ni ẹsan nla. Lara ẹsan nla naa ni: pípa àníyàn, ìbànújẹ́, àti àwọn ìpọ́njú ati irú wọn bẹbẹ lọ.
Ọlá àti pataki ṣíṣe airoju pẹlu iṣẹ kan nínú awan iṣẹ tàbí imọn kàn nínú awàn imọn tí o wúlò.
Nínú àwọn okùnfà tí a fi n gbé ìdààmú kúrò, èyí tí o n jẹyọ látipasẹ̀ ìdààmú ara, àti níbi ṣíṣe airoju ọkàn sí àwọn ohun tí odaru ni kíkọjúmọ́ iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tàbí ìmọ̀ kan nínú àwọn ìmọ̀ ; nítorí pé wọ́n n pa ọkàn lára dà kúrò níbi kíkọjúmọ́ sí ọ̀rọ̀ tí n dá a láàmú. Bóyá ó sì lè gbàgbé àwọn okunfa tí ó se ìbànújẹ́ ọkàn fún un ni dandan, ẹmí rẹ̀ sì dunnu, okun rẹ̀ sì pọ̀ síi. Okunfa yii pẹ̀lú sì jẹ́ àjọní láàrin olùgbàgbọ́ àti ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n Mu’mini ( olugbagbọ òdodo) yàtọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀, ìṣotitọ rẹ̀, àti bí ó ṣe n retí ẹ̀san lọ́dọ̀ Ọlọ́hun nígbà tó bá n ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ìmọ̀ tí ó n kọ́ tàbí tí ó n kọ́ni, àti pẹ̀lú iṣẹ́ rere tí ó n ṣe. Tí iṣẹ́ náà bá jẹ́ ìjọsìn, ìjọsìn ni; tí ó bá sì jẹ́ iṣẹ́ ayé tàbí àṣà tí èròǹgbà rere bá tẹ̀lé é, pẹ̀lú èròǹgbà láti fi wá ìkúnlọ́wọ́ lórí títẹle Ọlọ́hun. Nítorí èyí, ó ní ipa tó múnádóko láti le ìbànújẹ́, ìdààmú àti ìbìnújẹ́ ọkàn lọ. Ènìyàn mélòó mélòó ni a ti dánwò pẹ̀lú àníyàn àti ìbànújẹ́ gbére, tí èyí sì fa oríṣiríṣi àìsàn fún un, tí ó fi jẹ́ pé òògùn rẹ̀ tó múnádóko wá di (gbígbàgbé okùnfà ohun tó bí i nínú tí ó sì kó àníyàn bá a, àti fífi ara jìn sí ṣíṣe iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ pàtàkì rẹ̀).
Ó sì yẹ kí iṣẹ́ tí ènìyàn n ṣe jẹ́ èyí tí ọkàn ènìyàn n fà sí, tí ó sì n ṣàfẹ́rí rẹ̀, nítorí pé èyí ló súnmọ́ jù sí rírí nǹkan tí a gbà lérò oní-ànfàní yìí gbà, Ọlọhun l'Ọ mọ jùlọ.
Kiko ọkan àti irori jọ papọ lórí ifemi sí iṣẹ́ ọjọ́ òní, Àti nínú ohun tí a fi ń lé àníyàn àti ìbànújẹ́ ni pípa gbogbo èrò pọ̀ sórí ṣíṣe àníjú iṣẹ́ ọjọ́ ìsinsìnyí, àti gbígbé ọkàn kúrò lórí ṣíṣe àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, àti kúrò nínú ìbànújẹ́ lórí ohun tó ti kọjá. Fún ìdí èyí ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe wá ààbò kúrò níbi ìbànújẹ ọkan . Nítorí pé ìbànújẹ́ kò ṣe ànfàní lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọjá èyí tí kò ṣeé dá padà tàbí kí á ṣe àtúnṣe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni àníyàn tí ó ń ṣẹlẹ̀ látàrí ìbẹ̀rù ọjọ́ iwájú lè ṣe ìpalára. Nítorí náà, ó yẹ kí ẹrúsìn jẹ́ ọmọ ọjọ́ rẹ̀, kí ó kó ìtara àti ìsapá rẹ̀ jọ sí ṣíṣe àtúnṣe ọjọ́ rẹ̀ àti àsìkò ìsinsìnyí rẹ̀. Nítorí pé pípa ọkàn pọ̀ sórí ìyẹn yóò jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ ó pé, ẹrúsìn yóò sì fi èyí tu ara rẹ̀ nínú kúrò níbi àníyàn àti ìbànújẹ́. Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - tí ó bá ṣe adúà kan tàbí ó tọ́ àwọn ìjọ rẹ̀ sí adúà kan, dájú dájú ó máa n rọ̀ wọ́n sí itẹramọ́ṣẹ àti ṣíṣe àkìtìyàn nínú mímú ohun tí ó n gbàdúrà fún wá sí ìmúṣẹ, pẹ̀lú wíwá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́hun àti níní ìrètí nínú oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Ati fífi ohun tí ó ń gbàdúrà pé kí a tì dànù sílẹ̀; nítorí pé adua rọ̀ mọ́ iṣẹ́ ṣíṣe, ẹrú a máa ṣe àìpọ́n nínú ohun tí ó máa ṣe é ní anfaani nínú ẹ̀sìn àti ayé, ó sì ń tọrọ àṣeyọrí ète rẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀, ó sì ń wá ìrànwọ́ Rẹ̀ lórí ìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe sọ pé:
(احْرِصْ عَلَى مَا يَنْفَعُكَ وَاسْتَعِنْ بِاللَّهِ وَلَا تَعْجِزْ، وَإِذَا أَصَابَكَ شَيْءٌ فَلَا تَقُلْ: لَوْ أَنِّي فَعَلْتُ كَذَا كَانَ كَذَا وَكَذَا، وَلَكِنْ قُلْ: قَدَرُ اللَّهِ وَمَا شَاءَ فَعَلَ، فَإِنَّ لَوْ تَفْتَحُ عَمَلَ الشَّيْطَانِ).
Ṣe ojukokoro lori ohun ti yio wulo fun ọ, wá iranlọwọ Ọlọhun, má se kagara, tí nkankan bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, má ṣe sọ pé: tó bá jẹ́ pé mo ṣe báyìí ni, ìbá rí báyìí báyìí, ṣùgbọ́n sọ pé: Kádàrá Ọlọ́hun ni, ohun tí Ó fẹ́ ni Ó ṣe, torí pé gbólóhùn “kàní” (lao) a máa ń ṣí iṣẹ́ Èṣù sílẹ̀. Muslim ni o gba a wa. Nítorí náà, Anabi -kí ìkẹ àti ọlá Ọlọ́hun máa bá a- ṣe àpapọ̀ láàrin àṣẹ fún ṣíṣe ojúkòkòrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ anfaani ní gbogbo ipò, àti wíwá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́hun àti àìtẹríba fún agara tí í ṣe ọ̀lẹ onípàlàrà, àti láàrin ìtẹríba fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti kọjá lọ tí ó sì ti wáyé, àti rírí ìdájọ́ Ọlọ́hun àti kádàrá Rẹ̀.
O si ṣe awọn ọ̀ràn di ipin méjì: apá kan tí ẹrú le sáápá láti jèrè rẹ̀, tàbí kí ó jèrè èyí tí agbára rẹ̀ bá ká nínú rẹ̀, tàbí kí ó yẹrí rẹ̀ tàbí kí ó mú un fúyẹ́; nínu irú èyí ni ẹrú yóò ti lo ìsapá rẹ̀, yóò sì tọrọ ìrànwọ́ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àti apá kan tí ìyẹn kò ṣeéṣe nínú rẹ̀, ní ti èyí, ẹrú a máa ní ìfọkànbàlẹ̀ sí i, a máa yọ́nú sí i, a sì máa tẹríba, kò sì sí iyèméjì pé rírọ̀ mọ́ ìpìlẹ̀ yìí jẹ́ okunfa fún ìdùnnú àti ìkúrò isoro okan àti bànújẹ́.
ỌLA ÀTI PÀTÀKÌ ṢÍṢE IRANTI ỌLỌHUN NÍ PÚPỌ̀
Ninu awọn okunfa nlanla fun idunnu inu ati ifọkanbalẹ: ni ṣiṣe ìrántí Ọlọhun lọpọlọpọ, dajudaju eyi ni ipa iyanu ninu idunnu inu ati ifọkanbalẹ, ati imukuro aniyan ati ibanujẹ, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pe:
﴿...أَلَا بِذِكۡرِ ٱللَّهِ تَطۡمَئِنُّ ٱلۡقُلُوبُ﴾
«Ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀». [Ar-Ra'd:28] Irántí Ọlọhun ní ipa ńlá nínú mímú àfojúsùn ti a nwa yíì waye, nítorí àdámọ́ pàtàkì rẹ̀, àti nítorí ohun tí ẹrú ń retí níbi èrè àti ẹsan rẹ̀.
Sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdẹ̀ra Ọlọhun tí ó hàn àti èyí tí ó pamọ́, Bẹẹgẹẹ ni sísọ nípa àwọn idẹra Ọlọhun tí ó hàn síta àti èyí tí ó pamọ́, nítorí pé mímọ̀ wọ́n àti sísọ nípa wọn ni Ọlọhun fi n mú idamu ọkan àti ìbànújẹ́ kúrò, tí ó sì n se ẹrú ní ojú kòkòrò síbi idupẹ, èyí tí í ṣe ipò gíga jùlọ, kódà bí ẹrú náà bá wà nínú ipò òṣì tàbí àìsàn tàbí àwọn mìíràn nínú oríṣiríṣi àwọn àdánwò. Nítorí pé tí ó bá fi àwọn idẹra Ọlọhun lórí rẹ̀ - èyí tí a kò le ka iye tàbí sírò rẹ̀ - wéra pẹ̀lú ohun burúkú tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ohun burúkú náà kò ní ìfiwéra rárá pẹ̀lú àwọn idẹra náà.
Kàkà bẹ́ẹ̀, nnkan tí a kòfẹ àti àwọn musiiba ( iṣẹlẹ laabi) , tí Ọlọhun bá fi dán ẹrú wò pẹ̀lú rẹ̀, tí ó sì ṣe sūru àti yiyọnu àti ìgbafa fún Ọlọhun níbẹ̀, ìrora rẹ̀ yóò fúyẹ́, inira rẹ̀ yóò sì dínkù, ìrètí ẹrú fún ẹsan rẹ̀ àti jíjọ́sìn fún Ọlọhun pẹ̀lú ṣíṣe sūru àti yiyọnu, ni yóò sọ àwọn nnkan korò di adùn, tí adùn ẹsan rẹ̀ yóò jẹ́ kó gbàgbé ìkorò sūru ṣíṣe sí i.
Wíwò àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ wa, tí wan koto wa Ati pe ninu awọn nnkan ti o ṣe anfaani julọ ni àkòrí yii tàbí ni ààyè yí ni lilo ohun ti Anọbi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- tọka si ninu Hadiisi to ni alaafia, nibiti o sọ pe:
(انْظُرُوا إِلَى مَنْ هُوَ أَسْفَلُ مِنْكُمْ وَلَا تَنْظُرُوا إِلَى مَنْ هُوَ فَوْقَكُمْ فَإِنَّهُ أَجْدَرُ أَنْ لَا تَزْدَرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ).
« Ẹ máa wo ẹni tí o wa lẹyìn yín tí o kéré sí yin , ẹ má se máa wo ẹni tí o wa l'oke yín tí o jù yín lọ, òunh ni o daaju tí kòní jẹ kí ẹ máà fí ojú kékeré wo idẹra tí Ọlọhun ṣe fún yín » Muslim ni o gba a wa. Dájúdájú tí ẹrú bá gbé àkíyèsí títóbi yìí síwájú ojú rẹ̀, yóò ríi pé òun pọ̀jù ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ẹ̀dá lọ ní ti àláfíà àti àwọn ohun tó tẹ̀lé e, àti nínú arisiki àti àwọn ohun tó tẹ̀lé e, bí ipò rẹ̀ ṣe lè rí tó, nígbà náà ni àníyàn rẹ̀, ìdààmú rẹ̀ àti ìbànújẹ́ rẹ̀ yóò kúrò, ayọ̀ àti ìdùnnú rẹ̀ yóò sì pọ̀ síi pẹ̀lú àwọn ìdẹ̀ra Ọlọ́hun èyí tí ó fi tayọ ẹlòmíràn nínú àwọn tí wọ́n kéré síi nípa rẹ̀.
Gbogbo ìgbà tí ìrònú àti ìwòyè ẹrú ( ẹda ) bá ti pọ̀ sí i lórí àwọn ìdẹra Ọlọ́hun èyí tó hàn síta àti èyí tó fara sin, ti ẹ̀sìn àti ti ayé, náà ni yóò rí i pé Olúwa rẹ̀ ti fún un ní oore, tí Ó sì ti lé àwọn aburú púpọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájú-dájú èyí yóò lé àwọn ẹdun ọkan àti ìbànújẹ́ kúrò, yóò sì fa ayọ̀ àti ìdùnnú wá.
Abala ọrọ nípa: Igbiyanju fún mímu àwọn okùnfà ìbànújẹ́ àti ìfòòro kúrò, àti ṣíṣe àwárí àwọn okùnfà ìdùnnú.
Ninu awọn okunfa ti o n fa idunnu ati imukuro ifooro ati ibanujẹ ni ṣiṣe akitiyan lati mu awọn okunfa ti o n fa ifooro kuro, ati ṣiṣe agbatẹru awọn okunfa ti o n fa idunnu; iyẹn si jẹ nipa gbigbagbe awọn ohun ti a kòfẹ ti kọja eyiti ko le da pada mọ, ati mimọ pe fifi ero si i jẹ iru isọkusọ ati ohun ti ko le ṣẹlẹ, ati pe dajudaju iyẹn jẹ iwa aṣiwere ati isinwin. Nitori naa, yio ba ọkan rẹ jagun lati ma ronu nipa rẹ mọ. Bẹẹ gẹgẹ ni yio ṣe ba ọkan rẹ jagun nipa aniyan rẹ fun ọjọ iwaju, ninu awọn ohun ti o n ro lasan bii osi tabi iberu tabi awọn ohun ikorira miiran ti o n wo ni oju inu rẹ nipa ọjọ iwaju igbesi aye rẹ. Yóò sì mọ̀ pé dájúdájú àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ iwájú jẹ́ àìmọ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ti oore àti aburú, àti àwọn ìrètí àti ìrora, àti pé dájúdájú ó wà lọ́wọ́ Ọlọhun Ọba Alágbára, Ọlọ́gbọ́n, kò sí ohunkóhun nínú rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú àyàfi sísá ipá nínu rírí oore rẹ̀ gbà, àti dídènà ìpalára rẹ̀. Ẹrú yóò sì mọ̀ pé dájúdájú tí ó bá gbé èrò-inú rẹ̀ kúrò lórí àníyàn rẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú àlámọ̀rí rẹ̀, tí ó sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa rẹ̀ fún àtúnṣe rẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ Sí I lórí ìyẹn, tí ó bá ṣe èyí, ọkàn rẹ̀ yóò balẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé rẹ̀ yóò sì dára, ìbànújẹ́ àti ẹdun ọkan rẹ̀ yóò sì kúrò lórí rẹ̀.
Lilo adura ṣíṣe , Lára ohun tó lánfàní jùlọ nípa wíwo ọjọ́ iwájú ni lílo ádùrá yíì, èyí tí Ànábì -kí ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ọlá Rẹ̀ máa bá a- máa ń ṣe:
(اللَّهُمَّ أَصْلِحْ لِي دِينِيَ الَّذِي هُوَ عِصْمَةُ أَمْرِي وَأَصْلِحْ لِي دُنْيَايَ الَّتِي فِيهَا مَعَاشِي، وَأَصْلِحْ لِي آخِرَتِيَ الَّتِي إِلَيْهَا مَعَادِي، وَاجْعَلِ الْحَيَاةَ زِيَادَةً لِي فِي كُلِّ خَيْرٍ، وَالْمَوْتَ رَاحَةً لِي مِنْ كُلِّ شَرٍّ).
«Olohun, ba mi tun ẹsin mi ṣe, èyí tí ó jẹ́ ìdábo bo fún àlámọrí mi, àti ba mi tun ayé mi ṣe, èyí tí iṣẹmi mi wà nínú rẹ̀, àti ba mi tun ọrun mi ṣe, èyí tí ó jẹ́ ibùpadàsí mi, kí O sì ṣe ìgbésí ayé ní àlékún fún mi nínú gbogbo òòrè, àti ikú ní ìsinmi fún mi kúrò nínú gbogbo aburú» Muslim ni o gba a wa. Bákan náà ni ọrọ Ọlọhun ti o sọ pe:
(اللَّهُمَّ رَحْمَتَكَ أَرْجُو فَلَا تَكِلْنِي إِلَى نَفْسِي طَرْفَةَ عَيْنٍ وَأَصْلِحْ لِي شَأْنِي كُلَّهُ، لَا إِلَهَ إِلَّا أَنتَ).
« Olohun, ikẹ Rẹ ni mo nse agbẹkẹle rẹ, ma se da mi da araa mi laarin kadiju ki a la a, ba mi tun gbogbo alamori mi se, ko si eniti ijosin to si ayafi Iwọ. Abū Dāud ni o gba a wa pẹlu Isnaad ti o pé. Nígbàtí ẹru bá se adua , èyí tí àtúnṣe ọjọ iwájú rẹ̀ ti jẹ ti ẹsin àti ti ayé wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn tí o wà nílẹ̀ , nitosi , àti pẹlu èrò-inú òdodo, pẹ̀lú ìsapá rẹ̀ lórí ohun tí yóò mú èyí ṣẹ, Allahu yóò mú ṣẹ fún un ohun tí o fi gbàdúrà sí, tí o nírètí, tí o sì ṣiṣẹ́ fún, ẹdun ọkan rẹ̀ yóò sì yípadà sí ayọ̀ àti inú dídùn.
Abala Ọrọ kan : Ṣíṣe afoju da èyí tó burú jùlọ nínú àwọn ohun tó ṣeé ṣe.
Lára àwọn okunfa tí ó ṣe ànfààní jùlọ fún kíkúrò ẹdun ọkan àti ìbànújẹ, nígbàtí nnkan kan nínú àwọn musiibab( iṣẹlẹ laabi) bá ṣẹlẹ sí ẹrú, ni pé kí ó sapá láti mú un fúyẹ́ nípa gbígbà á sí ọkàn pé ibi tí ó burú jùlọ tí ọ̀rọ̀ náà le pada já sí, kí ó sì fi ọkàn balẹ̀ lórí ìyẹn. Tí ó bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, kí ó wá sapá láti mú ohun tí ó ṣe é mú fúyẹ́ kẹ́rẹ́ ní ìwọ̀n agbára rẹ̀. Nítorí pẹ̀lú fífi ọkàn balẹ̀ yìí àti ìsapá eléèré yìí, ni àwọn ìbànújẹ àti àníyàn rẹ̀ yóò fi kúrò, ìsapá yẹn yóò sì jẹ́ ní mímú àwọn ànfààní wá, àti ní títì àwọn ìpalára tí a ṣe ní ìrọ̀rùn fún ẹrú danu.
Nigba ti awọn okunfa ibẹru, ati awọn okunfa aisan, ati awọn okunfa osi ati aini fun awọn nnkan ti o n fẹ ninu awọn ohun ifẹ oniruuru ba de ba a, nígbà náà kí ó fi ifayabalẹ gbaa mọra , kí o sì fi ọkan balẹ lórí rẹ, àní lórí èyí tí o le jùlọ nínú rẹ, nítorí pé dájúdájú, fifi ọkàn balẹ̀ lórí gbígba àwọn ohun àìdára, máa n sọ ọ́ di ìrọ̀rùn, ó sì máa n mu líle rẹ̀ kúrò, pàápàá jùlọ tí ó bá fi ọkàn rẹ̀ sí i láti máa tako ó gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, nígbà náà ni fifi ọkàn balẹ̀ yóò wá papọ̀ fún un pẹ̀lú ìsapá eléré, èyí tí yóò gbà á lọ́kàn kúrò níbi fífi àròkàn sí àwọn mùsìbà ( iṣẹlẹ laabi ) , tí yóò sì máa bá ẹmí rẹ̀ jà lórí síso agbára àtakò sí àwọn ohun àìdára di ọ̀tun, pẹ̀lú gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́hun nínú ìyẹn àti níní èrò rere sí I. Kò sí iyèméjì pé dájúdájú àwọn nǹkan wọ̀nyí ní àǹfààní ńlá nínú rírí ìdùnnú àti ìtújúká ọkàn, pẹ̀lú ohun tí ẹrú ń retí nínú ẹ̀san ti ayé àti ti ọ̀la, Èyí jẹ́ ohun tí a rí, tí a sì dánwò, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti dán an wò.
Ìpín kan: Agbára ọkàn, àti àìrúbìi àti àìmì rẹ̀.
Ati pe ninu awọn ìwòsàn to tóbi jùlọ fun awọn àìsàn ọkàn ti o jẹmọ ìdààmú èrò-inú, koda bakan naa fun awọn àìsàn ti ara ni: agbara ọkàn, ati àìní ìdààmú àti ìrunú rẹ si àwọn àròbòsùn àti àwọn àròdá tí àwọn èrò burúkú àti irori burúkú n gbé wá. Ibinu àti ìdààmú, àti ṣíṣe àròbájẹ́pé ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ohun àìdùnnú àti pípadanù àwọn ohun ìfẹ́ni, jẹ́ nínú àwọn òkùnfà adanilóró tí ó máa ń sọ ènìyàn sínú àwọn ẹdun ọkan àti ìbànújẹ́, àti àwọn àìsàn ọkàn àti ti ara, àti rírù ọpọlọ èyí tí ó ní àwọn ipa búburú rẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti rí ìnira rẹ tí o pọ púpọ.
Ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun, Igba ti ọkan ba gbára lé Ọlọhun, ti o si gbẹkẹle E, ti ko si juwọ́ silẹ fun awọn èrò-asán tabi ki awọn iro-inu búburú gba a mọ́ra, ti o si ni igbẹkẹle ninu Ọlọhun ti o si ṣe ojúkòkòrò oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀, awọn ìbànújẹ́ ati ìbìnínú yoo ti i danu kuro lọdọ rẹ pẹlu iyẹn, ọpọlọpọ ninu awọn aisan ara ati ti ọkan yoo si parẹ kuro fun un, ọkan yoo si ni ninu agbara, itẹlọrun, ati inu-didun ohun ti a ko le fi ẹnu sọ. Melo ni ile-iwosan ti kun fun awọn alaisan èrò-asán ati awọn iro-inu ti o bajẹ, melo ni awọn ọrọ wọnyi ti ni ipa lori ọkan ọpọlọpọ ninu awọn alagbara, ki a to wa sọ ti awọn ọ̀lẹ, melo ni o si ti fa a de dídì were ati asínwín. Aláàláfíà ni ẹni ti Ọlọhun ba fun ni alaafia ti O si ba a ṣe lati gbogun ti ẹ̀mí rẹ lati ri awọn okunfa anfaani ti o n fun ọkan ni agbara gbà, ti o n ti ìdààmú rẹ danu, Ọlọhun- Eleduaa sọ pe:
﴿...وَمَن يَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِ فَهُوَ حَسۡبُهُۥٓۚ...﴾
Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o. [At-Tolāq: 3] Ìtumọ nipe Ó máa n to fun un nínú gbogbo ọ̀rọ̀ ẹsin rẹ̀ àti ayé rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ lógún.
Nitori naa, olùgbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun ni ẹni ti o ni agbara ọkan; àwọn àròkéhìndà ko ki n ni ipa lori rẹ, bẹẹni àwọn iṣẹlẹ ko ki n ko airoju ba a, nitori imọ rẹ pe dájúdájú iyẹn jẹ ara ailagbara ẹmi, ati ara ìbòjo ati ìbẹru ti ko ni òdodo kan. O si tun mọ pẹlu iyẹn pe dájúdájú Ọlọhun ti ṣe onigbọwọ itọ́ pipe fun ẹni ti o gbẹkẹle E, nitori naa yio gbẹkẹle Ọlọhun, ọkan rẹ yio si balẹ si adehun Rẹ. Bayii ni ànìyàn rẹ ati àìbalè ọkàn rẹ yio ṣe kuro, ti inira rẹ yio yípadà si irọrun, ti ìbànújé rẹ yio di ayọ̀ (at-tarḥ: ìbànújé), ti ìbẹru rẹ yio si di ifọkanbalẹ. Nitori naa, a n beere lọwọ Rẹ -ti ọla Rẹ ga- fun àlàáfíà, ati pe ki O ṣe ojurere fun wa pẹlu agbara ọkan ati ifẹsẹmulẹ rẹ, ati pẹlu Ìgbẹ́kẹ̀lé pipe, eyi ti Ọlọhun ṣe onigbọwọ fun awọn eniyan rẹ pẹlu gbogbo oore, ati yiyẹri gbogbo ohun ìríra ati ipalara (aḍ-ḍoir: ìpalára).
Abala Ọrọ kan: mímú ẹmi dúró ṣinṣin láti máa faradà laifi àti ààyẹ àwọn ẹlòmíràn.
Ati ninu ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - to sọ pe:
(لَا يَفْرَكْ مُؤْمِنٌ مُؤْمِنَةً إِنْ كَرِهَ مِنْهَا خُلُقًا رَضِيَ مِنْهَا خُلُقًا آخَرَ).
«Olugbagbọ l'ọkunrin o gbọ dọ maa korira olugbagbọ lóbìnrin, ti o ba korira tàbí tiko fẹ iwa kan lara rẹ, yio yọnu si iwa omiran lara rẹ» Muslim ni o gba a wa.
Anfaani meji ti wọn tobi:
Èkinní nínú àwọn méjèèjì: Itọsọna sí ibalopọ pẹlu iyawo, àti ẹbí, àti ọ̀rẹ́, àti ẹni tí ẹnjọ n ṣe ìbálòpọ̀, àti gbogbo ẹni tí ìbáṣepọ̀ àti ìsopọ̀ wà láàrin ìwọ pẹ̀lú rẹ̀; àti pé ó yẹ kí o mú ọkàn rẹ balẹ̀ lórí wípé dandan ni pé kí àbàwọ́n tàbí àìpé tàbí nǹkan tí o kóríìra wà lára rẹ̀. Nígbàtí o bá rí ìyẹn, wá fi wé ohun tí ó jẹ́ dandan lórí rẹ tàbí tí ó yẹ fún ọ nípa mímú ìsopọ̀ dúró ṣinṣin àti pípa ìfẹ́ mọ́, nípa rírántí àwọn ìwà rere rẹ̀, àti àwọn èròǹgbà pàtàkì àti ti gbogbogbòò. Pẹ̀lú ṣíṣe àmojúkúrò lórí àwọn àìdá àti fífi ojú sí àwọn ìwà rere, ni igbepọ àti ìsopọ̀ yóò fi wà pẹ́ títí, ìsinmi yóò sì pé, ìwọ yóò sì rí i gbà.
Èrè Keji: Oun ni yíyẹra ifooro àti ifòyà, àti wíwà ìfàyàbàlẹ̀ ọkàn, àti dídúró ṣinṣin lórí ṣíṣe àwọn ẹ́tọ́ tí ó jẹ́ dandan àti èyí tí ó wuni, àti wíwáyé ìsinmi láàrin àwọn méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ ipa èyí tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- mẹ́nukàn yíì -ṣùgbọ́n tí ó yí ọ̀rọ̀ náà padà tí ó wá ń wo àwọn àbùkù, tí ojú rẹ̀ sì fọ́ sí àwọn ohun rere-, dajudaju ó gbọdọ̀ ní ifòyà, dajudaju ifẹ́ tí ó wà láàrin òun àti ẹni tí ó bá ṣe pọ̀ gbọdọ̀ dojúrú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ́tọ́ tí ó jẹ́ ojúṣe lórí ọkọ̀ọ̀kan nínú wọn láti máa ṣọ́ yíò sì já.
Ọpọlọpọ ninu awọn eeyan oní ìpinnu gíga a máa jẹ́ kí ọkàn wọn ó balẹ̀ lórí sùúrù àti ìfọkànbàlẹ̀ nígbàtí àwọn àjálù àti àwọn ohun ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó bá kan àwọn ọ̀rọ̀ yẹpẹrẹ kéékèèké, wọ́n a máa káyasókè, ìfàyàbalẹ̀ wọn á sì dàrú. Ohun tí ó sì fa èyí ni pé, wọ́n ti palẹ̀ ọkàn wọn mọ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ ńláńlá, wọ́n sì pa àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké tì; èyí sì ṣe wọ́n ní ìpalára, ó sì nípa lórí ìsinmi wọn. Abiyè a máa palẹ̀ ọkàn rẹ̀ mọ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké àti ńláńlá, a sì máa bẹ Ọlọhun fún ìrànlọ́wọ́ lórí wọn, àti pé kí Ó má fi í sílẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀ fún ìṣẹ́jú àáyá kan. Nígbà náà, èyí kékeré yóò rọrùn fún un, gẹ́gẹ́ bí èyí ńlá ṣe rọrùn fún un. Yóó sì sẹku ni ẹni tí yóò fí emi balẹ tí ọ̀kàn rẹ yóò si balẹ̀.
Abala ọrọ kan : Àìsí títẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìbànújẹ́.
Ẹni ti o ni làákàyè mọ̀ pé ìgbésí ayé rẹ̀ tó tọ́ ni ìgbésí ayé idunnu àti ìfọkànbalẹ̀, àti pé ó kúrú púpọ̀, kò sì yẹ fún un láti sọ ọ́ di kúkúrú síi pẹ̀lú ẹdun ọkan àti títẹra mọ́ àwọn ìdààmú, nítorí pé èyí lòdì sí ìgbésí ayé tó tọ́. Yóò sì kedere sí ìgbésí ayé rẹ̀ kí púpọ̀ nínú rẹ̀ má baà lọ fún àwọn àti ìdààmú. Kò sì sí ìyàtọ̀ nínú èyí láàárín ẹni rere àti oníwà ìbàjẹ́, ṣùgbọ́n olùgbàgbọ́ ni ó ní ipín tó pọ̀ jùlọ nínú kí ó jẹ́ ẹni tí àpèjúwe yìí bá mu, àti ipín tó ṣe àǹfààní ní ayé àti ní ọ̀run.
Ifíwéra láàrin Awọn idẹra Ọlọhun àti ohun tí kò wuu tí ó ṣẹlẹ̀ sí, O sí yẹ pẹlu, tí nkán tí kò fẹ bá ṣẹlẹ̀ sí i tàbí tí ó n bẹ̀rù rẹ̀, ki ó ṣe àfiwé láàrin àwọn idẹra yòókù tí o ní tojẹ ti ẹsin tabi ti aye, ati laarin ibanujẹ ti o kọlu, nigbati o ba ṣe afiwe yii, yoo han si pe idẹra ti ohun wa ninu rẹ pọ gan, bẹẹni ibanujẹ ti o kọlu kere pupọ.
Bẹẹ naa ni yoo ṣe afiwé láàrin ohun ti o nbẹru nípa ṣíṣẹlẹ̀ aburú si i, àti ọpọlọpọ àwọn ọ̀nà àti rí àkóyọ kúrò nínú rẹ̀, kì yóò wá jẹ́ kí àfojúsùn tí kò fi bẹẹ lágbára borí ọpọlọpọ àwọn àfojúsùn tó lágbára. Pẹlu ìyẹn ni àníyàn àti ìbẹ̀rù rẹ̀ yoo fi kúrò, yóò sì tún wo ohun tó burú jùlọ nínú àwọn ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí i, yóò wá fi pese ara rẹ̀ kalẹ̀ fún ṣíṣẹlẹ̀ rẹ̀ bí ó bá ti ṣẹlẹ̀, yóò sì máa sa ipá láti dènà èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀, àti láti gbé èyí tó ti ṣẹlẹ̀ kúrò tàbí kí ó mú un fúyẹ́.
Ipalara awọn eniyan wa lori wọn, niwọn igba ti o ko ba fi se airoju, Lara awọn ọrọ to n ṣe anfaani ni ki o mọ pe dajudaju fifi suta ti awọn eeyan n fi kan ọ, pàápàá jùlọ ninu awọn ọrọ buruku, kò le ṣe ìnira fún ọ, ṣugbọn àwọn gan-an ni yoo ṣe ìnira fún. Ayafi ti o bá jẹ ki o kó ọ lọ́kàn, ti o si jẹ ki o gba idari ìmọ̀lára rẹ. Nígbà náà ni yoo ṣe ìnira fún ọ gẹgẹ bi o ṣe ṣe ìnira fún wọn. Ti o bá jẹ wipe o kò kà á sí, kò ní ṣe ìnira fún ọ rárá.
Fi àwọn èrò tí ó ṣe àǹfààní ṣe ọ̀ṣọ́ sí ìgbésí ayé rẹ, Lọ mọ pe ìgbésí ayé rẹ dálórí àwọn èrò inú rẹ, tí ó bá jẹ́ pé àwọn èrò rẹ jẹ́ lórí ohun tí yóò ṣe ọ́ ní ànfàní nínú ẹ̀sìn tàbí ayé, ìgbésí ayé rẹ yóò jẹ́ ìgbésí ayé rere, tó sì kún fún ayọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀ràn náà yóò di òdìkejì.
Ki ajọṣepọ jẹ fun Ọlọhun, kii ṣe fun ẹda, Ati pe lara awọn ọrọ to ṣe anfaani ju lati le ibanujẹ kuro ni pe ki o mu ọkan rẹ bale lori pe o ko gbọdọ wa ọpẹ lọdọ ẹnikẹni bikoṣe lati ọdọ Ọlọhun. Nitori naa, ti o ba ṣe daadaa si ẹni ti o ni ẹtọ lori rẹ tabi ẹni ti ko ni ẹtọ, ki o mọ daju pe ìbáṣe rẹ pẹlu Ọlọhun ni eleyii. Nitori naa, maṣe nani ọpẹ ẹni ti o ṣe idẹra fun, gẹgẹ bi Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ṣe sọ nipa awọn ayanfẹ ninu awọn ẹda Rẹ:
﴿إِنَّمَا نُطۡعِمُكُمۡ لِوَجۡهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمۡ جَزَآءٗ وَلَا شُكُورًا 9﴾
(Wọ́n sì ń sọ pé:) “Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ jẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín. [Al-Insaan:9]
Èyí si tún fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínu ìbálò pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ọmọ, àti nípa bí ìsopọ̀ rẹ ṣe lágbára tó pẹ̀lú wọn; nígbàkígbà tí o bá kọ́ ẹ̀mí rẹ lórí yíyẹra fún ṣíṣe ibi sí wọn, dájúdájú o ti fún wọn ní ìsinmi, ìwọ náà sì ti ní ìsinmi. Nínú àwọn ohun tí ó n fa ìsinmi ni gbígba àwọn ìwà ọlọ́lá mọ́ra, àti ṣíṣe iṣẹ́ lórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìpè ẹ̀mí, láìsí ìfipámúniṣe tí ó n kó ìdààmú bá ọ, tí o ó sì fi padà sẹ́yìn pẹ̀lú àìṣeyọrí níbi gbígba ìwà ọlọ́lá náà, nígbàtí o gba ọ̀nà wíwọ́. Èyí sì wà nínú ọgbọ́n, pé kí o máa yí àwọn ọ̀ràn tó rúgúdù sí àwọn ọ̀ràn tó mọ́ tó sì dùn; pẹ̀lú èyí ni isẹ́mọ́ àwọn adùn yóò fi máa pọ̀ si, tí àwọn rúdurùdu yóò sì pòórá.
Kiko airoju pẹlu ohun anfaani, àti gbigbe ohun ìpalára ju silẹ. Jẹ́ kí àwọn àlámọrí tó wúlò jẹ́ àfojúsùn rẹ, kí o sì máa ṣiṣẹ́ láti mú wọn ṣẹ, má sì ṣe yíjú sí àwọn ohun abinilára; kí o fi ìyẹn kọjú kúrò níbi àwọn okùnfà àníyàn àti ìbànújẹ́. Sì wá ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìsinmi àti ìkójọpọ̀ ọkàn lórí àwọn iṣẹ́ pàtàkì.
Yiyanjú awọn iṣẹ lẹsẹkẹsẹ, Ati ninu awọn àlámọrí ti o ṣanfani ni gbigbe awọn iṣẹ́ yanjú lẹsẹkẹsẹ, ati gbigba ará silẹ fun ọjọ iwaju; nitori pe ti a ko ba gbe awọn iṣẹ́ yanjú, àwọn iṣẹ́ iṣaaju ti o ku yoo ko jọ pọ̀ mọ́ ọ lórí, a ó sì fi àwọn iṣẹ́ ti n bọ̀ kún un, bẹẹ ni ẹrù rẹ̀ yoo ṣe pọ̀ si. Tí o bá gbe ohun gbogbo yanjú ni akoko rẹ, ìwọ yoo koju awọn àlámọrí ọjọ iwaju pẹlu agbára ìrònú ati agbára iṣẹ́ ṣíṣe.
Tito awọn ohun ti ọrọ kan jùlọ l'ẹsẹẹsẹ pẹlu ṣíṣe ìmọ̀ràn, O tọ kí o máa yan èyí tó ṣe pàtàkì jù sí èyí tó tún ṣe pàtàkì nínú àwọn iṣẹ́ tó wúlò, kí o sì ṣe ìyàtọ̀ láàrin ohun tí ọkàn rẹ fà sí tí o sì ní ìfẹ́-ọkàn sí gidigidi, nítorípé ìdàkejì rẹ̀ a máa fa sìsú ni àti àárẹ̀ àti ìbànújẹ́. Kí o sì wá ìrànlọ́wọ́ lórí ìyẹn pẹ̀lú ìrònú gidi àti gbígba ìbádọ́ràn, nítorí ẹni tí ó bá gba ìbádọ́ràn kìí kabámọ̀. Kí o ṣe àgbéyẹ̀wò fínnífínní lórí ohun tí o fẹ́ ṣe, tí o bá ti rí dájú pé ànfààní wà níbẹ̀ tí o sì ti pinnu, nígbà náà gbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun, dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbẹ́kẹ̀lé.
Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Kí Ọlọhun ṣe ikẹ àti ọlà fún asíwájú àti oga wa Muhammad, àti àwọn araale rẹ̀ àti àwọn saabe rẹ̀.
***
Index
Ọrọ itisiwaju 2
Apá ọrọ kan : Igbagbọ ati iṣẹ rere 3
Ọlá àti pataki ṣíṣe airoju pẹlu iṣẹ kan nínú awan iṣẹ tàbí imọn kàn nínú awàn imọn tí o wúlò. 9
ỌLA ÀTI PÀTÀKÌ ṢÍṢE IRANTI ỌLỌHUN NÍ PÚPỌ̀ 11
Abala ọrọ nípa: Igbiyanju fún mímu àwọn okùnfà ìbànújẹ́ àti ìfòòro kúrò, àti ṣíṣe àwárí àwọn okùnfà ìdùnnú. 13
Abala Ọrọ kan : Ṣíṣe afoju da èyí tó burú jùlọ nínú àwọn ohun tó ṣeé ṣe. 15
Ìpín kan: Agbára ọkàn, àti àìrúbìi àti àìmì rẹ̀. 16
Abala Ọrọ kan: mímú ẹmi dúró ṣinṣin láti máa faradà laifi àti ààyẹ àwọn ẹlòmíràn. 18
Abala ọrọ kan : Àìsí títẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn ìbànújẹ́. 20
***
yo21v2.1 - 10/03/2026